Orí Kejìlá
Ẹ Má Fòyà Ará Ásíríà Náà
1, 2. (a) Táa bá fojú tèèyàn wò ó, èé ṣe tó fi jọ pé Jónà ní ìdí tó ṣe gúnmọ́ láti kọ̀ láti jẹ́ iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un pé kó lọ wàásù fáwọn ará Ásíríà? (b) Kí ni ìṣarasíhùwà àwọn ará Nínéfè sí iṣẹ́ tí Jónà jẹ́ fún wọn?
LÁÀÁRÍN ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣááju Sànmánì Tiwa, wòlíì Hébérù náà, Jónà, ọmọ Ámítáì, wọ Nínéfè, olú ìlú Ilẹ̀ Ọba Ásíríà. Ó fẹ́ jẹ́ iṣẹ́ ńlá kan fún wọn. Jèhófà ló sọ fún un pé: “Dìde, lọ sí Nínéfè ìlú ńlá títóbi náà, kí o sì pòkìkí lòdì sí i pé ìwà búburú wọn ti gòkè wá síwájú mi.”—Jónà 1:2, 3.
2 Nígbà tí Jónà kọ́kọ́ gbọ́ iṣẹ́ tí yóò lọ jẹ́, ńṣe ló sá, ó forí lé ọ̀nà òdìkejì, ọ̀nà Táṣíṣì. Táa bá fojú tèèyàn wò ó, ìdí wà tí Jónà fi lọ́ tìkọ̀. Ìkà ènìyàn làwọn ará Ásíríà jẹ́. Gbọ́ ohun tí ọba Ásíríà kan fi ṣe àwọn ọ̀tá rẹ̀, ó ní: “Mo ké ọwọ́ àti ẹsẹ̀ àwọn ọ̀gá wọn dànù . . . Mo dáná sun ọ̀pọ̀ lára wọn ti mo mú lóǹdè, mo sì kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ nígbèkùn lọ. Mo ké ọwọ́ àti ìka òmíràn nínú wọn, mo sì rẹ́ imú àwọn mìíràn dànù.” Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà tí Jónà jíṣẹ́ Jèhófà fáwọn ará Nínéfè níkẹyìn, wọ́n ronú pìwà dà, Jèhófà sì dá ìlú náà sí nígbà yẹn.—Jónà 3:3-10; Mátíù 12:41.
Jèhófà Mú “Ọ̀pá”
3. Báwo ni ìṣarasíhùwà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí ìkìlọ̀ àwọn wòlíì Jèhófà ṣe yàtọ̀ sí ìṣarasíhùwà àwọn ará Nínéfè?
3 Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí Jónà wàásù fún bákan náà, gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu? (2 Àwọn Ọba 14:25) Rárá o. Ṣe ni wọ́n kẹ̀yìn sí ìjọsìn mímọ́ gaara. Àní wọ́n tiẹ̀ ṣe é débi pé wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí tẹrí ba fún gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run, wọ́n sì ń sin Báálì.” Kódà, wọ́n tún “ń bá a lọ ní mímú àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn la iná kọjá, wọ́n sì ń woṣẹ́, wọ́n sì ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀, wọ́n sì ń bá a nìṣó ní títa ara wọn fún ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, láti mú un bínú.” (2 Àwọn Ọba 17:16, 17) Ísírẹ́lì kò ṣe bí ti àwọn ará Nínéfè o, Jèhófà rán àwọn wòlíì láti kìlọ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n fàáké kọ́rí. Nítorí náà, Jèhófà pinnu láti fi ọwọ́ líle mú ọ̀ràn wọn.
4, 5. (a) Kí ni “ará Ásíríà” túmọ̀ sí, báwo sì ni Jèhófà yóò ṣe lò ó gẹ́gẹ́ bí “ọ̀pá”? (b) Ìgbà wo ni Samáríà ṣubú?
4 Jíjà tí Ásíríà ń jagun kiri dín kù fúngbà díẹ̀ lẹ́yìn tí Jónà lọ sí Nínéfè.a Àmọ́, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa, Ásíríà tún ti di ológun abìjàwàrà padà, Jèhófà sì lò ó lọ́nà ìyanu. Wòlíì Aísáyà sọ ìkìlọ̀ Jèhófà fún ìjọba Ísírẹ́lì níhà àríwá pé: “Àháà, ará Ásíríà, ọ̀pá tí ó wà fún ìbínú mi, àti póńpó tí ó wà ní ọwọ́ wọn fún ìdálẹ́bi tí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá! Èmi yóò rán an sí orílẹ̀-èdè apẹ̀yìndà, èmi yóò sì pàṣẹ fún un lòdì sí àwọn ènìyàn ìbínú kíkan mi, pé kí ó kó ohun ìfiṣèjẹ púpọ̀, kí ó sì piyẹ́ ohun púpọ̀, kí ó sì sọ ọ́ di ibi ìtẹ̀mọ́lẹ̀ bí amọ̀ àwọn ojú pópó.”—Aísáyà 10:5, 6.
5 Ẹ̀tẹ́ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbáà! Orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà, ìyẹn “ará Ásíríà,” ni Ọlọ́run lò bí “ọ̀pá” láti fi jẹ wọ́n níyà. Lọ́dún 742 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ṣálímánésà Karùn-ún, ọba Ásíríà sàga ti Samáríà, olú ìlú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà. Orí òkè tó ga tó nǹkan bí àádọ́rùn-ún mítà ni Samáríà wà, láti ibi tó rọrùn láti jagun yìí ló ti ń lé àwọn ọ̀tá yìí sẹ́yìn fún nǹkan bí ọdún mẹ́ta. Ṣùgbọ́n kò sí ọgbọ́n téèyàn lè ta tó lè dènà ète Ọlọ́run. Lọ́dún 740 ṣááju Sànmánì Tiwa, Samáríà ṣubú, Ásíríà ti tẹ̀ ẹ́ rẹ́.—2 Àwọn Ọba 18:10.
6. Ọ̀nà wo ni ará Ásíríà náà gba fi ré kọjá ohun tí Jèhófà fẹ́ kó ṣe?
6 Àwọn ará Ásíríà alára kò ka Jèhófà kún bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lò wọ́n láti fi kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́gbọ́n. Ìyẹn ni Jèhófà fi sọ pé: “Bí [ará Ásíríà] kò bá tilẹ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀, òun yóò ní ìtẹ̀sí bẹ́ẹ̀; bí ọkàn-àyà rẹ̀ kò bá tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, òun yóò pète-pèrò bẹ́ẹ̀, nítorí pé láti pa rẹ́ ráúráú ni ó wà ní ọkàn-àyà rẹ̀, àti láti ké àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe díẹ̀ kúrò.” (Aísáyà 10:7) Ńṣe ni Jèhófà fẹ́ kí Ásíríà jẹ́ irinṣẹ́ lọ́wọ́ òun. Ṣùgbọ́n, nǹkan mìíràn ni Ásíríà fẹ́ dà ní tiẹ̀. Ńṣe ni ọkàn-àyà rẹ̀ ń tì í láti pète ohun tó ga ju ìyẹn lọ—láti ṣẹ́gun gbogbo ibi tí wọ́n mọ̀ pé ayé dé nígbà yẹn!
7. (a) Ṣàlàyé gbólóhùn náà “Àwọn ọmọ aládé mi kì í ha ṣe ọba bákan náà?” (b) Kí ló yẹ kí àwọn tó kọ Jèhófà sílẹ̀ lónìí ṣàkíyèsí?
7 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú tí kì í ṣe ti Ísírẹ́lì, tí ará Ásíríà ṣẹ́gun, ló lọ́ba tí ń ṣàkóso wọn tẹ́lẹ̀. Àwọn tó jẹ́ ọba tẹ́lẹ̀ rí yìí sì ti wá di baálẹ̀ lábẹ́ ọba Ásíríà, ìyẹn ló fi lè yangàn lóòótọ́ pé: “Àwọn ọmọ aládé mi kì í ha ṣe ọba bákan náà?” (Aísáyà 10:8) Òrìṣà àwọn ìlú olókìkí tó jẹ́ ti àwọn orílẹ̀-èdè wọnnì kò lè gba àwọn olùjọsìn wọn lọ́wọ́ ìparun. Àwọn òrìṣà bíi Báálì, Mólékì, àti àwọn ère ọmọ màlúù wúrà tí àwọn èèyàn Samáríà ń bọ kò ní dáàbò bo ìlú yẹn. Nígbà tí Samáríà sì ti kọ Jèhófà sílẹ̀, kò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa retí pé kí Jèhófà dá sí ọ̀ràn òun. Kí ẹnikẹ́ni tó bá kọ Jèhófà sílẹ̀ lóde òní tètè fi ti Samáríà kọ́gbọ́n o! Ìyẹn lára Ásíríà náà fi jàre nígbà tó fi Samáríà àti àwọn ìlú yòókù tó ṣẹ́gun yangàn pé: “Kálínò kò ha rí bí Kákémíṣì? Hámátì kò ha rí bí Áápádì? Samáríà kò ha rí bí Damásíkù?” (Aísáyà 10:9) Bákan náà ni gbogbo wọ́n já sí lójú ará Ásíríà, ìjẹ ni wọ́n jẹ́ fún un.
8, 9. Èé ṣe tó fi jẹ́ pé ará Ásíríà náà kọjá àyè rẹ̀ nígbà tó dójú lé Jerúsálẹ́mù?
8 Ṣùgbọ́n ará Ásíríà náà wá sọ àsọbóro. Ó sọ pé: “Ìgbàkigbà tí ọwọ́ mi bá tẹ àwọn ìjọba tí ó jẹ́ ti ọlọ́run tí kò ní láárí, tí àwọn ère fífín wọn pọ̀ ju àwọn èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù àti Samáríà, kì yóò ha jẹ́ pé gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí Samáríà àti sí àwọn ọlọ́run rẹ̀ tí kò ní láárí, àní bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe sí Jerúsálẹ́mù àti sí àwọn òrìṣà rẹ̀?” (Aísáyà 10:10, 11) Òrìṣà àwọn ìjọba tí ará Ásíríà ṣẹ́gun pọ̀ ju ti Jerúsálẹ́mù àti Samáríà lọ fíìfíì. Lará Ásíríà náà bá ronú pé, ‘kí ló wá fẹ́ dí mi lọ́wọ́ kí n má han Jerúsálẹ́mù léèmọ̀ bí ti Samáríà?’
9 Áà, afọ́nnu yẹn sọ̀yí tán! Jèhófà ò ní jẹ́ kó gba Jerúsálẹ́mù. Lóòótọ́, ìtìlẹyìn tí Júdà ń fún ìjọsìn tòótọ́ mẹ́hẹ. (2 Àwọn Ọba 16:7-9; 2 Kíróníkà 28:24) Jèhófà ti kìlọ̀ fún Júdà pé àìṣòótọ́ rẹ̀ yóò jẹ ẹ́ níyà gidigidi nígbà tí Ásíríà bá gbógun tì í. Àmọ́, Jerúsálẹ́mù yóò bọ́. (Aísáyà 1:7, 8) Hesekáyà lọba Jerúsálẹ́mù nígbà tí àwọn ará Ásíríà lọ ṣígun bá wọn. Hesekáyà kò sì rí bí baba rẹ̀, Áhásì. Kódà, oṣù kìíní tí Hesekáyà gorí àlééfà ló ti ṣí àwọn ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì padà, tó sì mú ìjọsìn mímọ́ gaara bọ̀ sípò!—2 Kíróníkà 29:3-5.
10. Kí ni ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa ará Ásíríà?
10 Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà kò fọwọ́ sí ogun tí Ásíríà fẹ́ bá Jerúsálẹ́mù jà. Jèhófà ṣèlérí pé agbára ayé aláfojúdi yẹn ń bọ̀ wá jíhìn, ó sọ pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí Jèhófà bá mú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ kásẹ̀ nílẹ̀ ní Òkè Ńlá Síónì àti ní Jerúsálẹ́mù, èmi yóò béèrè ìjíhìn nítorí èso àfojúdi ti ọkàn-àyà ọba Ásíríà àti nítorí ìkara-ẹni-sí-pàtàkì ti ìgafíofío ojú rẹ̀.”—Aísáyà 10:12.
Júdà àti Jerúsálẹ́mù Yá!
11. Èé ṣe tí ará Ásíríà náà fi rò pé bí ìgbín lòun ṣe máa he Jerúsálẹ́mù?
11 Ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn ìṣubú ìjọba àríwá lọ́dún 740 ṣááju Sànmánì Tiwa, Senakéríbù, ọba tuntun tó jẹ ní Ásíríà, ṣígun lọ bá Jerúsálẹ́mù. Aísáyà fi ewì ṣàpèjúwe ohun tí Senakéríbù fi ìgbéraga pète, ó sọ pé: “Èmi yóò sì mú àwọn ààlà àwọn ènìyàn kúrò, àwọn nǹkan tí wọ́n sì tò jọ pa mọ́ ni èmi yóò kó ní ìkógun dájúdájú, èmi yóò sì rẹ àwọn olùgbé ibẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alágbára. Gẹ́gẹ́ bí ìtẹ́ ẹyẹ, ọwọ́ mi yóò sì tẹ ohun àmúṣọrọ̀ àwọn ènìyàn; gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn kó àwọn ẹyin tí a fi sílẹ̀ jọ, èmi fúnra mi yóò kó gbogbo ilẹ̀ ayé pàápàá jọ, dájúdájú, kì yóò sí èyí tí yóò máa gbọn ìyẹ́ apá rẹ̀ bàlàbàlà tàbí tí yóò máa la ẹnu rẹ̀ tàbí tí yóò máa ké ṣíoṣío.” (Aísáyà 10:13, 14) Èrò Senakéríbù ni pé àwọn ìlú yòókù ti ṣubú, Samáríà kò sì sí mọ́, nítorí náà, bí ìgbín lòun ṣe máa he Jerúsálẹ́mù! Ìlú yẹn lè kọ́kọ́ jà ṣúkẹ́ṣúkẹ́, àmọ́ bóyá làwọn aráàlú yóò fi ké ṣíoṣío kọ́wọ́ tó tẹ̀ wọ́n, tí yóò sì kó wọn ní dúkìá bí ẹní kó ẹyin látinú ìtẹ́ tí ẹyẹ ti sá kúrò.
12. Irú ojú wo ni Jèhófà sọ pé ó yẹ kí a fi wo gbogbo ẹnu tára Ásíríà náà ń fọ́n?
12 Àmọ́, ìgbàgbé ló ṣe Senakéríbù. Ìyà tó tọ́ sí Samáríà apẹ̀yìndà ló jẹ ẹ́. Ṣùgbọ́n lábẹ́ Hesekáyà Ọba, Jerúsálẹ́mù tún ti di ibi tí ìsìn mímọ́ gaara fìdí kalẹ̀ sí. Ẹnikẹ́ni tó bá sì ta félefèle dé ọ̀dọ̀ Jerúsálẹ́mù yóò rí pupa ojú Jèhófà! Tìbínú-tìbínú ni Aísáyà fi béèrè pé: “Àáké yóò ha gbé ara rẹ̀ lékè ẹni tí ń fi í gé nǹkan, tàbí kẹ̀, ayùn yóò ha gbé ara rẹ̀ ga ju ẹni tí ń mú kí ó lọ síwá-sẹ́yìn, bí ẹni pé ọ̀gọ ni ó mú kí àwọn tí ó gbé e sókè lọ síwá-sẹ́yìn, bí ẹni pé ọ̀pá ni ó gbé ẹni tí kì í ṣe igi sókè?” (Aísáyà 10:15) Bí àáké ṣe jẹ́ irinṣẹ́ lọ́wọ́ agbẹ́gi, tí ayùn jẹ́ irinṣẹ́ lọ́wọ́ alapákó, tí ọ̀gọ tàbí ọ̀pá sì jẹ́ irinṣẹ́ lọ́wọ́ olùṣọ́ àgùntàn, bẹ́ẹ̀ náà ni Ilẹ̀ Ọba Ásíríà ṣe jẹ́ irinṣẹ́ lásánlàsàn lọ́wọ́ Jèhófà. Àgbẹdọ̀, ọ̀pá ò jẹ́ gbé ara rẹ̀ lékè ẹni tí ń lò ó!
13. Sọ àwọn tí gbólóhùn wọ̀nyí tọ́ka sí àti ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn (a) ‘àwọn tó sanra.’ (b) ‘èpò àti àwọn igi kéékèèké ẹlẹ́gùn-ún.’ (d) “ògo igbó rẹ.”
13 Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ará Ásíríà náà? “Olúwa tòótọ́, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò máa rán òkùnrùn amúnijoro sára àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó sanra, àti pé lábẹ́ ògo rẹ̀, jíjó kan yóò máa jó nìṣó bí jíjó iná. Ìmọ́lẹ̀ Ísírẹ́lì yóò sì di iná, Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóò sì di ọwọ́ iná; yóò sì jó, yóò sì jẹ èpò àti àwọn igi kéékèèké rẹ̀ ẹlẹ́gùn-ún run ní ọjọ́ kan. Ògo igbó rẹ̀ àti ti ọgbà igi eléso rẹ̀ ni Òun yóò sì mú wá sí òpin, àní láti ọkàn títí lọ dé ẹran ara, yóò sì dà bí yíyọ́dànù ẹni tí ń ṣòjòjò. Àti ìyókù àwọn igi igbó rẹ̀—wọn yóò di èyí tí ọmọdékùnrin kan lásán yóò lè kọ iye wọn sílẹ̀.” (Aísáyà 10:16-19) Bẹ́ẹ̀ ni, tẹ́ẹ́rẹ́ báyìí ni Jèhófà yóò fá “ọ̀pá” yẹn kù, èyíinì ni Ásíríà! ‘Àwọn ènìyàn tí ó sanra’ lára ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ásíríà, àwọn gìrìpá nínú àwọn sójà rẹ̀, ni “òkùnrùn amúnijoro” yóò kọ lù. Hẹ́gẹhẹ̀gẹ ni wọ́n máa dà! Jèhófà Ọlọ́run, Ìmọ́lẹ̀ Ísírẹ́lì, yóò wá jó agbo ọmọ ogun orí ilẹ̀ tó ní, bí ìgbà tí iná jó èpò àti àwọn igi kéékèèké ẹlẹ́gùn-ún. “Ògo igbó rẹ̀,” ìyẹn àwọn ọ̀gágun rẹ̀, yóò sì pa rẹ́. Ìgbà tí Jèhófà bá fi máa bá ará Ásíríà yẹn kanlẹ̀, olórí ogun rẹ̀ tó máa ṣẹ́ kù yóò kéré níye débi pé, ọmọdékùnrin kan lásán yóò lè fi ọmọ ìka rẹ̀ ṣírò iye wọn!—Wo Aísáyà 10:33, 34 pẹ̀lú.
14. Ṣàlàyé lórí bí ará Ásíríà náà ṣe ń tẹ̀ síwájú lórí ilẹ̀ Júdà ní nǹkan bí ọdún 732 ṣááju Sànmánì Tiwa.
14 Síbẹ̀, yóò ṣòro fáwọn Júù tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù lọ́dún 732 ṣááju Sànmánì Tiwa láti gbà gbọ́ pé Ásíríà ṣe é ṣẹ́gun. Ńṣe ni ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ásíríà tó lọ súà ń jagun bọ̀ láìsọsẹ̀. Gbọ́ orúkọ àwọn ìlú Júdà tọ́wọ́ wọn ti tẹ̀: “Òun ti dé bá Áyátì . . . Mígírónì . . . Míkímáṣì . . . Gébà . . . Rámà . . . Gíbíà ti Sọ́ọ̀lù . . . Gálímù . . . Láíṣà . . . Ánátótì . . . Mádíménà . . . Gébímù . . . Nóbù.” (Aísáyà 10:28-32a)b Wọ́n sì ti wá jagun wọn dé Lákíṣì, ní nǹkan bí àádọ́ta kìlómítà péré sí Jerúsálẹ́mù. Kò sì pẹ́ tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ásíríà rẹpẹtẹ fi bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ ìlú náà. “Ó mi ọwọ́ lọ́nà ìhalẹ̀mọ́ni sí òkè ńlá ọmọbìnrin Síónì, òkè kékeré Jerúsálẹ́mù.” (Aísáyà 10:32b) Kí ló wá fẹ́ dá ará Ásíríà náà dúró?
15, 16. (a) Èé ṣe tó fi ń béèrè pé kí Hesekáyà Ọba ní ìgbàgbọ́ tó lágbára? (b) Kí nìdí tí Hesekáyà fi gbà gbọ́ pé Jèhófà yóò ran òun lọ́wọ́?
15 Nínú ìlú lọ́hùn-ún, ọkàn Hesekáyà Ọba kò balẹ̀ mọ́ láàfin rẹ̀. Ó gbọn ẹ̀wù rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ àpò ìdọ̀họ bora. (Aísáyà 37:1) Ó wá ránni sí wòlíì Aísáyà pé kó lọ bá Júdà ṣèwádìí lọ́dọ̀ Jèhófà. Kò sì pẹ́ tí wọ́n fi mú èsì Jèhófà wá pé: “Má fòyà . . . Dájúdájú, èmi yóò . . . gbèjà ìlú ńlá yìí.” (Aísáyà 37:6, 35) Síbẹ̀, àkòtagìrì làwọn ará Ásíríà, àyà wọ́n sì le bíi kìnnìún.
16 Ìgbàgbọ́ nìkan ni ohun tó lè mú kí Hesekáyà Ọba la yánpọnyánrin yìí já. Ìgbàgbọ́ ni “ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Hébérù 11:1) Ọ̀ràn ìgbàgbọ́ kọjá wíwo nǹkan lóréfèé. Àmọ́, ìgbàgbọ́ sinmi lórí ohun téèyàn bá mọ̀. Ó ṣeé ṣe kí Hesekáyà rántí pé ṣáájú ìgbà yìí, Jèhófà ti sọ̀rọ̀ ìtùnú yìí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi tí ń gbé ní Síónì, ẹ má fòyà nítorí ará Ásíríà náà . . . Nítorí pé ní ìgbà díẹ̀ sí i—ìdálẹ́bi náà yóò ti wá sí òpin, àti ìbínú mi, yóò ti rọlẹ̀. Dájúdájú, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò ju pàṣán kan fìrìfìrì lára rẹ̀ bí ti ìgbà ìṣẹ́gun Mídíánì lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpáta Órébù; ọ̀gọ rẹ̀ yóò sì wà lórí òkun, yóò sì gbé e sókè dájúdájú bí ó ti ṣe sí Íjíbítì.” (Aísáyà 10:24-26)c Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn èèyàn Ọlọ́run ti ko ìṣòro rí. Létí Òkun Pupa, àwọn baba ńlá Hesekáyà kò jù táṣẹ́rẹ́ lọ ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Íjíbítì. Bí iyanrìn làwọn tí Gídéónì dojú kọ ṣe pọ̀ súà nígbà tí Mídíánì àti Ámálékì ṣígun lọ bá Ísírẹ́lì ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn. Síbẹ̀, Jèhófà gba àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ nígbà méjèèjì yẹn.—Ẹ́kísódù 14:7-9, 13, 28; Àwọn Onídàájọ́ 6:33; 7:21, 22.
17. Báwo ni a ṣe “ba” àjàgà ará Ásíríà “jẹ́,” kí ló sì fà á?
17 Ṣé Jèhófà yóò tún ṣe bó ti ṣe ní àwọn ìgbà yẹn lọ́hùn-ún? Bẹ́ẹ̀ ni. Jèhófà ṣèlérí pé: “Yóò . . . ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé ẹrù rẹ̀ yóò kúrò ní èjìká rẹ, àjàgà rẹ̀ yóò sì kúrò ní ọrùn rẹ, a ó sì ba àjàgà náà jẹ́ dájúdájú nítorí òróró.” (Aísáyà 10:27) Àjàgà Ásíríà yóò kúrò ní èjìká àti ọrùn àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú. Kódà, a ó “ba” àjàgà yẹn “jẹ́,” ó sì kúkú bà jẹ́ lóòótọ́! Lóru ọjọ́ kan, áńgẹ́lì Jèhófà pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] lára àwọn ará Ásíríà. Bí ewu yẹn ṣe dópin nìyẹn o, tí àwọn ará Ásíríà sì káńgárá wọn kúrò ní ilẹ̀ Júdà títí ayé. (2 Àwọn Ọba 19:35, 36) Èé ṣe? “Nítorí òróró.” Èyí lè tọ́ka sí òróró tí wọ́n fi yan Hesekáyà ní ọba láti ìlà Dáfídì. Báyìí ni Jèhófà mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ìyẹn ni: “Dájúdájú, èmi yóò gbèjà ìlú ńlá yìí láti gbà á là nítorí tèmi àti nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi.”—2 Àwọn Ọba 19:34.
18. (a) Ǹjẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ní ìmúṣẹ tó ju ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ? Ṣàlàyé. (b) Ètò òde òní wo ló dà bí Samáríà àtijọ́?
18 Ìtàn inú ìwé Aísáyà, tí a jíròrò ní orí yìí, jẹ mọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní Júdà ní èyí tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rìnlá [2,700] ọdún sẹ́yìn. Ṣùgbọ́n òde òní ni ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyẹn ti ṣe pàtàkì jù lọ. (Róòmù 15:4) Ṣé ó wá túmọ̀ sí pé àwọn tó kó ipa pàtàkì nínú ìtàn amóríyá yìí—àwọn olùgbé Samáríà àti Jerúsálẹ́mù àti àwọn ará Ásíríà pẹ̀lú—ní àwọn aláfijọ lóde òní bí? Bẹ́ẹ̀ ni o. Bí ti Samáríà abọ̀rìṣà, Kirisẹ́ńdọ̀mù sọ pé Jèhófà lòun ń sìn, ṣùgbọ́n apẹ̀yìndà paraku ni. Nínú ìwé An Essay on the Development of Christian Doctrine, John Henry Cardinal Newman, ọmọ ìjọ Àgùdà, gbà pé àwọn ohun èlò tí Kirisẹ́ńdọ̀mù fi ń ṣèsìn láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá, irú bíi tùràrí, àbẹ́là, omi mímọ́, aṣọ oyè àlùfáà, àti àwọn ère, “jẹ́ èyí tó tinú ìbọ̀rìṣà wá.” Bí inú Jèhófà kò ṣe dùn sí ìbọ̀rìṣà àwọn ará Samáríà náà ni inú rẹ̀ kò ṣe dùn sí ìsìn oníbọ̀rìṣà tí Kirisẹ́ńdọ̀mù ń ṣe.
19. Kí ni Kirisẹ́ńdọ̀mù ti gba ìkìlọ̀ lé lórí, ta ló sì kì í nílọ̀?
19 Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kìlọ̀ fún Kirisẹ́ńdọ̀mù pé inú Jèhófà ò dùn sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1955, kárí ayé ni wọ́n sọ àwíyé fún gbogbo ènìyàn tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́ “Kirisẹ́ńdọ̀mù Tàbí Jíjẹ́ Kristẹni—Èwo Ni ‘Ìmọ́lẹ̀ Ayé’?” Àsọyé yìí ló lani lóye yékéyéké nípa bí Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe yapa kúrò nínú ojúlówó ẹ̀kọ́ àti ìṣe Kristẹni. Lẹ́yìn náà ni wọ́n wá fi ẹ̀dà àsọyé tó fakíki yìí ránṣẹ́ sí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè. Gẹ́gẹ́ bí àjọ kan, Kirisẹ́ńdọ̀mù kọ etí ikún sí ìkìlọ̀ yìí. Ó ti wá dá Jèhófà lágara débi pé Jèhófà kúkú máa yọ “ọ̀pá” tì í ni.
20. (a) Kí ni yóò jẹ́ Ásíríà òde òní, báwo la ó sì ṣe lò ó gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá? (b) Báwo ni ìyà Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe máa pọ̀ tó?
20 Ta ni Jèhófà yóò wá lò láti fi jẹ Kirisẹ́ńdọ̀mù níyà? Orí kẹtàdínlógún ìwé Ìṣípayá ni ìdáhùn rẹ̀ wà. Ibẹ̀ la ti gbọ́ nípa aṣẹ́wó kan, ìyẹn “Bábílónì Ńlá,” tó dúró fún gbogbo ẹ̀sìn èké àgbáyé, títí kan Kirisẹ́ńdọ̀mù. Aṣẹ́wó yìí gun ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò kan tó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá. (Ìṣípayá 17:3, 5, 7-12) Ẹranko ẹhànnà yìí dúró fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.d Gẹ́gẹ́ bí Ásíríà ìgbà àtijọ́ ṣe pa Samáríà run, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yẹn yóò ṣe “kórìíra aṣẹ́wó náà . . . yóò sì sọ ọ́ di ìparundahoro àti ìhòòhò . . . yóò sì jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara rẹ̀ tán . . . yóò sì fi iná sun ún pátápátá.” (Ìṣípayá 17:16) Bí Ásíríà òde òní (àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè) yóò ṣe rọ́ lu Kirisẹ́ńdọ̀mù nìyẹn, tí yóò sì pa á kú fin-ín fin-ín.
21, 22. Ta ni yóò ti ẹranko ẹhànnà náà láti gbéjà ko àwọn ènìyàn Ọlọ́run?
21 Ṣé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà olùṣòtítọ́ yóò pa run pọ̀ mọ́ Bábílónì Ńlá ni? Rárá o. Ọlọ́run kò bínú sí wọn ní tiwọn. Ìsìn mímọ́ gaara yóò là á já. Àmọ́ ṣá o, ńṣe ni ẹranko ẹhànnà tó pa Bábílónì Ńlá run tún ń wo ìhà ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn Jèhófà fẹ̀tòfẹ̀tò. Ṣùgbọ́n, kì í ṣe èrò ọkàn Ọlọ́run lohun tí ẹranko ẹhànnà yẹn ń ṣe yìí, èrò tẹlòmíràn ni. Ti ta ni? Ti Sátánì Èṣù ni.
22 Jèhófà táṣìírí ète agbéraga tí Sátánì ń pa, ó sọ pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé àwọn nǹkan yóò wá sí ọkàn-àyà rẹ [ìyẹn, Sátánì], dájúdájú, ìwọ yóò sì gbìrò ìpètepèrò tí ń ṣeni léṣe; ìwọ yóò sì wí pé: ‘Èmi yóò . . . wá sórí àwọn tí kò ní ìyọlẹ́nu, àwọn tí ń gbé ní ààbò, tí gbogbo wọn ń gbé láìsí ògiri [ààbò kankan] . . . ’ Yóò jẹ́ láti kó ohun ìfiṣèjẹ rẹpẹtẹ àti láti piyẹ́ ohun púpọ̀.” (Ìsíkíẹ́lì 38:10-12) Ohun tí Sátánì máa rò lọ́kan ni pé, ‘Tóò, mi ò ṣe kúkú dẹ àwọn orílẹ̀-èdè sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Ṣebí wọ́n kúkú wà níbi tọ́wọ́ á ti tètè tẹ̀ wọ́n, ìta gbalasa ni wọ́n wà, wọn ò sì ní alátìlẹyìn lágbo àwọn olóṣèlú. Wọn ò tiẹ̀ ní janpata rárá. Wẹ́rẹ́ ni màá kó wọn, bí ìgbà téèyàn kó ẹyin nínú ìtẹ́ ẹyẹ!’
23. Èé ṣe tí ará Ásíríà òde òní kò fi ní lè ṣe àwọn ènìyàn Ọlọ́run bí ó ṣe ṣe Kirisẹ́ńdọ̀mù?
23 Ṣùgbọ́n, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, ẹ jẹ́ ṣọ́ra! Kó tètè yée yín pé, bí ẹ bá fọwọ́ kan àwọn ènìyàn Jèhófà pẹ́nrẹ́n, ẹ ó gba Ọlọ́run lọ́gàá! Jèhófà fẹ́ràn àwọn èèyàn rẹ̀, gẹ́lẹ́ bó ṣe gbèjà Jerúsálẹ́mù nígbà ayé Hesekáyà náà ni yóò ṣe jà fáwọn náà. Nígbà tí ará Ásíríà tòde òní bá gbìyànjú láti pa àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà rẹ́, Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi, Ọ̀dọ́ àgùntàn náà, ni yóò máa bá jà yẹn o. Ìyẹn sì jẹ́ ogun tí ará Ásíríà ò lè ṣẹ́gun. “Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò ṣẹ́gun wọn,” nítorí Bíbélì sọ pé, “òun ni Olúwa àwọn olúwa àti Ọba àwọn ọba.” (Ìṣípayá 17:14; fi wé Mátíù 25:40.) Bí ti Ásíríà ìgbà àtijọ́ ni ẹranko ẹhànnà yẹn yóò ṣe “kọjá lọ sínú ìparun.” Ẹ̀rù rẹ̀ kò ní ba ẹnikẹ́ni mọ́.—Ìṣípayá 17:11.
24. (a) Kí làwọn Kristẹni tòótọ́ ti pinnu láti ṣe ní ìmúrasílẹ̀ de ọjọ́ iwájú? (b) Báwo ló ṣe jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ọjọ́ iwájú lọ́hùn-ún ni Aísáyà ń sọ? (Wo àpótí ojú ìwé 155.)
24 Ẹ̀rù ọjọ́ iwájú kò ní ba àwọn Kristẹni tòótọ́ rárá bí wọ́n bá ń bá a lọ láti jẹ́ kí àárín àwọn àti Jèhófà túbọ̀ máa dán mọ́rán sí i, tí wọ́n sì ń fi ìfẹ́ tirẹ̀ ṣáájú ohunkóhun nínú ìgbésí ayé wọn. (Mátíù 6:33) A jẹ́ pé kò sídìí fún wọn láti “bẹ̀rù ohun búburú kankan.” (Sáàmù 23:4) Wọn yóò fi ojú ìgbàgbọ́ rí i bí Ọlọ́run ṣe na apá rẹ̀ sókè, láìṣe pé ó fẹ́ fi jẹ wọ́n níyà bí kò ṣe láti fi dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ ni yóò máa dún sí wọ́n létí pé: “Ẹ má fòyà.”—Aísáyà 10:24.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé Insight on the Scriptures, Apá Kìíní, ojú ewé 203.
b Kí òye lè yéni yékéyéké, a kọ́kọ́ ṣàlàyé Aísáyà 10:28-32 ṣáájú Aísáyà 10:20-27.
c Ní ti ìjíròrò Aísáyà 10:20-23, wo “Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ Iwájú Lọ́hùn-ún Ni Aísáyà Ń Sọ,” lójú ìwé 155.
d A lè rí àfikún ìsọfúnni nípa ẹni tí aṣẹ́wó náà àti ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà jẹ́ nínú orí kẹrìnlélọ́gbọ̀n àti ìkarùndínlógójì ìwé Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 155, 156]
Ọ̀RỌ̀ ỌJỌ́ IWÁJÚ LỌ́HÙN-ÚN NI AÍSÁYÀ Ń SỌ
Ní pàtàkì, orí kẹwàá ìwé Aísáyà dá lórí bí Jèhófà yóò ṣe lo ogun tí Ásíríà ń gbé bọ̀ láti fi mú ìdájọ́ ṣẹ lórí Ísírẹ́lì àti lórí ìlérí tó ṣe láti gbèjà Jerúsálẹ́mù. Bó sì ṣe jẹ́ pé àárín àsọtẹ́lẹ̀ yìí ni ẹsẹ ogún sí ìkẹtàlélógún bọ́ sí, a lè wò wọ́n bí èyí tó ní ìmúṣẹ lọ́nà kan ṣá lákòókò yìí kan náà. (Fi wé Aísáyà 1:7-9.) Àmọ́, ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ wọ̀nyí fi hàn pé àwọn àkókò kan ń bọ̀ lẹ́yìn ìgbà náà, tí wọ́n yóò wá ní ìmúṣẹ lọ́nà tó túbọ̀ ṣe pàtó, nígbà tí Jerúsálẹ́mù yóò ní láti jẹ́jọ́ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
Ààbò ni Áhásì Ọba ń wá tó fi yíjú sọ́dọ̀ Ásíríà fún ìrànlọ́wọ́. Wòlíì Aísáyà sàsọtẹ́lẹ̀ pé, ìgbà kan ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, tí àwọn tó là á já ní ilé Ísírẹ́lì kò tún ní jẹ́ dáwọ́ lé irú ìwà òmùgọ̀ bẹ́ẹ̀ mọ́. Aísáyà 10:20 sọ pé wọn yóò “gbé ara wọn lé Jèhófà, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, nínú òótọ́.” Ṣùgbọ́n ẹsẹ kọkànlélógún fi hàn pé, àwọn díẹ̀ péré ló máa ṣe bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Àṣẹ́kù lásán ni yóò padà.” Èyí mú wa rántí Ṣeari-jáṣúbù ọmọ Aísáyà, tó jẹ́ àmì ní Ísírẹ́lì, tórúkọ rẹ̀ sì túmọ̀ sí “Kìkì Àṣẹ́kù Ni Yóò Padà.” (Aísáyà 7:3) Orí kẹwàá ẹsẹ kejìlélógún kìlọ̀ nípa “ìparun pátápátá” tí ń bọ̀, èyí tí a ti ṣe ìpinnu lé lórí. Irú ìparun pátápátá bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ nínú òdodo nítorí pé ó jẹ́ ìyà tó tọ́ sí àwọn èèyàn aláìgbọràn. Nítorí èyí, kìkì àṣẹ́kù ni yóò padà wá lára orílẹ̀-èdè tí àwọn èèyàn kún fọ́fọ́ “bí àwọn egunrín iyanrìn òkun.” Ẹsẹ kẹtàlélógún kìlọ̀ pé ìparun pátápátá tí ń bọ̀ yìí yóò kan gbogbo ilẹ̀ náà. Jerúsálẹ́mù kò ní yèbọ́ lọ́tẹ̀ yìí.
Ẹsẹ wọ̀nyí ṣàpèjúwe ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa dáadáa, nígbà tí Jèhófà lo Ilẹ̀ Ọba Bábílónì gẹ́gẹ́ bí “ọ̀pá” rẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ náà, títí kan Jerúsálẹ́mù ló ṣubú sọ́wọ́ agbóguntini. Ni àwọn Júù bá dèrò ìgbèkùn ní Bábílónì fún àádọ́rin ọdún. Àmọ́ ṣá, lẹ́yìn ìyẹn, àwọn kan—ì báà tiẹ̀ jẹ́ kìkì “àṣẹ́kù lásán”—padà wá láti mú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò ní Jerúsálẹ́mù.
Àsọtẹ́lẹ̀ inú Aísáyà 10:20-23 ní ìmúṣẹ síwájú sí i ní ọ̀rúndún kìíní, gẹ́gẹ́ bí Róòmù 9:27, 28 ṣe fi hàn. (Fi wé Aísáyà 1:9; Róòmù 9:29.) Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé, nípa tẹ̀mí, “àṣẹ́kù” àwọn Júù “padà” wá sọ́dọ̀ Jèhófà ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, níwọ̀n bí díẹ̀ lára àwọn Júù olóòótọ́ ti di ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jọ́sìn Jèhófà “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) Àwọn Kèfèrí tó gbà gbọ́ wá dara pọ̀ mọ́ wọn lẹ́yìn ìgbà náà, tí wọ́n fi di orílẹ̀-èdè tẹ̀mí, “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gálátíà 6:16) Ìgbà yìí ni ọ̀rọ̀ Aísáyà 10:20 wá ṣẹ tó fi jẹ́ pé orílẹ̀-èdè tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà ‘kò tún’ yí padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ “mọ́” láé láti lọ gbára lé ọmọ aráyé fún ìrànlọ́wọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 147]
Senakéríbù rò ó lọ́kàn pé wẹ́rẹ́ bí ìgbà téèyàn kó ẹyin nínú ìtẹ́ ẹyẹ lòun ṣe màá kó àwọn orílẹ̀-èdè