Àkọsílẹ̀ Mátíù
14 Ní àkókò yẹn, Hẹ́rọ́dù, alákòóso agbègbè náà,* gbọ́ ìròyìn nípa Jésù,+ 2 ó sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Jòhánù Arinibọmi nìyí. A ti jí i dìde, ìdí sì nìyẹn tó fi lè ṣe àwọn iṣẹ́ agbára yìí.”+ 3 Hẹ́rọ́dù* ti mú Jòhánù, ó dè é, ó sì fi sẹ́wọ̀n torí Hẹrodíà, ìyàwó Fílípì arákùnrin rẹ̀.+ 4 Jòhánù sì ti ń sọ fún un pé: “Kò bófin mu fún ọ láti fẹ́ obìnrin yìí.”+ 5 Àmọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́ pa á, ó ń bẹ̀rù àwọn èèyàn, torí pé wòlíì ni wọ́n kà á sí.+ 6 Àmọ́ nígbà tí wọ́n ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí+ Hẹ́rọ́dù, ọmọbìnrin Hẹrodíà jó níbi ayẹyẹ náà, ó sì múnú Hẹ́rọ́dù dùn gan-an+ 7 débi pé ó ṣèlérí, ó sì búra pé òun máa fún un ní ohunkóhun tó bá béèrè. 8 Ìyá ọmọbìnrin náà kọ́ ọ ní ohun tó máa sọ, ó sì sọ pé: “Fún mi ní orí Jòhánù Arinibọmi níbí yìí nínú àwo pẹrẹsẹ.”+ 9 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ọba ò dùn rárá, ó pàṣẹ pé kí wọ́n fún un, torí pé ó ti búra àti torí àwọn tó ń bá a jẹun.* 10 Ó wá ránṣẹ́ pé kí wọ́n lọ bẹ́ orí Jòhánù nínú ẹ̀wọ̀n. 11 Wọ́n gbé orí rẹ̀ wá nínú àwo pẹrẹsẹ, wọ́n sì fún ọmọbìnrin náà, ó wá gbé e wá fún ìyá rẹ̀. 12 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá gbé òkú rẹ̀ kúrò, wọ́n sì sin ín; wọ́n wá ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Jésù. 13 Nígbà tí Jésù gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibi tó dá, kó lè dá wà. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn èrò gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n fi ẹsẹ̀ rìn tẹ̀ lé e látinú àwọn ìlú.+
14 Nígbà tó wá sí etíkun, ó rí èrò rẹpẹtẹ, àánú wọn ṣe é,+ ó sì wo àwọn tó ń ṣàìsàn nínú wọn sàn.+ 15 Àmọ́ nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sọ pé: “Ibí yìí dá, ọjọ́ sì ti lọ; jẹ́ kí àwọn èèyàn yìí máa lọ, kí wọ́n lè lọ sínú àwọn abúlé, kí wọ́n sì ra ohun tí wọ́n máa jẹ.”+ 16 Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún wọn pé: “Wọn ò nílò kí wọ́n lọ; ẹ fún wọn ní nǹkan tí wọ́n máa jẹ.” 17 Wọ́n sọ fún un pé: “A ò ní nǹkan kan níbí àfi búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì.” 18 Ó sọ pé: “Ẹ mú un wá síbí fún mi.” 19 Ó wá sọ fún àwọn èrò náà pé kí wọ́n jókòó* sórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó wo ojú ọ̀run, ó sì súre,+ lẹ́yìn tó bu búrẹ́dì náà, ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì fún àwọn èrò náà. 20 Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì kó èyí tó ṣẹ́ kù jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá (12).+ 21 Àwọn tó jẹun tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.+ 22 Láìjáfara, ó mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi, kí wọ́n sì lọ ṣáájú rẹ̀ sí etíkun tó wà ní òdìkejì, ó sì ní kí àwọn èrò náà máa lọ.+
23 Lẹ́yìn tó ní kí àwọn èrò náà máa lọ, òun nìkan lọ sórí òkè láti gbàdúrà.+ Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, òun nìkan ló wà níbẹ̀. 24 Ní àkókò yẹn, ọkọ̀ ojú omi náà ti wà ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìwọ̀n yáàdì* sí orí ilẹ̀, wọ́n ń bá ìgbì òkun fà á, torí pé atẹ́gùn náà ń dà wọ́n láàmú. 25 Àmọ́ ní ìṣọ́ kẹrin òru,* ó wá bá wọn, ó ń rìn lórí òkun. 26 Nígbà tí wọ́n tajú kán rí i tó ń rìn lórí òkun, ọkàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ò balẹ̀, wọ́n sọ pé: “Ìran abàmì nìyí!” Wọ́n bá kígbe torí ẹ̀rù bà wọ́n. 27 Àmọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ mọ́kàn le! Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.”+ 28 Pétérù sọ fún un pé: “Olúwa, tó bá jẹ́ ìwọ ni, pàṣẹ fún mi pé kí n wá bá ọ lórí omi.” 29 Ó sọ pé: “Máa bọ̀!” Pétérù wá jáde nínú ọkọ̀ ojú omi, ó rìn lórí omi, ó sì ń lọ sọ́dọ̀ Jésù. 30 Àmọ́ nígbà tó wo ìjì tó ń jà, ẹ̀rù bà á. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í rì, ó ké jáde pé: “Olúwa, gbà mí!” 31 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jésù na ọwọ́ rẹ̀, ó sì dì í mú, ó sọ fún un pé: “Ìwọ tí ìgbàgbọ́ rẹ kéré, kí ló dé tí o fi ṣiyèméjì?”+ 32 Lẹ́yìn tí wọ́n wọnú ọkọ̀ ojú omi náà, ìjì tó ń jà rọlẹ̀. 33 Àwọn tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi náà wá tẹrí ba* fún un, wọ́n sọ pé: “Ọmọ Ọlọ́run ni ọ́ lóòótọ́.” 34 Wọ́n sọdá, wọ́n sì gúnlẹ̀ sí Jẹ́nẹ́sárẹ́tì.+
35 Nígbà tí àwọn èèyàn ibẹ̀ wá mọ̀ pé òun ni, wọ́n ránṣẹ́ sí gbogbo ìgbèríko tó wà ní àyíká yẹn, àwọn èèyàn sì mú gbogbo àwọn tó ń ṣàìsàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 36 Wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kí àwọn ṣáà fọwọ́ kan wajawaja tó wà létí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+ ara gbogbo àwọn tó fọwọ́ kàn án sì yá pátápátá.