113 Ẹ yin Jáà!
Ẹ mú ìyìn wá, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Jèhófà,
Ẹ yin orúkọ Jèhófà.
2 Kí á máa yin orúkọ Jèhófà
Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.+
3 Láti yíyọ oòrùn títí dé wíwọ̀ rẹ̀,
Kí á máa yin orúkọ Jèhófà.+
4 Jèhófà ga ju gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè;+
Ògo rẹ̀ ga ju ọ̀run lọ.+
5 Ta ló dà bíi Jèhófà Ọlọ́run wa,+
Ẹni tó ń gbé ibi gíga?
6 Ó tẹ̀ ba láti wo ọ̀run àti ayé,+
7 Ó ń gbé aláìní dìde látinú eruku.
Ó ń gbé tálákà dìde látorí eérú+
8 Kí ó lè mú un jókòó pẹ̀lú àwọn èèyàn pàtàkì,
Àwọn ẹni pàtàkì nínú àwọn èèyàn rẹ̀.
9 Ó ń fún àgàn ní ilé
Kí ó lè di abiyamọ aláyọ̀, ìyá àwọn ọmọ.+
Ẹ yin Jáà!