ORÍ 89
Ó Ń Kọ́ni ní Pèríà Bó Ṣe Ń Lọ sí Jùdíà
EWU TÓ WÀ NÍNÚ MÍMÚ ÀWỌN MÍÌ KỌSẸ̀
MÁA DÁRÍ JINI, KÓ O SÌ NÍGBÀGBỌ́
Jésù ti lo ọjọ́ bíi mélòó kan ní agbègbè kan tí wọ́n ń pè ní Pèríà tó wà ní “òdìkejì Jọ́dánì.” (Jòhánù 10:40) Àmọ́ ní báyìí ó ń rìnrìn àjò lọ sí apá gúúsù, ìyẹn sítòsí Jerúsálẹ́mù.
Jésù nìkan kọ́ ló ń rìnrìn àjò náà. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, títí kan àwọn “èrò rẹpẹtẹ,” àwọn agbowó orí àtàwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. (Lúùkù 14:25; 15:1) Àwọn Farisí àtàwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n ń ṣàríwísí ẹ̀kọ́ Jésù àtohun tó ń ṣe náà wà níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà lọ́kàn wọn lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ àpèjúwe tí Jésù sọ nípa àgùntàn tó sọ nù, ọmọ tó sọ nù àti àpèjúwe ọkùnrin ọlọ́rọ̀ àti Lásárù.—Lúùkù 15:2; 16:14.
Nígbà tí Jésù rántí báwọn alátakò yẹn ṣe ń rí sí òun àti bí wọ́n ṣe ń fi òun ṣe yẹ̀yẹ́, ó yíjú sáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó wá sọ nǹkan kan tó ti sọ fún wọn tẹ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n wà ní Gálílì.
Jésù sọ pé: “Kò sí bí àwọn ohun tó ń fa ìkọ̀sẹ̀ ò ṣe ní wá. Àmọ́, ẹni tí wọ́n tipasẹ̀ rẹ̀ wá gbé! . . . Ẹ kíyè sí ara yín. Tí arákùnrin rẹ bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, bá a wí, tó bá sì ronú pìwà dà, dárí jì í. Kódà, tó bá ṣẹ̀ ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́, tó sì pa dà wá bá ọ ní ìgbà méje, tó ń sọ pé, ‘Mo ti ronú pìwà dà,’ o gbọ́dọ̀ dárí jì í.” (Lúùkù 17:1-4) Ó ṣeé ṣe kí ohun tí Jésù sọ yìí rán Pétérù létí ìbéèrè tó béèrè nípa kéèyàn dárí jini nígbà méje.—Mátíù 18:21.
Àmọ́, ṣé ó máa rọrùn fáwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn láti ṣe ohun tí Jésù sọ yìí? Wọ́n bi í pé, “Fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i,” Jésù wá jẹ́ kó dá wọn lójú pé: “Tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ tó rí bíi hóró músítádì, ẹ máa sọ fún igi mọ́líbẹ́rì dúdú yìí pé, ‘Fà tu, kí o sì lọ fìdí sọlẹ̀ sínú òkun!’ ó sì máa gbọ́ tiyín.” (Lúùkù 17:5, 6) Ká sòótọ́, tá a bá nígbàgbọ́, a máa lè ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan.
Jésù tún jẹ́ káwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kí wọ́n sì ní èrò tó tọ́ nípa ara wọn nígbà tó sọ fún wọn pé: “Èwo nínú yín, tó ní ẹrú kan tó ń túlẹ̀ tàbí tó ń tọ́jú agbo ẹran, ló máa sọ fún un tó bá dé láti oko pé, ‘Máa bọ̀ níbí kíá, kí o sì wá jẹun lórí tábìlì’? Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣebí ó máa sọ fún un pé, ‘Ṣètò nǹkan fún mi kí n lè jẹ oúnjẹ alẹ́, gbé épírọ́ọ̀nù kan wọ̀, kí o sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi títí màá fi parí jíjẹ àti mímu, lẹ́yìn náà o wá lè jẹ, kí o sì mu’? Kò ní dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹrú náà, torí pé iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un ló ṣe, àbí ó máa ṣe bẹ́ẹ̀? Bákan náà, tí ẹ bá ti ṣe gbogbo ohun tí a yàn fún yín, kí ẹ sọ pé: ‘Ẹrú tí kò dáa fún ohunkóhun ni wá. Ohun tó yẹ ká ṣe ni a ṣe.’”—Lúùkù 17:7-10.
Gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run ló yẹ kó lóye ìdí tó fi ṣe pàtàkì kéèyàn máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́. Bákan náà, ó yẹ kí wọ́n máa rántí àǹfààní tí wọ́n ní láti máa sin Ọlọ́run àti pé wọ́n jẹ́ apá kan ìdílé rẹ̀.
Ó jọ pé àárín àsìkò yìí ni ẹni tí Màríà àti Màtá rán sí Jésù dé. Arábìnrin Lásárù làwọn méjèèjì, ìlú Bẹ́tánì tó wà ní Jùdíà ni wọ́n sì ń gbé. Ìránṣẹ́ náà sọ pé: “Olúwa, wò ó! ẹni tí o nífẹ̀ẹ́ gan-an ń ṣàìsàn.”—Jòhánù 11:1-3.
Lóòótọ́, Jésù ti gbọ́ pé Lásárù ọ̀rẹ́ òun ń ṣàìsàn tó le gan-an, àmọ́ kò jẹ́ kíyẹn kó ẹ̀dùn ọkàn bá òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Ikú kọ́ ló máa gbẹ̀yìn àìsàn yìí, àmọ́ ó jẹ́ fún ògo Ọlọ́run, ká lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.” Ó wá dúró síbi tó wà fún ọjọ́ méjì, lẹ́yìn náà ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ ká tún lọ sí Jùdíà.” Àmọ́ wọ́n sọ fún un pé: “Rábì, ẹnu àìpẹ́ yìí ni àwọn ará Jùdíà fẹ́ sọ ọ́ lókùúta, ṣé o tún fẹ́ lọ síbẹ̀ ni?”—Jòhánù 11:4, 7, 8.
Jésù wá dá wọn lóhùn pé: “Wákàtí méjìlá (12) ló wà ní ojúmọmọ, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Tí ẹnikẹ́ni bá ń rìn ní ojúmọmọ, kì í kọ lu ohunkóhun, torí ó ń rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí. Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá ń rìn ní òru, ó máa kọsẹ̀, torí ìmọ́lẹ̀ kò sí nínú rẹ̀.” (Jòhánù 11:9, 10) Ohun tí Jésù ń sọ ni pé àkókò tí Ọlọ́run yàn kalẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun lórí ilẹ̀ ayé kò tíì pé. Torí náà títí dìgbà tó máa pé, Jésù máa lo ìwọ̀nba àkókò tó ṣẹ́ kù lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.
Jésù wá sọ pé: “Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti sùn, àmọ́ mò ń rìnrìn àjò lọ síbẹ̀ kí n lè jí i.” Torí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà rò pé ṣe ni Lásárù wulẹ̀ ń sùn, wọ́n sọ pé: “Olúwa, tó bá jẹ́ pé ó ń sùn ni, ara rẹ̀ máa yá.” Ni Jésù bá sọ fún wọn ní tààràtà pé: “Lásárù ti kú . . . Àmọ́ ẹ jẹ́ ká lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.”—Jòhánù 11:11-15.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Tọ́másì mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n pa Jésù ní Jùdíà, síbẹ̀ ó wù ú pé kó dúró ti Jésù. Torí náà ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù pé: “Ẹ jẹ́ kí àwa náà lọ, ká lè bá a kú.”—Jòhánù 11:16.