Ìsíkíẹ́lì
20 Ní ọdún keje, ní oṣù karùn-ún, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, àwọn kan lára àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wá, wọ́n sì jókòó síwájú mi kí wọ́n lè wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà. 2 Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 3 “Ọmọ èèyàn, bá àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ṣé ọ̀dọ̀ mi lẹ ti fẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ ni? ‘Bí mo ti wà láàyè, mi ò ní dá yín lóhùn,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”’
4 “Ṣé o ṣe tán láti dá wọn lẹ́jọ́?* Ọmọ èèyàn, ṣé o ṣe tán láti dá wọn lẹ́jọ́? Jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ohun ìríra tí àwọn baba ńlá wọn ṣe.+ 5 Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ní ọjọ́ tí mo yan Ísírẹ́lì,+ mo tún búra* fún ọmọ* ilé Jékọ́bù, mo sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ mí ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Àní, mo búra fún wọn, mo sì sọ pé, ‘Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’ 6 Ní ọjọ́ yẹn, mo búra fún wọn pé màá mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì lọ sí ilẹ̀ tí mo ṣàwárí* fún wọn, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.+ Ibi tó rẹwà* jù ní gbogbo ilẹ̀ náà. 7 Mo wá sọ fún wọn pé, ‘Kí kálukú yín ju ohun ìríra tó wà níwájú rẹ̀ nù; ẹ má fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* Íjíbítì sọ ara yín di ẹlẹ́gbin.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’+
8 “‘“Àmọ́ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi, kò sì wù wọ́n láti fetí sí mi. Wọn ò ju ohun ìríra tó wà níwájú wọn nù, wọn ò sì fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin Íjíbítì sílẹ̀.+ Torí náà, mo pinnu pé màá bínú sí wọn, inú mi á sì ru sí wọn gidigidi ní ilẹ̀ Íjíbítì. 9 Àmọ́, mo gbé ìgbésẹ̀ torí orúkọ mi, kí wọ́n má bàa kó ẹ̀gàn bá a lójú àwọn orílẹ̀-èdè, láàárín àwọn tí wọ́n ń gbé.+ Torí nígbà tí mo mú wọn* kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, mo jẹ́ kí wọ́n* mọ̀ mí níṣojú àwọn orílẹ̀-èdè yìí.+ 10 Torí náà, mo mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, mo sì mú wọn wá sí aginjù.+
11 “‘“Mo wá fún wọn ní àwọn àṣẹ mi, mo sì jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ìdájọ́ mi,+ èyí tó lè mú kí ẹni tó bá ń pa wọ́n mọ́ wà láàyè.+ 12 Mo tún fún wọn ní àwọn sábáàtì mi,+ kó lè jẹ́ àmì láàárín èmi àti àwọn,+ kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi Jèhófà ló ń sọ wọ́n di mímọ́.
13 “‘“Àmọ́, ilé Ísírẹ́lì ṣọ̀tẹ̀ sí mi ní aginjù.+ Wọn ò tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi, wọ́n sì kọ àwọn ìdájọ́ mi, èyí tó lè mú kí ẹni tó bá ń pa wọ́n mọ́ wà láàyè. Wọ́n sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́ pátápátá. Torí náà, mo pinnu pé màá bínú sí wọn nínú aginjù kí n lè pa wọ́n run.+ 14 Àmọ́, mo gbé ìgbésẹ̀ torí orúkọ mi, kí wọ́n má bàa kó ẹ̀gàn bá a lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n rí i nígbà tí mo mú wọn* jáde.+ 15 Mo tún búra fún wọn nínú aginjù pé mi ò ní mú wọn wá sí ilẹ̀ tí mo fún wọn,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ ibi tó rẹwà* jù ní gbogbo ilẹ̀ náà, 16 torí pé wọ́n kọ àwọn ìdájọ́ mi, wọn ò tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi, wọ́n sì sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́ torí ọkàn wọn ń fà sí àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn.+
17 “‘“Àmọ́ mo* ṣàánú wọn, mi ò sì pa wọ́n run; mi ò pa wọ́n rẹ́ ní aginjù. 18 Mo sọ fún àwọn ọmọ wọn nínú aginjù pé,+ ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ pa ìlànà àwọn baba ńlá yín mọ́,+ ẹ ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìdájọ́ wọn, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn sọ ara yín di ẹlẹ́gbin. 19 Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín. Ẹ máa tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi, kí ẹ rìn nínú àwọn ìdájọ́ mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́.+ 20 Ẹ sọ àwọn sábáàtì mi di mímọ́,+ kó sì jẹ́ àmì láàárín èmi àti ẹ̀yin, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’+
21 “‘“Àmọ́ àwọn ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀tẹ̀ sí mi.+ Wọn ò tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi mọ́, wọn ò tẹ̀ lé àwọn ìdájọ́ mi, wọn ò sì rìn nínú rẹ̀, èyí tó lè mú kí ẹni tó bá ń pa wọ́n mọ́ wà láàyè. Wọ́n sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́. Torí náà, mo pinnu pé màá bínú sí wọn, inú mi á sì ru sí wọn gidigidi ní aginjù.+ 22 Àmọ́ mi ò ṣe bẹ́ẹ̀,+ mo sì gbé ìgbésẹ̀ nítorí orúkọ mi,+ kí wọ́n má bàa kó ẹ̀gàn bá a lójú àwọn orílẹ̀-èdè tó rí i nígbà tí mo mú wọn* jáde. 23 Bákan náà, mo búra fún wọn nínú aginjù pé màá fọ́n wọn ká sí àwọn orílẹ̀-èdè, màá sì tú wọn ká sí àwọn ilẹ̀,+ 24 torí wọn ò pa àwọn ìdájọ́ mi mọ́, wọ́n sì kọ àwọn àṣẹ mi sílẹ̀,+ wọ́n sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́, wọ́n sì ń tẹ̀ lé* àwọn òrìṣà ẹ̀gbin tí àwọn baba ńlá wọn ń sìn.+ 25 Mo tún gbà wọ́n láyè láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà tí kò dáa àti àwọn ìdájọ́ tí kò lè mú kí wọ́n wà láàyè.+ 26 Mo jẹ́ kí àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú sọ wọ́n di aláìmọ́, bí wọ́n ṣe ń sun àwọn àkọ́bí ọmọ wọn nínú iná,+ kí n lè sọ wọ́n di ahoro, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’
27 “Torí náà, ọmọ èèyàn, bá ilé Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Bí àwọn baba ńlá yín ṣe sọ̀rọ̀ òdì sí mi nìyẹn tí wọ́n hùwà àìṣòótọ́ sí mi. 28 Mo mú wọn wá sí ilẹ̀ tí mo búra pé màá fún wọn.+ Nígbà tí wọ́n rí gbogbo òkè tó ga àti àwọn igi tí ewé kún orí rẹ̀,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rú àwọn ẹbọ wọn, wọ́n sì ń mú àwọn ọrẹ wọn tó ń múnú bí mi lọ síbẹ̀. Wọ́n ń gbé àwọn ẹbọ wọn tó ní òórùn dídùn* lọ síbẹ̀, wọ́n sì ń da àwọn ọrẹ ohun mímu wọn sílẹ̀ níbẹ̀. 29 Mo wá bi wọ́n pé, ‘Kí ni ìtumọ̀ ibi gíga tí ẹ̀ ń lọ yìí? (Wọ́n ṣì ń pè é ní Ibi Gíga títí dòní.)’”’+
30 “Kí o wá sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ṣé ẹ fẹ́ sọ ara yín di ẹlẹ́gbin bíi ti àwọn baba ńlá yín ni, tí wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn kí wọ́n lè bá wọn ṣe àgbèrè ẹ̀sìn?+ 31 Ṣé ẹ ṣì ń sọ ara yín di ẹlẹ́gbin títí dòní olónìí, tí ẹ̀ ń rúbọ sí gbogbo òrìṣà ẹ̀gbin yín, tí ẹ̀ ń sun àwọn ọmọ yín nínú iná?+ Ṣé ó wá yẹ kí n dá yín lóhùn pẹ̀lú gbogbo ohun tí ẹ ṣe yìí, ilé Ísírẹ́lì?”’+
“‘Bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘mi ò ní dá yín lóhùn.+ 32 Ohun tí ẹ sì ní lọ́kàn* nígbà tí ẹ̀ ń sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká dà bí àwọn orílẹ̀-èdè, bí àwọn ìdílé tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ míì, tí wọ́n ń jọ́sìn* igi àti òkúta,”+ kò ní ṣẹlẹ̀ láé.’”
33 “‘Bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘ọwọ́ agbára, apá tí mo nà jáde àti ìbínú ni màá fi ṣàkóso yín.+ 34 Èmi yóò mú yín jáde láàárín àwọn èèyàn, màá sì fi ọwọ́ agbára, apá tí mo nà jáde àti ìbínú kó yín jọ láti àwọn ilẹ̀ tí ẹ ti fọ́n ká sí.+ 35 Èmi yóò mú yín wá sínú aginjù àwọn èèyàn, màá sì dá yín lẹ́jọ́ níbẹ̀ ní ojúkojú.+
36 “‘Bí mo ṣe dá àwọn baba ńlá yín lẹ́jọ́ nínú aginjù ilẹ̀ Íjíbítì, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe dá yín lẹ́jọ́,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 37 ‘Màá mú kí ẹ kọjá lábẹ́ ọ̀pá olùṣọ́ àgùntàn,+ màá sì mú kí ẹ tẹ̀ lé* májẹ̀mú náà. 38 Àmọ́ èmi yóò mú àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn tó ń ṣẹ̀ mí kúrò láàárín yín.+ Màá mú wọn kúrò ní ilẹ̀ àjèjì tí wọ́n wà, àmọ́ wọn ò ní wọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì;+ ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’
39 “Ní tìrẹ, ìwọ ilé Ísírẹ́lì, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Kí kálukú yín lọ sin àwọn òrìṣà ẹ̀gbin rẹ̀.+ Àmọ́, tí ẹ kò bá fetí sí mi lẹ́yìn náà, ẹ ò ní lè fi àwọn ẹbọ yín àti àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ mi mọ́.’+
40 “‘Torí ní òkè mímọ́ mi, ní òkè gíga Ísírẹ́lì,+ ni gbogbo ilé Ísírẹ́lì yóò ti sìn mí ní ilẹ̀ náà, gbogbo wọn pátá,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.+ ‘Inú mi yóò dùn sí wọn níbẹ̀, èmi yóò sì béèrè ọrẹ yín àti àwọn àkọ́so ẹ̀bùn yín, gbogbo ohun mímọ́ yín.+ 41 Òórùn dídùn* náà yóò mú kí inú mi dùn sí yín, nígbà tí mo bá mú yín jáde láàárín àwọn èèyàn, tí mo sì kó yín jọ láti àwọn ilẹ̀ tí ẹ fọ́n ká sí;+ màá sì fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ láàárín yín níṣojú àwọn orílẹ̀-èdè.’+
42 “‘Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,+ nígbà tí mo bá mú yín wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì,+ sí ilẹ̀ tí mo búra pé màá fún àwọn baba ńlá yín. 43 Ibẹ̀ ni ẹ ó sì ti rántí gbogbo ìwà àti ìṣe yín tí ẹ fi sọ ara yín di aláìmọ́,+ ẹ ó sì kórìíra ara* yín nítorí gbogbo ohun búburú tí ẹ ṣe.+ 44 Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá dojú ìjà kọ yín nítorí orúkọ mi,+ kì í ṣe nítorí ìwà búburú yín tàbí ìwà ìbàjẹ́ yín, ìwọ ilé Ísírẹ́lì,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
45 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 46 “Ọmọ èèyàn, yíjú sí gúúsù, kí o kéde ọ̀rọ̀ fún gúúsù, kí o sì sọ tẹ́lẹ̀ fún igbó tó wà ní oko gúúsù. 47 Sọ fún igbó tó wà ní gúúsù pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà. Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò dáná sun ọ́,+ yóò sì jó gbogbo igi tútù àti gbogbo igi gbígbẹ inú rẹ run. Iná tó ń jó náà kò ní kú,+ yóò sì jó gbogbo ojú láti gúúsù dé àríwá. 48 Gbogbo ẹlẹ́ran ara* yóò wá rí i pé èmi Jèhófà, ló dáná sun ún, iná náà kò sì ní kú.”’”+
49 Mo sì sọ pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Ohun tí wọ́n ń sọ nípa mi ni pé, ‘Ṣebí àlọ́* lásán ló ń pa?’”