Ìwé Kìíní sí Tímótì
2 Torí náà, mò ń pàrọwà fún yín ṣáájú ohun gbogbo pé kí ẹ máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀, kí ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ máa dúpẹ́, kí ẹ sì máa bẹ̀bẹ̀ torí onírúurú èèyàn, 2 kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ torí àwọn ọba àti gbogbo àwọn tó wà ní ipò gíga,*+ ká lè máa gbé ìgbé ayé tó pa rọ́rọ́ nìṣó pẹ̀lú ìbàlẹ̀ ọkàn, bí a ti ń fi gbogbo ọkàn wa sin Ọlọ́run, tí a sì ń fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan.+ 3 Èyí dáa, ó sì ní ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run, Olùgbàlà wa,+ 4 ẹni tó fẹ́ ká gba onírúurú èèyàn là,+ kí wọ́n sì ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́. 5 Torí Ọlọ́run kan ló wà+ àti alárinà kan+ láàárín Ọlọ́run àtàwọn èèyàn,+ ọkùnrin kan, Kristi Jésù,+ 6 ẹni tó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà tó bá a mu rẹ́gí fún gbogbo èèyàn*+—ohun tí a máa jẹ́rìí sí nìyí tí àkókò rẹ̀ bá tó. 7 Torí ìjẹ́rìí yìí + ni a ṣe yàn mí láti jẹ́ oníwàásù àti àpọ́sítélì+—òótọ́ ni mò ń sọ, mi ò parọ́—olùkọ́ àwọn orílẹ̀-èdè+ ní ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti òtítọ́.
8 Nítorí náà, ní ibi gbogbo mo fẹ́ kí àwọn ọkùnrin máa gbàdúrà, kí wọ́n máa gbé ọwọ́ mímọ́* sókè,+ láìsí ìbínú+ àti fífa ọ̀rọ̀.+ 9 Bákan náà, kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tó bójú mu* ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmọ̀wọ̀n ara ẹni àti àròjinlẹ̀,* kì í ṣe dídi irun lọ́nà àrà àti lílo wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ olówó ńlá,+ 10 àmọ́ kó jẹ́ lọ́nà tó yẹ àwọn obìnrin tó sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn,+ ìyẹn nípa àwọn iṣẹ́ rere.
11 Kí obìnrin kẹ́kọ̀ọ́ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́* kó sì máa tẹrí ba délẹ̀délẹ̀.+ 12 Mi ò fọwọ́ sí kí obìnrin kọ́ni tàbí kó pàṣẹ lé ọkùnrin lórí, àmọ́ kí ó dákẹ́.*+ 13 Torí Ádámù ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá, kó tó wá dá Éfà.+ 14 Bákan náà, a kò tan Ádámù jẹ, àmọ́ a tan obìnrin náà jẹ pátápátá,+ ó sì di arúfin. 15 Síbẹ̀, ọmọ bíbí máa dáàbò bò ó,+ tó* bá rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ àti ìjẹ́mímọ́ àti àròjinlẹ̀.*+