ORÍ 88
Ọkùnrin Ọlọ́rọ̀ Kan Àti Lásárù
ÀPÈJÚWE ỌKÙNRIN ỌLỌ́RỌ̀ ÀTI LÁSÁRÙ
Ọ̀rọ̀ nípa bó ṣe yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fọgbọ́n lo ohun ìní wọn ni Jésù ti ń bá wọn sọ. Àmọ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nìkan kọ́ ló ń gbọ́rọ̀ yìí. Àwọn Farisí náà wà níbẹ̀, ó sì yẹ kí wọ́n fọkàn sóhun tí Jésù ń sọ. Kí nìdí tọ́rọ̀ yẹn fi kàn wọ́n? Ìdí ni pé wọ́n “nífẹ̀ẹ́ owó.” Àmọ́, ṣe ni wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí í yínmú sí” Jésù nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tó ń sọ.—Lúùkù 15:2; 16:13, 14.
Ohun tí wọ́n ṣe yẹn ò tu irun kan lára Jésù. Torí náà, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin lẹ̀ ń kéde pé olódodo ni yín níwájú àwọn èèyàn, àmọ́ Ọlọ́run mọ ohun tó wà lọ́kàn yín. Torí ohun tí àwọn èèyàn kà sí ohun tí a gbé ga jẹ́ ohun ìríra lójú Ọlọ́run.”—Lúùkù 16:15.
Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń ka àwọn Farisí yẹn sí ẹni “tí a gbé ga,” àmọ́ ìgbà ọ̀tun ti dé, nǹkan sì máa tó yí pa dà. Báwọn èèyàn tiẹ̀ ń gbé wọn ga torí bí wọ́n ṣe lówó lọ́wọ́, tí wọ́n lẹ́nu lágbo òṣèlú, tí wọ́n sì jẹ́ aṣáájú ẹ̀sìn, Ọlọ́run máa tó rẹ̀ wọ́n wálẹ̀. Ọlọ́run sì máa gbé àwọn tí wọ́n kà sí èèyàn lásán ga, torí wọ́n gbà pé ó yẹ káwọn máa wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé ìyípadà pàtàkì yẹn máa tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó sọ pé:
“Òfin àti àwọn Wòlíì wà títí dìgbà Jòhánù. Látìgbà yẹn lọ, à ń kéde Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere, onírúurú èèyàn sì ń fi agbára lépa rẹ̀. Ní tòótọ́, ó rọrùn kí ọ̀run àti ayé kọjá lọ ju kí ìlà kan lára lẹ́tà inú Òfin lọ láìṣẹ.” (Lúùkù 3:18; 16:16, 17) Báwo lohun tí Jésù sọ yìí ṣe fi hàn pé nǹkan máa tó yí pa dà lóòótọ́?
Ó dá àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù lójú pé tọkàntọkàn làwọn fi ń tẹ̀ lé Òfin Mósè. Ẹ rántí pé nígbà tí Jésù la ojú ọkùnrin kan ní Jerúsálẹ́mù, ṣe làwọn Farisí tó wà níbẹ̀ fi gbogbo ẹnu sọ pé: “Ọmọ ẹ̀yìn Mósè ni àwa. A mọ̀ pé Ọlọ́run bá Mósè sọ̀rọ̀.” (Jòhánù 9:13, 28, 29) Ọ̀kan lára ìdí tí Ọlọ́run fi fún Mósè ní Òfin ni pé ó fẹ́ kí Òfin náà darí àwọn èèyàn lọ sọ́dọ̀ Mèsáyà, ìyẹn Jésù. Jòhánù Arinibọmi sì pe Jésù ní Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run. (Jòhánù 1:29-34) Torí náà, àtìgbà tí Jòhánù ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ làwọn Júù tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ní pàtàkì àwọn aláìní ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa “Ìjọba Ọlọ́run.” Ká sòótọ́, “ìhìn rere” wà fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ wà nínú Ìjọba Ọlọ́run, kí wọ́n sì jàǹfààní Ìjọba náà.
Kì í ṣe pé Òfin Mósè ò wúlò, ó ṣe tán òun ló jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa Mèsáyà. Àmọ́ ní báyìí, kò pọn dandan fún wọn láti pa Òfin yẹn mọ́. Bí àpẹẹrẹ, Òfin fàyè gbà á kí ẹnì kan kọ aya tàbí ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ lórí ẹ̀sùn èyíkéyìí, àmọ́ Jésù ṣàlàyé pé “gbogbo ẹni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, tó sì fẹ́ ẹlòmíì ti ṣe àgbèrè, ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ obìnrin tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀ ti ṣe àgbèrè.” (Lúùkù 16:18) Ẹ wo bíyẹn ṣe máa múnú bí àwọn Farisí tí wọ́n ní onírúurú òfin tí ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ fún gbogbo ohun táwọn èèyàn ń ṣe!
Jésù wá fi àpèjúwe kan ṣàlàyé bí ìyípadà náà ṣe máa lágbára tó. Nínú àpèjúwe yìí, ó mẹ́nu ba àwọn ọkùnrin méjì tí ipò wọn yí pa dà bìrí. Bí Jésù ṣe ń sọ àpèjúwe yìí, ẹ fi sọ́kàn pé àwọn Farisí tó nífẹ̀ẹ́ owó táwọn èèyàn sì ń gbé ga wà lára àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀.
Jésù sọ pé: “Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà tó máa ń wọ aṣọ aláwọ̀ pọ́pù àti aṣọ ọ̀gbọ̀, ojoojúmọ́ ló ń gbádùn ara rẹ̀ dọ́ba. Àmọ́ wọ́n máa ń gbé alágbe kan tó ń jẹ́ Lásárù sí ẹnubodè rẹ̀, egbò wà ní gbogbo ara rẹ̀, ó sì máa ń wù ú pé kó jẹ lára àwọn nǹkan tó ń já bọ́ látorí tábìlì ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà. Àní àwọn ajá pàápàá máa ń wá pọ́n àwọn egbò rẹ̀ lá.”—Lúùkù 16:19-21.
Àwọn Farisí nífẹ̀ẹ́ owó gan-an, torí náà kò nira láti mọ ẹni tí “ọkùnrin ọlọ́rọ̀” inú àpèjúwe yìí dúró fún. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù fẹ́ràn láti máa wọ aṣọ olówó ńlá tó sì jojú ní gbèsè. Yàtọ̀ síyẹn, ojú ọlọ́rọ̀ làwọn èèyàn fi ń wò wọ́n torí àǹfààní tí wọ́n ní àti ipò tí wọ́n wà. Ṣe ló bá a mu wẹ́kú bí Jésù ṣe sọ pé wọ́n wọ aṣọ aláwọ̀ pọ́pù, torí ìyẹn jẹ́ ká rí i pé ẹni ńlá làwọn èèyàn kà wọ́n sí, bó sì ṣe sọ pé wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun fi hàn pé wọ́n jẹ́ olódodo lójú ara wọn.—Dáníẹ́lì 5:7.
Ojú wo làwọn agbéraga aṣáájú ẹ̀sìn tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ yìí fi ń wo àwọn tálákà tí wọ́n kà sí èèyàn lásán? Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn kórìíra wọn débi pé wọ́n máa ń pè wọ́n ní ‛am ha·’aʹrets, tó túmọ̀ sí “àwọn ẹni ilẹ̀.” Wọ́n gbà pé àwọn èèyàn náà ò mọ Òfin, kò sì yẹ kéèyàn kọ́ wọn nípa ẹ̀. (Jòhánù 7:49) Ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn yẹn dà bíi ti “alágbe kan tó ń jẹ́ Lásárù,” tí ebi pa débi pé ó máa ń wù ú pé kó jẹ lára “àwọn nǹkan tó ń já bọ́ látorí tábìlì ọkùnrin ọlọ́rọ̀” yẹn. Bíi ti Lásárù tí egbò wà ní gbogbo ara rẹ̀, ojú ẹni tí kò wúlò làwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn fi ń wo àwọn èèyàn bíi pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run.
Ọjọ́ pẹ́ táwọn aṣáájú ìsìn ti ń hùwà burúkú yẹn, àmọ́ Jésù mọ̀ pé àkókó ti tó kí nǹkan yí pa dà fún àwọn tó dà bí ọlọ́rọ̀ yẹn àtàwọn tó dà bíi ti Lásárù.
ÀYÍPADÀ DÉ BÁ ỌKÙNRIN ỌLỌ́RỌ̀ NÁÀ ÀTI LÁSÁRÙ
Jésù ṣàlàyé bí nǹkan ṣe yí pa dà bìrí fún àwọn méjèèjì. Ó sọ pé: “Nígbà tó yá, alágbe náà kú, àwọn áńgẹ́lì sì gbé e lọ sí ẹ̀gbẹ́ Ábúráhámù. Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn náà kú, wọ́n sì sin ín. Ó gbé ojú rẹ̀ sókè nínú Isà Òkú, ó ń joró, ó wá rí Ábúráhámù ní ọ̀ọ́kán, ó sì rí Lásárù ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.”—Lúùkù 16:22, 23.
Àwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù mọ̀ pé ó ti pẹ́ tí Ábúráhámù ti kú, wọ́n sì mọ̀ pé inú Isà Òkú ló wà. Ìwé Mímọ́ jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn tó wà nínú Isà Òkú tàbí Ṣìọ́ọ̀lù ò lè sọ̀rọ̀, wọn ò sì lè rí ohunkóhun, bọ́rọ̀ sì ṣe rí nípa Ábúráhámù nìyẹn. (Oníwàásù 9:5, 10) Kí wá làwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn máa rò nípa àpèjúwe yìí? Àlàyé wo ni Jésù fẹ́ fi àpèjúwe yìí ṣe nípa àwọn èèyàn àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ owó yẹn?
Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàlàyé ohun kan tó yí pa dà fún wọn ni, ìyẹn nígbà tó sọ pé, ‘Òfin àti àwọn Wòlíì wà títí dìgbà Jòhánù Arinibọmi, àmọ́ àtìgbà yẹn lọ la ti ń kéde Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere.’ Èyí fi hàn pé ìwàásù tí Jòhánù àti Jésù Kristi ṣe ló mú kí ipò tí Lásárù àti ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn wà tẹ́lẹ̀ yí pa dà lójú Ọlọ́run.
Ká sòótọ́, ọjọ́ pẹ́ tí wọn ò ti jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ tí wọ́n kà sí tálákà yẹn lóye ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́ bí Jòhánù Arinibọmi ṣe kọ́kọ́ wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run, tí Jésù náà sì ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, àwọn èèyàn yẹn tẹ́wọ́ gbà á, ìyẹn sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Ṣáájú ìgbà yẹn, ìwọ̀nba ẹ̀kọ́ tó dà bí ‘nǹkan tó já bọ́ látorí tábìlì’ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn làwọn èèyàn náà gbára lé. Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ti ń mọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́, ní pàtàkì àwọn ohun àgbàyanu tí Jésù ń ṣàlàyé fún wọn. Ṣe ló dà bíi pé wọ́n ti wá rí ojúure Jèhófà Ọlọ́run.
Ọ̀rọ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ yẹn ò rí bẹ́ẹ̀ ní tiwọn, wọn ò fetí sí ìwàásù Jòhánù, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò tẹ́wọ́ gba ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù ń kéde ní gbogbo ilẹ̀ náà. (Mátíù 3:1, 2; 4:17) Kódà, ṣe ni inú ń bí wọn tó sì dà bíi pé wọ́n ń joró nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa ìdájọ́ Ọlọ́run tó ń bọ̀ lórí wọn. (Mátíù 3:7-12) Torí náà, tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bá dá ìkéde yìí dúró, ara máa tu àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó nífẹ̀ẹ́ owó yẹn. Ṣe lọ̀rọ̀ wọn dà bíi ti ọkùnrin ọlọ́rọ̀ inú àpèjúwe yẹn tó sọ pé: “Ábúráhámù baba, ṣàánú mi, kí o sì rán Lásárù pé kó ki orí ìka rẹ̀ bọ omi, kó sì mú kí ahọ́n mi tutù, torí mò ń jẹ̀rora nínú iná tó ń jó yìí.”—Lúùkù 16:24.
Àmọ́ ìyẹn ò ní jẹ́ ṣẹlẹ̀ láé, torí ọ̀pọ̀ lára àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn ò lè yí pa dà. Wọn ò “fetí sí Mósè àti àwọn Wòlíì,” bẹ́ẹ̀ sì rèé ohun táwọn Wòlíì yẹn sọ ì bá ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbà pé Jésù ni Mèsáyà àti Ọba tí Ọlọ́run yàn. (Lúùkù 16:29, 31; Gálátíà 3:24) Bákan náà, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn ò lè rẹ ara wọn sílẹ̀ bíi tàwọn tálákà tó nígbàgbọ́ nínú Jésù, tíyẹn sì ti mú kí wọ́n rí ojúure Ọlọ́run. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ò sì ní yí ìwàásù wọn pa dà láé tàbí bomi la ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n lè tẹ́ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó ń jẹ̀rora yẹn lọ́rùn. Jésù wá ṣàlàyé òótọ́ yìí lọ́nà tó ṣe tààràtà pẹ̀lú ohun tí “Ábúráhámù baba” sọ fún ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn:
“Ọmọ, rántí pé ìwọ gbádùn ohun rere dáadáa nígbà ayé rẹ, àmọ́ ohun burúkú ni Lásárù gbà ní tiẹ̀. Ní báyìí, ó ń gba ìtura níbí, àmọ́ ìwọ ń jẹ̀rora. Yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan yìí, a ti mú kí ọ̀gbun ńlá kan wà láàárín àwa àti ẹ̀yin, kí àwọn tó fẹ́ lọ sọ́dọ̀ yín láti ibí má bàa kọjá, kí àwọn èèyàn má sì kọjá láti ibẹ̀ yẹn sọ́dọ̀ wa.”—Lúùkù 16:25, 26.
Ẹ wo bí àyípadà yẹn ṣe bọ́gbọ́n mu tó, tíyẹn sì jẹ́ ká rí i pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà! Ó jẹ́ ká rí bí nǹkan ṣe yí pa dà fáwọn aṣáájú ẹ̀sìn agbéraga yẹn àti bí nǹkan ṣe yí pa dà fáwọn onírẹ̀lẹ̀ torí wọ́n rí ìtura lẹ́yìn tí wọ́n gba àjàgà Jésù, tí wọ́n sì gba ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. (Mátíù 11:28-30) Àyípadà yìí máa hàn kedere ní oṣù mélòó kan sígbà yẹn tí Ọlọ́run bá fi májẹ̀mú tuntun rọ́pò Májẹ̀mú Òfin. (Jeremáyà 31:31-33; Kólósè 2:14; Hébérù 8:7-13) Nígbà tí Ọlọ́run bá tú ẹ̀mí mímọ́ jáde ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 S.K., ó máa túbọ̀ ṣe kedere sàwọn èèyàn pé Ọlọ́run ti kọ àwọn Farisí àtàwọn aṣáájú ìsìn tó kù sílẹ̀, ó sì ti fi ojúure hàn sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù.