Àkọsílẹ̀ Máàkù
7 Àwọn Farisí àti àwọn kan lára àwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n wá láti Jerúsálẹ́mù kóra jọ yí i ká.+ 2 Wọ́n sì rí i tí àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, ìyẹn ọwọ́ tí wọn ò wẹ̀.* 3 (Torí àwọn Farisí àti gbogbo àwọn Júù kì í jẹun láìwẹ ọwọ́ wọn títí dé ìgúnpá, wọ́n rin kinkin mọ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn èèyàn àtijọ́, 4 tí wọ́n bá sì ti ọjà dé, wọn kì í jẹun àfi tí wọ́n bá wẹ ara wọn. Ọ̀pọ̀ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ míì wà tí wọ́n gbà, tí wọ́n sì rin kinkin mọ́, irú bí ìbatisí àwọn ife, ṣágo àti àwọn ohun èlò tí wọ́n fi bàbà ṣe.)+ 5 Àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé òfin yìí wá bi í pé: “Kí ló dé tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ ò tẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn èèyàn àtijọ́, àmọ́ tí wọ́n ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun?”+ 6 Ó sọ fún wọn pé: “Bí Àìsáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nípa ẹ̀yin alágàbàgebè ló rí gẹ́lẹ́, ó kọ ọ́ pé, ‘Àwọn èèyàn yìí ń fi ètè wọn bọlá fún mi, àmọ́ ọkàn wọn jìnnà gan-an sí mi.+ 7 Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, torí pé àṣẹ èèyàn ni ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni.’+ 8 Ẹ pa àṣẹ Ọlọ́run tì, ẹ wá ń rin kinkin mọ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn èèyàn.”+
9 Ó tún sọ fún wọn pé: “Ẹ̀ ń dọ́gbọ́n kọ àṣẹ Ọlọ́run sílẹ̀ kí ẹ lè máa tẹ̀ lé àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yín.+ 10 Bí àpẹẹrẹ, Mósè sọ pé, ‘Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ,’+ àti pé, ‘Kí ẹ pa ẹni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí* bàbá tàbí ìyá rẹ̀.’+ 11 Àmọ́ ẹ sọ pé, ‘Tí ọkùnrin kan bá sọ fún bàbá tàbí ìyá rẹ̀ pé: “Kọ́bánì (ìyẹn, ẹ̀bùn tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run) ni ohunkóhun tí mo ní tó lè ṣe yín láǹfààní,”’ 12 ẹ kì í jẹ́ kó ṣe ohunkóhun fún bàbá tàbí ìyá rẹ̀ mọ́.+ 13 Ẹ̀ ń tipa bẹ́ẹ̀ fi àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yín, tí ẹ fi lé àwọn èèyàn lọ́wọ́, sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.+ Ọ̀pọ̀ irú nǹkan báyìí lẹ sì ń ṣe.”+ 14 Torí náà, ó tún pe àwọn èrò náà jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Gbogbo yín, ẹ fetí sí mi, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì yé yín.+ 15 Kò sí ohun kankan tó wá láti òde ara èèyàn tó sì wọnú rẹ̀ tó lè sọ ọ́ di aláìmọ́; àmọ́ àwọn ohun tó ń jáde látinú èèyàn ló ń sọ èèyàn di aláìmọ́.”+ 16* ——
17 Nígbà tó kúrò lọ́dọ̀ àwọn èrò náà, tó wọ inú ilé kan, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bi í nípa àpèjúwe náà.+ 18 Torí náà, ó sọ fún wọn pé: “Ṣé kò yé ẹ̀yin náà bíi tiwọn ni? Ṣé ẹ ò mọ̀ pé kò sí ohun kankan tó wá láti òde ara èèyàn tó sì wọnú rẹ̀ tó lè sọ ọ́ di aláìmọ́, 19 torí pé inú ọkàn rẹ̀ kọ́ ló wọ̀, inú ikùn rẹ̀ ni, ó sì máa yà á jáde sínú kòtò ẹ̀gbin?” Ó tipa bẹ́ẹ̀ kéde pé gbogbo oúnjẹ ló mọ́. 20 Ó tún sọ pé: “Ohun tó ń tinú èèyàn jáde ló ń sọ ọ́ di aláìmọ́.+ 21 Torí láti inú, láti ọkàn àwọn èèyàn,+ ni àwọn èrò burúkú ti ń wá: ìṣekúṣe,* olè jíjà, ìpànìyàn, 22 àwọn ìwà àgbèrè, ojúkòkòrò, àwọn ìwà burúkú, ẹ̀tàn, ìwà àìnítìjú,* ojú tó ń ṣe ìlara, ọ̀rọ̀ òdì, ìgbéraga àti ìwà òmùgọ̀. 23 Láti inú ni gbogbo nǹkan burúkú yìí ti ń wá, tí wọ́n sì ń sọ èèyàn di aláìmọ́.”
24 Ó gbéra níbẹ̀, ó sì lọ sí agbègbè Tírè àti Sídónì.+ Ó wọ ilé kan níbẹ̀, kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ nípa rẹ̀, síbẹ̀ àwọn èèyàn mọ̀. 25 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, obìnrin kan tí ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré ní ẹ̀mí àìmọ́ gbọ́ nípa rẹ̀, ó sì wá wólẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀.+ 26 Ará Gíríìsì ni obìnrin náà, ọmọ* ilẹ̀ Foníṣíà ní Síríà; ó sì ń bẹ̀ ẹ́ ṣáá pé kó lé ẹ̀mí èṣù náà jáde lára ọmọbìnrin òun. 27 Àmọ́ ó sọ fún un pé: “Jẹ́ kí àwọn ọmọ kọ́kọ́ yó ná, torí kò tọ́ ká mú búrẹ́dì àwọn ọmọ, ká sì jù ú sí àwọn ajá kéékèèké.”+ 28 Àmọ́ obìnrin náà dá a lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni sà, síbẹ̀, àwọn ajá kéékèèké tó wà lábẹ́ tábìlì pàápàá, máa ń jẹ lára èérún tó já bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ kéékèèké.” 29 Ó wá sọ fún un pé: “Torí ohun tí o sọ yìí, máa lọ; ẹ̀mí èṣù náà ti kúrò lára ọmọbìnrin rẹ.”+ 30 Torí náà, ó lọ sí ilé rẹ̀, ó sì rí i tí ọmọ kékeré náà dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn, ẹ̀mí èṣù náà ti kúrò lára rẹ̀.+
31 Nígbà tí Jésù pa dà láti agbègbè Tírè, ó gba Sídónì lọ sí Òkun Gálílì, ó gba agbègbè Dekapólì* kọjá.+ 32 Wọ́n mú ọkùnrin adití kan tí kò lè sọ̀rọ̀ dáadáa wá bá a níbẹ̀,+ wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé kó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e. 33 Ó mú ọkùnrin yẹn nìkan kúrò lọ́dọ̀ àwọn èrò náà lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan. Ó ki ìka rẹ̀ bọ etí ọkùnrin náà méjèèjì, lẹ́yìn tó tutọ́, ó fọwọ́ kan ahọ́n rẹ̀.+ 34 Ó gbójú sókè ọ̀run, ó mí kanlẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Éfátà,” tó túmọ̀ sí, “Là.” 35 Ni etí ọkùnrin náà bá là,+ kò níṣòro ọ̀rọ̀ sísọ mọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ dáadáa. 36 Àmọ́, ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má sọ fún ẹnì kankan,+ síbẹ̀ bó ṣe ń kìlọ̀ fún wọn tó ni wọ́n túbọ̀ ń kéde rẹ̀.+ 37 Lóòótọ́, ẹnu yà wọ́n kọjá sísọ,+ wọ́n sì sọ pé: “Gbogbo nǹkan ló ṣe dáadáa. Ó tiẹ̀ ń mú kí àwọn adití gbọ́ràn, kí àwọn tí kò lè sọ̀rọ̀ sì sọ̀rọ̀.”+