Ìsíkíẹ́lì
9 Lẹ́yìn náà, ó fi ohùn tó dún ketekete bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Pe àwọn tí yóò fìyà jẹ ìlú náà wá, kí kálukú wọn mú ohun ìjà tó máa fi pa á run dání!”
2 Mo rí ọkùnrin mẹ́fà tí wọ́n ń bọ̀ láti ẹnubodè apá òkè,+ tó dojú kọ àríwá, kálukú mú ohun ìjà tí wọ́n fi ń fọ́ nǹkan dání; ọkùnrin kan wà lára wọn tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀,* ìwo yíǹkì akọ̀wé* sì wà ní ìbàdí rẹ̀. Wọ́n wọlé, wọ́n sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ bàbà.+
3 Ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì+ wá gbéra lórí àwọn kérúbù níbi tó wà tẹ́lẹ̀, lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé náà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pe ọkùnrin tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, tí ìwo yíǹkì akọ̀wé wà ní ìbàdí rẹ̀. 4 Jèhófà sọ fún un pé: “Lọ káàkiri ìlú náà, káàkiri Jerúsálẹ́mù, kí o sì sàmì sí iwájú orí àwọn èèyàn tó ń kẹ́dùn, tí wọ́n sì ń kérora+ torí gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe ní ìlú náà.”+
5 Mo sì gbọ́ tó sọ fún àwọn yòókù pé: “Ẹ tẹ̀ lé e káàkiri ìlú náà, kí ẹ sì pa wọ́n. Ẹ má ṣàánú wọn, ẹ má sì yọ́nú sí wọn rárá.+ 6 Ẹ pa àwọn àgbàlagbà ọkùnrin pátápátá àti àwọn géńdé ọkùnrin, wúńdíá, ọmọdé àti àwọn obìnrin.+ Àmọ́ ẹ má ṣe sún mọ́ ẹnikẹ́ni tí àmì náà wà lórí rẹ̀.+ Ibi mímọ́ mi ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀.”+ Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà níwájú ilé náà.+ 7 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ sọ ilé náà di ẹlẹ́gbin, kí ẹ sì fi òkú èèyàn kún inú àwọn àgbàlá.+ Ẹ lọ!” Ni wọ́n bá lọ, wọ́n sì pa àwọn èèyàn ní ìlú náà.
8 Bí wọ́n ṣe ń pa wọ́n, ó wá ku èmi nìkan, mo bá dojú bolẹ̀, mo sì ké jáde pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Ṣé inú tó ń bí ọ sí Jerúsálẹ́mù máa mú kí o pa gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì run ni?”+
9 Torí náà, ó sọ fún mi pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì àti Júdà pọ̀ gidigidi.+ Ìtàjẹ̀sílẹ̀ kún ilẹ̀ náà,+ ìwà ìbàjẹ́ sì kún ìlú náà.+ Wọ́n ń sọ pé, ‘Jèhófà ti fi ilẹ̀ wa sílẹ̀, Jèhófà ò sì rí wa.’+ 10 Àmọ́ ní tèmi, mi ò ní ṣàánú wọn, mi ò sì ní yọ́nú sí wọn.+ Màá fi ìwà wọn san wọ́n lẹ́san.”
11 Mo wá rí ọkùnrin tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀, tí ìwo yíǹkì wà ní ìbàdí rẹ̀, ó pa dà wá jíṣẹ́ pé: “Mo ti ṣe ohun tí o pa láṣẹ fún mi.”