Sáàmù
Sí olùdarí; kí a yí i sí “Òdòdó Lílì.” Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Másíkílì.* Orin ìfẹ́.
45 Ohun rere kan ń gbé mi lọ́kàn.
Mo sọ pé: “Orin mi dá lórí* ọba kan.”+
Kí ahọ́n mi jẹ́ kálàmù*+ ọ̀jáfáfá adàwékọ.*+
2 Ìwọ lo rẹwà jù lọ nínú àwọn ọmọ èèyàn.
Ọ̀rọ̀ rere ń jáde lẹ́nu rẹ.+
Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi bù kún ọ títí láé.+
4 Nínú ọlá ńlá rẹ, kí o ṣẹ́gun;*+
Máa gẹṣin lọ nítorí òtítọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ àti òdodo,+
Ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì ṣe* àwọn ohun àgbàyanu.
7 O nífẹ̀ẹ́ òdodo,+ o sì kórìíra ìwà burúkú.+
Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ, fi fòróró ayọ̀+ yàn ọ́+ ju àwọn ojúgbà rẹ.
8 Òjíá àti álóè àti kaṣíà ń já fíkán lára gbogbo aṣọ rẹ;
Ìró àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín látinú ààfin títóbi lọ́lá tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ ń mú inú rẹ dùn.
9 Àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba wà lára àwọn obìnrin ọlọ́lá rẹ.
Ayaba* dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ, a fi wúrà Ófírì+ ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́.
10 Gbọ́, ìwọ ọmọbìnrin, fiyè sí i, kí o sì fetí sílẹ̀;
Gbàgbé àwọn èèyàn rẹ àti ilé bàbá rẹ.
14 A ó mú un wá sọ́dọ̀ ọba nínú aṣọ tí a hun dáadáa.*
A ó mú àwọn wúńdíá ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó ń tẹ̀ lé e wọlé síwájú rẹ.
15 A ó mú wọn wá pẹ̀lú ayọ̀ àti ìdùnnú,
Wọ́n á sì wọ ààfin ọba.
16 Àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò gba ipò àwọn baba ńlá rẹ.
Wàá yàn wọ́n ṣe olórí ní gbogbo ayé.+
17 Màá jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ rẹ jálẹ̀ gbogbo ìran tó ń bọ̀.+
Ìdí nìyẹn tí àwọn èèyàn á fi máa yìn ọ́ títí láé àti láéláé.