Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí
7 Lẹ́yìn èyí, mo rí áńgẹ́lì mẹ́rin tí wọ́n dúró lórí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, wọ́n di atẹ́gùn mẹ́rin ayé mú pinpin, kí atẹ́gùn kankan má bàa fẹ́ sórí ayé tàbí sórí òkun tàbí sórí igi èyíkéyìí. 2 Mo rí áńgẹ́lì míì tó ń gòkè láti ibi tí oòrùn ti ń yọ,* ó ní èdìdì Ọlọ́run alààyè; ó sì ké jáde sí àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tí a gbà láyè kí wọ́n pa ayé àti òkun lára, 3 ó sọ pé: “Ẹ má ṣe pa ayé tàbí òkun tàbí àwọn igi lára, títí a fi máa gbé èdìdì lé+ iwájú orí+ àwọn ẹrú Ọlọ́run wa.”
4 Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a gbé èdìdì lé, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì+ (144,000), a gbé èdìdì lé wọn látinú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì:+
5 Látinú ẹ̀yà Júdà, a gbé èdìdì lé ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);
látinú ẹ̀yà Rúbẹ́nì, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);
látinú ẹ̀yà Gádì, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);
6 látinú ẹ̀yà Áṣérì, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);
látinú ẹ̀yà Náfútálì, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);
látinú ẹ̀yà Mánásè,+ ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);
7 látinú ẹ̀yà Síméónì, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);
látinú ẹ̀yà Léfì, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);
látinú ẹ̀yà Ísákà, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);
8 látinú ẹ̀yà Sébúlúnì, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);
látinú ẹ̀yà Jósẹ́fù, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);
látinú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, a gbé èdìdì lé ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000).
9 Lẹ́yìn èyí, wò ó! mo rí ogunlọ́gọ̀ èèyàn,* tí èèyàn kankan kò lè ka iye wọn, wọ́n wá látinú gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti èèyàn àti ahọ́n,*+ wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, wọ́n wọ aṣọ funfun;+ imọ̀ ọ̀pẹ sì wà lọ́wọ́ wọn.+ 10 Wọ́n ń ké jáde pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa tó jókòó sórí ìtẹ́+ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni ìgbàlà wa ti wá.”+
11 Gbogbo àwọn áńgẹ́lì dúró yí ká ìtẹ́ náà àti àwọn àgbààgbà náà+ àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, wọ́n dojú bolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run, 12 wọ́n ń sọ pé: “Àmín! Kí ìyìn àti ògo àti ọgbọ́n àti ọpẹ́ àti ọlá àti agbára àti okun jẹ́ ti Ọlọ́run wa títí láé àti láéláé.+ Àmín.”
13 Ọ̀kan nínú àwọn àgbààgbà náà dáhùn, ó bi mí pé: “Àwọn wo ni àwọn tó wọ aṣọ funfun yìí,+ ibo ni wọ́n sì ti wá?” 14 Mo sọ fún un lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé: “Olúwa mi, ìwọ lo mọ̀ ọ́n.” Ó wá sọ fún mi pé: “Àwọn yìí ni àwọn tó wá látinú ìpọ́njú ńlá náà,+ wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.+ 15 Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi wà níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run, wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún un tọ̀sántòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀; Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́+ sì máa fi àgọ́ rẹ̀ bò wọ́n.+ 16 Ebi ò ní pa wọ́n mọ́, òùngbẹ ò sì ní gbẹ wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni oòrùn ò ní pa wọ́n, ooru èyíkéyìí tó ń jóni ò sì ní mú wọn,+ 17 torí Ọ̀dọ́ Àgùntàn,+ tó wà ní àárín ìtẹ́ náà, máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn,+ ó sì máa darí wọn lọ sí àwọn ìsun* omi ìyè.+ Ọlọ́run sì máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn.”+