Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí
1 Ìfihàn* látọ̀dọ̀ Jésù Kristi, èyí tí Ọlọ́run fún un,+ kó lè fi àwọn nǹkan tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ han àwọn ẹrú rẹ̀.+ Ó rán áńgẹ́lì rẹ̀ láti fi han ẹrú rẹ̀, Jòhánù,+ nípasẹ̀ àwọn àmì, 2 ẹni tó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fúnni àti sí ẹ̀rí tí Jésù Kristi jẹ́, kódà sí gbogbo ohun tó rí. 3 Aláyọ̀ ni ẹni tó ń ka àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sókè àti àwọn tó ń gbọ́, tí wọ́n sì ń pa àwọn ohun tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́,+ torí àkókò tí a yàn ti sún mọ́.
4 Èmi Jòhánù ń kọ̀wé sí àwọn ìjọ méje+ tó wà ní ìpínlẹ̀ Éṣíà:
Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ “Ẹni tó ti wà tipẹ́, tó wà báyìí, tó sì ń bọ̀”+ àti látọ̀dọ̀ ẹ̀mí méje+ tó wà níwájú ìtẹ́ rẹ̀ 5 àti látọ̀dọ̀ Jésù Kristi, “Ẹlẹ́rìí Olóòótọ́,”+ “àkọ́bí nínú àwọn òkú,”+ àti “Alákòóso àwọn ọba ayé.”+
Ẹni tó nífẹ̀ẹ́ wa,+ tó fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dá wa sílẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa+— 6 tó sì mú ká di ìjọba kan,+ àlùfáà+ fún Ọlọ́run àti Baba rẹ̀—àní, òun ni kí ògo àti agbára jẹ́ tirẹ̀ títí láé. Àmín.
7 Wò ó! Ó ń bọ̀ pẹ̀lú ìkùukùu,*+ gbogbo ojú sì máa rí i, títí kan àwọn tó gún un lọ́kọ̀; ìbànújẹ́ nítorí rẹ̀ sì máa mú kí gbogbo ẹ̀yà tó wà ní ayé lu ara wọn.+ Bẹ́ẹ̀ ni kó rí, Àmín.
8 Jèhófà* Ọlọ́run sọ pé, “Èmi ni Ááfà àti Ómégà,*+ Ẹni tó ti wà tipẹ́, tó wà báyìí, tó sì ń bọ̀, Olódùmarè.”+
9 Èmi Jòhánù, arákùnrin yín, tó bá yín pín nínú ìpọ́njú+ àti ìjọba+ àti ìfaradà+ ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Jésù,+ mo wà ní erékùṣù tí wọ́n ń pè ní Pátímọ́sì torí mò ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, mo sì ń jẹ́rìí nípa Jésù. 10 Mo wà ní ọjọ́ Olúwa nípasẹ̀ ìmísí, mo sì gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn mi tó rinlẹ̀ bíi ti kàkàkí, 11 ó sọ pé: “Kọ ohun tí o rí sínú àkájọ ìwé, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ méje tó wà ní: Éfésù,+ Símínà,+ Págámù,+ Tíátírà,+ Sádísì,+ Filadéfíà+ àti Laodíkíà.”+
12 Mo wẹ̀yìn kí n lè rí ẹni tó ń bá mi sọ̀rọ̀, nígbà tí mo sì wẹ̀yìn, mo rí ọ̀pá fìtílà méje tí wọ́n fi wúrà ṣe,+ 13 ẹnì kan tó dà bí ọmọ èèyàn+ wà láàárín àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ó wọ aṣọ tó balẹ̀ dé ọrùn ẹsẹ̀, ó de ọ̀já wúrà mọ́ àyà rẹ̀. 14 Yàtọ̀ síyẹn, orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú, bíi yìnyín, ojú rẹ̀ sì dà bí ọwọ́ iná tó ń jó fòfò,+ 15 ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bíi bàbà tó dáa gan-an+ tó ń tàn yòò nínú iná ìléru, ohùn rẹ̀ sì dà bí ìró omi tó pọ̀. 16 Ìràwọ̀ méje wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀,+ idà olójú méjì,+ tó mú, tó sì gùn yọ jáde láti ẹnu rẹ̀, ìrísí ojú rẹ̀ sì dà bí oòrùn tó ń mú ganrín-ganrín.+ 17 Nígbà tí mo rí i, mo ṣubú síbi ẹsẹ̀ rẹ̀ bíi pé mo ti kú.
Ó gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó sì sọ pé: “Má bẹ̀rù. Èmi ni Ẹni Àkọ́kọ́+ àti Ẹni Ìkẹyìn+ 18 àti alààyè,+ mo ti kú tẹ́lẹ̀,+ àmọ́ wò ó! mo wà láàyè títí láé àti láéláé,+ mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti Isà Òkú.*+ 19 Torí náà, kọ àwọn ohun tí o rí sílẹ̀ àti àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ àti àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí. 20 Àṣírí mímọ́ ti ìràwọ̀ méje tí o rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi àti ti ọ̀pá fìtílà méje tí wọ́n fi wúrà ṣe náà nìyí: Ìràwọ̀ méje náà túmọ̀ sí àwọn áńgẹ́lì ìjọ méje, ọ̀pá fìtílà méje náà sì túmọ̀ sí ìjọ méje.+