Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì
23 Bí Pọ́ọ̀lù ṣe tẹjú mọ́ Sàhẹ́ndìrìn, ó sọ pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, mo ti hùwà níwájú Ọlọ́run pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ láìkù síbì kan+ títí di òní yìí.” 2 Ni Ananáyà àlùfáà àgbà bá pàṣẹ fún àwọn tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n gbá a lẹ́nu. 3 Nígbà náà, Pọ́ọ̀lù sọ fún un pé: “Ọlọ́run yóò gbá ọ, ìwọ ògiri tí a kùn lẹ́fun. Ṣebí torí kí o lè fi Òfin ṣèdájọ́ mi lo ṣe jókòó, kí ló dé tí ìwọ fúnra rẹ tún ń rú Òfin bí o ṣe ní kí wọ́n gbá mi?” 4 Ni àwọn tó wà níbẹ̀ bá sọ pé: “Ṣé ò ń bú àlùfáà àgbà Ọlọ́run ni?” 5 Pọ́ọ̀lù fèsì pé: “Ẹ̀yin ará, mi ò mọ̀ pé àlùfáà àgbà ni. Nítorí ó wà lákọsílẹ̀ pé, ‘O ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ alákòóso àwọn èèyàn rẹ láìdáa.’”+
6 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rí i pé apá kan wọn jẹ́ Sadusí, àwọn tó kù sì jẹ́ Farisí, ó ké jáde ní Sàhẹ́ndìrìn pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, Farisí ni mí,+ mo sì jẹ́ ọmọ àwọn Farisí. Torí ìrètí àjíǹde àwọn òkú ni wọ́n ṣe ń dá mi lẹ́jọ́.” 7 Nítorí ohun tó sọ yìí, ìyapa dé sáàárín àwọn Farisí àti àwọn Sadusí, àpéjọ náà sì pín sí méjì. 8 Torí àwọn Sadusí sọ pé kò sí àjíǹde tàbí áńgẹ́lì tàbí ẹ̀mí, àmọ́ àwọn Farisí gbà pé gbogbo wọn wà.*+ 9 Nítorí náà, ariwo ńlá sọ, lára àwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ àwọn Farisí dìde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jiyàn kíkankíkan, wọ́n ń sọ pé: “A ò rí ohun àìtọ́ kankan tí ọkùnrin yìí ṣe, àmọ́ tí ẹ̀mí tàbí áńgẹ́lì bá bá a sọ̀rọ̀+ —.” 10 Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà di rannto, ẹ̀rù ba ọ̀gágun pé wọ́n á fa Pọ́ọ̀lù ya, ló bá pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ ogun sọ̀ kalẹ̀, kí wọ́n já a gbà kúrò láàárín wọn, kí wọ́n sì mú un wá sí ibùdó àwọn ọmọ ogun.
11 Àmọ́ ní òru ọjọ́ náà, Olúwa dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì sọ pé: “Mọ́kàn le!+ Nítorí pé bí o ṣe ń jẹ́rìí kúnnákúnná nípa mi ní Jerúsálẹ́mù, bẹ́ẹ̀ lo ṣe máa jẹ́rìí ní Róòmù.”+
12 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn Júù gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n sì fi ègún de ara wọn, pé àwọn ò ní jẹ, àwọn ò sì ní mu títí àwọn á fi pa Pọ́ọ̀lù. 13 Ó ju ogójì (40) ọkùnrin tó di ọ̀tẹ̀ oníbùúra yìí. 14 Àwọn ọkùnrin yìí lọ bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà, wọ́n sì sọ pé: “A ti fi ègún de ara wa* lọ́nà tó rinlẹ̀ láti má ṣe jẹ nǹkan kan títí a ó fi pa Pọ́ọ̀lù. 15 Torí náà, ní báyìí, kí ẹ̀yin pẹ̀lú Sàhẹ́ndìrìn sọ fún ọ̀gágun pé kí ó mú un sọ̀ kalẹ̀ wá sọ́dọ̀ yín bíi pé ẹ fẹ́ túbọ̀ gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ yẹ̀ wò. Àmọ́ kó tó sún mọ́ tòsí, àá ti wà ní sẹpẹ́ láti pa á.”
16 Ṣùgbọ́n, ọmọ arábìnrin Pọ́ọ̀lù gbọ́ pé wọ́n fẹ́ lúgọ de Pọ́ọ̀lù, ló bá wọ ibùdó àwọn ọmọ ogun, ó sì sọ fún Pọ́ọ̀lù. 17 Pọ́ọ̀lù wá pe ọ̀kan lára àwọn ọ̀gá ọmọ ogun, ó sì sọ pé: “Mú ọ̀dọ́kùnrin yìí lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun, torí ó ní ohun kan tó fẹ́ sọ fún un.” 18 Torí náà, ó mú un lọ bá ọ̀gágun, ó sì sọ fún un pé: “Ẹlẹ́wọ̀n tó ń jẹ́ Pọ́ọ̀lù pè mí, ó sì ní kí n mú ọ̀dọ́kùnrin yìí wá bá ọ, torí ó ní ohun kan tó fẹ́ sọ fún ọ.” 19 Ọ̀gágun fà á lọ́wọ́, ó mú un lọ sí kọ̀rọ̀ kan, ó sì bi í pé: “Kí lo fẹ́ sọ fún mi?” 20 Ó sọ pé: “Àwọn Júù ti fohùn ṣọ̀kan pé àwọn á ní kí o mú Pọ́ọ̀lù sọ̀ kalẹ̀ wá sí Sàhẹ́ndìrìn lọ́la bíi pé wọ́n fẹ́ mọ̀ sí i nípa ẹjọ́ rẹ̀.+ 21 Má ṣe gbọ́ tiwọn, torí ó ju ogójì (40) ọkùnrin lára wọn tó lúgọ dè é, wọ́n sì ti fi ègún* de ara wọn pé àwọn ò ní jẹ, àwọn ò sì ní mu títí àwọn á fi pa á;+ wọ́n ti múra tán báyìí, wọ́n ń dúró de àṣẹ látọ̀dọ̀ rẹ.” 22 Nítorí náà, ọ̀gágun ní kí ọ̀dọ́kùnrin náà máa lọ lẹ́yìn tó pàṣẹ fún un pé: “Má sọ fún ẹnikẹ́ni pé o ti sọ nǹkan yìí fún mi.”
23 Ó wá pe méjì lára àwọn ọ̀gá ọmọ ogun, ó sì sọ pé: “Ẹ múra igba (200) ọmọ ogun sílẹ̀ láti lọ sí Kesaríà ní wákàtí kẹta òru,* ẹ tún mú àádọ́rin (70) agẹṣin àti igba (200) àwọn tó ń fọ̀kọ̀ jà dání. 24 Bákan náà, ẹ fún Pọ́ọ̀lù ní àwọn ẹṣin tó máa gbé e dé ọ̀dọ̀ gómìnà Fẹ́líìsì láìséwu.” 25 Ó wá kọ lẹ́tà kan tó lọ báyìí pé:
26 “Kíláúdíù Lísíà sí Ọlọ́lá Jù Lọ, Gómìnà Fẹ́líìsì: Mo kí ọ! 27 Àwọn Júù mú ọkùnrin yìí, wọ́n sì ti fẹ́ pa á, àmọ́ mo tètè wá pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun mi, mo sì gbà á sílẹ̀,+ torí mo gbọ́ pé ará Róòmù ni.+ 28 Torí pé mo fẹ́ mọ ìdí tí wọ́n fi ń fẹ̀sùn kàn án, mo mú un sọ̀ kalẹ̀ wá sí Sàhẹ́ndìrìn wọn.+ 29 Mo rí i pé wọ́n fẹ̀sùn kàn án lórí àwọn ọ̀ràn Òfin wọn,+ àmọ́ kò ṣe ohunkóhun tó yẹ fún ikú tàbí fún ìdè. 30 Ṣùgbọ́n nítorí mo gbọ́ pé wọ́n ń gbìmọ̀ pọ̀ láti pa ọkùnrin yìí,+ mò ń fi í ránṣẹ́ sí ọ ní kíákíá, mo sì pàṣẹ fún àwọn tó ń fi ẹ̀sùn kàn án kí wọ́n wá ta kò ó níwájú rẹ.”
31 Nítorí náà, àwọn ọmọ ogun yìí mú Pọ́ọ̀lù+ bí wọ́n ṣe pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì mú un wá sí Antipátírísì ní òru. 32 Ní ọjọ́ kejì, wọ́n ní kí àwọn agẹṣin máa mú un lọ, àwọn ọmọ ogun tó kù sì pa dà sí ibùdó àwọn ọmọ ogun. 33 Àwọn agẹṣin náà wọ Kesaríà, wọ́n fi lẹ́tà náà jíṣẹ́ fún gómìnà, wọ́n sì mú Pọ́ọ̀lù wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 34 Torí náà, ó kà á, ó béèrè ìpínlẹ̀ tó ti wá, ó sì rí i pé Sìlíṣíà ló ti wá.+ 35 Ó wá sọ pé: “Màá gbọ́ ẹjọ́ rẹ látòkèdélẹ̀ nígbà tí àwọn tó fẹ̀sùn kàn ọ́ bá dé.”+ Ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n máa ṣọ́ ọ ní ààfin* Hẹ́rọ́dù.