Àkọsílẹ̀ Máàkù
5 Lẹ́yìn náà, wọ́n dé òdìkejì òkun, ní agbègbè àwọn ará Gérásà.+ 2 Gbàrà tí Jésù sọ̀ kalẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú omi, ọkùnrin kan tí ẹ̀mí àìmọ́ ń dà láàmú wá pàdé rẹ̀ láti àárín àwọn ibojì.* 3 Àárín àwọn ibojì ló máa ń wà, títí di àkókò yẹn, ẹnì kankan ò lè dè é pinpin, wọn ò lè fi ẹ̀wọ̀n dè é pàápàá. 4 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n dè é, àmọ́ ṣe ló já ẹ̀wọ̀n náà pàrà, tó sì já ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ náà sí wẹ́wẹ́; kò sí ẹni tó lágbára láti kápá rẹ̀. 5 Tọ̀sántòru ló ń ké ṣáá láwọn ibojì àti àwọn òkè, ó sì máa ń fi àwọn òkúta ya ara rẹ̀ yánnayànna. 6 Àmọ́ bó ṣe tajú kán rí Jésù ní ọ̀ọ́kán, ó sáré lọ forí balẹ̀ fún un.+ 7 Ó sì ké jáde pé: “Kí ló pa wá pọ̀, Jésù Ọmọ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ? Fi Ọlọ́run búra fún mi pé o ò ní dá mi lóró.”+ 8 Torí Jésù ti ń sọ fún un pé: “Jáde nínú ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́.”+ 9 Àmọ́ Jésù bi í pé: “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó fèsì pé: “Líjíónì lorúkọ mi, torí a pọ̀.” 10 Ó ṣáà ń bẹ Jésù pé kó má ṣe lé àwọn ẹ̀mí náà jáde kúrò ní ilẹ̀ náà.+
11 Ó ṣẹlẹ̀ pé ọ̀wọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀+ tó pọ̀ ń jẹun níbẹ̀ níbi òkè.+ 12 Torí náà, àwọn ẹ̀mí náà bẹ̀ ẹ́ pé: “Lé wa lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, ká lè wọnú wọn.” 13 Torí náà, ó gbà wọ́n láyè. Àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà bá jáde, wọ́n sì wọnú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, ọ̀wọ́ ẹran náà rọ́ kọjá ní etí òkè* sínú òkun, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ni wọ́n, wọ́n sì kú sínú òkun. 14 Àmọ́ àwọn tó ń dà wọ́n sá lọ, wọ́n sì ròyìn rẹ̀ nínú ìlú àti ní ìgbèríko, àwọn èèyàn sì wá wo ohun tó ṣẹlẹ̀.+ 15 Torí náà, wọ́n wá bá Jésù, wọ́n sì rí ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu náà, ẹni tí líjíónì wà nínú rẹ̀ tẹ́lẹ̀, ó jókòó, ó ti wọṣọ, orí rẹ̀ sì ti wálé, ni ẹ̀rù bá bẹ̀rẹ̀ sí í bà wọ́n. 16 Bákan náà, àwọn tí wọ́n rí i ròyìn fún wọn nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu náà àti àwọn ẹlẹ́dẹ̀. 17 Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jésù pé kó kúrò ní agbègbè wọn.+
18 Bó ṣe ń wọ ọkọ̀ ojú omi, ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu tẹ́lẹ̀ náà bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí òun tẹ̀ lé e.+ 19 Àmọ́ kò gbà fún un, ṣe ló sọ fún un pé: “Máa lọ sílé lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, kí o sì ròyìn fún wọn gbogbo ohun tí Jèhófà* ti ṣe fún ọ àti bó ṣe ṣàánú rẹ.” 20 Ọkùnrin náà lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kéde gbogbo ohun tí Jésù ṣe fún un ní Dekapólì,* ẹnu sì ya gbogbo èèyàn.
21 Lẹ́yìn tí Jésù tún fi ọkọ̀ ojú omi sọdá sí èbúté tó wà ní òdìkejì, èrò rẹpẹtẹ kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wà létí òkun.+ 22 Ọ̀kan nínú àwọn alága sínágọ́gù, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jáírù wá, nígbà tó sì tajú kán rí i, ó wólẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀.+ 23 Ó bẹ̀ ẹ́ léraléra, ó ní: “Ọmọbìnrin mi kékeré ń ṣàìsàn gidigidi.* Jọ̀ọ́, wá gbé ọwọ́ rẹ lé e+ kí ara rẹ̀ lè yá, kó má sì kú.” 24 Jésù wá tẹ̀ lé e, èrò rẹpẹtẹ sì ń rọ́ tẹ̀ lé e, wọ́n fún mọ́ ọn.
25 Obìnrin kan wà tó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀+ fún ọdún méjìlá (12).+ 26 Ó ti jìyà gan-an* lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ oníṣègùn, ó sì ti ná gbogbo ohun tó ní, àmọ́ kàkà kí ara rẹ̀ yá, ṣe ló ń burú sí i. 27 Nígbà tó gbọ́ ìròyìn nípa Jésù, ó gba àárín èrò wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+ 28 torí ó ń sọ ṣáá pé: “Tí mo bá fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ lásán, ara mi á yá.”+ 29 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ gbẹ láú, ó sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé àìsàn burúkú tó ń ṣe òun ti lọ.
30 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jésù mọ̀ ọ́n lára pé agbára+ ti jáde lára òun, ó wá yíjú pa dà láàárín èrò náà, ó sì béèrè pé: “Ta ló fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè mi?”+ 31 Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé: “O rí i tí èrò ń fún mọ́ ọ, o wá ń béèrè pé, ‘Ta ló fọwọ́ kàn mí?’” 32 Ṣùgbọ́n ó ń wò yí ká kó lè rí ẹni tó fọwọ́ kàn án. 33 Ẹ̀rù ba obìnrin náà, jìnnìjìnnì sì bò ó, torí ó ti mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí òun, ó wá wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ gbogbo òótọ́ ọ̀rọ̀ náà fún un. 34 Ó dá a lóhùn pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà,+ kí àìsàn burúkú tó ń ṣe ọ́ sì lọ.”+
35 Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àwọn ọkùnrin kan láti ilé alága sínágọ́gù wá, wọ́n sì sọ pé: “Ọmọbìnrin rẹ ti kú! Kí ló dé tí o ṣì ń yọ Olùkọ́ lẹ́nu?”+ 36 Àmọ́ Jésù fetí kọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ, ó sì sọ fún alága sínágọ́gù náà pé: “Má bẹ̀rù,* ṣáà ti ní ìgbàgbọ́.”+ 37 Kò jẹ́ kí ẹnì kankan tẹ̀ lé òun, àfi Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù arákùnrin Jémíìsì.+
38 Wọ́n sì dé ilé alága sínágọ́gù náà, ó rí i tí ariwo ń sọ, tí àwọn èèyàn ń sunkún, tí wọ́n sì ń pohùn réré ẹkún gidigidi,+ 39 Lẹ́yìn tó wọlé, ó sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sunkún, tí ẹ sì ń pariwo báyìí? Ọmọ náà ò tíì kú, ó ń sùn ni.”+ 40 Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́rìn-ín, wọ́n sì ń fi ṣẹlẹ́yà. Àmọ́ lẹ́yìn tó ní kí gbogbo wọn bọ́ síta, ó mú bàbá àti ìyá ọmọ náà àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì wọlé síbi tí ọmọ náà wà. 41 Ó wá di ọwọ́ ọmọ náà mú, ó sì sọ fún un pé: “Tàlítà kumì,” tó túmọ̀ sí: “Ọmọbìnrin, mo sọ fún ọ, dìde!”+ 42 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọmọbìnrin náà dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn. (Ọmọ ọdún méjìlá [12] ni.) Lójú ẹsẹ̀, ṣe ni inú wọn bẹ̀rẹ̀ sí í dùn gidigidi. 43 Àmọ́ ó kìlọ̀ fún wọn léraléra* pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan mọ ohun tó ṣẹlẹ̀,+ ó sì ní kí wọ́n fún ọmọbìnrin náà ní nǹkan tó máa jẹ.