Àwọn Ọba Kìíní
12 Rèhóbóámù lọ sí Ṣékémù, nítorí gbogbo Ísírẹ́lì ti wá sí Ṣékémù+ láti fi í jọba.+ 2 Gbàrà tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì gbọ́ (ó ṣì wà ní Íjíbítì torí ó sá lọ nítorí Ọba Sólómọ́nì, ó sì ń gbé ní Íjíbítì),+ 3 wọ́n ránṣẹ́ pè é. Lẹ́yìn náà, Jèróbóámù àti gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì wá bá Rèhóbóámù, wọ́n sì sọ pé: 4 “Bàbá rẹ mú kí àjàgà wa wúwo.+ Àmọ́ tí o bá mú kí iṣẹ́ tó nira tí bàbá rẹ fún wa rọ̀ wá lọ́rùn, tí o sì mú kí àjàgà tó wúwo* tó fi kọ́ wa lọ́rùn fúyẹ́, a ó máa sìn ọ́.”
5 Ló bá sọ fún wọn pé: “Ẹ máa lọ, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta; kí ẹ pa dà wá.” Torí náà, àwọn èèyàn náà lọ.+ 6 Ọba Rèhóbóámù wá fọ̀rọ̀ lọ àwọn àgbà ọkùnrin* tó bá Sólómọ́nì bàbá rẹ̀ ṣiṣẹ́ nígbà tó wà láàyè, ó ní: “Ẹ gbà mí nímọ̀ràn, èsì wo ni ká fún àwọn èèyàn yìí?” 7 Wọ́n dá a lóhùn pé: “Tí o bá sọ ara rẹ di ìránṣẹ́ àwọn èèyàn yìí lónìí, tí o ṣe ohun tí wọ́n fẹ́, tí o sì fún wọn ní èsì rere, ìwọ ni wọ́n á máa sìn títí lọ.”
8 Àmọ́, ó kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbà ọkùnrin* fún un, ó sì fọ̀rọ̀ lọ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jọ dàgbà, àmọ́ tí wọ́n ti di ẹmẹ̀wà* rẹ̀ báyìí.+ 9 Ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ẹ gbà mí nímọ̀ràn, èsì wo ni ká fún àwọn èèyàn tó sọ fún mi pé, ‘Mú kí àjàgà tí bàbá rẹ fi kọ́ wa lọ́rùn fúyẹ́’?” 10 Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jọ dàgbà sọ fún un pé: “Èyí ni ohun tí o máa sọ fún àwọn èèyàn tó sọ fún ọ pé, ‘Bàbá rẹ mú kí àjàgà wa wúwo, ṣùgbọ́n mú kí ó fúyẹ́ lọ́rùn wa’; ohun tí wàá sọ fún wọn ni pé, ‘Ọmọ ìka ọwọ́ mi tó kéré jù* yóò nípọn ju ìbàdí bàbá mi lọ. 11 Bàbá mi fi àjàgà tó wúwo kọ́ yín lọ́rùn, àmọ́ ńṣe ni màá fi kún àjàgà yín. Pàṣán ni bàbá mi fi nà yín, ṣùgbọ́n kòbókò oníkókó ni màá fi nà yín.’”
12 Jèróbóámù àti gbogbo àwọn èèyàn náà wá bá Rèhóbóámù ní ọjọ́ kẹta, bí ọba ṣe sọ pé: “Ẹ pa dà wá bá mi ní ọjọ́ kẹta.”+ 13 Àmọ́, ńṣe ni ọba jágbe mọ́ àwọn èèyàn náà, kò gba ìmọ̀ràn tí àwọn àgbà ọkùnrin* fún un. 14 Ìmọ̀ràn tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin fún un ló tẹ̀ lé, ó sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Bàbá mi mú kí àjàgà yín wúwo, ṣùgbọ́n ṣe ni màá fi kún àjàgà yín. Pàṣán ni bàbá mi fi nà yín, ṣùgbọ́n kòbókò oníkókó ni màá fi nà yín.” 15 Nítorí náà, ọba ò fetí sí àwọn èèyàn náà, torí pé Jèhófà ló mú kí ìyípadà náà wáyé,+ kí ọ̀rọ̀ Jèhófà lè ṣẹ, èyí tó gbẹnu Áhíjà+ ọmọ Ṣílò sọ fún Jèróbóámù ọmọ Nébátì.
16 Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì rí i pé ọba ò gbọ́ tiwọn, àwọn èèyàn náà fún ọba lésì pé: “Kí ló pa àwa àti Dáfídì pọ̀? A ò ní ogún kankan nínú ọmọ Jésè. Lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì. Máa mójú tó ilé ara rẹ, ìwọ Dáfídì!” Bí Ísírẹ́lì ṣe pa dà sí ilé* wọn nìyẹn.+ 17 Àmọ́ Rèhóbóámù ń jọba nìṣó lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń gbé ní àwọn ìlú Júdà.+
18 Lẹ́yìn náà, Ọba Rèhóbóámù rán Ádórámù,+ ẹni tó jẹ́ olórí àwọn tí ọba ní kó máa ṣiṣẹ́ fún òun sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n gbogbo Ísírẹ́lì sọ ọ́ ní òkúta pa. Agbára káká ni Ọba Rèhóbóámù fi rọ́nà gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ láti sá lọ sí Jerúsálẹ́mù.+ 19 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń ṣọ̀tẹ̀+ sí ilé Dáfídì títí di òní yìí.
20 Gbàrà tí gbogbo Ísírẹ́lì gbọ́ pé Jèróbóámù ti pa dà dé, wọ́n pè é wá sí àpéjọ, wọ́n sì fi jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.+ Kò sí ìkankan lára àwọn èèyàn náà tó wà lẹ́yìn ilé Dáfídì àfi ẹ̀yà Júdà.+
21 Nígbà tí Rèhóbóámù dé Jerúsálẹ́mù, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló pe gbogbo ilé Júdà àti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì jọ, ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án (180,000) akọgun,* láti bá ilé Ísírẹ́lì jà, kí wọ́n lè gba ipò ọba pa dà fún Rèhóbóámù ọmọ Sólómọ́nì.+ 22 Ìgbà náà ni Ọlọ́run tòótọ́ bá Ṣemáyà,+ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ sọ̀rọ̀, ó ní: 23 “Sọ fún Rèhóbóámù ọmọ Sólómọ́nì ọba Júdà àti gbogbo ilé Júdà àti Bẹ́ńjámínì pẹ̀lú ìyókù àwọn èèyàn náà pé, 24 ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ lọ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn arákùnrin yín jà. Kí kálukú yín pa dà sí ilé rẹ̀, torí èmi ló mú kí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀.”’”+ Nítorí náà, wọ́n ṣe ohun tí Jèhófà sọ, wọ́n sì pa dà sílé bí Jèhófà ṣe sọ fún wọn.
25 Jèróbóámù wá kọ́* Ṣékémù+ ní agbègbè olókè Éfúrémù, ó sì ń gbé ibẹ̀. Láti ibẹ̀, ó lọ kọ́* Pénúélì.+ 26 Jèróbóámù sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: “Ní báyìí, ìjọba náà máa pa dà sí ilé Dáfídì.+ 27 Torí bí àwọn èèyàn yìí bá ṣì ń lọ rú ẹbọ ní ilé Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù,+ ọkàn wọn máa pa dà sọ́dọ̀ olúwa wọn, Rèhóbóámù ọba Júdà. Ó dájú pé wọ́n á pa mí, wọ́n á sì pa dà sọ́dọ̀ Rèhóbóámù ọba Júdà.” 28 Lẹ́yìn tí ọba gba ìmọ̀ràn, ó ṣe ère ọmọ màlúù wúrà méjì,+ ó sì sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Wàhálà yìí ti pọ̀ jù fún yín láti máa lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ọlọ́run rẹ rèé, ìwọ Ísírẹ́lì, tí ó mú ọ jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.”+ 29 Ìgbà náà ni ó gbé ọ̀kan sí Bẹ́tẹ́lì,+ ó sì gbé ìkejì sí Dánì.+ 30 Nǹkan yìí mú kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀,+ àwọn èèyàn náà sì lọ títí dé Dánì kí wọ́n lè jọ́sìn èyí tó wà níbẹ̀.
31 Ó kọ́ àwọn ilé ìjọsìn sórí àwọn ibi gíga, ó sì yan àwọn àlùfáà látinú gbogbo àwọn èèyàn náà, àwọn tí kì í ṣe ọmọ Léfì.+ 32 Jèróbóámù tún dá àjọyọ̀ kan sílẹ̀ ní oṣù kẹjọ, ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù náà, bí àjọyọ̀ tó wà ní Júdà.+ Ó rú ẹbọ sí àwọn ère ọmọ màlúù tó ṣe sórí àwọn pẹpẹ tó ṣe ní Bẹ́tẹ́lì,+ ó sì yan àwọn àlùfáà ní Bẹ́tẹ́lì fún àwọn ibi gíga tó ṣe. 33 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn ọrẹ wá sórí pẹpẹ tó ṣe ní Bẹ́tẹ́lì ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún ní oṣù kẹjọ, ní oṣù tí òun fúnra rẹ̀ yàn; ó dá àjọyọ̀ kan sílẹ̀ fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì, ó sì lọ sórí pẹpẹ láti mú ọrẹ àti ẹbọ rú èéfín.