ORIN 133
Sin Jèhófà Nígbà Ọ̀dọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà fẹ́ràn àwa ọ̀dọ́ gan-an.
Tọkàntọkàn sì la fi ń jọ́sìn rẹ̀.
Ó dájú pé ó ń fiyè síṣẹ́ wa,
Yóò sì bù kún wa jálẹ̀ ayé wa.
2. Àwa ọ̀dọ́ ń bọ̀wọ̀ fún òbí wa,
A sì ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an.
Èyí ń jẹ́ kí inú wọn dùn sí wa,
A sì túbọ̀ ń sún mọ́ Jáà, Ọ̀rẹ́ wa.
3. Káwa ọ̀dọ́ rántí Ọlọ́run wa.
Kí òtítọ́ máa jinlẹ̀ lọ́kàn wa.
Tá a bá fi ayé wa sin Jèhófà,
Inú rẹ̀ yóò dùn, yóò sì bù kún wa.
(Tún wo Sm. 71:17; Ìdárò 3:27; Éfé. 6:1-3.)