Àkọsílẹ̀ Mátíù
3 Nígbà yẹn, Jòhánù+ Arinibọmi wá, ó ń wàásù+ ní aginjù Jùdíà, 2 ó ń sọ pé: “Ẹ ronú pìwà dà, torí Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.”+ 3 Òun gangan ni ẹni tí wòlíì Àìsáyà+ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé: “Ohùn ẹnì kan ń ké nínú aginjù pé: ‘Ẹ ṣètò ọ̀nà Jèhófà!* Ẹ mú àwọn ọ̀nà rẹ̀ tọ́.’”+ 4 Jòhánù wọ aṣọ tí wọ́n fi irun ràkúnmí ṣe, ó sì de àmùrè tí wọ́n fi awọ ṣe mọ́ ìbàdí rẹ̀.+ Eéṣú àti oyin ìgàn ni oúnjẹ rẹ̀.+ 5 Àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù àti gbogbo Jùdíà àti gbogbo ìgbèríko tó yí Jọ́dánì ká máa ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀,+ 6 ó ń ṣèrìbọmi* fún wọn ní odò Jọ́dánì,+ wọ́n sì ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní gbangba.
7 Nígbà tó rí i tí ọ̀pọ̀ lára àwọn Farisí àti Sadusí+ ń wá síbi ìrìbọmi náà, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀,+ ta ló kìlọ̀ fún yín pé kí ẹ sá fún ìbínú tó ń bọ̀?+ 8 Torí náà, ẹ so èso tó yẹ ìrònúpìwàdà. 9 Ẹ má ṣe dá ara yín lójú, kí ẹ sì sọ fún ara yín pé, ‘A ní Ábúráhámù ní baba.’+ Torí mò ń sọ fún yín pé Ọlọ́run lè gbé àwọn ọmọ dìde fún Ábúráhámù látinú àwọn òkúta yìí. 10 Àáké ti wà níbi gbòǹgbò àwọn igi báyìí. Torí náà, gbogbo igi tí kò bá so èso tó dáa la máa gé lulẹ̀, tí a sì máa jù sínú iná.+ 11 Ní tèmi, mò ń fi omi batisí yín torí pé ẹ ronú pìwà dà,+ àmọ́ ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi lágbára jù mí lọ, ẹni tí mi ò tó bọ́ bàtà rẹ̀.+ Ẹni yẹn máa fi ẹ̀mí mímọ́+ àti iná+ batisí yín. 12 Ṣọ́bìrì tó fi ń fẹ́ ọkà wà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì máa gbá ibi ìpakà rẹ̀ mọ́ tónítóní, ó máa kó àlìkámà* rẹ̀ jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí, àmọ́ ó máa fi iná+ tí kò ṣeé pa sun ìyàngbò.”*
13 Lẹ́yìn náà, Jésù wá láti Gálílì sí Jọ́dánì, ó wá sọ́dọ̀ Jòhánù kó lè ṣèrìbọmi fún òun.+ 14 Àmọ́ ẹni yẹn gbìyànjú láti dá a dúró, ó sọ pé: “Ìwọ ló yẹ kí o ṣèrìbọmi fún mi, ṣé ọ̀dọ̀ mi lo wá ń bọ̀ ni?” 15 Jésù sọ fún un pé: “Jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí, torí ọ̀nà yẹn ló yẹ ká gbà ṣe gbogbo ohun tó jẹ́ òdodo.” Kò wá dá a dúró mọ́. 16 Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi, ó jáde látinú omi lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀; sì wò ó! ọ̀run ṣí sílẹ̀,+ ó sì rí i tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀ kalẹ̀ bí àdàbà bọ̀ wá sórí rẹ̀.+ 17 Wò ó! Ohùn kan tún dún láti ọ̀run+ pé: “Èyí ni Ọmọ mi,+ àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.”+