Àìsáyà
25 Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run mi.
Mo gbé ọ ga, mo yin orúkọ rẹ,
Torí o ti ṣe àwọn ohun àgbàyanu,+
Àwọn ohun tí o pinnu* láti ìgbà àtijọ́,+
Nínú òtítọ́,+ nínú ìfọkàntán.
2 Torí o ti sọ ìlú kan di òkúta tí a tò jọ pelemọ,
O ti sọ ìlú olódi di ibi tí a rún wómúwómú.
Ilé gogoro àjèjì kì í ṣe ìlú mọ́;
Wọn ò ní tún un kọ́ láé.
4 Torí o ti di ibi ààbò fún ẹni rírẹlẹ̀,
Ibi ààbò fún aláìní nínú ìdààmú rẹ̀,+
Ibi ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò,
Àti ibòji kúrò lọ́wọ́ ooru.+
Nígbà tí atẹ́gùn líle àwọn ìkà bá dà bí ìjì òjò tó kọ lu ògiri,
5 Bí ooru ní ilẹ̀ tí kò lómi,
O dáwọ́ ariwo àwọn àjèjì dúró.
Bí òjìji ìkùukùu* ṣe ń lé ooru lọ,
Bẹ́ẹ̀ ni a máa mú kí orin àwọn ìkà dáwọ́ dúró.
6 Lórí òkè yìí,+ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa se àkànṣe àsè tó dọ́ṣọ̀+
Fún gbogbo èèyàn,
Àkànṣe àsè tó ní wáìnì tó dáa,*
Àsè tó dọ́ṣọ̀ tí mùdùnmúdùn kún inú rẹ̀,
Àsè tó ní wáìnì tó dáa tí wọ́n sẹ́.
Ó máa mú ẹ̀gàn àwọn èèyàn rẹ̀ kúrò ní gbogbo ayé,
Torí Jèhófà fúnra rẹ̀ ti sọ ọ́.
9 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa sọ pé:
“Wò ó! Ọlọ́run wa nìyí!+
Jèhófà nìyí!
A ti gbẹ́kẹ̀ lé e.
Ẹ jẹ́ ká máa yọ̀, kí inú wa sì dùn torí ìgbàlà rẹ̀.”+
10 Torí ọwọ́ Jèhófà máa wà lórí òkè yìí,+
A sì máa tẹ Móábù mọ́lẹ̀ ní àyè rẹ̀+
Bíi pòròpórò tí wọ́n tẹ̀ mọ́ inú ajílẹ̀ tí wọ́n kó jọ.
11 Ó máa na ọwọ́ rẹ̀ jáde sínú rẹ̀
Bí ìgbà tí òmùwẹ̀ bá na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lúwẹ̀ẹ́,
Ó sì máa rẹ ìgbéraga rẹ̀ wálẹ̀,+
Pẹ̀lú bó ṣe ń gbé ọwọ́ rẹ̀ lọ́nà tó já fáfá.
12 Ó sì máa wó ìlú olódi rẹ lulẹ̀,
Pẹ̀lú àwọn ògiri gíga tí o fi ṣe ààbò;
Ó máa wó o palẹ̀, ó máa wó o lulẹ̀ pátápátá.