Àìsáyà
55 Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin tí òùngbẹ ń gbẹ,+ ẹ wá síbi omi!+
Ẹ̀yin tẹ́ ò ní owó, ẹ wá, ẹ rà, kí ẹ sì jẹ!
Àní, ẹ wá, ẹ ra wáìnì àti wàrà+ lọ́fẹ̀ẹ́, láìsan owó.+
2 Kí ló dé tí ẹ fi ń sanwó fún ohun tí kì í ṣe oúnjẹ,
Kí ló sì dé tí ẹ fi ń lo ohun tí ẹ ṣiṣẹ́ fún* sórí ohun tí kì í tẹ́ni lọ́rùn?
3 Ẹ dẹ etí yín sílẹ̀, kí ẹ sì wá sọ́dọ̀ mi.+
Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ* ó sì máa wà láàyè nìṣó,
Ó sì dájú pé màá bá yín dá májẹ̀mú tó máa wà títí láé+
Bí mo ṣe fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, tó jẹ́ òótọ́,* hàn sí Dáfídì.+
5 Wò ó! O máa pe orílẹ̀-èdè tí o kò mọ̀,
Àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́ sì máa sáré wá sọ́dọ̀ rẹ,
Torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,
Torí pé ó máa ṣe ọ́ lógo.+
6 Ẹ wá Jèhófà nígbà tí ẹ lè rí i.+
Ẹ pè é nígbà tó wà nítòsí.+
7 Kí èèyàn burúkú fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀,+
Kí ẹni ibi sì yí èrò rẹ̀ pa dà;
Kó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹni tó máa ṣàánú rẹ̀,+
10 Torí bí òjò àti yìnyín ṣe ń rọ̀ láti ọ̀run gẹ́lẹ́,
Tí kì í sì í pa dà síbẹ̀, àfi tó bá mú kí ilẹ̀ rin, tó jẹ́ kó méso jáde, kí nǹkan sì hù,
Tó jẹ́ kí ẹni tó fúnrúgbìn ká irúgbìn, tí ẹni tó ń jẹun sì rí oúnjẹ,
Kò ní pa dà sọ́dọ̀ mi láìṣẹ,+
Àmọ́ ó dájú pé ó máa ṣe ohunkóhun tí inú mi bá dùn sí,*+
Ó sì dájú pé ohun tí mo rán an pé kó ṣe máa yọrí sí rere.