Ìsíkíẹ́lì
39 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí Gọ́ọ̀gù,+ kí o sì sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò bá ọ jà, Gọ́ọ̀gù, ìwọ olórí ìjòyè* Méṣékì àti Túbálì.+ 2 Èmi yóò mú kí o yíjú pa dà, màá darí rẹ, màá sì mú kí o wá láti ibi tó jìnnà jù ní àríwá,+ èmi yóò sì mú ọ wá sórí àwọn òkè Ísírẹ́lì. 3 Èmi yóò gbá ọrun rẹ dà nù ní ọwọ́ òsì rẹ, èmi yóò sì mú kí àwọn ọfà rẹ já bọ́ kúrò ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ. 4 Ìwọ yóò ṣubú sí orí àwọn òkè Ísírẹ́lì,+ ìwọ àti gbogbo ọmọ ogun rẹ àti àwọn èèyàn tí yóò wà pẹ̀lú rẹ. Màá mú kí onírúurú ẹyẹ aṣọdẹ àti ẹran inú igbó fi ọ́ ṣe oúnjẹ.”’+
5 “‘Wàá ṣubú sórí pápá gbalasa,+ bẹ́ẹ̀ ni mo sọ,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
6 “‘Màá mú kí iná jó Mágọ́gù àti àwọn tó ń gbé àwọn erékùṣù láìséwu,+ wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà. 7 Màá mú kí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì mọ orúkọ mímọ́ mi, mi ò sì tún ní jẹ́ kí wọ́n kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ mi mọ́; àwọn orílẹ̀-èdè á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,+ Ẹni Mímọ́ ní Ísírẹ́lì.’+
8 “‘Àní, ó ń bọ̀, yóò sì ṣẹlẹ̀,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. ‘Ọjọ́ tí mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nìyí. 9 Àwọn tó ń gbé ní àwọn ìlú Ísírẹ́lì yóò jáde lọ, wọ́n á sì fi àwọn ohun ìjà dáná, àwọn asà* àti àwọn apata, àwọn ọrun àti àwọn ọfà, àwọn kóńdó* àti àwọn aṣóró. Wọn yóò sì fi wọ́n dáná+ fún ọdún méje. 10 Wọn kò ní máa lọ ṣa igi lóko tàbí kí wọ́n ṣẹ́gi ìdáná nínú igbó torí àwọn ohun ìjà náà ni wọ́n á fi dáná.’
“‘Wọn yóò kó ẹrù àwọn tó ti kó wọn lẹ́rù rí, wọn yóò sì kó ohun ìní àwọn tó máa ń kó ohun ìní wọn,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
11 “‘Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò yan ibì kan níbẹ̀ ní Ísírẹ́lì tí wọn yóò sin Gọ́ọ̀gù+ sí, ní àfonífojì tí àwọn tó ń rìnrìn àjò ní ìlà oòrùn òkun ń gbà kọjá, yóò sì dí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà kọjá. Ibẹ̀ ni wọn yóò sin Gọ́ọ̀gù àti gbogbo èèyàn rẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ sí, wọ́n á sì máa pe ibẹ̀ ní Àfonífojì Hamoni-Gọ́ọ̀gù.*+ 12 Oṣù méje ni ilé Ísírẹ́lì máa fi sin wọ́n kí wọ́n lè fọ ilẹ̀ náà mọ́.+ 13 Gbogbo èèyàn ilẹ̀ náà ni yóò sin wọ́n, èyí sì máa mú kí wọ́n lókìkí ní ọjọ́ tí mo bá ṣe ara mi lógo,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
14 “‘Wọ́n á yan àwọn èèyàn tí yóò máa lọ káàkiri ilẹ̀ náà, kí wọ́n lè sin àwọn òkú tó ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀, láti fọ ilẹ̀ náà mọ́. Oṣù méje ni wọ́n á fi máa lọ káàkiri. 15 Tí àwọn tó ń lọ káàkiri ilẹ̀ náà bá rí egungun èèyàn, wọ́n á fi àmì kan sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àwọn tí wọ́n yàn láti sin òkú yóò wá lọ sin ín sí Àfonífojì Hamoni-Gọ́ọ̀gù.+ 16 Ìlú kan tún máa wà níbẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ á máa jẹ́ Hámónà.* Wọ́n á sì fọ ilẹ̀ náà mọ́.’+
17 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Sọ fún onírúurú ẹyẹ àti gbogbo ẹran inú igbó pé, “Ẹ kó ara yín jọ, kí ẹ sì wá. Ẹ kóra jọ yí ká ẹbọ mi tí mò ń pèsè fún yín, ẹbọ tó pọ̀ gan-an lórí àwọn òkè Ísírẹ́lì.+ Ẹ ó jẹ ẹran, ẹ ó sì mu ẹ̀jẹ̀.+ 18 Ẹ ó jẹ ẹran àwọn alágbára, ẹ ó sì mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ìjòyè ayé, àwọn àgbò, àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn, àwọn òbúkọ àti àwọn akọ màlúù, gbogbo ẹran Báṣánì tí wọ́n bọ́ sanra. 19 Ẹ ó jẹ ọ̀rá ní àjẹyó, ẹ ó sì mu ẹ̀jẹ̀ yó nínú ẹbọ tí mo pèsè fún yín.”’
20 “‘Ẹ ó jẹ ẹṣin àti àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin, àwọn alágbára àti onírúurú jagunjagun lórí tábìlì mi, ẹ ó sì yó,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
21 “‘Èmi yóò fi ògo mi hàn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì rí ìdájọ́ tí mo ṣe àti bí mo ṣe fi agbára* hàn láàárín wọn.+ 22 Láti ọjọ́ yẹn lọ, ilé Ísírẹ́lì á wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn. 23 Àwọn orílẹ̀-èdè á sì wá mọ̀ pé torí ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì, torí wọ́n hùwà àìṣòótọ́ sí mi ni wọ́n fi lọ sí ìgbèkùn.+ Torí náà, mo fi ojú mi pa mọ́ fún wọn,+ mo fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́,+ idà sì pa gbogbo wọn. 24 Mo fìyà jẹ wọ́n nítorí ìwà àìmọ́ wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn, mo sì fi ojú mi pa mọ́ fún wọn.’
25 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò dá àwọn èèyàn Jékọ́bù tí wọ́n kó lẹ́rú pa dà,+ màá sì ṣàánú gbogbo ilé Ísírẹ́lì;+ èmi yóò fi ìtara gbèjà orúkọ mímọ́ mi.*+ 26 Lẹ́yìn tí wọ́n bá sì ti dójú tì wọ́n torí gbogbo ìwà àìṣòótọ́ tí wọ́n hù sí mi,+ wọn yóò máa gbé lórí ilẹ̀ wọn láìséwu, ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.+ 27 Nígbà tí mo bá mú wọn pa dà láti ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn, tí mo sì kó wọn jọ láti ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn,+ èmi yóò tún mú kí wọ́n mọ̀ pé ẹni mímọ́ ni mí lójú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.’+
28 “‘Wọ́n á wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn nígbà tí mo bá mú kí wọ́n lọ sí ìgbèkùn ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì kó wọn jọ pa dà sórí ilẹ̀ wọn, láìfi ìkankan nínú wọn sílẹ̀.+ 29 Mi ò ní fi ojú mi pa mọ́ fún wọn mọ́,+ torí màá tú ẹ̀mí mi sórí ilé Ísírẹ́lì,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”