Dáníẹ́lì
7 Ní ọdún kìíní Bẹliṣásárì+ ọba Bábílónì, Dáníẹ́lì lá àlá, ó sì rí àwọn ìran nígbà tó dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn rẹ̀.+ Ó wá kọ àlá náà sílẹ̀;+ ó kọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 2 Dáníẹ́lì sọ pé:
“Mò ń wò nínú ìran tí mo rí ní òru, sì wò ó! atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run ń ru alagbalúgbú òkun sókè.+ 3 Ẹranko ńlá mẹ́rin+ sì jáde látinú òkun, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yàtọ̀ síra.
4 “Èyí àkọ́kọ́ dà bíi kìnnìún,+ ó sì ní ìyẹ́ idì.+ Mò ń wò ó títí a fi fa ìyẹ́ rẹ̀ tu, a sì gbé e sókè lórí ayé, a mú kó fi ẹsẹ̀ méjì dúró bí èèyàn, a sì fún un ní ọkàn èèyàn.
5 “Wò ó! ẹranko míì, èkejì, ó dà bíi bíárì.+ A gbé e sókè lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, egungun ìhà mẹ́ta sì wà ní ẹnu rẹ̀ láàárín eyín rẹ̀; a sì sọ fún un pé, ‘Dìde, jẹ ẹran púpọ̀.’+
6 “Lẹ́yìn èyí, mò ń wò, sì wò ó! ẹranko míì tó dà bí àmọ̀tẹ́kùn,+ àmọ́ tó ní ìyẹ́ mẹ́rin bíi ti ẹyẹ ní ẹ̀yìn rẹ̀. Ẹranko náà ní orí mẹ́rin,+ a sì fún un ní àṣẹ láti ṣàkóso.
7 “Lẹ́yìn èyí, mò ń wò nínú ìran òru, mo sì rí ẹranko kẹrin, ó ń bani lẹ́rù, ó sì ń dáyà jáni, agbára rẹ̀ ṣàrà ọ̀tọ̀, ó sì ní eyín ńlá tó jẹ́ irin. Ó ń jẹ nǹkan run, ó ń fọ́ nǹkan túútúú, ó sì ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ ohun tó ṣẹ́ kù mọ́lẹ̀.+ Ó yàtọ̀ sí gbogbo ẹranko yòókù tó wà ṣáájú rẹ̀, ó sì ní ìwo mẹ́wàá. 8 Bí mo ṣe ń ronú nípa àwọn ìwo náà, wò ó! ìwo míì tó kéré + jáde láàárín wọn, a sì fa mẹ́ta lára àwọn ìwo àkọ́kọ́ tu kúrò níwájú rẹ̀. Wò ó! ojú tó dà bíi ti èèyàn wà lára ìwo yìí, ó sì ní ẹnu tó ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga.*+
9 “Mò ń wò títí a fi gbé àwọn ìtẹ́ kalẹ̀, tí Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé+ sì jókòó.+ Aṣọ rẹ̀ funfun bíi yìnyín,+ irun orí rẹ̀ sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ọwọ́ iná ni ìtẹ́ rẹ̀; iná tó ń jó ni àgbá kẹ̀kẹ́ rẹ̀.+ 10 Iná ń ṣàn jáde lọ níwájú rẹ̀.+ Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì dúró níwájú rẹ̀.+ Kọ́ọ̀tù+ jókòó, a sì ṣí àwọn ìwé.
11 “Mò ń wò nígbà yẹn torí bí mo ṣe ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìgbéraga* tí ìwo náà ń sọ;+ mò ń wò ó títí a fi pa ẹranko náà, tí a pa ara rẹ̀ run, a sì jù ú sínú iná kó lè jó o. 12 Àmọ́ ní ti àwọn ẹranko yòókù,+ a gba àkóso lọ́wọ́ wọn, a sì mú kí ẹ̀mí wọn gùn sí i fún ìgbà kan àti àsìkò kan.
13 “Mò ń wò nínú ìran òru, sì wò ó! ẹnì kan bí ọmọ èèyàn+ ń bọ̀ pẹ̀lú ìkùukùu* ojú ọ̀run; a jẹ́ kó wọlé wá sọ́dọ̀ Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,+ wọ́n sì mú un wá sún mọ́ iwájú Ẹni yẹn. 14 A sì fún un ní àkóso,+ ọlá+ àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn èèyàn, orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà máa sìn ín.+ Àkóso rẹ̀ jẹ́ àkóso tó máa wà títí láé, tí kò ní kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ ò sì ní pa run.+
15 “Ní ti èmi, Dáníẹ́lì, ìdààmú bá ẹ̀mí mi nínú mi, torí àwọn ìran tí mo rí dẹ́rù bà mí.+ 16 Mo sún mọ́ ọ̀kan lára àwọn tó dúró síbẹ̀, kí n lè bi í ní ohun tí èyí túmọ̀ sí gan-an. Ó dá mi lóhùn, ó sì sọ ìtumọ̀ àwọn nǹkan yìí fún mi.
17 “‘Ẹranko ńlá mẹ́rin+ yìí ni ọba mẹ́rin tó máa dìde ní ayé.+ 18 Àmọ́ àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ+ máa gba ìjọba,+ ìjọba náà sì máa jẹ́ tiwọn+ títí láé, àní títí láé àti láéláé.’
19 “Mo fẹ́ mọ̀ sí i nípa ẹranko kẹrin, tó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn yòókù; ó ń bani lẹ́rù lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó ní eyín irin àti èékánná bàbà, ó ń jẹ nǹkan run, ó ń fọ́ nǹkan túútúú, ó sì ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ ohun tó ṣẹ́ kù mọ́lẹ̀;+ 20 àti nípa ìwo mẹ́wàá+ tó wà ní orí rẹ̀ àti ìwo míì tó jáde, tí mẹ́ta sì ṣubú níwájú rẹ̀,+ ìwo tó ní ojú àti ẹnu tó ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìgbéraga,* tí ìrísí rẹ̀ sì tóbi ju ti àwọn yòókù.
21 “Mò ń wò ó bí ìwo yẹn ṣe bá àwọn ẹni mímọ́ jagun, ó sì ń borí wọn,+ 22 títí Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé+ fi dé, tí a sì dá àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ láre,+ àkókò tí a yàn pé kí àwọn ẹni mímọ́ gba ìjọba sì dé.+
23 “Ohun tó sọ nìyí: ‘Ní ti ẹranko kẹrin, ìjọba kẹrin máa wà ní ayé. Ó máa yàtọ̀ sí gbogbo ìjọba yòókù, ó máa jẹ gbogbo ayé run, ó máa tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, ó sì máa fọ́ ọ túútúú.+ 24 Ní ti ìwo mẹ́wàá náà, ọba mẹ́wàá máa dìde látinú ìjọba yẹn, òmíràn tún máa dìde lẹ́yìn wọn, ó máa yàtọ̀ sí àwọn ti àkọ́kọ́, ó sì máa rẹ ọba mẹ́ta wálẹ̀.+ 25 Ó máa sọ̀rọ̀ sí Ẹni Gíga Jù Lọ,+ á sì máa fòòró àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ. Ó máa gbèrò láti yí àwọn àkókò àti òfin pa dà, a sì máa fi wọ́n lé e lọ́wọ́ fún àkókò kan, àwọn àkókò àti ààbọ̀ àkókò.*+ 26 Àmọ́ Kọ́ọ̀tù jókòó, wọ́n gba àkóso lọ́wọ́ rẹ̀, kí wọ́n lè pa á rẹ́, kí wọ́n sì pa á run pátápátá.+
27 “‘A sì fún àwọn èèyàn tó jẹ́ ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ ní ìjọba, àkóso àti títóbi àwọn ìjọba lábẹ́ gbogbo ọ̀run.+ Ìjọba tó máa wà títí láé ni ìjọba wọn,+ gbogbo ìjọba á máa sìn wọ́n, wọ́n á sì máa ṣègbọràn sí wọn.’
28 “Òpin ọ̀rọ̀ náà nìyí. Ní ti èmi, Dáníẹ́lì, èrò ọkàn mi dẹ́rù bà mí gan-an, débi pé ara mi funfun;* àmọ́ mo fi ọ̀rọ̀ náà pa mọ́ sínú ọkàn mi.”