Òwe
25 Àwọn òwe míì tí Sólómọ́nì pa,+ èyí tí àwọn ọkùnrin Hẹsikáyà+ ọba Júdà dà kọ* nìyí:
3 Bí ọ̀run ṣe ga, tí ilẹ̀ sì jìn,
Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn àwọn ọba jẹ́ ohun àwámáridìí.
4 Yọ́ ìdàrọ́ kúrò lára fàdákà,
Á sì mọ́ pátápátá.+
5 Mú ẹni burúkú kúrò níwájú ọba,
Ìtẹ́ rẹ̀ yóò sì fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú òdodo.+
6 Má bọlá fún ara rẹ níwájú ọba,+
Má sì jókòó ní àyè àwọn ẹni ńlá,+
7 Nítorí ó sàn kó sọ fún ọ pé, “Máa bọ̀ níbí,”
Ju pé kó kàn ọ́ lábùkù níwájú àwọn èèyàn pàtàkì.+
8 Má fi ìkánjú gbé ọ̀rọ̀ lọ sílé ẹjọ́,
Àbí kí lo máa ṣe tí ọmọnìkejì rẹ bá kàn ọ́ lábùkù?+
9 Ro ẹjọ́ rẹ pẹ̀lú ọmọnìkejì rẹ,+
Àmọ́ má sọ ọ̀rọ̀ àṣírí tí o gbọ́,*+
10 Kí ẹni tó ń fetí sílẹ̀ má bàa kó ìtìjú bá ọ,
Ọ̀rọ̀ burúkú* tí o tàn kálẹ̀ kò sì ní ṣeé kó pa dà.
12 Bíi yẹtí wúrà àti ohun ọ̀ṣọ́ tí wọ́n fi wúrà tó dára ṣe
Ni ọlọ́gbọ́n tó ń báni wí jẹ́ ní etí ẹni tó ń gbọ́ràn.+
13 Bí ìtutù yìnyín ní ọjọ́ ìkórè
Ni òjíṣẹ́ olóòótọ́ jẹ́ fún àwọn tó rán an,
14 Bí òjò tó ṣú, tó sì ń fẹ́ atẹ́gùn àmọ́ tí kò rọ̀
16 Tí o bá rí oyin, èyí tí o nílò nìkan ni kí o jẹ,
Torí tí o bá jẹ ẹ́ ní àjẹjù, o lè bì í.+
17 Má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ṣe lemọ́lemọ́ ní ilé ọmọnìkejì rẹ,
Kí ọ̀rọ̀ rẹ má bàa sú u, kó sì kórìíra rẹ.
18 Bíi kùmọ̀ ogun àti idà àti ọfà tó mú
Ni ẹni tó ń jẹ́rìí èké sí ọmọnìkejì rẹ̀.+
19 Bí eyín tó ká tàbí ẹsẹ̀ tó ń gbò yèpéyèpé
Ni ìgbọ́kànlé téèyàn ní nínú ẹni tí kò ṣe é fọkàn tán* lásìkò wàhálà.
20 Bí ẹni tó bọ́ aṣọ lọ́jọ́ òtútù
Àti bí ọtí kíkan tí wọ́n dà sórí sódà*
Ni ẹni tó ń kọrin fún ọkàn tí ìbànújẹ́ bá.+
21 Tí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ,* fún un ní oúnjẹ jẹ;
Tí òùngbẹ bá sì ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu,+
22 Torí ṣe ni wàá máa kó ẹyin iná jọ lé e lórí,*+
Jèhófà yóò sì san èrè fún ọ.
23 Ẹ̀fúùfù láti àríwá ń mú kí òjò rọ̀,
Ahọ́n tó ń ṣòfófó sì ń mú kí ojú fà ro.+
26 Bí ìsun omi tó rú àti kànga tó ti bà jẹ́
Ni olódodo tó gbà fún* ẹni burúkú.