Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì
19 Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Àpólò+ wà ní Kọ́ríńtì, Pọ́ọ̀lù gba àwọn agbègbè tó jìnnà sí òkun kọjá, ó sì wá sí Éfésù.+ Ó rí àwọn ọmọ ẹ̀yìn kan níbẹ̀, 2 ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ṣé ẹ gba ẹ̀mí mímọ́ nígbà tí ẹ di onígbàgbọ́?”+ Wọ́n dá a lóhùn pé: “Hàà, a kò gbọ́ ọ rí pé ẹ̀mí mímọ́ wà.” 3 Ó wá sọ pé: “Irú ìrìbọmi wo lẹ wá ṣe?” Wọ́n sọ pé: “Ìrìbọmi Jòhánù ni.”+ 4 Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìrìbọmi tí Jòhánù ṣe fún àwọn èèyàn jẹ́ àmì ìrònúpìwàdà,+ ó ń sọ fún wọn pé kí wọ́n gba ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn òun gbọ́,+ ìyẹn Jésù.” 5 Bí wọ́n ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, a batisí wọn ní orúkọ Jésù Olúwa. 6 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù gbé ọwọ́ lé wọn, ẹ̀mí mímọ́ bà lé wọn,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè àjèjì, wọ́n sì ń sọ tẹ́lẹ̀.+ 7 Lápapọ̀, wọ́n jẹ́ nǹkan bí ọkùnrin méjìlá (12).
8 Fún oṣù mẹ́ta, ó ń wọ sínágọ́gù,+ ó sì ń fìgboyà sọ̀rọ̀, ó ń sọ àsọyé, ó sì ń bá wọn fèròwérò nípa Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà tó ń yíni lérò pa dà.+ 9 Àmọ́ nígbà tí àwọn kan kọ̀ jálẹ̀ pé àwọn ò ní gbà á gbọ́,* tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ burúkú nípa Ọ̀nà Náà+ lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, ó kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ ó sì ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ́tọ̀ kúrò lára wọn, ó ń sọ àsọyé lójoojúmọ́ nínú gbọ̀ngàn àpéjọ ilé ẹ̀kọ́ Tíránù. 10 Èyí ń bá a lọ fún ọdún méjì, tí gbogbo àwọn tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ Éṣíà fi gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, àti Júù àti Gíríìkì.
11 Ọlọ́run ń ṣe àwọn iṣẹ́ agbára tó ṣàrà ọ̀tọ̀ láti ọwọ́ Pọ́ọ̀lù nìṣó,+ 12 débi pé, àwọn aṣọ àti épírọ́ọ̀nù* tó kan ara rẹ̀ pàápàá ni wọ́n ń mú lọ bá àwọn tó ń ṣàìsàn,+ àwọn àìsàn náà ń fi wọ́n sílẹ̀, àwọn ẹ̀mí burúkú sì ń jáde kúrò lára wọn.+ 13 Àmọ́ lára àwọn Júù tó ń rìnrìn àjò kiri, tí wọ́n ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde náà gbìyànjú láti máa pe orúkọ Jésù Olúwa sórí àwọn tó ní àwọn ẹ̀mí burúkú; wọ́n á ní: “Mo pàṣẹ tó rinlẹ̀ fún yín nípasẹ̀ Jésù tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù rẹ̀.”+ 14 Lásìkò yìí, àwọn ọmọkùnrin méje kan wà tí wọ́n ń ṣe èyí, wọ́n jẹ́ ọmọ Síkéfà, ọ̀kan lára àwọn olórí àlùfáà àwọn Júù. 15 Àmọ́ ẹ̀mí burúkú náà dá wọn lóhùn pé: “Mo mọ Jésù,+ mo sì mọ Pọ́ọ̀lù;+ àmọ́ ta lẹ̀yin?” 16 Ni ọkùnrin tó ní ẹ̀mí burúkú náà bá bẹ́ mọ́ wọn, ó mú wọn balẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan, ó sì borí wọn, débi pé ìhòòhò ni wọ́n sá jáde nínú ilé náà, tí ara wọn sì gbọgbẹ́. 17 Ọ̀rọ̀ yìí dé etí gbogbo èèyàn, ó dé etí àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì tó ń gbé ní Éfésù; ẹ̀rù ba gbogbo wọn, àwọn èèyàn sì ń gbé orúkọ Jésù Olúwa ga. 18 Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ti di onígbàgbọ́ sì ń jáde wá jẹ́wọ́, wọ́n ń sọ àwọn ohun tí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀ ní gbangba. 19 Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń pidán kó àwọn ìwé wọn jọ, wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú gbogbo èèyàn.+ Wọ́n ṣírò iye tó jẹ́, wọ́n sì rí i pé ó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta (50,000) ẹyọ fàdákà. 20 Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ Jèhófà* ń gbilẹ̀ nìṣó, ó sì ń borí lọ́nà tó lágbára.+
21 Lẹ́yìn tí àwọn nǹkan yìí ti ṣẹlẹ̀, Pọ́ọ̀lù pinnu lọ́kàn rẹ̀ pé, lẹ́yìn tí òun bá ti la Makedóníà+ àti Ákáyà kọjá, òun á rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù.+ Ó sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo bá lọ síbẹ̀, mo gbọ́dọ̀ dé Róòmù pẹ̀lú.”+ 22 Torí náà, ó rán Tímótì+ àti Érásítù,+ méjì lára àwọn tó ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, lọ sí Makedóníà, àmọ́ òun fúnra rẹ̀ lo àkókò díẹ̀ sí i ní ìpínlẹ̀ Éṣíà.
23 Ní àkókò yẹn, àwọn èèyàn dá rògbòdìyàn+ púpọ̀ sílẹ̀ nípa Ọ̀nà Náà.+ 24 Nítorí ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ Dímẹ́tíríù, alágbẹ̀dẹ fàdákà tó ń fi fàdákà ṣe ojúbọ Átẹ́mísì, ó máa ń mú èrè púpọ̀ wọlé fún àwọn oníṣẹ́ ọnà.+ 25 Ó kó wọn jọ pẹ̀lú àwọn míì tó ń ṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ mọ̀ dáadáa pé òwò yìí ló mú ká láásìkí. 26 Ní báyìí, ẹ ti rí i, ẹ sì ti gbọ́ bí Pọ́ọ̀lù yìí ṣe yí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lérò pa dà, tó sì mú kí wọ́n ní èrò míì, kì í ṣe ní Éfésù nìkan,+ àmọ́ ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ní gbogbo ìpínlẹ̀ Éṣíà, tó ń sọ pé àwọn ọlọ́run tí a fi ọwọ́ ṣe kì í ṣe ọlọ́run.+ 27 Yàtọ̀ síyẹn, ewu tó wà níbẹ̀ kọjá pé àwọn èèyàn á máa bẹnu àtẹ́ lu òwò wa, wọn ò tún ní ka tẹ́ńpìlì abo ọlọ́run ńlá tó ń jẹ́ Átẹ́mísì sí, ẹni tí gbogbo ìpínlẹ̀ Éṣíà àti ilẹ̀ ayé tí à ń gbé ń jọ́sìn kò sì ní níyì mọ́.” 28 Bí àwọn èèyàn náà ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n gbaná jẹ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé: “Títóbi ni Átẹ́mísì àwọn ará Éfésù!”
29 Ni gbogbo ìlú bá dà rú, wọ́n sì jọ rọ́ wọnú gbọ̀ngàn ìwòran náà, wọ́n wọ́ Gáyọ́sì àti Àrísítákọ́sì jáde,+ àwọn ará Makedóníà tí wọ́n máa ń bá Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò. 30 Ní ti Pọ́ọ̀lù, ó fẹ́ wọlé lọ bá àwọn èèyàn náà, àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn kò gbà á láyè. 31 Kódà, lára àwọn kọmíṣọ́nnà àjọyọ̀ àti eré tí wọ́n fẹ́ràn rẹ̀ ránṣẹ́ sí i, wọ́n rọ̀ ọ́ pé kí ó má fi ẹ̀mí rẹ̀ wewu pé òun fẹ́ wọnú gbọ̀ngàn ìwòran náà. 32 Nítorí àpéjọ náà ti dà rú, bí àwọn kan ṣe ń pariwo tibí ni àwọn míì ń pariwo tọ̀hún, ọ̀pọ̀ nínú wọn ni ò sì mọ ìdí tí wọ́n fi kóra jọ. 33 Nítorí náà, wọ́n mú Alẹkisáńdà jáde láàárín èrò, àwọn Júù tì í síwájú, Alẹkisáńdà sì ju ọwọ́ rẹ̀, ó fẹ́ sọ̀rọ̀ láti gbèjà ara rẹ̀ níwájú àwọn èèyàn náà. 34 Àmọ́ nígbà tí wọ́n rí i pé Júù ni, gbogbo wọn pa ohùn pọ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe fún nǹkan bíi wákàtí méjì pé: “Títóbi ni Átẹ́mísì àwọn ará Éfésù!”
35 Nígbà tí akọ̀wé ìlú náà wá mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn náà dákẹ́, ó sọ pé: “Ẹ̀yin èèyàn Éfésù, ta ni nínú gbogbo èèyàn ni kò mọ̀ pé ìlú àwọn ará Éfésù ni ìlú tó ń bójú tó tẹ́ńpìlì Átẹ́mísì ńlá àti ère tó já bọ́ láti ọ̀run? 36 Nígbà tí ẹnikẹ́ni ò ti lè sọ pé àwọn nǹkan yìí ò rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ fara balẹ̀, kí ẹ má sì fi wàdùwàdù ṣe nǹkan. 37 Nítorí àwọn ọkùnrin tí ẹ mú wá síbí yìí kò jí nǹkan ní tẹ́ńpìlì, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sọ̀rọ̀ òdì sí abo ọlọ́run wa. 38 Torí náà, tí Dímẹ́tíríù+ àti àwọn oníṣẹ́ ọnà tó wà pẹ̀lú rẹ̀ bá ní ẹjọ́ pẹ̀lú ẹnì kan, àwọn ọjọ́ kọ́ọ̀tù wà, àwọn alákòóso ìbílẹ̀* sì wà; kí wọ́n wá fẹ̀sùn kan ara wọn. 39 Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ohun tó ju èyí lọ lẹ̀ ń wá, inú àpéjọ tó bófin mu ni wọ́n ti máa ṣèpinnu lórí rẹ̀. 40 Ohun tó ṣẹlẹ̀ lónìí lè mú kí wọ́n fẹ̀sùn kàn wá pé à ń dìtẹ̀ sí ìjọba, torí kò sí ìdí kankan tí a lè sọ pé ó fà á tí àwùjọ onírúgúdù yìí fi kóra jọ.” 41 Lẹ́yìn tó sọ ọ̀rọ̀ yìí, ó tú àpéjọ náà ká.