Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì
1 Tìófílọ́sì, nínú ìwé àkọ́kọ́ tí mo kọ sí ọ, mo sọ nípa gbogbo ohun tí Jésù ṣe àti ohun tí ó kọ́ni+ 2 títí di ọjọ́ tí Ọlọ́run gbé e lọ sókè,+ lẹ́yìn tó ti tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ sọ ohun tí àwọn àpọ́sítélì tó ti yàn máa ṣe.+ 3 Lẹ́yìn tó ti jìyà, ó fara hàn wọ́n láàyè nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó dájú.+ Wọ́n rí i jálẹ̀ ogójì (40) ọjọ́, ó sì ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run.+ 4 Nígbà tó ń bá wọn ṣèpàdé, ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe kúrò ní Jerúsálẹ́mù,+ àmọ́ ẹ dúró de ohun tí Baba ti ṣèlérí,+ èyí tí ẹ gbọ́ lẹ́nu mi; 5 lóòótọ́, Jòhánù fi omi batisí, àmọ́ a ó fi ẹ̀mí mímọ́ batisí yín+ láìpẹ́ ọjọ́.”
6 Nígbà tí wọ́n pé jọ, wọ́n bi í pé: “Olúwa, ṣé àkókò yìí lo máa dá ìjọba pa dà fún Ísírẹ́lì?”+ 7 Ó sọ fún wọn pé: “Kì í ṣe tiyín láti mọ ìgbà tàbí àsìkò tí Baba ti fi sí ìkáwọ́* rẹ̀.+ 8 Àmọ́, ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín,+ ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí+ mi ní Jerúsálẹ́mù,+ ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà+ àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.”*+ 9 Lẹ́yìn tó ti sọ àwọn nǹkan yìí, bí wọ́n ṣe ń wò ó, a gbé e sókè, àwọsánmà sì gbà á lọ mọ́ wọn lójú.+ 10 Bí wọ́n ṣe tẹjú mọ́ sánmà nígbà tó ń lọ, lójijì ọkùnrin méjì tó wọ aṣọ funfun+ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, 11 wọ́n sì sọ pé: “Ẹ̀yin èèyàn Gálílì, kí ló dé tí ẹ dúró tí ẹ̀ ń wojú sánmà? Jésù yìí tí a gbà sókè kúrò lọ́dọ̀ yín sínú sánmà yóò wá ní irú ọ̀nà kan náà bí ẹ ṣe rí i tó ń lọ sínú sánmà.”
12 Lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù+ láti òkè tí wọ́n ń pè ní Òkè Ólífì, tó wà nítòsí Jerúsálẹ́mù, ó tó ìrìn ọjọ́ sábáàtì kan. 13 Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n lọ sínú yàrá òkè tí wọ́n ń gbé. Àwọn ni: Pétérù pẹ̀lú Jòhánù àti Jémíìsì àti Áńdérù, Fílípì àti Tọ́másì, Batolómíù àti Mátíù, Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì àti Símónì onítara pẹ̀lú Júdásì ọmọ Jémíìsì.+ 14 Gbogbo wọn tẹra mọ́ àdúrà pẹ̀lú èrò tó ṣọ̀kan, àwọn àti àwọn obìnrin kan+ pẹ̀lú Màríà ìyá Jésù àti àwọn arákùnrin rẹ̀.+
15 Lásìkò yẹn, Pétérù dìde láàárín àwọn ará, (iye àwọn èèyàn* náà lápapọ̀ jẹ́ nǹkan bí ọgọ́fà [120]) ó sì sọ pé: 16 “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, ó pọn dandan kí ìwé mímọ́ ṣẹ, èyí tí ẹ̀mí mímọ́ gba ẹnu Dáfídì sọ nípa Júdásì,+ ẹni tó ṣamọ̀nà àwọn tó wá mú Jésù.+ 17 Nítorí a ti kà á mọ́ wa,+ ó sì ní ìpín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí. 18 (Ọkùnrin yìí fi owó iṣẹ́ ibi+ rẹ̀ ra ilẹ̀ kan, àmọ́, ó fi orí sọlẹ̀, ikùn rẹ̀ bẹ́,* gbogbo ìfun rẹ̀ sì tú síta.+ 19 Gbogbo àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì pe ilẹ̀ náà ní Ákélídámà ní èdè wọn, ìyẹn, “Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀.”) 20 Nítorí ó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Sáàmù pé, ‘Kí ibi tó ń gbé di ahoro, kí ó má ṣe sí ẹnì kankan tí á máa gbé inú rẹ̀’+ àti pé, ‘Kí ẹlòmíì gba iṣẹ́ àbójútó rẹ̀.’+ 21 Nítorí náà, ó pọn dandan pé nínú àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú wa ní gbogbo àkókò tí Jésù Olúwa fi ṣe iṣẹ́ rẹ̀* láàárín wa, 22 látìgbà tí Jòhánù ti ṣèrìbọmi fún un+ títí di ọjọ́ tí a gbé e sókè kúrò lọ́dọ̀ wa,+ kí ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin yìí di ẹlẹ́rìí àjíǹde rẹ̀ pẹ̀lú wa.”+
23 Nítorí náà, wọ́n dábàá àwọn méjì, Jósẹ́fù tí wọ́n ń pè ní Básábà, tí wọ́n tún ń pè ní Jọ́sítù àti ẹnì kejì, Màtáyásì. 24 Wọ́n wá gbàdúrà, wọ́n sì sọ pé: “Jèhófà,* ìwọ ẹni tó mọ ọkàn gbogbo èèyàn,+ fi ẹni tí o yàn lára àwọn ọkùnrin méjì yìí hàn, 25 tó máa gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti iṣẹ́ àpọ́sítélì yìí, tí Júdásì gbé sílẹ̀ kí ó lè lọ ṣe tirẹ̀.”+ 26 Nítorí náà, wọ́n ṣẹ́ kèké lé wọn,+ kèké sì mú Màtáyásì, a sì kà á mọ́* àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá (11).