Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kẹta àti Ìkẹrin Sáàmù
NÍGBÀ kan tí onísáàmù ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó sọ pé: “A ó ha polongo inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ní ibi ìsìnkú bí, ìṣòtítọ́ rẹ ní ibi ìparun bí?” (Sáàmù 88:11) Láìsí àní-àní, ìyẹn ò lè ṣeé ṣe. Òkú ò lè yin Jèhófà. Nítorí náà, ìdí pàtàkì kan tó fi yẹ ká fẹ́ máa wà láàyè nìṣó ni láti lè máa yin Jèhófà, ó sì yẹ ká máa yìn ín nítorí pé a wà láàyè.
Ìwé Kẹta àti Ìkẹrin Sáàmù, nínú ibi tí Sáàmù ìkẹtàléláàádọ́rin [73] sí ọgọ́rùn-ún ó lé mẹ́fà [106] wà, jẹ́ ká rí ọ̀pọ̀ ìdí tó fi yẹ ká máa yin Ẹlẹ́dàá ká sì máa fi ìyìn fún orúkọ rẹ̀. Ó yẹ kí àṣàrò tá a bá ń ṣe lórí àwọn sáàmù wọ̀nyí mú ká túbọ̀ mọrírì “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” ká sì túbọ̀ fi kún ìyìn wa sí i. (Hébérù 4:12) Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ gbé ohun tó wà nínú Ìwé Kẹta Sáàmù yẹ̀ wò.
“SÍSÚNMỌ́ ỌLỌ́RUN DÁRA FÚN MI”
Ásáfù tàbí àwọn kan nínú ìdílé rẹ̀ ló kọ Sáàmù mọ́kànlá àkọ́kọ́ tó wà nínú Ìwé Kẹta Sáàmù. Sáàmù àkọ́kọ́ nínú ìsọ̀rí yìí sọ ohun tí kò jẹ́ kí èrò àìtọ́ mú kí Ásáfù ṣí ẹsẹ̀ gbé. Ó ti wá mọ ohun tó yẹ kí òun ṣe. Ó kọ ọ́ lórin pé: “Ní tèmi, sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.” (Sáàmù 73:28) Nínú sáàmù ìkẹrìnléláàádọ́rin [74], onísáàmù kédàárò nítorí ìparun Jerúsálẹ́mù. Sáàmù karùndínlọ́gọ́rin [75], Sáàmù kẹrìndínlọ́gọ́rin [76] àti Sáàmù kẹtàdínlọ́gọ́rin [77] fi hàn pé Onídàájọ́ òdodo, Olùgbàlà àwọn ọlọ́kàntútù àti Olùgbọ́ àdúrà ni Jèhófà. Sáàmù kejìdínlọ́gọ́rin [78] sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì látìgbà ayé Mósè títí di ìgbà ayé Dáfídì. Sáàmù kọkàndínlọ́gọ́rin [79] jẹ́ ìdárò nítorí pípa tí wọ́n pa tẹ́ńpìlì run. Nínú Sáàmù ọgọ́rin [80], onísáàmù gbàdúrà pé kí Ọlọ́run mú àwọn èèyàn rẹ̀ padà sí ilẹ̀ wọn. Sáàmù kọkànlélọ́gọ́rin [81] jẹ́ àrọwà pé kí àwọn èèyàn ṣègbọràn sí Jèhófà. Àdúrà pé kí Ọlọ́run ṣèdájọ́ àwọn onídàájọ́ burúkú ló wà nínú Sáàmù kejìlélọ́gọ́rin [82] nígbà tí Sáàmù kẹtàlélọ́gọ́rin [83] jẹ́ àdúrà pé kí Ọlọ́run dá àwọn ọ̀tá rẹ̀ lẹ́jọ́.
Ọ̀kan lára àwọn orin atunilára tí àwọn ọmọ Kórà kọ sọ pé: “Ọkàn mi ti ṣàfẹ́rí, ó sì ti joro lẹ́nu wíwọ̀nà fún àwọn àgbàlá Jèhófà.” (Sáàmù 84:2) Sáàmù ìkarùndínláàádọ́rùn-ún [85] jẹ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pé kí Ọlọ́run bù kún àwọn tó padà bọ̀ láti ìgbèkùn. Sáàmù yìí jẹ́ kó hàn gbangba pé àwọn ìbùkún tẹ̀mí ṣe pàtàkì ju àwọn ìbùkún tara lọ. Nínú Sáàmù kẹrìndínláàádọ́rùn-ún [86], Dáfídì bẹ Ọlọ́run pé kó dáàbò bo òun, kó sì kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́. Orin atunilára nípa Síónì àtàwọn tí wọ́n bí níbẹ̀ làwọn ọmọ Kórà kọ nínú Sáàmù kẹtàdínláàádọ́rùn-ún [87], àdúrà sí Jèhófà ló sì wà nínú Sáàmù kejìdínláàádọ́rùn-ún [88]. Inú rere onífẹ̀ẹ́ Jèhófà, èyí tó fara hàn gbangba nínú májẹ̀mú tí Jèhófà bá Dáfídì dá, ni Sáàmù kọkàndinláàádọ́rùn-ún [89] dá lé lórí. Étánì ló kọ ọ́, ó sì ṣeé ṣe kí Étánì yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin ọlọ́gbọ́n mẹ́rin tó wà nígbà ayé Sólómọ́nì.—1 Àwọn Ọba 4:31.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
73:9—Báwo làwọn ẹni ibi ṣe “gbé ẹnu wọn àní sí ọ̀run, [tí] ahọ́n wọn pàápàá sì ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ ayé”? Níwọ̀n bí àwọn ẹni ibi ò ti bẹ̀rù ẹnikẹ́ni láyé àtọ̀run, wọn kì í pẹ́ fẹnu wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run. Wọ́n tún máa ń fi ahọ́n wọn ba àwọn ẹlòmíì lórúkọ jẹ́.
74:13, 14—Nígbà wo ni Jèhófà ‘fọ́ orí àwọn ẹran ńlá abàmì inú òkun nínú omi tó sì fọ́ orí Léfíátánì sí wẹ́wẹ́’? Bíbélì pe “Fáráò, ọba Íjíbítì” ní “ẹran ńlá abàmì inú òkun tí ó nà gbalaja ní àárín àwọn ipa odò Náílì rẹ̀.” (Ìsíkíẹ́lì 29:3) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé “àwọn alágbára Fáráò” ni Léfíátánì dúró fún. (Sáàmù 74:14, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé NW) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí fífọ́ orí wọn túmọ̀ sí ni bí Jèhófà ṣe ṣẹ́gun Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ pátápátá nígbà tó gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì tó ń fi wọ́n sìnrú.
75:4, 5, 10—Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ìwo” dúró fún? Ohun ìjà tó lágbára ni ìwo orí ẹranko jẹ́. Nítorí náà, agbára tàbí okun ni ọ̀rọ̀ náà “ìwo” dúró fún. Jèhófà ń gbé ìwo àwọn èèyàn rẹ̀ ga, ìyẹn ni pé ó ń mú kí wọ́n di ẹni ìgbéga, àmọ́ ńṣe ló ń ‘ké ìwo àwọn ẹni burúkú lulẹ̀.’ Ìkìlọ̀ lèyí jẹ́ fún wa pé ká má ṣe ‘gbé ìwo wa ga sí ibi gíga lókè,’ tó túmọ̀ sí pé a kò gbọ́dọ̀ máa gbéra ga tàbí ká máa fẹgẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ló ń gbéni ga, ńṣe ló yẹ ká máa wo àwọn ẹrù iṣẹ́ táwọn ará wa ní nínú ètò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ló ti wá.—Sáàmù 75:7.
76:10—Báwo ni “ìhónú ènìyàn” ṣe lè gbé Jèhófà lárugẹ? Tí Ọlọ́run bá gba àwọn èèyàn láyè láti fi ìhónú hàn sí wa torí pé a jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, ó lè yọrí sí ohun tó dára fún wa. A lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ láwọn ọ̀nà kan látinú ìyà èyíkéyìí tí wọ́n bá fi jẹ wá. Ìyà tó sì máa jẹ́ ká lè rí irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ kọ́ ni Jèhófà máa ń gbà láyè kí wọ́n fi jẹ wá. (1 Pétérù 5:10) ‘Ọlọ́run máa ń fi ìyókù ìhónú èèyàn di ara rẹ̀ lámùrè.’ Ká ní ìyà náà pọ̀ débi pé ó yọrí sí ikú ńkọ́? Èyí náà lè gbé Jèhófà ga ní ti pé àwọn tó rí i pé a fara da ìnira náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í fògo fún Ọlọ́run.
78:24, 25—Kí nìdí tí Bíbélì fi pe mánà ní “ọkà ọ̀run” àti “oúnjẹ àwọn alágbára”? Àwọn áńgẹ́lì ni “àwọn alágbára” tí ibí yìí ń sọ. Àmọ́, kò sí èyíkéyìí nínú ohun tí Bíbélì pe mánà yìí tó fi hàn pé oúnjẹ àwọn áńgẹ́lì ni. Ìdí tó fi jẹ́ “ọkà ọ̀run” ni pé láti ọ̀run ló ti wá. (Sáàmù 105:40) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òkè ọ̀run làwọn áńgẹ́lì tàbí “àwọn alágbára” ń gbé, ọ̀rọ̀ náà “oúnjẹ àwọn alágbára” lè túmọ̀ sí pé Ọlọ́run tó ń gbé òkè ọ̀run ló pèsè rẹ̀. (Sáàmù 11:4) Bákan náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn áńgẹ́lì ni Jèhófà lò láti fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní mánà ọ̀hún.
82:1, 6—Àwọn wo ni Bíbélì pè ní “àwọn ọlọ́run” àti “ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ”? Àwọn ẹ̀dá èèyàn tó jẹ́ onídàájọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì ni ibí yìí ń tọ́ka sí. Orúkọ méjèèjì yìí bá a mu nítorí pé agbọ̀rọ̀sọ àti aṣojú ni wọ́n jẹ́ fún Ọlọ́run láyé ìgbà yẹn.—Jòhánù 10:33-36.
83:2—Kí ni ‘gbígbé orí ẹni sókè’ túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé èèyàn múra tán láti lo agbára rẹ̀, èyí sì sábà máa jẹ́ láti ṣàtakò, láti jà, tàbí láti fojú àwọn ẹlòmíì gbolẹ̀.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
73:2-5, 18-20, 25, 28. A ò gbọ́dọ̀ máa ṣe ìlara àwọn ẹni ibi nítorí aásìkí wọn, ká wá máa hu irú àwọn ìwà àìníbẹ̀rù Ọlọ́run tí wọ́n ń hù. Orí ilẹ̀ yíyọ̀bọ̀rọ́ ni ibi tí àwọn ẹni ibi wà. Kò sí àní-àní pé wọn yóò “ṣubú ní rírún wómúwómú.” Ìyẹn nìkan kọ́ o, níwọ̀n bí ìjọba èèyàn aláìpé ò ti lè fòpin sí ìwà ibi, tí a bá wá ń sapá pé a fẹ́ fòpin sí i, àsán ni yóò já sí. Bíi ti Ásáfù, ohun tó yẹ ká ṣe tá ò fi ní bọkàn jẹ́ bá a ṣe ń rí ìwà ibi ni pé ká ‘sún mọ́ Ọlọ́run,’ ká sì ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Rẹ̀.
73:3, 6, 8, 27. A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ afọ́nnu, onírera, afinirẹ́rìn-ín-ẹlẹ́yà àti oníjìbìtì. Kò tiẹ̀ yẹ ká hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ rárá, àní bó bá tiẹ̀ dà bíi pé híhu irú ìwà bẹ́ẹ̀ yóò ṣe wá láwọn àǹfààní kan.
73:15-17. Nígbà tí nǹkan bá dà rú mọ́ wa lọ́kàn, tá ò mọ ohun tó yẹ ká ṣe, kò yẹ ká máa sọ àníyàn ọkàn wa lójú gbogbo èèyàn. Ńṣe ni sísọ “irú ìtàn bẹ́ẹ̀” yóò kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ẹlòmíì. Ńṣe ló yẹ ká ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ohun tó jẹ́ ìṣòro wa, ká sì wá ojútùú sí wọn nípa fífi ọ̀rọ̀ wa lọ àwọn ará wa.—Òwe 18:1.
73:21-24. Bíbélì fi hàn pé tí ‘ọkàn ẹnì kan bá korò’ nítorí bó ṣe dà bíi pé nǹkan ń lọ déédéé fún àwọn ẹni ibi, ńṣe ni onítọ̀hún ń hùwà bíi tàwọn ẹranko tí kì í ronú. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìwà àìnírònú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìmọ̀ràn Jèhófà la gbọ́dọ̀ jẹ́ kó máa ṣamọ̀nà wa, ká jẹ́ kó dá wa lójú hán-únhán-ún pé yóò ‘di ọwọ́ ọ̀tún wa mú’ yóò sì ràn wá lọ́wọ́. Síwájú sí i, Jèhófà yóò ‘mú wa wọnú ògo,’ tó túmọ̀ sí pé a ó ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú rẹ̀.
77:6. Ẹni tí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì bá jẹ lọ́kàn tó sì fẹ́ máa fara balẹ̀ wá ibi táwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí wà ní láti máa wá àyè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gidigidi pé kí àwọn àkókò kan wà tí a ó fi máa fara balẹ̀ ṣàṣàrò!
79:9. Jèhófà máa ń fetí sí àwọn àdúrà wa, pàápàá tí wọ́n bá jẹ mọ́ ìyàsímímọ́ orúkọ rẹ̀.
81:13, 16. Tá a bá ń fetí sí ohùn Jèhófà tá a sì ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀, Jèhófà yóò bù kún wa lọ́pọ̀ yanturu.—Òwe 10:22.
82:2, 5. Àìṣèdájọ́ òdodo máa ń mú kí ‘ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.’ Irú ìwà àìdáa bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ kí nǹkan lọ déédéé láwùjọ.
84:1-4, 10-12. Àwọn onísáàmù mọrírì ibi ìjọsìn Jèhófà wọ́n sì jẹ́ káwọn àǹfààní tí wọ́n ní nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà tẹ́ wọn lọ́rùn. Àpẹẹrẹ tó dára lèyí jẹ́ fún wa.
86:5. A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà “ṣe tán láti dárí jini”! Ńṣe ló máa ń wá ohun táá jẹ́ kó lè fi àánú hàn sí ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn.
87:5, 6. Ǹjẹ́ àwọn tó bá ń gbé nínú Párádísè yóò tiẹ̀ mọ orúkọ àwọn tí wọ́n jíǹde sí ọ̀run? Àwọn ẹsẹ wọ̀nyí fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó rí bẹ́ẹ̀.
88:13, 14. Bá ò bá tètè rí ìdáhùn sí àdúrà tá à ń gbà nípa ìṣòro kan, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Jèhófà fẹ́ mọ bá a ṣe ń fi tọkàntọkàn sin òun tó.
“Ẹ FI ỌPẸ́ FÚN UN, Ẹ FI ÌBÙKÚN FÚN ORÚKỌ RẸ̀”
Ronú nípa onírúurú nǹkan tó yẹ kó sún wa láti máa gbé Jèhófà ga, èyí tó wà nínú ìwé kẹrin Sáàmù. Nínú Sáàmù àádọ́rùn-ún [90], Mósè fi ìyàtọ̀ tó wà láàárín “Ọba ayérayé” tó wà títí ayé àti àwa ẹ̀dá èèyàn tí ìwàláàyè wa kúrú hàn. (1 Tímótì 1:17) Sáàmù 91:2 sọ pé Mósè pe Jèhófà ní ‘ibi ìsádi àti ibi odi agbára òun,’ ìyẹn ni pé ó ka Jèhófà sí ẹni tó ń dáàbò bò ó. Díẹ̀ lára àwọn sáàmù tó tẹ̀ lé e sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Ọlọ́run, àwọn èrò ọkàn rẹ̀ tó ga ju tèèyàn lọ àtàwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀. Sáàmù mẹ́ta ló bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà, “Jèhófà fúnra rẹ̀ ti di ọba.” (Sáàmù 93:1; 97:1; 99:1) Onísáàmù sọ pé Jèhófà ni Olùṣẹ̀dá wa, ó sì ní ká “fi ọpẹ́ fún un, [ká sì] fi ìbùkún fún orúkọ rẹ̀.”—Sáàmù 100:4.
Báwo ló ṣe yẹ kí alákòóso tó bá bẹ̀rù Jèhófà máa ṣe? Sáàmù kọkànlélọ́gọ́rùn-ún [101] tí Dáfídì Ọba kọ ló dáhùn ìbéèrè yìí. Sáàmù tó tẹ̀ lé èyí sọ fún wa pé: “Ó dájú pé [Jèhófà] yóò yíjú sí àdúrà àwọn tí a kó gbogbo nǹkan ìní wọn lọ, kì yóò sì tẹ́ńbẹ́lú àdúrà wọn.” (Sáàmù 102:17) Sáàmù kẹtàlélọ́gọ́rùn-ún [103] jẹ́ ká mọ̀ pé inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti àánú Jèhófà pọ̀ gidigidi. Onísáàmù náà tún sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ nǹkan tí Ọlọ́run dá sórí ilẹ̀ ayé, ó wá sọ pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! Gbogbo wọn ni o fi ọgbọ́n ṣe.” (Sáàmù 104:24) Àwọn sáàmù méjì tó gbẹ̀yìn Ìwé Kẹrin yìí gbé Jèhófà ga nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀.—Sáàmù 105:2, 5; 106:7, 22.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
91:1, 2—Kí ni “ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ,” báwo la sì ṣe lè ‘gbé’ ibẹ̀? Èyí ṣàpẹẹrẹ ibi ààbò àti ìfọ̀kànbalẹ̀ tẹ̀mí, ohun tó sì túmọ̀ sí ni pé a wà nípò tí ohunkóhun kò ti ní lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Ibi ìkọ̀kọ̀ ni ibẹ̀ jẹ́ nítorí pé àwọn tí kò bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run kò lè mọbẹ̀. Bá a ṣe lè fi Jèhófà ṣe ibùgbé wa ni pé ká máa wò ó bí ibi ìsádi wa àti ibi odi agbára wa, ká máa yìn ín lógo torí pé òun ni Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run, ká sì máa wàásù ìhìn rere Ìjọba rẹ̀. Mímọ̀ tá a mọ̀ pé Jèhófà múra tán láti ràn wá lọ́wọ́ jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ pé kò sóhun tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́.—Sáàmù 90:1.
92:12—Báwo làwọn olódodo ṣe ń “yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pẹ”? Igi ọ̀pẹ máa ń so èso gan-an. Bí àwọn olódodo sì ṣe dà bí igi ọ̀pẹ ni pé, wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin lójú Jèhófà, wọn kì í sì í yéé so “èso àtàtà,” lára èso àtàtà ọ̀hún sì ni àwọn iṣẹ́ rere wọn.—Mátíù 7:17-20.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
90:7, 8, 13, 14. Ẹ̀ṣẹ̀ máa ń ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run tòótọ́ jẹ́. Ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ ò sì ṣeé fi pa mọ́ fún Ọlọ́run. Àmọ́ o, bá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn tá a sì jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀, Jèhófà yóò tún padà máa fi ojú rere wò wá, ‘yóò fi inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ tẹ́ wa lọ́rùn.’
90:10, 12. Níwọ̀n bí ìwàláàyè àwa èèyàn ti kúrú, ó yẹ ká máa “ka àwọn ọjọ́ wa.” Lọ́nà wo? Nípa ‘jíjèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n’ ni, èyí tó túmọ̀ sí pé ká máa fi ọgbọ́n hùwà ká má bàa fi àwọn ọjọ́ ayé wa tó kù ṣòfò, àmọ́ kó jẹ́ èyí tá a lò lọ́nà tó múnú Jèhófà dùn. Láti ṣe èyí, a gbọ́dọ̀ fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sípò àkọ́kọ́, ká sì máa fi ọgbọ́n lo àkókò wa.—Éfésù 5:15, 16; Fílípì 1:10.
90:17. Kò sóhun tó burú nínú pé ká máa gbàdúrà pé kí Jèhófà “fìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in,” kó sì rọ̀jò ìbùkún sórí àwọn ohun tá à ń sapá láti ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
92:14, 15. Táwọn àgbàlagbà bá ń fi tọkàntara kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń bá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kẹ́gbẹ́ déédéé, wọ́n á “máa bá a lọ ní sísanra àti ní jíjàyọ̀yọ̀,” èyí tó túmọ̀ sí pé wọ́n á jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí. Bákan náà, wọ́n á jẹ́ ẹni tó wúlò gan-an nínú ìjọ.
94:19. Ohun yòówù kó máa fa ‘ìrònú tí ń gbé wa lọ́kàn sókè,’ tá a bá ń ka àwọn ọ̀rọ̀ “ìtùnú” tí ń bẹ nínú Bíbélì tá a sì ń ṣàṣàrò lé wọn lórí, ìwọ̀nyí lè tù wá nínú.
95:7, 8. Tá a bá ń tẹ́tí sí ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́, tí à ń fiyè sí i, tí a sì ń ṣègbọràn sí i láìjáfara, a ò ní di ọlọ́kàn líle.—Hébérù 3:7, 8.
106:36, 37. Àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí jẹ́ ká mọ̀ pé ìbọ̀rìṣà ò yàtọ̀ sí rírúbọ sí àwọn ẹ̀mí èṣù. Èyí fi hàn pé béèyàn bá ń bọ ère, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè di ẹni táwọn ẹ̀mí èṣù ń darí. Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà.”—1 Jòhánù 5:21.
“Ẹ yin Jáà!”
Ọ̀rọ̀ ìṣílétí yìí: “Ẹ yin Jáà!” ló gbẹ̀yìn sáàmù mẹ́ta tó kẹ́yìn nínú Ìwé Kẹrin Sáàmù. Ọ̀rọ̀ yìí náà ló tún bẹ̀rẹ̀ sáàmù tó kẹ́yìn nínú Ìwé Kẹrin Sáàmù. (Sáàmù 104:35; 105:45; 106:1, 48) Àní, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ̀rọ̀ yìí “Ẹ yin Jáà!” fara hàn nínú Ìwé Kẹrin Sáàmù, ìyẹn sáàmù àádọ́rùn-ún [90] si ìkẹrìndínláàádọ́fà [106].
Dájúdájú, ọ̀pọ̀ nǹkan ló yẹ kó mú ká fẹ́ láti máa yin Jèhófà. Sáàmù kẹtàléláàádọ́rin [73] sí ìkẹrìndínláàádọ́fà [106] ti jẹ́ ká rí ọ̀pọ̀ nǹkan tá a lè ṣàṣàrò lé lórí, èyí sì ń jẹ́ ká túbọ̀ dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Baba wa ọ̀run. Tá a bá ronú nípa gbogbo ohun tó ti ṣe fún wa àtàwọn tó máa ṣe fún wa lọ́jọ́ ọ̀la, ǹjẹ́ kì í wù wá láti fi gbogbo okun àti agbára wa “yin Jáà”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Bíi ti Ásáfù, “sísúnmọ́ Ọlọ́run” lè jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe tá ò fi ní bọkàn jẹ́ bá a ṣe ń rí àwọn tó ń hùwà ibi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Fáráò kàgbákò ní Òkun Pupa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Bíbélì fi pe mánà ní “oúnjẹ àwọn alágbára”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Kí ló lè mú ‘ìrònú tí ń gbé wa lọ́kàn sókè’ kúrò?