ORÍ KẸRÌNDÍNLÓGÚN
Pinnu Láti Jọ́sìn Ọlọ́run
1, 2. Ìbéèrè wo ló yẹ kó o bi ara rẹ, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì?
ÀWỌN ohun tó o ti kọ́ nínú Bíbélì ti jẹ́ kó o mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn tó sọ pé àwọn ń jọ́sìn Ọlọ́ruń ni wọ́n ń kọ́ni ní ohun ti Ọlọ́run kórìíra, tí wọ́n sì ń fi àwọn nǹkan náà ṣèwà hù. (2 Kọ́ríńtì 6:17) Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi pàṣẹ pé ká jáde kúrò nínú ẹ̀sìn èké, ìyẹn “Bábílónì Ńlá.” (Ìfihàn 18:2, 4) Kí lo máa ṣe? Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa pinnu ohun tó máa ṣe, ó sì gbọ́dọ̀ bi ara rẹ̀ pé, ‘Ṣé mo fẹ́ sin Ọlọ́run lọ́nà tó fẹ́ kí n sin òun, àbí mo fẹ́ máa sìn ín bí mo ṣe ń sìn ín tẹ́lẹ̀?
2 Tó o bá ti fi ẹ̀sìn èké sílẹ̀ tàbí tó o ti kọ̀wé fi í sílẹ̀, ìyẹn dáa gan-an. Àmọ́, lọ́kàn ẹ lọ́hùn-ún o ṣì lè máa rò pé àwọn ayẹyẹ tàbí àwọn àṣà ẹ̀sìn èké kan dáa. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn ayẹyẹ tàbí àṣà yẹn, ká sì rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wọ̀nyẹn wò wọ́n.
FÍFI ÈRE ṢE ÌJỌSÌN ÀTI JÍJỌ́SÌN ÀWỌN BABA ŃLÁ
3. (a) Kí nìdí tó fi ṣòro fún àwọn kan láti jáwọ́ nínú fífi ère ṣe ìjọsìn wọn? (b) Kí ni Bíbélì sọ nípa fífi ère jọ́sìn Ọlọ́run?
3 Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn èèyàn kan ti fi ère tàbí ojúbọ jọ́sìn Ọlọ́run ní ilé wọn. Tí ìwọ náà bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè má bá ẹ lára mu láti jọ́sìn Ọlọ́run láìlo àwọn nnkan yẹn tàbí kó lòdì lójú ẹ téèyàn ò bá lò wọ́n. Àmọ́, rántí pé Jèhófà kọ́ wa bó ṣe yẹ ká jọ́sìn òun. Bíbélì sì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ò fẹ́ ká lo ère nínú ìjọsin wa.—Ka Ẹ́kísódù 20:4, 5; Sáàmù 115:4-8; Àìsáyà 42:8; 1 Jòhánù 5:21.
4. (a) Kí nìdí ti kò fi yẹ ká máa jọ́sìn àwọn baba ńlá wa? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ bá òkú sọ̀rọ̀?
4 Àwọn kan lè lo ọ̀pọ̀ àkókò àti okun wọn láti mú inú àwọn baba ńlá wọn dùn. Kódà wọ́n lè jọ́sìn wọn. Àmọ́, a ti kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn tó ti kú ò lè ràn wá lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n ṣe wá ní jàǹbá. Nítorí pé wọn ò sí mọ́. Ká sòótọ́, ó léwu láti bá wọn sọ̀rọ̀, torí pé ọ̀rọ̀ tá a rò pé ó wá látọ̀dọ̀ èèyàn wa tó tí kú ló jẹ́ pe ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí èṣù ló ti wá. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ bá òkú sọ̀rọ̀ tàbí kí wọ́n lọ́wọ́ sí ìbẹ́mìílò èyíkéyìí.—Diutarónómì 18:10-12; wo Àlàyé Ìparí Ìwé 26 àti 31.
5. Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú fífi ère jọ́sìn Ọlọ́run àti jíjọ́sìn àwọn baba ńlá?
5 Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú fífi ère jọ́sìn Ọlọ́run tàbi jíjọ́sìn àwọn baba ńlá? Ó yẹ kó o ka Bíbélì, kó o sì ronú jinlẹ̀ nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn nǹkan yẹn. Ó kà wọ́n sí “ohun ìríra.” (Diutarónómì 27:15) Máa gbàdúrà sí Jèhófà lójoojúmọ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa fi ojú tó fi ń wo nǹkan wò ó, kó sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó fẹ́. (Àìsáyà 55:9) Ó dájú pé Jèhófà á fún ẹ lágbára láti mú ohunkóhun tó wá látinú ìjọsìn èké kúrò ní igbésí ayé rẹ.
ṢÉ Ó YẸ KÁ MÁA ṢE KÉRÉSÌMESÌ?
6. Kí nìdí tí wọ́n fi yan December 25 láti fi ṣe ọjọ́ ìbí Jésù?
6 Kárí ayé, Kérésìmesì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àjọ̀dún tó lókìkí jù lọ, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì rò pé ó jẹ́ ọjọ́ ìbí Jésù. Àmọ́ ká sòótọ́, Kérésìmesì wá látinú ìjọsìn èké. Ìwé gbédègbẹyọ̀ kan ṣàlàyé pé àwọn ará Róòmù tó jẹ́ abọ̀rìṣà máa ń ṣe ọjọ́ ìbí oòrùn ní December 25. Torí pé àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì fẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn abọ̀rìṣà di Kristẹni, wọn pinnu láti máa ṣe ọjọ́ ìbí Jésù ní December 25, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò bí Jésù ní ọjọ́ yẹn. (Lúùkù 2:8-12) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò ṣe Kérésìmesì. Ìwe ìwádìí kan ṣàlàyé pé igba (200) ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù, “kò sẹ́ni tó mọ̀ ìgbà tí wọ́n bí i gangan, àwọn èèyàn díẹ̀ ló sì fẹ́ mọ̀ ọ́n.” (Sacred Origins of Profound Things) Ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí Jésù ti gbé ayé ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ Kérésìmesì.
7. Kí nìdí tí àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í fi í ṣe Kérésìmesì?
7 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ pé Kérésìmesì àtàwọn àṣà tó so mọ́ ọn wá látinú ìbọ̀rìṣà, irú bíi ṣíṣe àríyá àti fífúnni lẹ́bùn. Bí àpẹẹrẹ, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti àwọn apá ibì kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn ìgbà kan wá tí wọ́n fòfin de Kérésìmesì torí pé ó wá látinú ìbọ̀rìṣà. Wọ́n sì máa ń fìyà jẹ ẹnikẹ́ni tó bá ṣe é. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn èèyàn tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe Kérésìmesì. Kí nìdí tí àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í fi í ṣe Kérésìmesì? Ìdí ni pé wọ́n fẹ́ kí gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.
ṢÉ Ó YẸ KÁ MÁA ṢE ỌJỌ́ ÌBÍ?
8, 9. Kí nìdí tí àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ kì í fi í ṣe ọjọ́ ìbí?
8 Ayẹyẹ mìí tó lókìkí tí àwọn èèyàn máa ń ṣe ni ọjọ́ ìbí. Ṣé ó yẹ kí àwọn Kristẹni máa ṣe ọjọ́ ìbí? Àwọn tí kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà ló ṣe àwọn ayẹyẹ ọjọ́ ìbí méjèèjì tó wà nínú Bíbélì. (Jẹ́nẹ́sísì 40:20; Máàkù 6:21) Àwọn òrìṣà ni wọ́n máa ń fi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí bọlá fún. Ìdí nìyẹn tí àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ fi “gbà pé ṣíṣe ọjọ́ ìbí jẹ́ àṣà ìbọ̀rìṣà.”—The World Book Encycloepedia.
9 Àwọn ará Róòmù àti Gíríìkì àtijọ́ gbà gbọ́ pé ẹ̀mí àìrí kan máa ń wà níbi tí wọ́n bá ti fẹ́ bí ẹnì kan àti pé ẹ̀mí àìrí yìí láá máa dáàbò bo ẹni náà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Ìwé The Lore of Birthdays ṣàlàyé pé: “Ẹ̀mí yìí ti ní àjọṣe abàmì pẹ̀lú òrìṣà tó ni ọjọ́ ìbí tí wọ́n bí ẹni náà.”
10. Kí nìdí tí àwọn Kristẹni òde òní kì í fi í ṣe ọjọ́ ìbí?
10 Ṣé o rò pé Jèhófà fọwọ́ sí àwọn ayẹyẹ tó wá látinú ẹ̀sìn èké? (Àìsáyà 65:11,12) Rárá, kò fọwọ́ sí i. Ìdí nìyẹn tí a kì í fi í ṣe ọjọ́ ìbí tàbí àjọ̀dún èyíkéyìí tó wá látinú ẹ̀sìn èké.
ṢÉ Ó TIẸ̀ ṢE PÀTÀKÌ?
11. Kí nìdí tí àwọn kan fi ń ṣe àwọn àjọ̀dún? Kí ló yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí ẹ?
11 Àwọn kan mọ̀ pé Kérésìmesì àti àwọn àjọ̀dún míì wá látinú ìbọ̀rìṣà, síbẹ̀ wọ́n ń ṣe é. Wọ́n gbà pé àwọn àjọ̀dún yẹn máa fún àwọn láǹfààní láti ló àkókò pẹ̀lú ìdílé àwọn. Ṣé èrò tìẹ náà nìyẹn? Kò sóhun to burú nínú kó o lo àkókò pẹ̀lú ìdílé rẹ. Jèhófà ló dá ìdílé sílẹ̀, ó sì fẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ìdílé wa. (Éfésù 3:14, 15) Àmọ́, ó yẹ ká gbájú mọ́ bá a ṣe máa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà dípò ká máa wá bá ṣe fẹ́ tẹ́ àwọn mọ̀lẹ́bí wa lọ́rùn láti máa ṣe àjọ̀dún ẹ̀sìn èké. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Ẹ máa wádìí dájú ohun tí Olúwa tẹ́wọ́ gbà.”—Éfésù 5:10.
12. Àwọn nǹkan wo ni kò ní jẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba àjọ̀dún kan?
12 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò pé ibi tí àjọ̀dún kan ti wá kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, àmọ́ ojú tí Jèhófà fi wò ó kọ́ nìyẹn. Kò tẹ́wọ́ gba àwọn àjọ̀dún tó wá látinú ìjọsìn èké tàbí tó ń gbé èèyàn tàbí àmì orílẹ̀-èdè lárugẹ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará Íjíbítì máa ń ṣe ọ̀pọ̀ àjọ̀dún fún àwọn òrìṣà wọn. Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sá kúrò ní Íjíbítì, wọ́n ṣe ọ̀kan lára irú ayẹyẹ ìbọ̀rìṣà wọn, wọ́n sì pé é ní ‘Àjọyọ̀ fún Jèhófà.’ Àmọ́ Jèhófà fìyà jẹ wọ́n torí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. (Ẹ́kísódù 32:2-10) Bí wòlíì Àìsáyà ṣe sọ, a ò gbọ́dọ̀ “fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kankan!”—Ka Àìsáyà 52:11.
MÁA HÙWÀ RERE SÁWỌN ÈÈYÀN
13. Àwọn ìbéèrè wo lo lè ní tó o bá pinnu láti jáwọ́ nínú ṣíṣe àwọn àjọ̀dún?
13 Tó o bá pinnu láti jáwọ́ nínú ṣíṣe àwọn àjọ̀dún, o lè ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Bí àpẹẹrẹ: Kí ló yẹ kí n ṣe tí àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ bá béèrè ìdí tí mi ò fi ń bá wọn ṣe Kérésìmesì? Kí ló yẹ kí n ṣe tí ẹnì kan bá fún mi ni ẹ̀bùn Kérésìmesì? Kí ló yẹ kí n ṣe tí ọkọ mi tàbí ìyàwó mi bá fẹ́ kí n ṣe àjọ̀dún kan? Báwo ni mo ṣe lè ran àwọn ọmọ mi lọ́wọ́ kí inú wọn má bàa bà jẹ́ torí wọn kì í ṣe àjọ̀dún kan tàbí ọjọ́ ìbí wọn?
14, 15. Kí lo lè ṣe tí ẹnì kan bá kí ẹ kú ọdún tàbí tó bá fún ẹ ní ẹ̀bùn ọdún?
14 Ó ṣe pàtàkì pé kó o lo làákàyè rẹ tó o bá ń pinnu ohun tó o fẹ́ sọ tàbí ohun tó o fẹ́ ṣe nínú ipò kọ̀ọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, tí àwọn èèyàn bá kí ẹ kú ọdún, ó yẹ kó o dá wọn lóhùn. O lè sọ pé, “Ẹ ṣeun.” Àmọ́, tí ẹnì kan bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, o lè ṣàlàyé ìdí tí o kì í fi í ṣe àjọ̀dún kan. Àmọ́, máa finú rere hàn, kó o fọgbọ́n sọ̀rọ̀, kó o sì bọ̀wọ̀ fún wọn. Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín máa jẹ́ ọ̀rọ̀ onínúure, tí iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bó ṣe yẹ kí ẹ dá ẹnì kọ̀ọ̀kan lóhùn.” (Kólósè 4:6) O lè ṣàlàyé pé, o mọyì lílo àkókò pẹ̀lú àwọn èèyàn àti fífúnni lẹ́bùn, àmọ́ o kàn pinnu pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà àwọn àjọ̀dún.
15 Kí ló yẹ kó o ṣe tí ẹnì kan bá fún ẹ lẹ́bùn? Bíbélì kò ṣe àwọn òfin tó pọ̀ rẹpẹtẹ, àmọ́ ó sọ pé, a gbọ́dọ̀ ní ẹ̀rí ọkàn rere. (1 Tímótì 1:18, 19) Ó ṣeé ṣe kí ẹni tó fún ẹ lẹ́bùn náà má mọ̀ pé o kì í ṣe àjọ̀dún yìí. Tàbí kó tiẹ̀ sọ pé, “Mo mọ̀ pé o kì í ṣe àjọ̀dún yìí, àmọ́, ó ṣì wù mí kí n fún ẹ lẹ́bùn yìí.” Ní irú ipò yẹn, o lè pinnu láti gba ẹ̀bùn náà tàbí kó o má gbà á. Àmọ́ ìpinnu yòówù kó o ṣe, rí i dájú pé o ní ẹ̀rí ọkàn rere. A ò ní fẹ́ ṣe ohun tó máa ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́.
ÌWỌ ÀTI ÌDILE RẸ
16. Kí ló yẹ kó o ṣe tí ìdílé rẹ bá fẹ́ ṣe àwọn àjọ̀dún kan?
16 Kí ló yẹ kó o ṣe tí ìdílé rẹ bá fẹ́ ṣe àjọ̀dún kan? Kò yẹ kó o bá wọn jà. Rántí pé, wọ́n lẹ̀tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tí wọ́n bá fẹ́ ṣe. Hùwà rere sí wọn, kó o sì bọ̀wọ̀ fún ìpinnu wọn, torí ìwọ náa á fẹ́ kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún ìpinnu rẹ. (Ka Mátíù 7:12.) Àmọ́, kí lo máa ṣe tí ìdílé rẹ bá fẹ́ kó o lo àkókò pẹ̀lú àwọn lásìkò àjọ̀dún náà? Kó o tó pinnu ohun tó o máa ṣe, gbàdúrà sí Jèhófà kó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́. Ronú nípa ọ̀rọ̀ náà dáadáa, kó o sì ṣèwádìí nípa rẹ̀. Rántí pé, ohun tínú Jèhófà dùn sí lo máa ń fẹ́ ṣe nígbà gbogbo.
17. Kí lo lè ṣe láti ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa rò pé àwọn pàdánù ohun kan nígbà táwọn èèyàn bá ń ṣe àwọn àjọ̀dún?
17 Kí lo lè ṣe láti ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ tí wọ́n bá rí àwọn tó ń ṣe àjọ̀dún? O lè ṣètò ohun kan lákànṣe fún wọn látìgbàdégbà. O lè tún fún wọn ní àwọn ẹ̀bùn tí wọn kò rò tẹ́lẹ̀. Ara ẹ̀bùn tó dáa jù lọ tó o lè fún àwọn ọmọ rẹ ni pé kó o máa lo àkókò pẹ̀lú wọn, kó o sì máa fìfẹ́ hàn sí wọn.
ṢE Ẹ̀SÌN TÒÓTỌ́
18. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni?
18 Ká lè ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, a ní láti fi ẹ̀sìn èké silẹ̀ títí kan àwọn àṣà àti àjọ̀dún ìsìn èké. Àmọ́, a tún ní láti ṣe ẹ̀sìn tòótọ́. Lọ́nà wo? Ọ̀nà kan ni pé, ká máa lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé. (Ka Hébérù 10:24, 25.) Àwọn ìpàdé náà jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn tòótọ́. (Sáàmù 22:22; 122:1) A máa ń rí ìṣírí gbà nígbà tá a bá pé jọ.—Róòmù 1:12.
19. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o máa sọ ohun tó o ti kọ́ nínú Bíbélì fún àwọn èèyàn?
19 Ọ̀nà míì tó máa fi hàn pé ìjọsìn tòótọ́ lo yàn ni tó o bá ń sọ àwọn ohun tó o ti kọ́ nínú Bíbélì fún àwọn èèyàn. Ọ̀pọ̀ èèyàn làwọn ohun búburú tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé ń kó ìdààmú bá. Bóyá o tiẹ̀ mọ àwọn kan tó ní irú ìdààmú ọkàn yẹn. Sọ fún wọn nípa ohun àgbàyanu tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Bó o ṣé ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni tó o sì ń sọ òtítọ́ Bíbélì fún àwọn èèyàn, wàá rí i pé kò ní wù ẹ́ mọ́ láti jẹ́ apá kan ẹ̀sìn èké àti àwọn àṣà rẹ̀. Ó dájú pé wàá láyọ̀, Jèhófà á sì bù kún ìsapá rẹ lọ́pọ̀lọpọ̀ torí pé o pinnu láti jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó tọ́.—Málákì 3:10.