Jóòbù
39 “Ṣé o mọ ìgbà tí àwọn ewúrẹ́ orí òkè máa ń bímọ?+
Ṣé o ti rí àgbọ̀nrín tó ń bímọ rí?+
2 Ṣé o máa ń ka iye oṣù tí wọ́n máa ń lò?
Ṣé o mọ ìgbà tí wọ́n ń bímọ?
3 Wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ tí wọ́n bá ń bímọ,
Ìrora ìrọbí wọn á sì lọ.
4 Àwọn ọmọ wọn máa wá lágbára, wọ́n á sì dàgbà nínú pápá gbalasa;
Wọ́n á jáde lọ, wọn ò sì ní pa dà sọ́dọ̀ wọn mọ́.
6 Mo ti fi aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ṣe ilé rẹ̀,
Mo sì ti fi ilẹ̀ iyọ̀ ṣe ibùgbé rẹ̀.
7 Ó ń pẹ̀gàn rúkèrúdò tó wà nínú ìlú;
Kò sì gbọ́ ariwo darandaran.
8 Ó ń rìn kiri lórí àwọn òkè, ó ń wá ibi ìjẹko,
Ó ń wá gbogbo ewéko tútù.
9 Ṣé akọ màlúù igbó máa fẹ́ sìn ọ́?+
Ṣé ó máa sun ilé ẹran* rẹ mọ́jú?
10 Ṣé o lè fi okùn fa akọ màlúù igbó láàárín poro,
Àbí ó lè tẹ̀ lé ọ lọ túlẹ̀* ní àfonífojì?
11 Ṣé o lè fọkàn tán agbára ńlá rẹ̀,
Kí o sì jẹ́ kó bá ọ ṣe iṣẹ́ alágbára?
12 Ṣé o máa gbára lé e pé kó gbé irè oko* rẹ wá,
Ṣé ó sì máa kó o jọ sí ibi ìpakà rẹ?
13 Ògòǹgò ń fi ayọ̀ lu ìyẹ́ rẹ̀ pìpì,
Àmọ́ ṣé a lè fi àwọn ìyẹ́ tó fi ń fò àti ìyẹ́ tó bo ara rẹ̀ wé ti ẹyẹ àkọ̀?+
14 Torí ilẹ̀ ló máa ń fi ẹyin rẹ̀ sí,
Ó sì ń mú kí wọ́n móoru nínú iyẹ̀pẹ̀.
15 Ó gbàgbé pé àwọn ẹsẹ̀ kan lè tẹ̀ wọ́n fọ́,
Tàbí pé ẹran igbó lè tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.
16 Ó ń ṣe àwọn ọmọ rẹ̀ ṣúkaṣùka, bí ẹni pé òun kọ́ ló bí wọn;+
Kò bẹ̀rù pé làálàá òun lè já sí asán.
18 Àmọ́ tó bá dìde tó sì gbọn ìyẹ́ rẹ̀ pìpì,
Ó máa fi ẹṣin àti ẹni tó gùn ún rẹ́rìn-ín.
19 Ṣé ìwọ lo fún ẹṣin ní agbára?+
Àbí ìwọ lo fi irun* tó ń fẹ́ lẹ́lẹ́ wọ ọrùn rẹ̀ láṣọ?
20 Ṣé o lè mú kó fò sókè bíi tata?
Bó ṣe ń fọn imú rẹ̀ lọ́nà tó gbayì ń kó jìnnìjìnnì báni.+
22 Ó rí ìbẹ̀rù, ó rẹ́rìn-ín, ohunkóhun ò sì já a láyà.+
Kì í torí idà yíjú pa dà.
23 Apó ń mì pẹkẹpẹkẹ sí i,
Ọ̀kọ̀ àti ẹ̀ṣín ń tàn yanran.
24 Bí ara rẹ̀ ṣe ń yá gágá, tó sì ń gbọn ara nù, ó ń bẹ́ gìjà síwájú,*
Kò lè dúró jẹ́ẹ́* tí wọ́n bá fun ìwo.
25 Tí ìwo bá dún, á figbe ta!
Ó ń gbóòórùn ìjà láti òkèèrè,
Ó sì ń gbọ́ ariwo àwọn ọ̀gágun àti igbe ogun.+
26 Ṣé òye rẹ ló ń mú kí àṣáǹwéwé fò lọ sókè réré,
Tó sì ń na ìyẹ́ rẹ̀ sí apá gúúsù?