Oníwàásù
5 Ṣọ́ ẹsẹ̀ rẹ nígbàkigbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọ́run tòótọ́;+ ó sàn kéèyàn wá fetí sílẹ̀+ ju kó mú ẹbọ wá bí àwọn òmùgọ̀ ti ń ṣe,+ nítorí wọn ò mọ̀ pé ohun tí wọ́n ń ṣe kò dáa.
2 Má ṣe yánu sọ̀rọ̀ tàbí kí ọkàn rẹ sọ̀rọ̀ láìronú níwájú Ọlọ́run tòótọ́,+ nítorí Ọlọ́run tòótọ́ wà ní ọ̀run àmọ́ ìwọ wà ní ayé. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ níwọ̀n.+ 3 Nítorí ọ̀pọ̀ iṣẹ́* máa ń mú kí èèyàn lá àlá,+ àpọ̀jù ọ̀rọ̀+ sì máa ń mú kí àwọn òmùgọ̀ máa wí ìrégbè. 4 Nígbàkigbà tí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Ọlọ́run, má fi falẹ̀, san án,+ nítorí inú rẹ̀ kì í dùn sí àwọn òmùgọ̀.+ Ohun tí o jẹ́jẹ̀ẹ́, san án.+ 5 Ó sàn kí o má ṣe jẹ́jẹ̀ẹ́ ju pé kí o jẹ́jẹ̀ẹ́, kí o má sì san án.+ 6 Má ṣe jẹ́ kí ẹnu rẹ mú ọ* dẹ́ṣẹ̀,+ má sì sọ níwájú áńgẹ́lì* pé àṣìṣe ni.+ Kí nìdí tí wàá fi mú Ọlọ́run tòótọ́ bínú nítorí ohun tí o sọ, tí á sì pa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ run?+ 7 Nítorí bí ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ṣe ń mú kí èèyàn lá àlá,+ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ púpọ̀ ṣe ń já sí asán. Àmọ́, Ọlọ́run tòótọ́ ni kí o bẹ̀rù.+
8 Tí o bá rí i tí wọ́n ń ni àwọn aláìní lára tàbí tí wọ́n ń tẹ ìdájọ́ òdodo àti òtítọ́ lójú ní agbègbè rẹ, má ṣe jẹ́ kó yà ọ́ lẹ́nu.+ Torí ẹnì kan wà tó ń ṣọ́ ẹni tó wà nípò gíga, ẹni yẹn sì ga jù ú lọ, síbẹ̀ àwọn míì tún wà tó ga jù wọ́n lọ.
9 Bákan náà, wọ́n pín èrè ilẹ̀ náà láàárín ara wọn; kódà inú oko ni oúnjẹ ọba ti ń wá.+
10 Fàdákà kì í tó ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni owó kì í tó ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀.+ Asán ni èyí pẹ̀lú.+
11 Nígbà tí ohun rere bá pọ̀ sí i, àwọn tó ń jẹ ẹ́ á pọ̀ sí i.+ Àǹfààní wo ló sì jẹ́ fún ẹni tó ní in ju pé kó máa fi ojú rẹ̀ wò ó?+
12 Oorun ẹni tó ń sìn máa ń dùn, bóyá oúnjẹ díẹ̀ ló jẹ tàbí púpọ̀, àmọ́ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ọlọ́rọ̀ ní kì í jẹ́ kó rí oorun sùn.
13 Àdánù* ńlá kan wà tí mo ti rí lábẹ́ ọ̀run:* ọrọ̀ tí àwọn ọlọ́rọ̀ kó pa mọ́ fún ìpalára ara wọn. 14 Àwọn ọrọ̀ yẹn ṣègbé nítorí òwò* àṣedànù, nígbà tó sì bímọ, kò ní ohun ìní kankan lọ́wọ́ mọ́.+
15 Bí èèyàn ṣe jáde wá látinú ìyá rẹ̀ ní ìhòòhò, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe lọ.+ Kò lè mú ohunkóhun lọ nínú gbogbo iṣẹ́ àṣekára tó ti ṣe.+
16 Èyí pẹ̀lú jẹ́ àdánù* ńlá: Bí ẹni náà ṣe wá gẹ́lẹ́, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa lọ; èrè wo ló sì wà fún ẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára lórí asán?+ 17 Yàtọ̀ síyẹn, ojoojúmọ́ ló ń jẹun nínú òkùnkùn pẹ̀lú ìbànújẹ́ ńlá àti àìsàn àti ìbínú.+
18 Ohun tí mo rí pé ó dára tí ó sì tọ́ ni pé: kéèyàn máa jẹ, kó máa mu, kó sì jẹ ìgbádùn gbogbo iṣẹ́ àṣekára+ tó fi gbogbo agbára rẹ̀ ṣe lábẹ́ ọ̀run* láàárín ọjọ́ díẹ̀ tí Ọlọ́run tòótọ́ fún un, nítorí èrè* rẹ̀ nìyẹn.+ 19 Bákan náà, nígbà tí Ọlọ́run tòótọ́ bá fún ẹnì kan ní ọrọ̀ àti ohun ìní,+ tó sì jẹ́ kó lè gbádùn wọn, kí ẹni náà gba èrè* rẹ̀ kó sì máa yọ̀ nínú iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí.+ 20 Torí bóyá ló fi máa mọ̀* pé ọjọ́ ayé òun ń lọ, nítorí Ọlọ́run tòótọ́ ti mú kí ayọ̀ gbà á lọ́kàn.+