Àwọn Ọba Kìíní
13 Èèyàn Ọlọ́run+ kan wá láti Júdà sí Bẹ́tẹ́lì bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún un, nígbà tí Jèróbóámù dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ+ láti mú ẹbọ rú èéfín. 2 Ó kéde sórí pẹpẹ náà bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún un, ó ní: “Ìwọ pẹpẹ, pẹpẹ! Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Wò ó! Wọ́n á bí ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jòsáyà+ ní ilé Dáfídì! Ó máa fi àwọn àlùfáà ibi gíga rúbọ lórí rẹ, ìyẹn àwọn tó ń mú ẹbọ rú èéfín lórí rẹ, ó sì máa sun egungun èèyàn lórí rẹ.’”+ 3 Ó fi àmì kan* hàn ní ọjọ́ yẹn, ó sọ pé: “Àmì* tí Jèhófà sọ nìyí: Wò ó! Pẹpẹ náà yóò là sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, eérú* tó wà lórí rẹ̀ yóò sì dà nù.”
4 Bí Jèróbóámù ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ tí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà kéde sórí pẹpẹ tó wà ní Bẹ́tẹ́lì, ó na ọwọ́ rẹ̀ láti ibi pẹpẹ, ó sì sọ pé: “Ẹ gbá a mú!”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọwọ́ tó nà sí i gbẹ,* kò sì lè fà á pa dà.+ 5 Ni pẹpẹ náà bá là sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, eérú sì dà kúrò lórí pẹpẹ náà, bí àmì* tí Jèhófà sọ fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà.
6 Ọba wá sọ fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà pé: “Jọ̀wọ́, bá mi bẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ* pé kó ṣojú rere sí mi, sì bá mi gbàdúrà kí ọwọ́ mi lè pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀.”+ Ni èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà bá bẹ Jèhófà pé kó ṣojú rere sí i, ọwọ́ ọba sì pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. 7 Lẹ́yìn náà, ọba sọ fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà pé: “Jẹ́ ká jọ lọ sílé, kí o lè jẹun, kí n sì fún ọ ní ẹ̀bùn.” 8 Àmọ́ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà sọ fún ọba pé: “Tí o bá tiẹ̀ fún mi ní ìdajì ilé rẹ, mi ò ní bá ọ lọ, kí n sì jẹun tàbí kí n mu omi ní ibí yìí. 9 Nítorí àṣẹ tí Jèhófà pa fún mi ni pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ jẹun tàbí kí o mu omi, o ò sì gbọ́dọ̀ gba ọ̀nà tí o gbà lọ pa dà.’” 10 Torí náà, ó gba ọ̀nà míì lọ, kò sì gba ọ̀nà tó gbà wá sí Bẹ́tẹ́lì pa dà.
11 Wòlíì àgbà kan wà tó ń gbé ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn ọmọ rẹ̀ wá sílé, wọ́n sì ròyìn gbogbo ohun tí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ṣe lọ́jọ́ náà ní Bẹ́tẹ́lì fún un àti ọ̀rọ̀ tó sọ fún ọba. Lẹ́yìn tí wọ́n sọ gbogbo rẹ̀ fún bàbá wọn, 12 bàbá wọn béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ọ̀nà wo ni ó gbà lọ?” Torí náà, àwọn ọmọ rẹ̀ fi ọ̀nà tí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́, tó wá láti Júdà, gbà lọ hàn án. 13 Ó wá sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Ẹ bá mi di ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”* Wọ́n bá a di ohun ti wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,* ó sì gùn ún.
14 Ó wá èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà lọ, ó sì rí i tó jókòó lábẹ́ igi ńlá kan. Ni ó bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé ìwọ ni èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ tó wá láti Júdà?”+ Ó fèsì pé: “Èmi ni.” 15 Ó sọ fún un pé: “Jẹ́ ká jọ lọ sílé, kí o lè jẹun.” 16 Àmọ́ ó sọ pé: “Mi ò lè bá ọ pa dà tàbí kí n ṣe ohun tí o sọ, bẹ́ẹ̀ ni mi ò ní jẹun tàbí kí n mu omi pẹ̀lú rẹ ní ibí yìí. 17 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ fún mi ni pé, ‘O ò gbọ́dọ̀ jẹun tàbí kí o mu omi níbẹ̀. O ò sì gbọ́dọ̀ gba ọ̀nà tí o gbà lọ pa dà.’” 18 Ni ó bá sọ fún un pé: “Wòlíì bíi tìẹ ni èmi náà, áńgẹ́lì kan sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà fún mi pé, ‘Ní kó bá ọ pa dà sílé, kí ó lè jẹun, kí ó sì mu omi.’” (Ó tàn án jẹ.) 19 Nítorí náà, ó bá a pa dà lọ kí ó lè jẹun, kí ó sì mu omi.
20 Bí wọ́n ti jókòó nídìí tábìlì, Jèhófà bá wòlíì tí ó mú un pa dà wá sọ̀rọ̀, 21 ó pe èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ tí ó wá láti Júdà, ó sì sọ pé, “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Nítorí pé o kọ ìtọ́ni Jèhófà, o kò sì pa àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, 22 ṣùgbọ́n o pa dà lọ, kí o lè jẹun, kí o sì mu omi ní ibi tí ó sọ fún ọ pé, “Má jẹun, má sì mu omi,” wọn ò ní sin òkú rẹ sí ibi tí wọ́n sin àwọn baba ńlá rẹ+ sí.’”
23 Lẹ́yìn tí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà jẹun tán, tí ó sì mu, wòlíì àgbà náà de ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* fún wòlíì tí ó mú pa dà wá. 24 Lẹ́yìn náà, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà bọ́ sọ́nà, àmọ́ kìnnìún kan yọ sí i lójú ọ̀nà, ó sì pa á.+ Òkú rẹ̀ wà lójú ọ̀nà, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó gùn sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀; kìnnìún náà sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú náà. 25 Àwọn èèyàn tó ń kọjá rí òkú náà lójú ọ̀nà àti kìnnìún tó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú náà. Wọ́n wọ inú ìlú tí wòlíì àgbà náà ń gbé, wọ́n sì ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
26 Nígbà tí wòlíì tí ó mú un pa dà láti ojú ọ̀nà gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ pé: “Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ tó kọ ìtọ́ni Jèhófà ni;+ ìdí nìyẹn tí Jèhófà ṣe fi í lé kìnnìún lọ́wọ́ láti ṣe é léṣe, kí ó sì pa á, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún un.”+ 27 Ó wá sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Ẹ bá mi de ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”* Torí náà, wọ́n bá a dè é mọ́ ọn. 28 Lẹ́yìn náà, ó bọ́ sọ́nà, ó sì rí òkú náà lójú ọ̀nà pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kìnnìún náà kò jẹ òkú náà, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà léṣe. 29 Wòlíì náà gbé òkú èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì gbé e pa dà wá sí ìlú rẹ̀ láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, kí ó sì sin ín. 30 Torí náà, ó sin òkú náà sínú ibojì ti ara rẹ̀, wọ́n sì ń sunkún nítorí rẹ̀, wọ́n ń sọ pé: “Ó mà ṣe o, arákùnrin mi!” 31 Lẹ́yìn tí ó sin ín, ó sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Nígbà tí mo bá kú, ibi tí mo sin èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ yìí sí ni kí ẹ sin mí sí. Ẹ̀gbẹ́ egungun rẹ̀+ ni kí ẹ kó egungun mi sí. 32 Ó dájú pé ọ̀rọ̀ Jèhófà tí wòlíì náà kéde sórí pẹpẹ tó wà ní Bẹ́tẹ́lì àti sórí gbogbo àwọn ilé ìjọsìn tó wà lórí àwọn ibi gíga+ ní àwọn ìlú Samáríà máa ṣẹ.”+
33 Kódà lẹ́yìn tí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀, Jèróbóámù kò yí pa dà kúrò nínú ọ̀nà búburú rẹ̀, ńṣe ló ń yan ẹnikẹ́ni lára àwọn èèyàn náà láti fi ṣe àlùfáà ní àwọn ibi gíga.+ Ẹni tí ó bá wù ú ló máa ń fi ṣe àlùfáà,* á sì sọ pé: “Jẹ́ kó di ọ̀kan lára àwọn àlùfáà ibi gíga.”+ 34 Ẹ̀ṣẹ̀ agbo ilé Jèróbóámù+ yìí ló yọrí sí ìparun wọn, tí wọ́n sì pa rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀.+