Jẹ́nẹ́sísì
12 Jèhófà sì sọ fún Ábúrámù pé: “Kúrò ní ilẹ̀ rẹ, kí o kúrò lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ àti ilé bàbá rẹ, kí o lọ sí ilẹ̀ tí màá fi hàn ọ́.+ 2 Màá mú kí o di orílẹ̀-èdè ńlá, màá sì bù kún ọ. Màá mú kí orúkọ rẹ di ńlá, ó sì máa jẹ́ ìbùkún.+ 3 Màá súre fún àwọn tó ń súre fún ọ, màá sì gégùn-ún fún ẹni tó bá gégùn-ún fún ọ,+ ó dájú pé gbogbo ìdílé tó wà lórí ilẹ̀ yóò rí ìbùkún gbà* nípasẹ̀ rẹ.”+
4 Torí náà, Ábúrámù gbéra, bí Jèhófà ṣe sọ fún un, Lọ́ọ̀tì sì bá a lọ. Ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75) ni Ábúrámù nígbà tó kúrò ní Háránì.+ 5 Ábúrámù mú Sáráì+ ìyàwó rẹ̀ àti Lọ́ọ̀tì ọmọ arákùnrin rẹ̀,+ ó kó gbogbo ẹrù tí wọ́n ti ní+ àti àwọn èèyàn* tó jẹ́ tiwọn ní Háránì, wọ́n sì forí lé ilẹ̀ Kénáánì.+ Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ Kénáánì, 6 Ábúrámù rin ilẹ̀ náà já títí dé ibi tí Ṣékémù+ wà, nítòsí àwọn igi ńlá tó wà ní Mórè.+ Àwọn ọmọ Kénáánì wà ní ilẹ̀ náà nígbà yẹn. 7 Jèhófà wá fara han Ábúrámù, ó sì sọ pé: “Ọmọ* rẹ+ ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ yìí.”+ Ó sì mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà, ẹni tó fara hàn án. 8 Lẹ́yìn náà, ó kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè olókè tó wà ní ìlà oòrùn Bẹ́tẹ́lì,+ ó pa àgọ́ rẹ̀ síbẹ̀, Bẹ́tẹ́lì wà ní ìwọ̀ oòrùn àgọ́ náà, Áì+ sì wà ní ìlà oòrùn. Ó mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pe orúkọ Jèhófà.+ 9 Lẹ́yìn náà, Ábúrámù kó kúrò níbẹ̀, ó sì gba ọ̀nà Négébù+ lọ, ó ń pa àgọ́ láti ibì kan dé ibòmíì.
10 Ìyàn wá mú ní ilẹ̀ náà, Ábúrámù sì gbéra lọ sí Íjíbítì kó lè gbé ibẹ̀ fúngbà díẹ̀,*+ torí ìyàn mú gidigidi ní ilẹ̀ náà.+ 11 Bó ṣe fẹ́ wọ Íjíbítì, ó sọ fún Sáráì ìyàwó rẹ̀ pé: “Jọ̀ọ́, gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ! Mo mọ̀ pé o rẹwà gan-an lóbìnrin.+ 12 Tí àwọn ará Íjíbítì bá sì rí ọ, ó dájú pé wọ́n á sọ pé, ‘Ìyàwó rẹ̀ nìyí.’ Wọ́n á pa mí, àmọ́ wọ́n á dá ọ sí. 13 Jọ̀ọ́, sọ fún wọn pé àbúrò mi ni ọ́, kí nǹkan kan má bàa ṣe mí torí rẹ, kí wọ́n lè dá ẹ̀mí mi sí.”*+
14 Gbàrà tí Ábúrámù wọ Íjíbítì, àwọn ará Íjíbítì rí i pé obìnrin náà rẹwà gan-an. 15 Àwọn ìjòyè Fáráò pẹ̀lú rí i, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ròyìn rẹ̀ dáadáa fún Fáráò, débi pé wọ́n mú obìnrin náà lọ sí ilé Fáráò. 16 Fáráò tọ́jú Ábúrámù dáadáa nítorí obìnrin náà, Ábúrámù sì wá ní àwọn àgùntàn, màlúù, akọ àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ìránṣẹ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin àti àwọn ràkúnmí.+ 17 Jèhófà fi àjàkálẹ̀ àrùn* kọ lu Fáráò àti agbo ilé rẹ̀ nítorí Sáráì, ìyàwó Ábúrámù.+ 18 Ni Fáráò bá pe Ábúrámù, ó sì sọ fún un pé: “Kí lo ṣe sí mi yìí? Kí ló dé tí o ò sọ fún mi pé ìyàwó rẹ ni? 19 Kí ló dé tí o sọ pé, ‘Àbúrò+ mi ni,’ tó fi jẹ́ pé díẹ̀ ló kù kí n fi ṣe aya? Ìyàwó rẹ nìyí. Mú un, kí o sì máa lọ!” 20 Ni Fáráò bá pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin rẹ̀ nípa Ábúrámù, wọ́n sì ní kí Ábúrámù àti ìyàwó rẹ̀ kúrò ní ìlú náà pẹ̀lú gbogbo ohun tó ní.+