Àìsáyà
57 Olódodo ṣègbé,
Àmọ́ ẹnì kankan ò fi sọ́kàn.
2 Ó wọnú àlàáfíà.
Wọ́n sinmi lórí ibùsùn wọn,* gbogbo àwọn tó ń rìn lọ́nà títọ́.
4 Ta lẹ fi ń ṣe yẹ̀yẹ́?
Ta lẹ la ẹnu gbàù sí, tí ẹ sì yọ ahọ́n yín sí?
Ṣebí ọmọ ẹ̀ṣẹ̀ ni yín,
Ẹ̀yin ọmọ ẹ̀tàn,+
5 Tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti kó sí lórí láàárín àwọn igi ńlá,+
Lábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀,+
Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àwọn ọmọ ní àwọn àfonífojì,+
Lábẹ́ àwọn pàlàpálá àpáta?
6 Ìpín rẹ wà níbi àwọn òkúta tó jọ̀lọ̀ ní àfonífojì.+
Àní, àwọn ni ìpín rẹ.
Kódà, àwọn lò ń da ọrẹ ohun mímu sí, tí o sì ń mú ẹ̀bùn wá fún.+
Ṣé àwọn nǹkan yìí máa tẹ́ mi lọ́rùn?*
8 Ẹ̀yìn ilẹ̀kùn àti férémù ilẹ̀kùn lo gbé ìrántí rẹ kalẹ̀ sí.
O fi mí sílẹ̀, o sì ṣí ara rẹ sílẹ̀;
O lọ, o sì mú kí ibùsùn rẹ fẹ̀ dáadáa.
O sì bá wọn dá májẹ̀mú.
O rán àwọn aṣojú rẹ lọ sọ́nà jíjìn,
Tí o fi sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú Isà Òkú.*
10 O ti ṣiṣẹ́ kára láti rìn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà rẹ.
Àmọ́ o ò sọ pé, ‘Kò sírètí!’
A wá sọ agbára rẹ dọ̀tun.
Ìdí nìyẹn tí o kò fi sọ̀rètí nù.*
O ò rántí mi.+
O ò fi nǹkan kan sọ́kàn.+
Ṣebí mo ti dákẹ́, tí mo sì fà sẹ́yìn?*+
O ò wá bẹ̀rù mi rárá.
Atẹ́gùn máa gbé gbogbo wọn lọ,
Èémí lásán máa fẹ́ wọn lọ,
Àmọ́ ẹni tó bá fi mí ṣe ibi ààbò máa jogún ilẹ̀ náà,
Ó sì máa gba òkè mímọ́ mi.+
14 Wọ́n máa sọ pé, ‘Ẹ ṣe ọ̀nà, ẹ ṣe é! Ẹ tún ọ̀nà ṣe!+
Ẹ mú gbogbo ohun ìdíwọ́ kúrò ní ọ̀nà àwọn èèyàn mi.’”
15 Torí ohun tí Ẹni Gíga àti Ẹni Tó Ta Yọ sọ nìyí,
“Ibi gíga àti ibi mímọ́ ni mò ń gbé,+
Àmọ́ mo tún ń gbé pẹ̀lú àwọn tí a tẹ̀ rẹ́, tí wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì ní ẹ̀mí,
Láti mú kí ẹ̀mí ẹni tó rẹlẹ̀ sọ jí,
Kí n sì mú kí ọkàn àwọn tí a tẹ̀ rẹ́ sọ jí.+
16 Torí mi ò ní ta kò wọ́n títí láé,
Mi ò sì ní máa bínú títí lọ;+
Torí àárẹ̀ máa bá ẹ̀mí èèyàn nítorí mi,+
Títí kan àwọn ohun tó ń mí, tí mo dá.
17 Inú bí mi torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, bó ṣe ń wá èrè tí kò tọ́,+
Torí náà, mo kọ lù ú, mo fi ojú mi pa mọ́, inú sì bí mi.
Àmọ́ kò yéé rìn bí ọ̀dàlẹ̀,+ ó ń ṣe ìfẹ́ ọkàn rẹ̀.
18 Mo ti rí àwọn ọ̀nà rẹ̀,
Àmọ́ màá wò ó sàn,+ màá sì darí rẹ̀,+
Màá mú kí òun àti àwọn èèyàn rẹ̀+ tó ń ṣọ̀fọ̀ pa dà rí ìtùnú.”*+
19 “Màá dá èso ètè.
Màá fún ẹni tó wà lọ́nà jíjìn àti ẹni tó wà nítòsí ní àlàáfíà tí kò lópin,”+ ni Jèhófà wí,
“Màá sì wò ó sàn.”
20 “Àmọ́ àwọn ẹni burúkú dà bí òkun tó ń ru, tí kò lè rọ̀ wọ̀ọ̀,
Omi rẹ̀ sì ń ta koríko inú òkun àti ẹrẹ̀ sókè.