Àìsáyà
64 Ká ní o ti fa ọ̀run ya, tí o sì sọ̀ kalẹ̀,
Kí àwọn òkè lè mì tìtì nítorí rẹ,
2 Bí ìgbà tí iná ran igi wíwẹ́,
Tí iná sì mú kí omi hó,
Àwọn ọ̀tá rẹ máa wá mọ orúkọ rẹ,
Àwọn orílẹ̀-èdè sì máa gbọ̀n rìrì níwájú rẹ!
3 Nígbà tí o ṣe àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù, tí a ò jẹ́ retí,+
O sọ̀ kalẹ̀, àwọn òkè sì mì tìtì níwájú rẹ.+
4 Láti ìgbà àtijọ́, kò sẹ́ni tó gbọ́ tàbí tó fetí sílẹ̀,
Kò sí ojú tó rí Ọlọ́run kankan àfi ìwọ,
5 O ti bá àwọn tó ń fayọ̀ ṣe ohun tó tọ́ pàdé,+
Àwọn tó ń rántí rẹ, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn ọ̀nà rẹ.
Wò ó! Inú bí ọ, nígbà tí à ń ṣẹ̀ ṣáá,+
Ó pẹ́ gan-an tí a fi ṣe bẹ́ẹ̀.
Ṣé ó wá yẹ ká rígbàlà báyìí?
Gbogbo wa máa rọ bí ewé,
Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì máa gbé wa lọ bí atẹ́gùn.
7 Kò sẹ́ni tó ń pe orúkọ rẹ,
Kò sẹ́ni tó ń ru ara rẹ̀ sókè láti gbá ọ mú,
Torí o ti fi ojú rẹ pa mọ́ fún wa,+
8 Àmọ́ ní báyìí, Jèhófà, ìwọ ni Bàbá wa.+
Jọ̀ọ́, wò wá, torí èèyàn rẹ ni gbogbo wa.
10 Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aginjù.
Síónì ti di aginjù,
Jerúsálẹ́mù ti di ahoro.+
12 Pẹ̀lú èyí, ṣé o ṣì máa dúró, Jèhófà?
Ṣé o ṣì máa dákẹ́ jẹ́ẹ́, tí wàá sì jẹ́ kí ìyà jẹ wá gidigidi?+