Jẹ́nẹ́sísì
39 Wọ́n wá mú Jósẹ́fù lọ sí Íjíbítì,+ Pọ́tífárì+ ará Íjíbítì tó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin Fáráò àti olórí ẹ̀ṣọ́ sì rà á lọ́wọ́ àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì+ tó mú un lọ síbẹ̀. 2 Àmọ́ Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù.+ Ìyẹn mú kó ṣàṣeyọrí, ọ̀gá rẹ̀ tó jẹ́ ará Íjíbítì sì fi ṣe alábòójútó ilé rẹ̀. 3 Ọ̀gá rẹ̀ sì rí i pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀ àti pé Jèhófà ń mú kí gbogbo ohun tó ń ṣe yọrí sí rere.
4 Jósẹ́fù máa ń rí ojúure rẹ̀, ó sì di ìránṣẹ́ Pọ́tífárì fúnra rẹ̀. Ó wá fi ṣe olórí ilé rẹ̀, ó sì ní kó máa bójú tó gbogbo ohun ìní òun. 5 Látìgbà tí ọ̀gá rẹ̀ ti fi ṣe olórí ilé rẹ̀, tó sì ń bójú tó gbogbo ohun tó ní, Jèhófà ń bù kún ilé ará Íjíbítì náà torí Jósẹ́fù. Jèhófà sì bù kún gbogbo ohun ìní Pọ́tífárì nílé lóko.+ 6 Nígbà tó yá, ó fi gbogbo ohun tó ní sí ìkáwọ́ Jósẹ́fù, kò sì da ara rẹ̀ láàmú nípa ohunkóhun àfi oúnjẹ tó ń jẹ. Yàtọ̀ síyẹn, Jósẹ́fù taagun, ó sì rẹwà.
7 Lẹ́yìn náà, ojú ìyàwó ọ̀gá Jósẹ́fù kò kúrò lára rẹ̀, ó sì ń sọ fún un pé: “Wá bá mi sùn.” 8 Àmọ́ Jósẹ́fù ò gbà, ó sì sọ fún ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ pé: “Ọ̀gá mi kì í yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò nínú ilé, ó sì ti fa gbogbo ohun tó ní lé mi lọ́wọ́. 9 Kò sẹ́ni tó tóbi jù mí lọ nínú ilé yìí, kò sì fawọ́ ohunkóhun sẹ́yìn fún mi àyàfi ìwọ, torí pé ìwọ ni ìyàwó rẹ̀. Ṣé ó wá yẹ kí n hùwà burúkú tó tó báyìí, kí n sì ṣẹ Ọlọ́run?”+
10 Ojoojúmọ́ ló ń bá Jósẹ́fù sọ ọ́, àmọ́ Jósẹ́fù ò gbà rárá láti bá a sùn tàbí kó wà pẹ̀lú rẹ̀. 11 Lọ́jọ́ kan tí Jósẹ́fù wọnú ilé lọ ṣiṣẹ́ rẹ̀, kò sí ìránṣẹ́ ilé kankan nínú ilé. 12 Obìnrin náà di aṣọ rẹ̀ mú, ó sì sọ pé: “Wá bá mi sùn!” Àmọ́ Jósẹ́fù fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì sá jáde. 13 Bí obìnrin náà ṣe rí i pé ó ti fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, tó sì ti sá jáde, 14 ó bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe àwọn èèyàn tó wà nílé, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! Ó mú ọkùnrin Hébérù yìí wá sọ́dọ̀ wa kó lè fi wá ṣe ẹlẹ́yà. Ó wá bá mi, ó fẹ́ bá mi sùn, àmọ́ mo bẹ̀rẹ̀ sí í ké tantan. 15 Bó ṣe wá rí i pé mò ń pariwo, tí mo sì ń kígbe, ó fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, ó sì sá jáde.” 16 Lẹ́yìn náà, obìnrin náà fi aṣọ Jósẹ́fù sẹ́gbẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ títí ọ̀gá rẹ̀ fi dé sí ilé.
17 Ó sọ ohun kan náà fún un, ó ní: “Ìránṣẹ́ Hébérù tí o mú wá sọ́dọ̀ wa wá bá mi kó lè fi mí ṣe ẹlẹ́yà. 18 Àmọ́ gbàrà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo, tí mo sì kígbe, ó fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, ó sì sá jáde.” 19 Gbàrà tí ọ̀gá rẹ̀ gbọ́ ohun tí ìyàwó rẹ̀ sọ fún un pé: “Ohun tí ìránṣẹ́ rẹ ṣe sí mi nìyí,” inú bí i gan-an. 20 Ni ọ̀gá Jósẹ́fù bá ju Jósẹ́fù sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí wọ́n ń kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí, ó sì wà níbẹ̀ nínú ẹ̀wọ̀n.+
21 Àmọ́ Jèhófà ò fi Jósẹ́fù sílẹ̀, ó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí i, ó sì ń mú kó rí ojúure ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n+ náà. 22 Ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n náà wá fi Jósẹ́fù ṣe olórí gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà nínú ẹ̀wọ̀n, òun ló sì máa ń rí sí i pé wọ́n ṣe gbogbo iṣẹ́ tó wà níbẹ̀.+ 23 Ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ò yẹ Jósẹ́fù lọ́wọ́ wò rárá, torí Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, Jèhófà sì ń mú kí gbogbo ohun tó bá ṣe yọrí sí rere.+