Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì
9 Àmọ́ Sọ́ọ̀lù, tí inú rẹ̀ ṣì ń ru, tó sì ń fikú halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Olúwa,+ lọ bá àlùfáà àgbà, 2 ó sì ní kí ó fún òun ní àwọn lẹ́tà sí àwọn sínágọ́gù ní Damásíkù, kí ó lè mú ẹnikẹ́ni tó bá rí tí ó jẹ́ ti Ọ̀nà Náà+ wá sí Jerúsálẹ́mù ní dídè, àti ọkùnrin àti obìnrin.
3 Bí ó ṣe ń rin ìrìn àjò lọ, tó sì ń sún mọ́ Damásíkù, lójijì, ìmọ́lẹ̀ kan láti ọ̀run kọ mànà yí i ká,+ 4 ó ṣubú lulẹ̀, ó sì gbọ́ tí ohùn kan sọ fún un pé: “Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, kí nìdí tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi?” 5 Ó béèrè pé: “Ta ni ọ́, Olúwa?” Ó sọ pé: “Èmi ni Jésù,+ ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí.+ 6 Ní báyìí, dìde, kí o sì wọnú ìlú, wọ́n á sọ ohun tí o máa ṣe fún ọ.” 7 Àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ ń rin ìrìn àjò dúró, wọn ò lè sọ̀rọ̀, ní tòótọ́, wọ́n ń gbọ́ ìró, àmọ́ wọn ò rí ẹnì kankan.+ 8 Sọ́ọ̀lù wá dìde nílẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojú rẹ̀ là sílẹ̀, kò rí nǹkan kan. Torí náà, wọ́n dì í lọ́wọ́ mú, wọ́n sì mú un wọ Damásíkù. 9 Ọjọ́ mẹ́ta ni kò fi rí nǹkan kan,+ kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu.
10 Ọmọ ẹ̀yìn kan wà ní Damásíkù tó ń jẹ́ Ananáyà,+ Olúwa sọ fún un nínú ìran pé: “Ananáyà!” Ó sọ pé: “Èmi nìyí, Olúwa.” 11 Olúwa sọ fún un pé: “Dìde, lọ sí ojú ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní Títọ́, kí o sì wá ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù láti Tásù+ ní ilé Júdásì. Wò ó! ó ń gbàdúrà, 12 àti pé nínú ìran, ó ti rí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ananáyà tí ó wọlé wá, tí ó sì gbé ọwọ́ lé e kí ó lè tún máa ríran.”+ 13 Àmọ́ Ananáyà dáhùn pé: “Olúwa, mo ti gbọ́ nípa ọkùnrin yìí lẹ́nu ọ̀pọ̀ èèyàn, mo ti gbọ́ gbogbo jàǹbá tó ṣe sí àwọn ẹni mímọ́ rẹ ní Jerúsálẹ́mù. 14 Ní báyìí, ó ti gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn olórí àlùfáà láti mú* gbogbo àwọn tó ń ké pe orúkọ rẹ.”+ 15 Àmọ́ Olúwa sọ fún un pé: “Lọ! nítorí ohun èlò tí a ti yàn ni ọkùnrin yìí jẹ́ fún mi+ láti mú orúkọ mi lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè+ àti àwọn ọba+ àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 16 Nítorí màá fi hàn án ní kedere bí ìyà tó máa jẹ nítorí orúkọ mi ṣe máa pọ̀ tó.”+
17 Nítorí náà, Ananáyà lọ, ó sì wọ ilé náà, ó gbé ọwọ́ lé e, ó sì sọ pé: “Sọ́ọ̀lù, arákùnrin, Jésù Olúwa tó fara hàn ọ́ lójú ọ̀nà tí ò ń gbà bọ̀ ló rán mi kí o lè tún máa ríran, kí o sì kún fún ẹ̀mí mímọ́.”+ 18 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ohun tó rí bí ìpẹ́ já bọ́ láti ojú rẹ̀, ó sì tún ríran. Lẹ́yìn náà, ó dìde, ó sì ṣèrìbọmi, 19 ó jẹun, ó sì lókun.
Ó lo ọjọ́ mélòó kan pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Damásíkù,+ 20 lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nípa Jésù nínú àwọn sínágọ́gù, pé ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run. 21 Àmọ́ ẹnu ya gbogbo àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń sọ pé: “Ọkùnrin yìí kọ́ ló ń kó àwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n ń ké pe orúkọ yìí ni?+ Ṣé kì í ṣe torí kó lè fàṣẹ mú wọn, kó sì mú wọn* lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà ló ṣe wá síbí ni?”+ 22 Àmọ́ Sọ́ọ̀lù ń gba agbára kún agbára, ó sì ń pa àwọn Júù tó ń gbé ní Damásíkù lẹ́nu mọ́, bí ó ṣe ń fi ẹ̀rí tó bọ́gbọ́n mu hàn pé Jésù ni Kristi náà.+
23 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọjọ́, àwọn Júù gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.+ 24 Àmọ́, Sọ́ọ̀lù gbọ́ nípa ohun tí wọ́n ń gbèrò sí òun. Kódà, tọ̀sántòru ni wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹnubodè lójú méjèèjì, kí wọ́n lè pa á. 25 Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbé e, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ gba ojú ihò kan lára ògiri lóru, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ nínú apẹ̀rẹ̀.+
26 Nígbà tó dé Jerúsálẹ́mù,+ ó sapá láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àmọ́ gbogbo wọn ń bẹ̀rù rẹ̀, torí wọn ò gbà gbọ́ pé ọmọ ẹ̀yìn ni. 27 Nítorí náà, Bánábà+ ràn án lọ́wọ́, ó mú un lọ bá àwọn àpọ́sítélì, ó sì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí ó ṣe rí Olúwa ní ojú ọ̀nà+ fún wọn àti pé Olúwa bá a sọ̀rọ̀. Ó tún sọ bó ṣe fìgboyà sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Jésù ní Damásíkù.+ 28 Nítorí náà, ó dúró tì wọ́n, ó sì ń rìn fàlàlà* ní Jerúsálẹ́mù, ó ń fìgboyà sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Olúwa. 29 Ó ń sọ̀rọ̀, ó sì ń bá àwọn Júù tó ń sọ èdè Gíríìkì fa ọ̀rọ̀, àmọ́ àwọn yìí gbìyànjú láti pa á.+ 30 Nígbà tí àwọn ará gbọ́ nípa èyí, wọ́n mú un wá sí Kesaríà, wọ́n sì rán an lọ sí Tásù.+
31 Ní tòótọ́, nígbà náà, ìjọ tó wà jákèjádò Jùdíà àti Gálílì àti Samáríà+ wọnú àkókò àlàáfíà, à ń gbé e ró; ó ń gbèrú sí i bó ṣe ń rìn nínú ìbẹ̀rù Jèhófà* àti nínú ìtùnú ẹ̀mí mímọ́.+
32 Bí Pétérù ṣe ń rìnrìn àjò gba gbogbo agbègbè yẹn kọjá, ó wá sọ́dọ̀ àwọn ẹni mímọ́ tó ń gbé ní Lídà.+ 33 Ó rí ọkùnrin kan níbẹ̀ tó ń jẹ́ Énéà, ọdún mẹ́jọ ló ti wà ní ìdùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, torí pé ó ní àrùn rọpárọsẹ̀. 34 Pétérù sọ fún un pé: “Énéà, Jésù Kristi mú ọ lára dá.+ Dìde, kí o sì tẹ́ ibùsùn rẹ.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó dìde. 35 Nígbà tí gbogbo àwọn tó ń gbé ní Lídà àti Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣárónì rí i, wọ́n yíjú sọ́dọ̀ Olúwa.
36 Ọmọ ẹ̀yìn kan wà ní Jópà tó ń jẹ́ Tàbítà, èyí tó túmọ̀ sí “Dọ́káàsì,”* tí a bá túmọ̀ rẹ̀. Àwọn iṣẹ́ rere àti ọrẹ àánú tó ń fúnni pọ̀ gidigidi. 37 Àmọ́ lákòókò yẹn, ó ṣàìsàn, ó sì kú. Torí náà, wọ́n wẹ̀ ẹ́, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí yàrá òkè. 38 Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn gbọ́ pé Pétérù wà ní Lídà, torí pé Lídà ò jìnnà sí Jópà, wọ́n rán ọkùnrin méjì lọ bá a láti pàrọwà fún un pé: “Jọ̀wọ́ tètè máa bọ̀ lọ́dọ̀ wa.” 39 Ni Pétérù bá dìde, ó sì bá wọn lọ. Nígbà tó débẹ̀, wọ́n mú un lọ sí yàrá òkè; gbogbo àwọn opó sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń sunkún, wọ́n sì ń fi ọ̀pọ̀ aṣọ àti ẹ̀wù* tí Dọ́káàsì ti ṣe nígbà tó wà lọ́dọ̀ wọn hàn án. 40 Pétérù wá ní kí gbogbo èèyàn bọ́ síta,+ ó kúnlẹ̀, ó sì gbàdúrà. Lẹ́yìn náà, ó yíjú sí òkú náà, ó sọ pé: “Tàbítà, dìde!” Obìnrin náà lajú, bó ṣe tajú kán rí Pétérù, ó dìde jókòó.+ 41 Pétérù na ọwọ́ sí i, ó gbé e dìde, ó sì pe àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn opó, ó wá fà á lé wọn lọ́wọ́ láàyè.+ 42 Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí tàn káàkiri Jópà, ọ̀pọ̀ èèyàn sì di onígbàgbọ́ nínú Olúwa.+ 43 Ó lo ọjọ́ mélòó kan sí i ní Jópà lọ́dọ̀ oníṣẹ́ awọ kan tó ń jẹ́ Símónì.+