Jẹ́nẹ́sísì
42 Nígbà tí Jékọ́bù gbọ́ pé ọkà wà ní Íjíbítì,+ ó sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí ẹ kàn ń wo ara yín lójú?” 2 Ó ní: “Mo ti gbọ́ pé ọkà wà ní Íjíbítì. Ẹ lọ rà á wá níbẹ̀ fún wa, ká lè wà láàyè, ká má bàa kú.”+ 3 Mẹ́wàá nínú àwọn arákùnrin+ Jósẹ́fù wá lọ ra ọkà ní Íjíbítì. 4 Àmọ́ Jékọ́bù ò jẹ́ kí Bẹ́ńjámínì+ àbúrò Jósẹ́fù tẹ̀ lé àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yòókù, torí ó sọ pé: “Jàǹbá lè lọ ṣe é.”+
5 Àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì lọ pẹ̀lú àwọn míì tí wọ́n fẹ́ ra oúnjẹ, torí pé ìyàn náà ti dé ilẹ̀ Kénáánì.+ 6 Jósẹ́fù ló ní àṣẹ lórí ilẹ̀+ Íjíbítì, òun ló sì ń ta ọkà fún gbogbo èèyàn tó wà láyé.+ Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù dé, wọ́n tẹrí ba fún un, wọ́n sì wólẹ̀.+ 7 Ojú ẹsẹ̀ tí Jósẹ́fù rí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ló dá wọn mọ̀, àmọ́ kò jẹ́ kí wọ́n+ mọ̀ pé òun ni. Ó wá fi ohùn líle bá wọn sọ̀rọ̀, ó ní: “Ibo lẹ ti wá?” Wọ́n fèsì pé: “Ilẹ̀ Kénáánì la ti wá, ká lè ra oúnjẹ.”+
8 Jósẹ́fù dá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mọ̀, àmọ́ wọn ò dá a mọ̀. 9 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jósẹ́fù rántí àwọn àlá tó lá nípa wọn, ó sì sọ fún wọn+ pé: “Amí ni yín! Ṣe lẹ wá wo ibi tí ẹ ti lè gbógun ja ilẹ̀ wa!”* 10 Àmọ́ wọ́n sọ fún un pé: “Rárá olúwa mi, oúnjẹ ni àwa ìránṣẹ́ rẹ wá rà. 11 Ọmọ bàbá kan náà ni gbogbo wa. Olódodo ni wá. Àwa ìránṣẹ́ rẹ kì í ṣe amí.” 12 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Irọ́ lẹ̀ ń pa! Ṣe lẹ wá wo ibi tí ẹ ti lè gbógun ja ilẹ̀ wa!” 13 Ni wọ́n bá sọ pé: “Ọkùnrin méjìlá (12) ni àwa ìránṣẹ́ rẹ.+ Ọmọ bàbá kan+ náà ni wá, ilẹ̀ Kénáánì sì ni bàbá+ wa wà. Àbúrò wa tó kéré jù wà lọ́dọ̀ bàbá wa, àmọ́ àbúrò wa kejì ò sí mọ́.”+
14 Jósẹ́fù sọ fún wọn pé: “Bí mo ṣe sọ ló rí, mo ní, ‘Amí ni yín!’ 15 Ohun tí màá fi dán yín wò nìyí: Bí Fáráò ti wà láàyè, ẹ ò ní kúrò níbí àfi tí àbúrò yín tó kéré jù bá wá síbí.+ 16 Ẹ rán ọ̀kan nínú yín kó lọ mú àbúrò yín wá, àmọ́ ẹ̀yin máa wà nínú ẹ̀wọ̀n níbí. Ohun tí màá fi mọ̀ nìyẹn bóyá òótọ́ lẹ̀ ń sọ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, bí Fáráò ti wà láàyè, amí ni yín.” 17 Ló bá tì wọ́n mọ́lé fún ọjọ́ mẹ́ta.
18 Ní ọjọ́ kẹta, Jósẹ́fù sọ fún wọn pé: “Mo bẹ̀rù Ọlọ́run, torí náà, ohun tí mo bá sọ ni kí ẹ ṣe, kí ẹ lè wà láàyè. 19 Tí ẹ bá jẹ́ olódodo, ẹ jẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin yín wà ní àtìmọ́lé níbí, àmọ́ kí ẹ̀yin tó kù máa lọ, kí ẹ sì gbé ọkà dání kí agbo ilé+ yín lè rí nǹkan jẹ. 20 Kí ẹ wá mú àbúrò yín tó kéré jù wá sọ́dọ̀ mi, kí n lè rí i pé òótọ́ lẹ̀ ń sọ, ẹ ò sì ní kú.” Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀.
21 Wọ́n sọ fún ara wọn pé: “Ó dájú pé torí Jósẹ́fù+ ni ìyà yìí ṣe ń jẹ wá, torí a rí ìdààmú tó bá a* nígbà tó bẹ̀ wá pé ká yọ́nú sí òun, àmọ́ a ò dá a lóhùn. Ìdí nìyẹn tí wàhálà yìí fi dé bá wa.” 22 Ni Rúbẹ́nì bá sọ fún wọn pé: “Ṣebí mo sọ fún yín pé, ‘Ẹ má ṣẹ ọmọ náà,’ àmọ́ ṣé ẹ dá mi lóhùn?+ Ẹ̀san+ ti wá dé báyìí torí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.” 23 Àmọ́ wọn ò mọ̀ pé Jósẹ́fù gbọ́ èdè wọn torí ògbufọ̀ ló ń túmọ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀. 24 Ló bá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún.+ Nígbà tó pa dà sọ́dọ̀ wọn, tó sì tún bá wọn sọ̀rọ̀, ó mú Síméónì+ láàárín wọn, ó sì dè é níṣojú+ wọn. 25 Jósẹ́fù wá pàṣẹ pé kí wọ́n fi ọkà kún àwọn àpò wọn, kí wọ́n dá owó kálukú pa dà sínú àpò rẹ̀, kí wọ́n sì fún wọn ní oúnjẹ tí wọ́n á jẹ lójú ọ̀nà. Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún wọn.
26 Torí náà, wọ́n kó ọkà wọn sórí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, wọ́n sì kúrò níbẹ̀. 27 Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn ṣí àpò rẹ̀ kó lè fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní oúnjẹ níbi tí wọ́n dé sí, ó rí owó rẹ̀ lẹ́nu àpò rẹ̀. 28 Ló bá sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Wọ́n dá owó mi pa dà, òun ló wà nínú àpò mi yìí!” Ni ẹ̀rù bá bẹ̀rẹ̀ sí í bà wọ́n, wọ́n sì ń gbọ̀n, wọ́n kọjú síra wọn, wọ́n sì sọ pé: “Kí ni Ọlọ́run ṣe sí wa yìí?”
29 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jékọ́bù bàbá wọn ní ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn fún un, wọ́n ní: 30 “Ọkùnrin tó jẹ́ olórí ilẹ̀ náà fi ohùn líle bá wa sọ̀rọ̀,+ ó sì fẹ̀sùn kàn wá pé amí la wá ṣe ní ilẹ̀ wọn. 31 Àmọ́ a sọ fún un pé, ‘Olódodo ni wá. A kì í ṣe amí.+ 32 Ọkùnrin méjìlá (12)+ ni wá, ọmọ bàbá kan náà ni wá. Ọ̀kan ò sí mọ́,+ àbúrò wa tó kéré jù sì wà lọ́dọ̀ bàbá wa báyìí ní ilẹ̀ Kénáánì.’+ 33 Àmọ́ ọkùnrin tó jẹ́ olórí ilẹ̀ náà sọ fún wa pé, ‘Ohun tí màá fi mọ̀ pé olódodo ni yín ni pé: Ẹ jẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin yín dúró sọ́dọ̀ mi.+ Kí ẹ sì máa lọ,+ kí ẹ mú nǹkan dání kí agbo ilé yín lè rí nǹkan jẹ. 34 Kí ẹ sì mú àbúrò yín tó kéré jù wá sọ́dọ̀ mi, kí n lè mọ̀ pé olódodo ni yín, pé ẹ kì í ṣe amí. Màá wá dá arákùnrin yín pa dà fún yín, ẹ sì lè máa ṣòwò ní ilẹ̀ yìí.’”
35 Bí wọ́n ṣe ń kó ẹrù inú àpò wọn jáde, àpò owó kálukú wà nínú rẹ̀. Nígbà tí àwọn àti bàbá wọn rí àpò owó wọn, ẹ̀rù bà wọ́n. 36 Jékọ́bù bàbá wọn wá sọ fún wọn pé: “Èmi ni ẹ mú kí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀!+ Jósẹ́fù ò sí mọ́,+ Síméónì náà ò sí mọ́,+ ẹ tún fẹ́ mú Bẹ́ńjámínì lọ! Èmi ni gbogbo nǹkan yìí wá ṣẹlẹ̀ sí!” 37 Àmọ́ Rúbẹ́nì sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “O lè pa àwọn ọmọkùnrin mi méjèèjì tí mi ò bá mú un pa dà wá bá ọ.+ Fà á lé mi lọ́wọ́, màá sì mú un pa dà wá bá ọ.”+ 38 Àmọ́ ó sọ pé: “Ọmọ mi ò ní bá yín lọ, torí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan ló sì ṣẹ́ kù.+ Bí jàǹbá bá lọ ṣe é ní ìrìn àjò tí ẹ fẹ́ lọ yìí, ó dájú pé ẹ ó mú kí n ṣọ̀fọ̀+ wọnú Isà Òkú*+ pẹ̀lú ewú orí mi.”