ORÍ 16
“Sàmì sí Iwájú Orí” Wọn
OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Bí wọ́n ṣe sàmì sí àwọn olóòótọ́ tó máa là á já nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì àti ìtumọ̀ àmì náà lóde òní
1-3. (a) Kí nìdí tí ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí fi yà á lẹ́nu, kí ló sì wá mọ̀ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò?
OHUN tí Ìsíkíẹ́lì rí yà á lẹ́nu gan-an! Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ìran àwọn ohun ìríra tí àwọn Júù apẹ̀yìndà ń ṣe nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù.a Àwọn ọlọ̀tẹ̀ èèyàn yẹn ti sọ ibi tó jẹ́ ojúkò ìjọsìn mímọ́ ní Ísírẹ́lì di ẹlẹ́gbin. Àmọ́, wọn ò fi ẹ̀gbin yẹn mọ sí tẹ́ńpìlì nìkan. Wọ́n tún fi ìwà ipá kún gbogbo ilẹ̀ Júdà débi pé ọ̀rọ̀ náà kọjá àtúnṣe. Ohun táwọn èèyàn Jèhófà tí wọ́n jẹ́ àyànfẹ́ rẹ̀ ṣe dùn ún gan-an débi tó fi sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé: “Màá bínú sí wọn.”—Ìsík. 8:17, 18.
2 Ẹ wo bí inú Ìsíkíẹ́lì ṣe máa bà jẹ́ tó nígbà tó wá mọ̀ pé Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ tó ti fìgbà kan rí jẹ́ ibi mímọ́ ni Jèhófà ń bínú sí báyìí, tó sì fẹ́ pa á run! Àmọ́ Ìsíkíẹ́lì lè máa rò ó pé: ‘Àwọn olóòótọ́ èèyàn tó wà nílùú yìí ńkọ́? Ṣé ó máa dá ẹ̀mí wọn sí báyìí? Báwo ló tiẹ̀ ṣe máa dá wọn sí?’ Kò pẹ́ rárá tí Ìsíkíẹ́lì rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yẹn. Bó ṣe ń gbọ́ ìdájọ́ mímúná tó ń bọ̀ sórí Jerúsálẹ́mù tán, bẹ́ẹ̀ ló gbọ́ ohùn kan tó ròkè, tó ń pe àwọn tó máa mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ. (Ìsík. 9:1) Bí ìran náà ṣe ń lọ, wòlíì yìí wá rí i pé àwọn kan ló máa pa run, kì í ṣe gbogbo èèyàn, ìyẹn sì fi í lọ́kàn balẹ̀ gan-an. Ó dá a lójú pé àwọn ẹni yíyẹ máa là á já!
3 Bí òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí ṣe ń sún mọ́lé, àwa náà lè máa ronú nípa bá a ṣe máa la ìparun tó sún mọ́lé yìí já. Torí náà, ẹ jẹ́ ká wá ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí: (1) Kí ni Ìsíkíẹ́lì tún rí nínú ìran? (2) Báwo ni ìran náà ṣe ṣẹ nígbà ayé rẹ̀? (3) Ìtumọ̀ wo ni ìran alásọtẹ́lẹ̀ yẹn ní fún wa lóde òní?
“Pe Àwọn Tí Yóò Fìyà Jẹ Ìlú Náà”
4. Sọ ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí àti ohun tó tún gbọ́ nínú ìran náà.
4 Kí ni Ìsíkíẹ́lì tún rí tó sì tún gbọ́ nínú ìran náà? (Ka Ìsíkíẹ́lì 9:1-11.) Ó rí ọkùnrin méje tí wọ́n “ń bọ̀ láti ẹnubodè apá òkè, tó dojú kọ àríwá,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ní tòsí ibi tí ère owú wà tàbí ibi tí àwọn obìnrin ti ń sunkún torí ọlọ́run tí wọ́n ń pè ní Támúsì. (Ìsík. 8:3, 14) Àwọn ọkùnrin méje náà wọ àgbàlá inú ní tẹ́ńpìlì, wọ́n sì dúró ní tòsí pẹpẹ bàbà tí wọ́n ti ń rúbọ. Àmọ́ kì í ṣe pé àwọn ọkùnrin yìí fẹ́ wá rúbọ o. Jèhófà ò kúkú tẹ́wọ́ gba ẹbọ tí wọ́n ń rú níbẹ̀ mọ́. Mẹ́fà lára wọn dúró, “kálukú mú ohun ìjà tí wọ́n fi ń fọ́ nǹkan dání.” Ọkùnrin keje yàtọ̀ sáwọn yòókù. Ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀, kò mú ohun ìjà, “ìwo yíǹkì akọ̀wé” ló mú dání, tàbí bó ṣe wà nínú àlàyé ìsàlẹ̀, “ibi tí akọ̀wé ń rọ yíǹkì sí.”
5, 6. Kí la lè sọ nípa àwọn tí wọ́n sàmì sí lórí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.)
5 Kí ni ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì náà fẹ́ ṣe? Jèhófà gbé iṣẹ́ pàtàkì kan fún un, ó ní: “Lọ káàkiri ìlú náà, káàkiri Jerúsálẹ́mù, kí o sì sàmì sí iwájú orí àwọn èèyàn tó ń kẹ́dùn, tí wọ́n sì ń kérora torí gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe ní ìlú náà.” Lójú ẹsẹ̀, ó ṣeé ṣe kí Ìsíkíẹ́lì rántí bí àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ní Ísírẹ́lì ṣe fi ẹ̀jẹ̀ sàmì sí òkè ẹnu ọ̀nà àtàwọn òpó ilẹ̀kùn wọn, kí àwọn àkọ́bí wọn má bàa pa run. (Ẹ́kís. 12:7, 22, 23) Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí yìí, ṣé iṣẹ́ kan náà ni àmì ọkùnrin tó gbé ìwo yíǹkì dání yìí ń ṣe, ìyẹn àmì tó ń fi síwájú orí àwọn èèyàn? Ṣé ó túmọ̀ sí pé ẹni tó bá ti ní àmì náà máa la ìparun Jerúsálẹ́mù já?
6 Ìdáhùn ìbéèrè yìí máa ṣe kedere tá a bá wo ohun tó ń mú wọn sàmì yẹn sórí àwọn èèyàn. Iwájú orí àwọn “tó ń kẹ́dùn, tí wọ́n sì ń kérora” torí àwọn ohun ìríra “tí wọ́n ń ṣe ní ìlú náà” ni wọ́n ń sàmì sí. Kí nìyẹn ń sọ fún wa nípa àwọn tí wọ́n sàmì sì lórí? Àkọ́kọ́ ni pé, kì í ṣe torí ìbọ̀rìṣà tí wọ́n ń ṣe nínú tẹ́ńpìlì nìkan ni ẹ̀dùn ọkàn ṣe bá wọn, àmọ́ wọ́n tún kẹ́dùn torí gbogbo ìwà ipá, ìṣekúṣe àti ìwà ìbàjẹ́ tó kúnnú Jerúsálẹ́mù. (Ìsík. 22:9-12) Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wọn ò fi bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára wọn pa mọ́. Ó dájú pé ọ̀rọ̀ ẹnu àti ìwà àwọn olóòótọ́ èèyàn yìí fi hàn pé wọ́n kórìíra àwọn ohun tó ń wáyé nílẹ̀ náà àti pé ìjọsìn mímọ́ ló jẹ wọ́n lógún. Jèhófà máa ṣàánú àwọn ẹni yíyẹ yìí, ó sì máa dá ẹ̀mí wọn sí.
7, 8. Báwo ni àwọn ọkùnrin mẹ́fà tí wọ́n mú ohun ìjà tí wọ́n fi ń fọ́ nǹkan dání ṣe máa ṣiṣẹ́ tiwọn? Ibo lọ̀rọ̀ náà wá já sí?
7 Báwo wá ni àwọn ọkùnrin mẹ́fà tí wọ́n mú ohun ìjà tí wọ́n fi ń fọ́ nǹkan dání ṣe máa ṣiṣẹ́ tiwọn? Ìsíkíẹ́lì gbọ́ ohun tí Jèhófà sọ fún wọn pé: Ẹ tẹ̀ lé ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì, kí ẹ sì pa gbogbo wọn àfi ẹni tí àmì náà bá wà níwájú orí rẹ̀. Jèhófà pàṣẹ fún wọn pé: “Ibi mímọ́ mi ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀.” (Ìsík. 9:6) Ibi tó ṣe pàtàkì jù ní Jerúsálẹ́mù ni wọ́n á ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wọn, ìyẹn inú tẹ́ńpìlì, ibẹ̀ kì í ṣe ibi mímọ́ mọ́ lójú Jèhófà. “Àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà níwájú ilé náà” ni wọ́n á kọ́kọ́ pa, ìyẹn àwọn àádọ́rin (70) àgbààgbà Ísírẹ́lì tí wọ́n ń fín tùràrí sí àwọn ọlọ́run èké ní tẹ́ńpìlì.—Ìsík. 8:11, 12; 9:6.
8 Ibo lọ̀rọ̀ náà wá já sí? Bí Ìsíkíẹ́lì ṣe ń wò tó sì ń tẹ́tí sílẹ̀, ó gbọ́ tí ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì wá jábọ̀ fún Jèhófà pé: “Mo ti ṣe ohun tí o pa láṣẹ fún mi.” (Ìsík. 9:11) A lè máa wò ó pé: ‘Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù? Ǹjẹ́ olóòótọ́ èèyàn kankan la ìparun yẹn já báyìí?’
Báwo Ni Ìran Yìí Ṣe Ṣẹ Nígbà Ayé Ìsíkíẹ́lì?
9, 10. Àwọn wo ló wà lára àwọn olóòótọ́ èèyàn tó la ìparun Jerúsálẹ́mù já? Kí la sì lè sọ nípa wọn?
9 Ka 2 Kíróníkà 36:17-20. Àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì ṣẹ lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà tí àwọn ọmọ ogun Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run. Jèhófà fi Bábílónì ṣe ohun èlò, bí ‘ife ní ọwọ́ Jèhófà’ tó fi da ìyà sórí àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù tí wọ́n ya aláìṣòótọ́. (Jer. 51:7) Ṣé gbogbo èèyàn ìlú náà ni wọ́n pa run? Rárá o. Ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn kan wà tí àwọn ará Bábílónì kò ní pa run.—Jẹ́n. 18:22-33; 2 Pét. 2:9.
10 Àwọn olóòótọ́ èèyàn kan la ìparun náà já, lára wọn ni àwọn ọmọ Rékábù, Ebedi-mélékì ará Etiópíà, Jeremáyà wòlíì àti Bárúkù akọ̀wé rẹ̀. (Jer. 35:1-19; 39:15-18; 45:1-5) Ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí jẹ́ ká rí i pé àwọn tá a mẹ́nu bà yìí á ti máa ‘kẹ́dùn, wọ́n á sì máa kérora torí gbogbo ohun ìríra’ tí wọ́n ń ṣe ní Jerúsálẹ́mù. (Ìsík. 9:4) Ṣáájú ìparun yẹn, wọ́n ti fi hàn kedere pé àwọn ò nífẹ̀ẹ́ sí ìwàkiwà àti pé ìjọsìn mímọ́ ló jẹ àwọn lógún, èyí ló jẹ́ kí wọ́n lè la ìparun yẹn já.
11. Àwọn wo ni ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì àtàwọn ọkùnrin mẹ́fà tí wọ́n mú ohun ìjà tí wọ́n fi ń fọ́ nǹkan dání ṣàpẹẹrẹ?
11 Ṣé àmì tá a lè fojú rí ni wọ́n fi síwájú orí àwọn olóòótọ́ èèyàn yẹn? Kò sí àkọsílẹ̀ tó fi hàn pé Ìsíkíẹ́lì tàbí wòlíì èyíkéyìí lọ káàkiri Jerúsálẹ́mù, tó sì wá ń sàmì tá a lè fojú rí síwájú orí àwọn olóòótọ́ èèyàn. Ó ṣe kedere nígbà náà pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lókè ọ̀run ni Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran tó fi sàsọtẹ́lẹ̀ yìí, kì í ṣohun táwa èèyàn lè fojú rí. Ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé àtàwọn ọkùnrin mẹ́fà tí wọ́n mú ohun ìjà tí wọ́n fi ń fọ́ nǹkan dání nínú ìran náà ṣàpẹẹrẹ àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ tí Jèhófà dá sí ọrun, tí wọ́n máa ń múra tán nígbà gbogbo láti jíṣẹ́ tó bá rán wọn. (Sm. 103:20, 21) Ó dájú pé Jèhófà lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù aláìṣòótọ́. Bí ẹni ń sàmì síwájú orí àwọn tó máa là á já, àwọn áńgẹ́lì náà rí i dájú pé gbogbo èèyàn kọ́ ló pa run, wọ́n dá ẹ̀mí àwọn kan sí.
Ìtumọ̀ Wo Ni Ìran Ìsíkíẹ́lì Ní Lóde Òní?
12, 13. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi bínú sí Jerúsálẹ́mù? Kí sì nìdí tá a fi retí pé kó bínú bẹ́ẹ̀ lóde òní? (b) Ṣé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni ìlú Jerúsálẹ́mù apẹ̀yìndà ṣàpẹẹrẹ? Ṣàlàyé. (Wo àpótí náà, “Ṣé Àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì Ni Ìlú Jerúsálẹ́mù Ṣàpẹẹrẹ?”)
12 Lóde òní, ìdájọ́ Ọlọ́run máa tó ṣẹ lọ́nà tí kò tíì wáyé rí, ìyẹn ni ‘ìpọ́njú ńlá, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé títí di báyìí, àní, irú rẹ̀ kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́.’ (Mát. 24:21) Bá a ṣe ń dúró de ìgbà tó máa ṣàrà ọ̀tọ̀ yẹn, àwọn ìbéèrè pàtàkì kan lè máa wá sí wa lọ́kàn: Ṣé èèyàn kankan máa la ìparun tó ń bọ̀ yẹn já? Ṣé wọ́n máa sàmì lọ́nà kan tàbí òmíì sórí àwọn tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́ Jèhófà? Lédè míì, ṣé ìran tí Ìsíkíẹ́lì fi sàsọtẹ́lẹ̀ nípa ọkùnrin tí ìwo yíǹkì wà níbàdí rẹ̀ yìí máa ṣẹ lóde òní? Bẹ́ẹ̀ ni, ni ìdáhùn ìbéèrè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká pa dà wo ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí.
13 Ṣé ẹ rántí ìdí tí Jèhófà fi bínú sí ìlú Jerúsálẹ́mù àtijọ́? Ẹ jẹ́ ká tún wo Ìsíkíẹ́lì 9:8, 9. (Kà á.) Nígbà tí ẹ̀rù ń ba Ìsíkíẹ́lì pé “gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì” lè bá ìparun náà lọ, Jèhófà sọ ohun mẹ́rin tó fà á tóun fi fẹ́ mú ìparun náà wá. Àkọ́kọ́ ni pé, ‘ẹ̀ṣẹ̀ wọn pọ̀ gidigidi.’b Ìkejì ni pé “ìtàjẹ̀sílẹ̀ kún ilẹ̀” Júdà. Ìkẹta ni pé wọ́n fi “ìwà ìbàjẹ́ kún” Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú ìjọba Júdà. Ìkẹrin sì ni pé, àwọn èèyàn náà ń ṣàwáwí ìwàkiwà wọn, wọ́n ń sọ fúnra wọn pé Jèhófà ‘ò rí’ gbogbo ìwàkiwà tí wọ́n ń hù. Ó ṣe kedere pé ọ̀rọ̀ wọn ò yàtọ̀ sí tàwọn oníwà ipá èèyàn tí wọ́n ń fìwà ìbàjẹ́ ṣayọ̀ lóde òní, tí wọn ò sì rí ti Ọlọ́run rò. Ó dájú pé Jèhófà ‘kì í yí pa dà, kì í sì í sún kiri,’ torí náà ohun tó mú kó bínú lọ́nà òdodo nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì ṣì máa bí i nínú lóde òní. (Jém. 1:17; Mál. 3:6) Ìyẹn jẹ́ ká rí i nígbà náà pé àwọn ọkùnrin mẹ́fà tí wọ́n mú ohun ìjà tí wọ́n fi ń fọ́ nǹkan dání àti ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì máa ríṣẹ́ ṣe lóde òní!
14, 15. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé Jèhófà kìlọ̀ fáwọn èèyàn kó tó pa wọ́n run?
14 Àwọn ọ̀nà wo wá ni ìran tí Ìsíkíẹ́lì fi sàsọtẹ́lẹ̀ gbà ń ṣẹ lóde òní? Tá a bá wo bí ìran náà ṣe ṣẹ nígbà àtijọ́, àá mọ ohun tó yẹ ká máa retí báyìí àti lọ́jọ́ iwájú. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ohun tá a ti rí àtàwọn ohun tá a máa rí láti fi mọ bí asọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì ṣe ń ṣẹ.
15 Jèhófà kìlọ̀ fáwọn èèyàn kó tó pa wọ́n run. Bá a ṣe rí i ní Orí 11 nínú ìwé yìí, Jèhófà fi Ìsíkíẹ́lì “ṣe olùṣọ́ fún ilé Ísírẹ́lì.” (Ìsík. 3:17-19) Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 613 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Ìsíkíẹ́lì kìlọ̀ fún Ísírẹ́lì nípa ìparun tó ń bọ̀. Àwọn wòlíì míì, tó fi mọ́ Àìsáyà àti Jeremáyà, tún kìlọ̀ fún wọn nípa àjálù tó máa wá sórí Jerúsálẹ́mù. (Àìsá. 39:6, 7; Jer. 25:8, 9, 11) Lóde òní, Jèhófà ń tipasẹ̀ Jésù lo àwùjọ kéréje ti àwọn ẹni àmì òróró láti máa bọ́ àwọn tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́, ìyẹn àwọn ará ilé, wọ́n sì tún ń kìlọ̀ fáwọn èèyàn nípa ìpọ́njú ńlá tó ti dé tán.—Mát. 24:45.
16. Ṣé àwa èèyàn Jèhófà ló ń sàmì sórí àwọn tó máa là á já? Ṣàlàyé.
16 Àwa èèyàn Jèhófà kọ́ ló ń sàmì sórí àwọn tó máa là á já. Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé kì í ṣe Ìsíkíẹ́lì ni Jèhófà ní kó lọ káàkiri Jerúsálẹ́mù láti sàmì sórí àwọn tó máa là á já. Bákan náà, kì í ṣe àwa èèyàn Jèhófà òde òní ló máa sàmì sórí àwọn ẹni yíyẹ tó máa la ìpọ́njú ńlá já. Kàkà bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù ni Jèhófà gbé lé àwa ará ilé Kristi nípa tẹ̀mí lọ́wọ́. À ń fi hàn pé a fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ yìí tá a bá ń fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, tá a sì ń kìlọ̀ gbọnmọ-gbọnmọ fáwọn èèyàn pé òpin ayé búburú yìí ti dé tán. (Mát. 24:14; 28:18-20) À ń tipa bẹ́ẹ̀ kópa nínú ríran àwọn olóòótọ́ èèyàn lọ́wọ́ láti wá ṣe ìjọsìn mímọ́.—1 Tím. 4:16.
17. Kí ni kálukú ní láti ṣe nísinsìnyí, kí wọ́n lè sàmì sí wọn lórí lọ́jọ́ iwájú láti là á já?
17 Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ la ìparun tó ń bọ̀ já gbọ́dọ̀ fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ báyìí. Bá a ṣe rí i, àwọn tó la ìparun Jerúsálẹ́mù já lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ti fi hàn ṣáájú ìgbà yẹn pé àwọn ò fara mọ́ ìwàkiwà àti pé ìjọsìn mímọ́ làwọn kà sí pàtàkì jù. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí lóde òní. Ṣáájú kí ìparun náà tó dé, kálukú gbọ́dọ̀ máa ‘kẹ́dùn, kí wọ́n sì máa kérora,’ ìyẹn ni pé kí wọ́n máa fi hàn látọkàn wá pé inú àwọn ò dùn rárá sí gbogbo ìwàkiwà tó kúnnú ayé yìí. Wọn ò ní fi bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára wọn pa mọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ máa fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn pé ìjọsìn mímọ́ ló ṣe pàtàkì jù sí àwọn. Kí ni wọ́n máa ṣe láti fi hàn bẹ́ẹ̀? Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ gbọ́ ìwàásù kí wọ́n sì ṣe ohun tó yẹ, kí wọ́n túbọ̀ máa fi àwọn ànímọ́ Kristi ṣèwà hù, kí wọ́n ṣèrìbọmi láti fi hàn pé wọ́n ti yara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, kí wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn arákùnrin Kristi. (Ìsík. 9:4; Mát. 25:34-40; Éfé. 4:22-24; 1 Pét. 3:21) Kìkì àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí, tí wọ́n sì ń ṣe ìjọsìn mímọ́ títí dìgbà ìpọ́njú ńlá, ló máa lè wà lára àwọn tí wọ́n máa sàmì sí láti la ìpọ́njú ńlá já.
18. (a) Báwo ni Jésù ṣe máa sàmì sáwọn ẹni yíyẹ, ìgbà wo ló sì máa ṣe bẹ́ẹ̀? (b) Ṣé wọ́n máa sàmì síwájú orí àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró? Ṣàlàyé.
18 Ọ̀run ni wọ́n ti máa sàmì sáwọn ẹni yíyẹ. Nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì, àwọn ańgẹ́lì kópa nínú bí wọ́n ṣe sàmì sáwọn olóòótọ́ èèyàn tó la ìparun yẹn já. Nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn lóde òní, ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé ṣàpẹẹrẹ Jésù Kristi nígbà tó bá “dé nínú ògo rẹ̀” gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè. (Mát. 25:31-33) Ìgbà ìpọ́njú ńlá ni Jésù máa dé, lẹ́yìn tí ìsìn èké bá pa run.c Ní àkókò tó ṣe pàtàkì yẹn, kí ogun Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀, Jésù máa ṣèdájọ́, á ka àwọn èèyàn sí àgùntàn tàbí ewúrẹ́. Ó máa ṣèdájọ́ “ogunlọ́gọ̀ èèyàn,” lédè míì, ó máa sàmì sí wọn pé wọ́n jẹ́ àgùntàn, ìyẹn fi hàn pé wọ́n á “lọ . . . sínú ìyè àìnípẹ̀kun.” (Ìfi. 7:9-14; Mát. 25:34-40, 46) Àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró ńkọ́? Wọn ò nílò láti gba àmì táá mú kí wọ́n la Amágẹ́dọ́nì já. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á gba èdìdì wọn tó kẹ́yìn kí wọ́n tó kú tàbí kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn náà, a máa gbé wọn lọ sí ọ̀run láàárín kan, kí Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀.—Ìfi. 7:1-3.
19. Jésù àtàwọn wo ló jọ máa mú ìdájọ́ ṣẹ sórí ètò àwọn nǹkan yìí? (Wo àpótí náà, “Ìgbà Wo Ni Ìkẹ́dùn, Ìkérora, Ìsàmì àti Fífọ́ Nǹkan Máa Ṣẹlẹ̀? Báwo Ló sì Ṣe Máa Ṣẹlẹ̀?”)
19 Jésù Kristi, Ọba tó jẹ ní ọ̀run, àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ọ̀run máa ṣèdájọ́ ètò àwọn nǹkan yìí. Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, àwọn ọkùnrin mẹ́fà tó mú ohun èlò tí wọ́n fi ń fọ́ nǹkan dání dúró dìgbà tí ọkùnrin tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ parí sísàmì sórí àwọn èèyàn, kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í pa wọ́n run. (Ìsík. 9:4-7) Bákan náà, lẹ́yìn tí Jésù bá ṣèdájọ́ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè tán, tó sì sàmì sí àwọn àgùntàn tó máa là á já ni ìparun tó ń bọ̀ náà máa bẹ̀rẹ̀. Tó bá wá dìgbà ogun Amágẹ́dọ́nì, Jésù máa ṣáájú àwọn ọmọ ogun ọ̀run, ìyẹn àwọn ańgẹ́lì mímọ́ àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n jọ máa jọba, láti mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ sórí ayé búburú yìí. Wọ́n máa pa ayé búburú yìí run pátápátá, wọ́n á sì gba àwọn tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́ là sínú ayé tuntun.—Ìfi. 16:14-16; 19:11-21.
20. Kí làwọn ohun tó fi wá lọ́kàn balẹ̀ tá a rí kọ́ nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé?
20 A dúpẹ́ gidigidi pé a rí àwọn ohun tó fi wá lọ́kàn balẹ̀ kọ́ nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé! Ó dá wa lójú gbangba pé Jèhófà ò ní pa olódodo run pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú. (Sm. 97:10) A ti mohun tó yẹ ká ṣe báyìí kí wọ́n lè sàmì sí wa lọ́jọ́ iwájú láti la ìparun tó ń bọ̀ já. Àwa tá à ń jọ́sìn Jèhófà ti pinnu pé a ó máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa kéde ìhìn rere, ká sì máa ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn tó ń kẹ́dùn, tí wọ́n sì ń kérora nítorí àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé Sátánì. Ìyẹn á jẹ́ ká láǹfààní láti ran àwọn “olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun” lọ́wọ́, kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ wa nínú ìjọsìn mímọ́, kí wọ́n sì lè wà lára àwọn tí wọ́n máa sàmì sí láti la ìparun ayé yìí já sínú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run.—Ìṣe 13:48.
a Ní Orí 5 ìwé yìí, a ti sọ̀rọ̀ nípa ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, èyí tó dá lorí àwọn ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe nínú tẹ́ńpìlì.
b Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ fi hàn pé, ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “ẹ̀ṣẹ̀” tún lè tọ́ka sí “ẹni tó ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tí kò dáa.” Ìwé míì sọ pé ọ̀rọ̀ yìí “wá látọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn, wọ́n sì máa ń lò ó lọ́pọ̀ ìgbà láti fi ṣàpèjúwe ìwà ẹ̀bi tàbí ìwàkiwà lójú Ọlọ́run.”
c Ó ṣeé ṣe kí gbogbo àwọn tó wà nínú ẹ̀sìn èké má pa run nígbà ìparun Bábílónì Ńlá. Torí pé nígbà yẹn, ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára àwọn aṣáájú ẹ̀sìn pàápàá fi ẹ̀sìn èké sílẹ̀, kí wọ́n sì sẹ́ pé àwọn ò ṣe é rí.—Sek. 13:3-6.