Diutarónómì
4 “Ní báyìí, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ fetí sí àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí mò ń kọ́ yín láti pa mọ́, kí ẹ lè máa wà láàyè,+ kí ẹ lè wọ ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín máa fún yín, kí ẹ sì gbà á. 2 Ẹ ò gbọ́dọ̀ fi kún ọ̀rọ̀ tí mò ń pa láṣẹ fún yín, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ yọ kúrò lára rẹ̀,+ kí ẹ lè máa tẹ̀ lé àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín tí mò ń pa láṣẹ fún yín.
3 “Ẹ ti fi ojú ara yín rí ohun tí Jèhófà ṣe nínú ọ̀rọ̀ Báálì Péórì; gbogbo ọkùnrin tó tọ Báálì Péórì+ lẹ́yìn ni Jèhófà Ọlọ́run yín pa run kúrò láàárín yín. 4 Àmọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ẹ rọ̀ mọ́ Jèhófà Ọlọ́run yín lẹ wà láàyè lónìí. 5 Ẹ wò ó, mo ti kọ́ yín ní àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́,+ bí Jèhófà Ọlọ́run mi ṣe pa á láṣẹ fún mi gẹ́lẹ́, kí ẹ lè máa pa wọ́n mọ́ ní ilẹ̀ tí ẹ máa gbà. 6 Kí ẹ rí i pé ẹ̀ ń pa wọ́n mọ́,+ torí èyí máa fi hàn pé ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n+ àti olóye+ lójú àwọn èèyàn tó máa gbọ́ nípa gbogbo ìlànà yìí, wọ́n á sì sọ pé, ‘Ó dájú pé ọlọ́gbọ́n àti olóye ni àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ńlá yìí.’+ 7 Orílẹ̀-èdè ńlá wo ni àwọn ọlọ́run rẹ̀ sún mọ́ ọn bíi ti Jèhófà Ọlọ́run wa nígbàkigbà tí a bá ké pè é?+ 8 Orílẹ̀-èdè ńlá wo ló sì ní àwọn ìlànà òdodo àti àwọn ìdájọ́ bíi ti gbogbo Òfin yìí tí mò ń fi sí iwájú yín lónìí?+
9 “Ṣáà máa kíyè sára, kí o sì máa ṣọ́ra gan-an,* kí o má bàa gbàgbé àwọn ohun tí o fi ojú rẹ rí, kí wọ́n má bàa kúrò lọ́kàn rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Kí o sì tún jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ mọ̀ nípa wọn.+ 10 Ní ọjọ́ tí o dúró níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní Hórébù, Jèhófà sọ fún mi pé, ‘Pe àwọn èèyàn náà jọ sọ́dọ̀ mi kí n lè mú kí wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mi,+ kí wọ́n lè kọ́ láti máa bẹ̀rù mi+ ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n á fi wà láàyè lórí ilẹ̀, kí wọ́n sì lè kọ́ àwọn ọmọ wọn.’+
11 “Ẹ wá sún mọ́ tòsí òkè náà, ẹ sì dúró sí ìsàlẹ̀ rẹ̀, òkè náà sì ń yọ iná títí dé ọ̀run;* òkùnkùn ṣú, ìkùukùu* yọ, ojú ọjọ́ sì ṣú dùdù.+ 12 Jèhófà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá yín sọ̀rọ̀ látinú iná náà.+ Ẹ̀ ń gbọ́ tí ẹnì kan ń sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ ò rí ẹnì kankan,+ ohùn nìkan lẹ̀ ń gbọ́.+ 13 Ó sì kéde májẹ̀mú rẹ̀ fún yín,+ èyí tó pa láṣẹ fún yín pé kí ẹ máa pa mọ́, ìyẹn Òfin Mẹ́wàá.*+ Lẹ́yìn náà, ó kọ ọ́ sórí wàláà òkúta méjì.+ 14 Nígbà yẹn, Jèhófà pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ yín ní àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí ẹ ó máa pa mọ́ ní ilẹ̀ tí ẹ fẹ́ lọ gbà.
15 “Torí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi,* torí pé ẹ ò rí ẹnikẹ́ni lọ́jọ́ tí Jèhófà bá yín sọ̀rọ̀ ní Hórébù láti àárín iná náà, 16 kí ẹ má bàa hùwàkiwà nípa gbígbẹ́ ère èyíkéyìí tó jọ ohunkóhun fún ara yín, ohun tó rí bí akọ tàbí abo,+ 17 ohun tó rí bí ẹranko èyíkéyìí ní ayé, bí ẹyẹ tó ń fò lójú ọ̀run,+ 18 bí ohunkóhun tó ń rákò lórí ilẹ̀ tàbí tó rí bí ẹja èyíkéyìí nínú omi lábẹ́ ilẹ̀.+ 19 Tí o bá wá yíjú sókè wo ọ̀run, tí o sì rí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀, gbogbo ọmọ ogun ọ̀run, o ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọkàn rẹ fà sí wọn débi pé o máa forí balẹ̀ fún wọn, tí o sì máa sìn wọ́n.+ Gbogbo èèyàn lábẹ́ ọ̀run ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi wọ́n fún. 20 Àmọ́ ẹ̀yin ni Jèhófà mú jáde nínú iná ìléru tí wọ́n ti ń yọ́ irin, kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, kí ẹ lè di ohun ìní rẹ̀*+ bí ẹ ṣe jẹ́ lónìí.
21 “Jèhófà bínú sí mi torí yín,+ ó sì búra pé mi ò ní sọdá Jọ́dánì, mi ò sì ní wọ ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín láti jogún.+ 22 Ilẹ̀ yìí ni màá kú sí; mi ò ní sọdá Jọ́dánì,+ ṣùgbọ́n ẹ̀yin máa sọdá, ẹ sì máa gba ilẹ̀ dáradára náà. 23 Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má bàa gbàgbé májẹ̀mú tí Jèhófà Ọlọ́run yín bá yín dá,+ ẹ má sì gbẹ́ ère fún ara yín, ohun tó rí bí ohunkóhun tí Jèhófà Ọlọ́run yín kà léèwọ̀ fún yín.+ 24 Torí iná tó ń jóni run ni Jèhófà Ọlọ́run yín,+ Ọlọ́run tó fẹ́ kí ẹ máa jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo.+
25 “Tí ẹ bá bí àwọn ọmọ, tí ẹ sì ní àwọn ọmọ ọmọ, tí ẹ sì ti pẹ́ ní ilẹ̀ náà, àmọ́ tí ẹ wá ṣe ohun tó lè fa ìparun, tí ẹ gbẹ́ ère+ èyíkéyìí, tí ẹ sì ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà Ọlọ́run yín láti mú un bínú,+ 26 mo fi ọ̀run àti ayé ṣe ẹlẹ́rìí ta kò yín lónìí, pé ó dájú pé kíákíá lẹ máa pa run ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọdá Jọ́dánì láti lọ gbà. Ẹ ò ní pẹ́ níbẹ̀, ṣe lẹ máa pa run pátápátá.+ 27 Jèhófà máa tú yín ká sáàárín àwọn èèyàn,+ díẹ̀ nínú yín ló sì máa ṣẹ́ kù+ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà máa lé yín lọ. 28 Àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi igi àti òkúta ṣe lẹ máa sìn níbẹ̀, èyí tí àwọn èèyàn fi ọwọ́ ṣe,+ àwọn ọlọ́run tí kò lè ríran, tí kò lè gbọ́ràn, tí kò lè jẹun, tí kò sì lè gbóòórùn.
29 “Tí ẹ bá wá Jèhófà Ọlọ́run yín níbẹ̀, ó dájú pé ẹ máa rí i+ tí ẹ bá fi gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín wá a.+ 30 Tí wàhálà tó le gan-an bá dé bá ọ, tí gbogbo nǹkan yìí sì wá ṣẹlẹ̀ sí ọ, wàá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, wàá sì fetí sí ohùn rẹ̀.+ 31 Torí Ọlọ́run aláàánú ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ Kò ní pa ọ́ tì, kò ní pa ọ́ run, kò sì ní gbàgbé májẹ̀mú tó bá àwọn baba ńlá rẹ dá.+
32 “Béèrè báyìí nípa ìgbà àtijọ́, ṣáájú ìgbà tìẹ, láti ọjọ́ tí Ọlọ́run ti dá èèyàn sí ayé; wádìí láti ìpẹ̀kun kan ọ̀run sí ìpẹ̀kun kejì. Ṣé irú nǹkan àgbàyanu bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ rí àbí ẹ ti gbọ́ ohunkóhun tó jọ ọ́ rí?+ 33 Ǹjẹ́ àwọn èèyàn míì gbọ́ ohùn Ọlọ́run tó ń sọ̀rọ̀ látinú iná bí ẹ ṣe gbọ́ ọ, tí ẹ ò sì kú?+ 34 Àbí Ọlọ́run ti gbìyànjú láti mú orílẹ̀-èdè kan fún ara rẹ̀ látinú orílẹ̀-èdè míì pẹ̀lú àwọn ìdájọ́,* àmì, iṣẹ́ ìyanu,+ ogun,+ pẹ̀lú ọwọ́ agbára,+ apá tó nà jáde, tó sì ṣe àwọn nǹkan tó ń bani lẹ́rù,+ bí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe ṣe fún yín ní Íjíbítì níṣojú yín? 35 Ẹ̀yin fúnra yín ti rí nǹkan wọ̀nyí kí ẹ lè mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́;+ kò sí ẹlòmíì àfi òun nìkan.+ 36 Ó mú kí o gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run, kó lè tọ́ ọ sọ́nà, ó mú kí o rí iná ńlá rẹ̀ ní ayé, o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ látinú iná.+
37 “Torí pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn baba ńlá rẹ, ó sì yan àtọmọdọ́mọ* wọn lẹ́yìn wọn,+ ó fi agbára ńlá rẹ̀ mú ọ kúrò ní Íjíbítì pẹ̀lú ojú rẹ̀ lára rẹ. 38 Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè tó tóbi, tí wọ́n sì lágbára jù ọ́ lọ kúrò níwájú rẹ, kó lè mú ọ wọlé, kó sì fún ọ ní ilẹ̀ wọn kí o lè jogún rẹ̀, bó ṣe rí lónìí.+ 39 Torí náà, kí o mọ̀ lónìí, kí o sì fi sọ́kàn pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ lókè ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.+ Kò sí ẹlòmíì.+ 40 Kí o máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà àti àwọn àṣẹ rẹ̀, èyí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ, kí o lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ.”+
41 Nígbà yẹn, Mósè ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ ní apá ìlà oòrùn Jọ́dánì.+ 42 Tí apààyàn èyíkéyìí bá ṣèèṣì pa ọmọnìkejì rẹ̀, tí kì í sì í ṣe pé ó kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀,+ kó sá lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú yìí, kí wọ́n má bàa pa á.+ 43 Àwọn ìlú náà ni Bésérì+ ní aginjù, lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú,* fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, Rámótì+ ní Gílíádì fún àwọn ọmọ Gádì àti Gólánì+ ní Báṣánì fún àwọn ọmọ Mánásè.+
44 Èyí ni Òfin+ tí Mósè fi lélẹ̀ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 45 Èyí ni àwọn ìrántí, àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì,+ 46 ní agbègbè Jọ́dánì, ní àfonífojì tó dojú kọ Bẹti-péórì,+ ní ilẹ̀ Síhónì ọba àwọn Ámórì, tó ń gbé ní Hẹ́ṣíbónì,+ ẹni tí Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì.+ 47 Wọ́n sì gba ilẹ̀ rẹ̀ àti ilẹ̀ Ógù+ ọba Báṣánì, àwọn ọba Ámórì méjèèjì, tí wọ́n wà ní agbègbè tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì, 48 láti Áróérì,+ èyí tó wà létí Àfonífojì Áánónì, títí dé Òkè Síónì, ìyẹn Hámónì,+ 49 àti gbogbo Árábà, ní agbègbè tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì, títí lọ dé Òkun Árábà,* ní ìsàlẹ̀ àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà.+