Kíróníkà Kejì
29 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni Hẹsikáyà+ nígbà tó jọba, ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ábíjà ọmọ Sekaráyà.+ 2 Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà,+ bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+ 3 Ní ọdún kìíní ìjọba rẹ̀, ní oṣù kìíní, ó ṣí àwọn ilẹ̀kùn ilé Jèhófà, ó sì tún wọn ṣe.+ 4 Lẹ́yìn náà, ó mú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì wọlé, ó sì kó wọn jọ sí ibi gbayawu ní apá ìlà oòrùn. 5 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin ọmọ Léfì. Ní báyìí, ẹ ya ara yín sí mímọ́,+ kí ẹ ya ilé Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín sí mímọ́, kí ẹ sì mú ohun àìmọ́ kúrò nínú ibi mímọ́.+ 6 Nítorí àwọn bàbá wa ti hùwà àìṣòótọ́, wọ́n sì ti ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà Ọlọ́run wa.+ Wọ́n fi í sílẹ̀, wọ́n yí ojú wọn kúrò níbi àgọ́ ìjọsìn Jèhófà, wọ́n sì kẹ̀yìn sí i.+ 7 Bákan náà, wọ́n ti àwọn ilẹ̀kùn ibi àbáwọlé,*+ wọ́n sì pa àwọn fìtílà.+ Wọn kò sun tùràrí mọ́,+ wọn kò sì rú ẹbọ sísun+ ní ibi mímọ́ sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì. 8 Jèhófà bínú sí Júdà àti Jerúsálẹ́mù,+ ó sì sọ wọ́n di ohun àríbẹ̀rù, ohun ìyàlẹ́nu àti ẹni àrísúfèé,* bí ẹ̀yin náà ṣe fojú ara yín rí i.+ 9 Idà ti pa àwọn baba ńlá wa,+ àwọn ọmọkùnrin wa, àwọn ọmọbìnrin wa àti àwọn ìyàwó wa sì ti lọ sóko ẹrú nítorí nǹkan yìí.+ 10 Ní báyìí, ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn mi láti bá Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú,+ kí ìbínú rẹ̀ tó ń jó bí iná lè kúrò lórí wa. 11 Ẹ̀yin ọmọ mi, kì í ṣe àkókò yìí ló yẹ ká dẹra nù,* nítorí Jèhófà ti yàn yín láti máa dúró níwájú rẹ̀, kí ẹ lè máa ṣe ìránṣẹ́ fún un,+ kí ẹ sì lè máa mú àwọn ẹbọ rẹ̀ rú èéfín.”+
12 Ni àwọn ọmọ Léfì bá dìde, àwọn ni: Máhátì ọmọ Ámásáì àti Jóẹ́lì ọmọ Asaráyà tó wá látinú àwọn ọmọ Kóhátì;+ látinú àwọn ọmọ Mérárì,+ Kíṣì ọmọ Ábídì àti Asaráyà ọmọ Jéhálélélì; látinú àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì,+ Jóà ọmọ Símà àti Édẹ́nì ọmọ Jóà; 13 látinú àwọn ọmọ Élísáfánì, Ṣímúrì àti Júẹ́lì; látinú àwọn ọmọ Ásáfù,+ Sekaráyà àti Matanáyà; 14 látinú àwọn ọmọ Hémánì,+ Jéhíélì àti Ṣíméì; látinú àwọn ọmọ Jédútúnì,+ Ṣemáyà àti Úsíélì. 15 Nígbà náà, wọ́n kó àwọn arákùnrin wọn jọ, wọ́n ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ọba pa láṣẹ, láti fọ ilé Jèhófà mọ́.+ 16 Lẹ́yìn náà, àwọn àlùfáà wọ inú ilé Jèhófà láti ṣe ìwẹ̀mọ́, wọ́n sì kó gbogbo ohun àìmọ́ tí wọ́n rí nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà jáde sí àgbàlá+ ilé Jèhófà. Àwọn ọmọ Léfì wá kó wọn, wọ́n sì gbé wọn jáde lọ sí Àfonífojì Kídírónì.+ 17 Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ ìyàsímímọ́ ní ọjọ́ kìíní oṣù kìíní nìyẹn, ní ọjọ́ kẹjọ oṣù náà, wọ́n dé ibi tí wọ́n ń gbà wọ* ilé Jèhófà.+ Wọ́n fi ọjọ́ mẹ́jọ ya ilé Jèhófà sí mímọ́, wọ́n sì parí rẹ̀ ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kìíní.
18 Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n lọ sọ́dọ̀ Ọba Hẹsikáyà, wọ́n sọ pé: “A ti fọ gbogbo ilé Jèhófà mọ́, pẹpẹ ẹbọ sísun+ pẹ̀lú gbogbo nǹkan èlò rẹ̀+ àti tábìlì búrẹ́dì onípele*+ pẹ̀lú gbogbo nǹkan èlò rẹ̀. 19 A ti ṣètò gbogbo nǹkan èlò tí Ọba Áhásì pa tì lákòókò ìjọba rẹ̀ nígbà tó hùwà àìṣòótọ́,+ a ti yà wọ́n sí mímọ́,+ wọ́n sì wà níwájú pẹpẹ Jèhófà.”
20 Ọba Hẹsikáyà dìde ní àárọ̀ kùtù, ó kó àwọn ìjòyè ìlú jọ, wọ́n sì lọ sí ilé Jèhófà. 21 Wọ́n mú akọ màlúù méje wá àti àgbò méje àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ méje gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba náà àti fún ibi mímọ́ àti fún Júdà.+ Nítorí náà, ó sọ fún àwọn àlùfáà, ìyẹn àwọn àtọmọdọ́mọ Áárónì pé kí wọ́n fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ Jèhófà. 22 Nígbà náà, wọ́n pa àwọn màlúù náà,+ àwọn àlùfáà gba ẹ̀jẹ̀ wọn, wọ́n sì wọ́n ọn sórí pẹpẹ;+ lẹ́yìn náà, wọ́n pa àwọn àgbò náà, wọ́n sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn sórí pẹpẹ, wọ́n pa àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn náà, wọ́n sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn sórí pẹpẹ. 23 Lẹ́yìn náà, wọ́n mú àwọn akọ ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá síwájú ọba àti ìjọ náà, wọ́n sì gbé ọwọ́ lé wọn. 24 Àwọn àlùfáà pa wọ́n, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lórí pẹpẹ, láti ṣe ètùtù fún gbogbo Ísírẹ́lì, nítorí ọba ti sọ pé gbogbo Ísírẹ́lì ni kí ẹbọ sísun náà àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà wà fún.
25 Ní àkókò yìí, ó ní kí àwọn ọmọ Léfì dúró sí ilé Jèhófà, pẹ̀lú síńbálì* àti àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù,+ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dáfídì + àti ti Gádì+ aríran ọba àti ti wòlíì Nátánì,+ nítorí pé Jèhófà ló pa àṣẹ náà nípasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀. 26 Nítorí náà, àwọn ọmọ Léfì dúró pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin Dáfídì lọ́wọ́, àwọn àlùfáà sì dúró pẹ̀lú kàkàkí lọ́wọ́.+
27 Nígbà náà, Hẹsikáyà pàṣẹ pé kí wọ́n rú ẹbọ sísun náà lórí pẹpẹ.+ Nígbà tí ẹbọ sísun náà bẹ̀rẹ̀, orin Jèhófà bẹ̀rẹ̀, kàkàkí sì bẹ̀rẹ̀ sí í dún, wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn ohun ìkọrin Dáfídì ọba Ísírẹ́lì. 28 Gbogbo ìjọ náà forí balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń kọrin, tí kàkàkí sì ń dún, gbogbo èyí ń bá a lọ títí ẹbọ sísun náà fi parí. 29 Gbàrà tí wọ́n parí ẹbọ rírú, ọba àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ wólẹ̀, wọ́n sì dojú bolẹ̀. 30 Ọba Hẹsikáyà àti àwọn ìjòyè wá sọ fún àwọn ọmọ Léfì pé kí wọ́n fi àwọn ọ̀rọ̀ Dáfídì+ àti ti Ásáfù+ aríran yin Jèhófà. Nítorí náà, wọ́n kọrin ìyìn tayọ̀tayọ̀, wọ́n wólẹ̀, wọ́n sì dojú bolẹ̀.
31 Lẹ́yìn náà, Hẹsikáyà sọ pé: “Ní báyìí tí a ti yà yín sọ́tọ̀* fún Jèhófà, ẹ mú àwọn ẹbọ àti àwọn ẹbọ ìdúpẹ́ wá sí ilé Jèhófà.” Ni ìjọ náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn ẹbọ àti àwọn ẹbọ ìdúpẹ́ wá, gbogbo ẹni tí ọkàn rẹ̀ múra tán sì mú àwọn ẹbọ sísun wá.+ 32 Iye ẹran ẹbọ sísun tí ìjọ náà mú wá jẹ́ àádọ́rin (70) màlúù, ọgọ́rùn-ún (100) àgbò, igba (200) akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, gbogbo èyí ni wọ́n fi rú ẹbọ sísun sí Jèhófà,+ 33 ọrẹ mímọ́ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) màlúù àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àgùntàn. 34 Àmọ́ kò sí àwọn àlùfáà tó pọ̀ tó láti bó awọ gbogbo ẹran ẹbọ sísun náà, torí náà, àwọn arákùnrin wọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì ràn wọ́n lọ́wọ́+ títí iṣẹ́ náà fi parí àti títí àwọn àlùfáà fi parí yíya ara wọn sí mímọ́,+ nítorí ó jẹ àwọn ọmọ Léfì lọ́kàn* láti ya ara wọn sí mímọ́ ju bó ṣe jẹ àwọn àlùfáà lọ́kàn lọ. 35 Bákan náà, ọ̀pọ̀ ẹbọ sísun ló wà,+ títí kan àwọn ibi tó lọ́ràá lára àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ àti àwọn ọrẹ ohun mímu fún àwọn ẹbọ sísun.+ Bí wọ́n ṣe mú iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà pa dà bọ̀ sípò* nìyẹn. 36 Nítorí náà, Hẹsikáyà àti gbogbo àwọn èèyàn náà yọ̀ lórí ohun tí Ọlọ́run tòótọ́ ṣe fún àwọn èèyàn náà,+ torí pé láìròtẹ́lẹ̀ ni gbogbo nǹkan yìí ṣẹlẹ̀.