Ẹ Maa Lepa Iṣeun-ifẹ Nigba Gbogbo
“Ẹni ti nlepa ododo ati iṣeun-ifẹ yoo ri iye, ododo ati ogo.”—OWE 21:21, NW.
1. Eeṣe ti a fi nilati reti awọn wọnni ti a dari nipasẹ ẹmi Ọlọrun lati fi inurere han?
JEHOFA jẹ oninuure ati oniyọnu. Oun jẹ “Ọlọrun alaanu ati oloore ọfẹ, onipamọra ati ẹni ti o pọ ni oore [“iṣeun-ifẹ,” NW] ati otitọ.” (Ẹkisodu 34:6, 7) O yeni, nigba naa, pe awọn eso ẹmi mimọ rẹ ni ifẹ ati inurere ninu.—Galatia 5:22, 23.
2. Awọn apẹẹrẹ wo ni awa yoo gbé yẹwo nisinsinyi?
2 Awọn wọnni ti a dari nipasẹ ẹmi mimọ tabi ipá agbékánkán ṣiṣẹ ti Jehofa, maa nfi eso rẹ̀ ti inurere han. Wọn fi iṣeun-ifẹ han ninu ibatan wọn pẹlu awọn ẹlomiran. Nitootọ, wọn tẹle apẹẹrẹ apọsiteli Pọọlu, ni didamọran araawọn gẹgẹ bi ojiṣẹ Ọlọrun “nipa inurere” ati ni awọn ọna miiran. (2 Kọrinti 6:3-10) Ẹmi oninuure, agbatẹniro, adarijini wọn baramu pẹlu animọ-iwa Jehofa, ẹni ti o “pọ ni iṣeun-ifẹ” ti Ọrọ rẹ si ni ọpọlọpọ apẹẹrẹ inurere ninu. (Saamu 86:15, NW; Efesu 4:32) Ki ni a le kẹkọọ lati inu diẹ lara iwọnyi?
Inurere Mu Wa Jẹ Alaimọtara Ẹni Nikan ati Ẹlẹmii Alejo Ṣiṣe
3. Ọna wo ni Aburahamu gba jẹ awofiṣapẹẹrẹ ninu fifi inurere han, iṣiri wo si ni Pọọlu fifunni ni isopọ pẹlu eyi?
3 Babanla igbaani naa Aburahamu (Aburamu)—“ọrẹ Jehofa” ati “baba gbogbo awọn wọnni ti wọn ní igbagbọ”—gbe apẹẹrẹ rere kalẹ ninu fifi inurere han. (Jakọbu 2:23; Roomu 4:11, NW) Oun ati idile rẹ, ati pẹlu ọmọkunrin arakunrin rẹ Lọti, fi ilu Uri ti Kalidea silẹ wọn sì wọnu Kenani labẹ aṣẹ Ọlọrun. Bi o tilẹ jẹ pe Aburahamu ni ọkunrin ti o dagba ju ati olori idile naa, oun jẹ oninuure ati alaimọtara ẹni nikan ni jijẹ ki Lọti mu awọn ilẹ koriko ti o dara julọ, nigba ti oun funraarẹ mu eyi ti o ṣẹku. (Jẹnẹsisi 13:5-18) Inurere ti o farajọra le sun wa lati yọnda fun awọn ẹlomiran lati janfaani lara wa. Iru inurere alaini imọtara ẹni nikan bẹẹ wà ni ibamu pẹlu imọran apọsiteli Pọọlu pe: “Ki ẹnikẹni maṣe maa wá ti ara rẹ, ṣugbọn ki olukuluku maa wa ire ọmọnikeji rẹ.” Pọọlu funraarẹ ‘tẹ́ gbogbo eniyan lọrun ninu ohun gbogbo, láìwá ire tirẹ funraarẹ ṣugbọn ti ọpọlọpọ, ki wọn ba le ni igbala.’—1 Kọrinti 10:24, 33.
4. Ọna wo ni a gba san ere fun Aburahamu ati Sera fun fifi inurere han ni ọna alejo ṣiṣe?
4 Nigba miiran inurere jẹ lọna ẹmi alejo ṣiṣe atọkanwa. Aburahamu ati aya rẹ, Sera, fi inurere ati ẹmi alejo ṣiṣe han sí awọn ajeji mẹta ti wọn nkọja lọ ni ọjọ kan. Aburahamu mu wọn duro fun akoko kan, nigba ti oun ati Sera fi pàjáwìrì gbọ́ ounjẹ adidun fun awọn olubẹwo naa. Awọn ajeji wọnni wa jasi awọn angẹli Jehofa, ọkan lara wọn jiṣẹ ileri naa pe Sera ọlọ́jọ́lórí ti kò bí ọmọ yoo bi ọmọkunrin kan. (Jẹnẹsisi 18:1-15) Ẹ wo iru ere ti eyi jẹ fun ẹmi alejo ṣiṣe oninuure!
5. Ni ọna wo ni Gayọsi gba fi inurere han, bawo si ni awa ṣe le ṣe ohun kan ti o farajọra?
5 Ọna kan ti gbogbo Kristẹni le gba fi inurere han ni nipa jijẹ ẹlẹmii alejo ṣiṣe. (Roomu 12:13; 1 Timoti 3:1, 2) Nitori naa, awọn iranṣẹ Jehofa fi inurere nawọ ẹmi alejo ṣiṣe si awọn alaboojuto arinrin-ajo. Eyi mu ni ranti inurere ti Gayọsi Kristẹni ọgọrun un ọdun kìn-ínní naa fihan. Oun ṣe “iṣẹ igbagbọ” ni gbigba awọn arakunrin ti nṣebẹwo pẹlu ẹmi alejo ṣiṣe—wọn si jẹ “awọn alejo” ti oun ko mọ tẹlẹ. (3 Johanu 5-8) Gẹgẹ bi o ti saba maa nri, awa mọ awọn wọnni ti awa le nawọ ẹmi alejo ṣiṣe si lọna inurere. Boya a ṣakiyesi pe arabinrin tẹmi kan ni ibanujẹ ọkan. Olubaṣegbeyawo rẹ le jẹ alaigbagbọ kan tabi ẹni ti a ti yọ lẹgbẹ paapaa. Iru anfaani lati fi inurere han wo ni eyi jẹ nipa kike sii lati gbadun idapọ tẹmi ati ounjẹ pẹlu idile wa lóòrèkóòrè! Bi o tilẹ jẹ pe awa lè má gbé àsè rẹpẹtẹ kalẹ, dajudaju idile wa yoo ri ayọ ninu fifi inurere han si iru arabinrin bẹẹ. (Fiwe Owe 15:17.) Oun laiṣiyemeji yoo si sọ imoore rẹ jade fun eyi lọna afẹnusọ tabi lọna iwe idupẹ kekere oninuure kan.
6. Bawo ni Lidia ṣe fi inurere han, eesitiṣe ti o fi ṣe pataki lati fi imọriri han fun awọn iṣe oninuure?
6 Lẹhin ti a baptisi obinrin onifọkansin naa Lidia, “o sọ pẹlu àrọwà pe: ‘Bi ẹyin eniyan [Pọọlu ati awọn alabakẹgbẹ rẹ] ba kà mi si olootọ si Jehofa, ẹ wọ ile mi ki ẹ si jokoo.’ O si mu wa wá,” ni Luuku fikun. Laiṣiyemeji, inurere Lidia ni a mọriri. (Iṣe 16:14, 15, 40, NW) Ṣugbọn ikuna lati fi imọriri han le panilara. Ni akoko kan, arabinrin ẹni ọdun 80 kan ti o ni iwọn okun ati owo ti ko pọ fi inurere ṣòpò lati se ounjẹ fun awọn alejo diẹ. Oun ni a jakulẹ ni pataki nigba ti ọdọmọkunrin kan ko tilẹ fi tó o leti pe oun ko le wa. Ni akoko miiran, awọn arabinrin meji ko wa sibi ounjẹ ti ọdọbinrin kan sè ni pataki fun wọn. Oun wipe, “Inu mi bajẹ gidigidi bi o ti jẹ pe awọn mejeeji ko gbagbe. . . . Ki ba ti tẹ́ mi lọrun lati gbọ pe wọn ti gbọkan kuro lara ounjẹ, ṣugbọn kaka bẹẹ ko si ọkan lara awọn arabinrin naa ti o ninurere tabi nifẹẹ tó lati sọ fun mi.” Njẹ eso inurere ti ẹmi mimọ yoo ha sun ọ lati jẹ onimọriri ati onironu labẹ awọn ipo ti o farajọra?
Inurere Mu Wa Ni Igbatẹniro
7. Koko wo niti inurere ni a ṣakawe nipa isapa ti a ṣe lati fohunṣọkan pẹlu awọn aniyan Jakọbu nipa isinku rẹ̀?
7 Inurere nilati mu wa ni igbatẹniro fun awọn ẹlomiran ati awọn aniyan titọna wọn. Lati ṣakawe: Jakọbu (Isirẹli) sọ fun ọmọkunrin rẹ Josẹfu lati fi iṣeun-ifẹ han si i nipa ṣiṣai sinku rẹ̀ si Ijibiti. Bi o tilẹ jẹ pe eyi beere pe oku Jakọbu ni a o gbe lọ si ọna jijin kan, Josẹfu ati awọn ọmọkunrin Jakọbu miiran “gbe e lọ si ilẹ Kenani wọ si sin in sinu iho ti papa Makpela, papa ti Aburahamu ti ra lọwọ Efuroni ara Hiti niwaju Mamre fun ìni àyè isinku.” (Jẹnẹsisi 47:29; 49:29-31; 50:12, 13) Ni ibamu pẹlu apẹẹrẹ yẹn, ko ha yẹ ki iṣeun-ifẹ sun wa lati huwa ni ibamu pẹlu awọn iṣeto isinku ti o ṣetẹwọgba ninu Iwe mimọ tí mẹmba idile Kristẹni kan fẹ?
8. Ki ni ọran Rahabu fi kọ wa nipa sisan inurere pada?
8 Nigba ti awọn miiran ba fi iṣeun-ifẹ han si wa, ko ha yẹ ki a fi imọriri han tabi da a pada ni ọna kan? Dajudaju o yẹ. Rahabu aṣẹwo fi inurere han nipa titọju awọn amí Isirẹli. Fun idi yii, awọn ọmọ Isirẹli fi iṣeun-ifẹ han nipa titọju rẹ ati agbo ile rẹ pamọ nigba ti wọn pa ilu Jẹriko run. (Joṣua 2:1-21; 6:20-23) Iru apẹẹrẹ rere wo ni eyi jẹ ti ó fihan pe a nilati san inurere pada nipa jijẹ agbatẹniro ati oninuure funraawa!
9. Eeṣe ti iwọ yoo fi sọ pe o tọna lati sọ fun ẹnikan lati fi iṣeun-ifẹ han si wa?
9 Fun idi eyi, o tọna lati sọ fun ẹnikan lati fi iṣeun-ifẹ han si wa. Eyi ni Jonatani ṣe, ọmọ ọba Isirẹli akọkọ, Sọọlu. Jonathan sọ fun Dafidi ọrẹ rẹ olufẹ ọwọn ti o kere sí i lati fi iṣeun-ifẹ han sí i oun ati agbo ile rẹ. (1 Samuẹli 20:14, 15; 2 Samuẹli 9:3-7) Dafidi ranti eyi nigba ti o gbẹsan awọn ara Gibioni ti Sọọlu ṣẹ̀ sí. Ni riranti “ibura Oluwa [“Jehofa,” NW]” laaarin oun ati Jonathan, Dafidi lo iṣeun-ifẹ nipa dídá ẹmi Mefiboṣeti ọmọkunrin Jonathan sí. (2 Samuẹli 21:7, 8) Awa bakan naa ha ‘njẹ ki Bẹẹni wa jẹ Bẹẹni’ bí? (Jakọbu 5:12) Bi awa ba si jẹ alagba ijọ, awa ha jẹ olugbatẹniro lọna ti o farajọra nigba ti a ba nilati fi iṣeun-ifẹ han si awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa?
Inurere fun Awọn Ìdè Lokun
10. Bawo ni a ṣe bukun iṣeun-ifẹ Ruutu?
10 Inurere nfun awọn ide idile lokun o si gbe ayọ larugẹ. Eyi ni a fihan ninu ọran ti Ruutu ara Moabu. Oun ṣiṣẹ kára gẹgẹ bi olùpèéṣẹ́ ninu pápá Boasi agbalagba lẹbaa Bẹtilẹhẹmu, ni pipese ounjẹ fun ara rẹ ati iya ọkọ rẹ Naomi opó ti o ṣe alaini. (Ruutu 2:14-18) Boasi lẹhin naa sọ fun Ruutu pe: “Iwọ ti fi iṣeun-ifẹ rẹ han jade lọna ti o dara ni igba ikẹhin ju igba akọkọ lọ, ninu aitọ awọn ọdọmọkunrin lẹhin yala talaka tabi ọlọrọ.” (Ruutu 3:10, NW) Lakọọkọ, Ruutu fi iṣeun-ifẹ han si Naomi. “Ni igba ikẹhin,” ara Moabu naa fi iṣeun-ifẹ han nipa mimuratan lati fẹ́ Boasi agbalagba ki o ba le gbé orukọ dide fun ọkọ rẹ ti o ti kú ati fun Naomi ọlọjọlori. Nipasẹ Boasi, Ruutu di iya Obẹdi babanla Dafidi. Ọlọrun si fun un ni “owo ọ̀yà pipe” ti jijẹ iyanla Jesu Kristi. (Ruutu 2:12; 4:13-17; Matiu 1:3-6, 16; Luuku 3:23, 31-33) Ẹ wo ohun ti awọn ibukun iṣeun-ifẹ Ruutu ti yọrisi fun oun ati idile rẹ! Lonii, awọn ibukun, ayọ, ati fifun awọn ìdè idile lokun tun nṣẹlẹ nigba ti iṣeun-ifẹ ba gbilẹ ninu ile oniwa bi Ọlọrun.
11. Inurere Filemoni ni ipa wo?
11 Inurere nfun ìdè ninu ijọ awọn eniyan Jehofa lokun. Kristẹni ọkunrin naa Filemoni ni a mọ fun fifi iṣeun-ifẹ han si awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀. Pọọlu sọ fun un pe: “Mo maa ndupẹ lọwọ Ọlọrun mi nigba gbogbo ti mo ba ndarukọ rẹ ninu awọn adura mi, gẹgẹ bi mo ti ngbọ nipa rẹ ati igbagbọ ti iwọ ni si Jesu Oluwa ati si gbogbo awọn ẹni mimọ; . . . Nitori mo ni ayọ pupọ ati itunu nipa ifẹ rẹ, nitori pe a ti sọ ifẹni onijẹlẹnkẹ awọn ẹni mimọ dọtun nipasẹ rẹ, arakunrin.” (Filemoni 4-7, NW) Iwe mimọ ko sọ bi a ti sọ ifẹni onijẹlẹnkẹ awọn ẹni mimọ dọtun nipasẹ Filemoni. Bi o ti wu ki o ri, oun gbọdọ ti fi iṣeun-ifẹ han si awọn ẹni ami ororo ẹlẹgbẹ rẹ̀ ni oniruuru ọna ti o jasi itura fun wọn, eyi laiṣiyemeji fun awọn ìdè ti o wa laaarin wọn lokun. Ohun ti o farajọra maa nṣẹlẹ nigba ti awọn Kristẹni ba fi iṣeun-ifẹ han lonii.
12. Ki ni o jẹyọ lati inu inurere ti Onesiforu fihan?
12 Inurere Onesiforu tun ni ipa rere. “Ki Oluwa ki o fi aanu fun ile Onesiforu,” ni Pọọlu wi, “nitori o maa ntu mi lara nigba pupọ, ẹ̀wọ̀n mi ko si ti i loju: ṣugbọn nigba ti o wà ni Roomu, o fi ẹ̀sọ̀ wá mi, o si ri mi. Ki Oluwa ki o fi fun un ki o le ri aanu lọdọ Oluwa [“Jehofa,” NW] ni ọjọ nì: iwọ tikaararẹ ṣa mọ dajudaju iye ohun ti o ṣe iranṣẹ fun mi ni Efesu.” (2 Timoti 1:16-18) Bi a ba lo ara wa tokuntokun lati fi iṣeun-ifẹ han si awọn olujọsin ẹlẹgbẹ wa, awa yoo layọ a o si maa fun awọn ìdè ti ifẹni ará lokun laaarin ijọ Kristẹni.
13, 14. Ọna wo ni ijọ ti o wa ni Filipi fi jẹ awofiṣapẹẹrẹ, bawo si ni Pọọlu ṣe dahun pada si inurere rẹ?
13 Nigba ti gbogbo ijọ ba fi iṣeun-ifẹ han si awọn olujọsin ẹlẹgbẹ wọn, eyi nfun ìdè ti o wà laaarin wọn lokun. Iru ìdè timọtimọ bẹẹ wà laaarin Pọọlu ati ijọ naa ti o wa ninu ilu Filipi. Nitootọ, idi pataki ti ó fi kọ lẹta si awọn ara Filipi ni lati sọ imoore rẹ fun inurere ati iranlọwọ wọn nipa ti ara. Oun kọwe pe: “Ni ibẹrẹ ihinrere, nigba ti mo kuro ni Makedonia, ko si ijọ kan ti o ba mi ṣe alabaapin niti gbigba ati fifunni, bikoṣe ẹyin nikan ṣoṣo. Nitori ni Tẹsalonika . . ., ẹyin ranṣẹ, ẹ si tun ranṣẹ fun aini mi. . . . Ṣugbọn mo ni ohun gbogbo, mo si ti di pipọ: mo si kun nigba ti mo gba nǹkan wọnni ti a ti rán lati ọdọ yin wa lọwọ Ẹpafiroditu, ọrẹ oloorun didun, ẹbọ itẹwọgba ti ṣe inu didun gidigidi si Ọlọrun.”—Filipi 4:15-18.
14 Abajọ ti awọn ara Filipi oninuure fi wa ninu adura Pọọlu! Oun wipe: “Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun mi fun gbogbo iranti yin ti mo nṣe, nigba gbogbo ninu gbogbo adura mi fun yin ni emi nfi ayọ bẹbẹ nitori idapọ yin ninu ihinrere lati ọjọ ìkínní wá titi fi di isinsinyi.” (Filipi 1:3-5) Iru itilẹhin iṣẹ iwaasu Ijọba oninuure ati ọlọlawọ bẹẹ kii mu ki ijọ jẹ otoṣi lae. Lẹhin ti awọn ara Filipi ti fi inurere ṣe ohun ti wọn le ṣe ni ọna yii, Pọọlu mu un dá wọn loju pe: “Ọlọrun mi yoo pese ni kikun fun gbogbo aini yin, gẹgẹ bi ọrọ rẹ ninu ogo ninu Kristi Jesu.” (Filipi 4:19) Bẹẹni, Ọlọrun nsan ẹsan inurere ati iwa ọlawọ pada. Ọrọ rẹ wipe: “Ohun rere kohunrere ti olukuluku ba ṣe, ohun naa ni yoo si gba pada lọdọ Oluwa [“Jehofa,” NW].”—Efesu 6:8.
Nigba Ti Awọn Obinrin Ba Fi Inurere Han
15, 16. (a) Ọna wo ni a gba fi ranti inurere Dọkaasi ki ni o si ṣẹlẹ nigba ti o kú? (b) Ọna wo ni awọn obinrin Kristẹni oninuure fi gbà kún fun awọn iṣe rere lonii?
15 Inurere ọmọ-ẹhin naa Dọkaasi (Tabita) ti Jọpa ko lọ laini ere. “Obinrin yii pọ ni iṣẹ oore, ati itọrẹ aanu ti o nṣe,” ati nigba ti ‘o ṣaisan ti o si ku,’ awọn ọmọ-ẹhin ranṣẹ kesi Peteru ni Lida. Ni dide rẹ, “wọn mu un lọ si yara oke naa: gbogbo awọn opó si duro tì í wọn nsọkun, wọn si nfi ẹwu ati aṣọ ti Dọkaasi dá han an, nigba ti o wà pẹlu wọn.” Foju inu yaworan iran naa: Awọn opo ti wọn banujẹ, ti wọn nsunkun sọ fun apọsiteli naa bi Dọkaasi ti jẹ oninuure tó ti wọn si fi awọn ẹwu awọleke wọnni han an gẹgẹ bi ẹri ifẹ ati inurere rẹ. Ni jijẹki olukuluku eniyan jade, Peteru gbadura o si yiju si oku naa. Gbọ́! Oun wipe: “Tabita, dide.” Si wò ó! “O si la oju rẹ: nigba ti o si ri Peteru, o dide jokoo. O si na ọwọ rẹ si i, o fa a dide; nigba ti o si pe awọn eniyan mimọ ati awọn opó, o fi le wọn lọwọ laaye.” (Iṣe 9:36-41) Ẹ wo iru ibukun ti eyi jẹ lati ọdọ Ọlọrun!
16 Eyi ni ajinde akọkọ ti a kọsilẹ ti apọsiteli Jesu Kristi kan ṣe. Awọn ayika ti o ṣamọna si agbayanu iṣẹ iyanu yii ni o ti inu inurere wa. Ta ni o le sọ pe Dọkaasi ni a ba ti ji dide si iye bi oun ko ba ti pọ ninu iṣe rere ati itọrẹ aanu—bi oun ko ba ti pọ ninu iṣeun-ifẹ? Kii ṣe kiki pe a bukun Dọkaasi ati awọn opó wọnni nikan ni ṣugbọn iṣẹ iyanu ajinde rẹ pese ẹri si ogo Ọlọrun. Bẹẹni, ‘eyi di mímọ̀ yi gbogbo Jọpa ká; ọpọlọpọ si gba Oluwa gbọ.’ (Iṣe 9:42) Lonii, awọn obinrin Kristẹni ọlọkan rere tun pọ ninu awọn iṣe rere—boya ni riran ẹwu fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn, sise ounjẹ fun awọn agbalagba laaarin wa, ninawọ ẹmi alejo ṣiṣe si awọn ẹlomiran. (1 Timoti 5:9, 10) Iru ẹri wo ni eyi jẹ si awọn alakiyesi! Ju gbogbo rẹ lọ, bawo ni a ti layọ tó pe ifọkansin oniwa bi Ọlọrun ati iṣeun-ifẹ sun ‘ẹgbẹ ọmọ ogun nla awọn obinrin ti nsọ ihinrere naa’ si ogo Ọlọrun wa, Jehofa!—Saamu 68:11, NW.
Ẹ Maa Baa Lọ Ni Lilepa Iṣeun-ifẹ
17. Ki ni a sọ ni Owe 21:21 (NW), bawo si ni awọn ọrọ wọnni ṣe kan awọn ẹnikọọkan oniwa bi Ọlọrun?
17 Gbogbo awọn ti wọn fẹ ojurere Ọlọrun gbọdọ lepa iṣeun-ifẹ. “Ẹni ti nlepa ododo ati iṣeun-ifẹ yoo ri iye, ododo ati ogo,” ni owe ọlọgbọn kan wi. (Owe 21:21, NW) Ẹni oniwa bi Ọlọrun kan nfi tapọntapon lepa ododo Ọlọrun, ti awọn ọ̀pá idiwọn atọrunwa si ndari rẹ̀ nigba gbogbo. (Matiu 6:33) Oun nfi ifẹ aduroṣinṣin tabi iṣeun-ifẹ han leralera, si awọn ẹlomiran nipa ti ara ati ni pataki nipa tẹmi. Nipa bayii, oun ri ododo, nitori ẹmi Jehofa ran an lọwọ lati gbé ni ọna ododo. Nitootọ, oun ni ‘a wọ pẹlu ododo’ gẹgẹ bi Joobu ọkunrin oniwa bi Ọlọrun ti jẹ. (Joobu 29:14) Iru ẹni bẹẹ kii wa ogo ti ara rẹ. (Owe 25:27) Kaka bẹẹ, oun gba ogo eyikeyi ti Jehofa yọnda fun un lati gba, boya ni ọna ti ọ̀wọ̀ lati ọdọ awọn eniyan ẹlẹgbẹ rẹ̀ ti Ọlọrun sun lati fi inurere ba a lò nitori iṣeun-ifẹ tirẹ funraarẹ si wọn. Ju bẹẹ lọ, awọn wọnni ti wọn nṣe ifẹ Ọlọrun pẹlu iduroṣinṣin ri iye—kii wulẹ ṣe fun awọn ọdun diẹ ti nyara kọja lọ ṣugbọn titilae.
18. Eeṣe ti a fi nilati lepa iṣeun-ifẹ?
18 Nitori naa, njẹ ki gbogbo awọn ti wọn nifẹẹ Jehofa Ọlọrun maa baa lọ lati lepa iṣeun-ifẹ. Animọ yii mu wa jẹ ẹni ọwọn si Ọlọrun ati awọn ẹlomiran. O gbé ẹmi alejo ṣiṣe larugẹ o si mu wa jẹ agbatẹniro. Inurere nfun awọn ide laaarin idile ati ijọ Kristẹni lokun. Awọn obinrin ti wọn nfi iṣeun-ifẹ han ni a mọriri ti a si kàsí gidigidi. Gbogbo awọn wọnni ti wọn si nlepa animọ titayọ yii mu ogo wa fun Ọlọrun iṣeun-ifẹ, Jehofa.
Bawo Ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun
◻ Ọna wo ni Aburahamu gba jẹ awofiṣapẹẹrẹ ninu fifi inurere han?
◻ Ki ni ọ̀ràn Rahabu fi kọni nipa sisan inurere pada?
◻ Bawo ni ijọ Filipi ṣe fi inurere han?
◻ Ọna wo ni awọn obinrin Kristẹni oninuure fi gbà kún fun awọn iṣe rere lonii?
◻ Eeṣe ti a fi nilati lepa iṣeun-ifẹ?