Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì
27 Ní báyìí tí wọ́n ti pinnu pé kí a wọkọ̀ òkun lọ sí Ítálì,+ wọ́n fa Pọ́ọ̀lù àti àwọn ẹlẹ́wọ̀n míì lé ọwọ́ ọ̀gá àwọn ọmọ ogun kan tó ń jẹ́ Júlíọ́sì, orúkọ àwùjọ ọmọ ogun rẹ̀ ni Ọ̀gọ́sítọ́sì. 2 A wọ ọkọ̀ òkun kan láti Adiramítíúmù tó fẹ́ lọ sí àwọn èbúté tó wà ní etíkun ìpínlẹ̀ Éṣíà, ọkọ̀ náà sì gbéra; Àrísítákọ́sì+ ará Makedóníà láti Tẹsalóníkà wà pẹ̀lú wa. 3 Lọ́jọ́ kejì, a gúnlẹ̀ sí Sídónì, Júlíọ́sì ṣojú rere* sí Pọ́ọ̀lù, ó sì gbà á láyè láti lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, kí wọ́n sì ṣìkẹ́ rẹ̀.
4 Nígbà tí a wọkọ̀ òkun kúrò níbẹ̀, a gba tòsí Sápírọ́sì, kí a lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù tó dojú kọ wá. 5 Lẹ́yìn náà, a gba ojú òkun kọjá Sìlíṣíà àti Panfílíà, a sì gúnlẹ̀ sí èbúté ní Máírà ní Líkíà. 6 Ibẹ̀ ni ọ̀gá ọmọ ogun náà ti rí ọkọ̀ òkun kan tó ń bọ̀ láti Alẹkisáńdíríà, tó ń lọ sí Ítálì, ó sì mú wa wọ̀ ọ́. 7 Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí a ti rọra ń tukọ̀ bọ̀, a dé Kínídọ́sì tipátipá. Nítorí pé ẹ̀fúùfù kò jẹ́ kí a lọ tààrà, a fi Sálímónè sílẹ̀ gba tòsí Kírétè. 8 Bí a ṣe ń tukọ̀ lọ ní etíkun náà tipátipá, a dé ibì kan tí wọ́n ń pè ní Èbúté Rere, tó wà nítòsí ìlú Láséà.
9 Àkókò púpọ̀ ti kọjá, ó sì ti wá léwu láti tukọ̀ torí ààwẹ̀ Ọjọ́ Ètùtù+ pàápàá ti kọjá, nítorí náà Pọ́ọ̀lù dá àbá kan 10 fún wọn pé: “Ẹ̀yin èèyàn, mo ri í pé ìrìn àjò yìí máa yọrí sí òfò àti àdánù ńlá, kì í ṣe ẹrù àti ọkọ̀ òkun yìí nìkan ló máa kàn, ó máa kan ẹ̀mí* wa náà.” 11 Àmọ́, ohun tí atukọ̀ àti ọlọ́kọ̀ sọ ni ọ̀gá ọmọ ogun fara mọ́, kò fara mọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ. 12 Torí pé kò dẹrùn láti lo ìgbà òtútù ní èbúté náà, àwọn tó pọ̀ jù dámọ̀ràn pé ká tukọ̀ kúrò níbẹ̀, wọ́n ń wò ó bóyá a máa lè dé Fóníìsì ká lè lo ìgbà òtútù níbẹ̀, ibẹ̀ jẹ́ èbúté kan ní Kírétè, ó dojú kọ àríwá ìlà oòrùn àti gúúsù ìlà oòrùn.
13 Nígbà tí atẹ́gùn gúúsù fẹ́ yẹ́ẹ́, wọ́n rò pé ọwọ́ wọn ti tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́, wọ́n bá fa ìdákọ̀ró sókè, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í tukọ̀ lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Kírétè nítòsí èbúté. 14 Àmọ́, lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ìjì líle tí wọ́n ń pè ní Yúrákúílò* rọ́ lù ú. 15 Bí ó ṣe fipá gba ọkọ̀ òkun náà, tí a kò sì lè dorí rẹ̀ kọ ìjì náà, a gba kámú, ìjì náà sì ń gbá wa lọ. 16 Lẹ́yìn náà, a sáré wọ erékùṣù kékeré kan tí wọ́n ń pè ní Káúdà, síbẹ̀ agbára káká la fi lè ṣèkáwọ́ ọkọ̀ ìgbájá* tó wà ní ẹ̀yìn ọkọ̀. 17 Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n fà á sókè sínú ọkọ̀, wọ́n fi àwọn nǹkan di ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀ òkun náà pọ̀ lábẹ́, torí pé ẹ̀rù ń bà wọ́n kí ọkọ̀ náà má lọ fàyà sọlẹ̀ ní Sítísì,* wọ́n ta ìgbòkun, ìjì náà sì ń gbé wa lọ. 18 Nítorí pé ìjì líle náà ń fi agbára gbá wa síwá-sẹ́yìn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í mú ọkọ̀ òkun náà fúyẹ́ ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e. 19 Ní ọjọ́ kẹta, wọ́n fi ọwọ́ ara wọn da àwọn ohun èlò inú ọkọ̀ òkun náà nù.
20 Nígbà tí oòrùn tàbí ìràwọ̀ kò yọ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, tí ìjì líle* sì ń bá wa fà á, a bẹ̀rẹ̀ sí í wò ó pé bóyá la fi lè là á já. 21 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò tí wọ́n ti lò láìjẹun, Pọ́ọ̀lù dìde dúró láàárín wọn, ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ó yẹ kí ẹ ti gba ìmọ̀ràn mi, kí ẹ má sì ṣíkọ̀ sójú òkun láti Kírétè, ẹ̀ bá má ti rí òfò àti àdánù yìí.+ 22 Síbẹ̀, ní báyìí, mo rọ̀ yín pé kí ẹ mọ́kàn le, torí kò sí ìkankan* lára yín tó máa ṣègbé, àyàfi ọkọ̀ òkun yìí. 23 Ní òru yìí, áńgẹ́lì+ Ọlọ́run tí mo jẹ́ tirẹ̀, tí mo sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, 24 ó sì sọ pé: ‘Má bẹ̀rù, Pọ́ọ̀lù. Wàá dúró níwájú Késárì,+ sì wò ó! Ọlọ́run ti fún ọ ní gbogbo àwọn tí ẹ jọ wà nínú ọkọ̀.’ 25 Nítorí náà, ẹ̀yin èèyàn, ẹ mọ́kàn le, torí mo gba Ọlọ́run gbọ́ pé bó ṣe sọ fún mi ló máa rí. 26 Àmọ́ ṣá o, ọkọ̀ wa máa lọ fàyà sọlẹ̀ sí èbúté ní erékùṣù kan.”+
27 Nígbà tó di òru kẹrìnlá, tí ìjì sì ń bì wá síwá-sẹ́yìn lórí Òkun Ádíríà, ní ọ̀gànjọ́ òru, àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fura pé wọ́n ti ń sún mọ́ ilẹ̀ kan. 28 Wọ́n wọn jíjìn omi náà wò, wọ́n sì rí i pé ó jẹ́ ogún (20) fátọ́ọ̀mù,* torí náà, wọ́n rìn síwájú díẹ̀, wọ́n tún wọn jíjìn omi náà, wọ́n sì rí i pé ó jẹ́ fátọ́ọ̀mù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15).* 29 Torí pé wọ́n ń bẹ̀rù kí a má lọ fàyà sọ àpáta, wọ́n ju ìdákọ̀ró mẹ́rin sínú omi láti ẹ̀yìn ọkọ̀, wọ́n sì ń retí pé kí ilẹ̀ mọ́. 30 Àmọ́ nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ fẹ́ sá kúrò nínú ọkọ̀ òkun náà, tí wọ́n sì ń rọ ọkọ̀ ìgbájá sílẹ̀ sínú òkun, bíi pé ṣe ni wọ́n fẹ́ rọ àwọn ìdákọ̀ró sísàlẹ̀ láti iwájú ọkọ̀, 31 Pọ́ọ̀lù sọ fún ọ̀gá àwọn ọmọ ogun àti àwọn ọmọ ogun pé: “Láìjẹ́ pé àwọn èèyàn yìí dúró sínú ọkọ̀ òkun yìí, ẹ ò lè yè bọ́ o.”+ 32 Ni àwọn ọmọ ogun bá gé okùn ọkọ̀ ìgbájá náà, ó sì já bọ́.
33 Nígbà tí ilẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ́, Pọ́ọ̀lù gba gbogbo wọn níyànjú pé kí wọ́n jẹun, ó ní: “Òní ló pé ọjọ́ kẹrìnlá tí ẹ ti ń wọ̀nà lójú méjèèjì, tí ẹ ò sì jẹ nǹkan kan rárá. 34 Nítorí náà, mo rọ̀ yín pé kí ẹ jẹun; torí kó má bàa sí ewu fún yín, nítorí kò sí ìkankan nínú irun orí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín tó máa ṣègbé.” 35 Lẹ́yìn tó sọ ọ̀rọ̀ yìí, ó mú búrẹ́dì, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run níwájú gbogbo wọn, ó bù ú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹun. 36 Torí náà, gbogbo wọn mọ́kàn le, àwọn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹun. 37 Gbogbo àwa* tí a wà nínú ọkọ̀ òkun náà jẹ́ igba ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́rin (276). 38 Nígbà tí wọ́n ti jẹun yó, wọ́n gbé àwọn àlìkámà* tó wà nínú ọkọ̀ náà jù sínú òkun kí ọkọ̀ náà lè fúyẹ́.+
39 Nígbà tí ojú mọ́, wọn ò mọ ojú ilẹ̀,+ àmọ́ wọ́n rí ibì kan tí ilẹ̀ wà ní etíkun, wọ́n sì pinnu pé àwọn á mú kí ọkọ̀ òkun náà gúnlẹ̀ síbẹ̀ tó bá ṣeé ṣe. 40 Torí náà, wọ́n gé àwọn ìdákọ̀ró kúrò, wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n já bọ́ sínú òkun, ní àkókò kan náà, wọ́n tú àwọn okùn tí wọ́n fi so àwọn àjẹ̀ ìtọ́kọ̀; lẹ́yìn tí wọ́n ta ìgbòkun iwájú ọkọ̀ sínú afẹ́fẹ́, wọ́n dorí kọ etíkun náà. 41 Nígbà tí wọ́n fàyà gbá òkìtì kan lábẹ́ omi, tí omi n gba ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ méjèèjì kọjá, ọkọ̀ wọn fàyà sọlẹ̀, iwájú ọkọ̀ fẹnu gúnlẹ̀, kò sì lè lọ mọ́, ni ìgbì bá bẹ̀rẹ̀ sí í fọ́ ìdí ọkọ̀ náà sí wẹ́wẹ́.+ 42 Àwọn ọmọ ogun wá fẹ́ pa àwọn ẹlẹ́wọ̀n kí ìkankan nínú wọn má bàa lúwẹ̀ẹ́ sá lọ. 43 Àmọ́ ọ̀gá àwọn ọmọ ogun pinnu láti mú Pọ́ọ̀lù gúnlẹ̀ láìséwu, kò sì jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n fẹ́. Ó pàṣẹ fún àwọn tó mọ̀ ọ́n wẹ̀ pé kí wọ́n bẹ́ sínú òkun, kí wọ́n sì kọ́kọ́ lọ sórí ilẹ̀, 44 kí àwọn tó kù wá tẹ̀ lé wọn, àwọn kan lórí pátákó, àwọn míì lórí àwọn àfọ́kù ara ọkọ̀ òkun náà. Nítorí náà, gbogbo wa dórí ilẹ̀ láìséwu.+