Àìsáyà
3 Ìbẹ̀rù Jèhófà máa jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.+
Kò ní gbé ìdájọ́ rẹ̀ ka ohun tó fojú rí,
Kò sì ní gbé ìbáwí rẹ̀ ka ohun tó fetí gbọ́ lásán.+
4 Ó máa dá ẹjọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀ bó ṣe tọ́,*
Ó sì máa fi òtítọ́ báni wí torí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ tó wà ní ayé.
6 Ìkookò máa bá ọ̀dọ́ àgùntàn gbé fúngbà díẹ̀,+
Àmọ̀tẹ́kùn máa dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́,
Ọmọ màlúù, kìnnìún* àti ẹran tó sanra á jọ wà pa pọ̀;*+
Ọmọ kékeré á sì máa dà wọ́n.
7 Màlúù àti bíárì á jọ máa jẹun,
Àwọn ọmọ wọn á sì jọ dùbúlẹ̀.
Kìnnìún máa jẹ pòròpórò bí akọ màlúù.+
8 Ọmọ ẹnu ọmú máa ṣeré lórí ihò ṣèbé,
Ọmọ tí wọ́n ti gba ọmú lẹ́nu rẹ̀ sì máa fọwọ́ sí ihò ejò olóró.
9 Wọn ò ní fa ìpalára kankan,+
Tàbí ìparun kankan ní gbogbo òkè mímọ́ mi,+
Torí ó dájú pé ìmọ̀ Jèhófà máa bo ayé,
Bí omi ṣe ń bo òkun.+
10 Ní ọjọ́ yẹn, gbòǹgbò Jésè+ máa dúró bí àmì* fún àwọn èèyàn.+
11 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà tún máa na ọwọ́ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, láti gba àṣẹ́kù àwọn èèyàn rẹ̀ pa dà, àwọn tó ṣẹ́ kù láti Ásíríà,+ Íjíbítì,+ Pátírọ́sì,+ Kúṣì,+ Élámù,+ Ṣínárì,* Hámátì àti àwọn erékùṣù òkun.+ 12 Ó máa gbé àmì* kan sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè, ó sì máa kó àwọn tó fọ́n ká lára Ísírẹ́lì jọ,+ ó máa kó àwọn tó tú ká lára Júdà jọ láti ìkángun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé.+
Éfúrémù ò ní jowú Júdà,
Júdà ò sì ní fi ẹ̀tanú hàn sí Éfúrémù.+
14 Wọ́n máa já ṣòòrò wálẹ̀ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́* àwọn Filísínì lápá ìwọ̀ oòrùn;
Wọ́n jọ máa kó ẹrù àwọn ará Ìlà Oòrùn.