Tẹ́wọ́gba Bibeli Nítorí Ohun Tí Ó Jẹ́ Nítòótọ́
“Awa pẹlu . . . ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun láìdabọ̀, nitori nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun, èyí tí ẹ gbọ́ lati ọ̀dọ̀ wa, ẹ̀yin tẹ́wọ́gbà á, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn, ṣugbọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọrun, èyí tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ pẹlu ninu ẹ̀yin onígbàgbọ́.”—1 TESSALONIKA 2:13.
1. Irú ìsọfúnni wo tí ó wà nínú Bibeli ni ó mú kí ìwé náà tayọlọ́lá nítòótọ́?
BIBELI Mímọ́ ni ìwé tí a tíì túmọ̀ sí èdè tí ó pọ̀ jùlọ tí a sì tíì pínkiri jùlọ ní àgbáyé. A tẹ́wọ́gbà á láìjanpata gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó ga lọ́lá. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọ̀nà tí ó ṣe pàtàkì jùlọ, Bibeli pèsè ìtọ́sọ́nà tí àwọn ènìyàn láti gbogbo ẹ̀yà àti orílẹ̀-èdè nílò ní kánjúkánjú, láìka iṣẹ́ wọn tàbí ipò wọn nínú ìgbésí-ayé sí. (Ìṣípayá 14:6, 7) Ní ọ̀nà tí ń mú èrò-inú àti ọkàn-àyà láyọ̀, Bibeli dáhùn àwọn ìbéèrè bíi: Kí ni ète ìwàláàyè ẹ̀dá-ènìyàn? (Genesisi 1:28; Ìṣípayá 4:11) Èéṣe tí àwọn ìjọba aráyé kò fi tíì lè mú àlàáfíà pípẹ́ títí àti àìléwu wá? (Jeremiah 10:23; Ìṣípayá 13:1, 2) Èéṣe tí àwọn ènìyàn fi ń kú? (Genesisi 2:15-17; 3:1-6; Romu 5:12) Láàárín ayé onídààmú yìí, báwo ni a ṣe lè ṣe àṣeyọrí ní kíkojú àwọn ìṣòro ìgbésí-ayé? (Orin Dafidi 119:105; Owe 3:5, 6) Kí ni ọjọ́-ọ̀la ní ní ìpamọ́ fún wa?—Danieli 2:44; Ìṣípayá 21:3-5.
2. Èéṣe tí Bibeli fi pèsè ìsọfúnni tí ó ṣeé gbáralé pátápátá sí àwọn ìbéèrè wa?
2 Èéṣe tí Bibeli fi dáhùn irú àwọn ìbéèrè yẹn pẹ̀lú ọlá-àṣẹ? Nítorí ó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ó lo àwọn ẹ̀dá ènìyàn láti kọ ọ́, ṣùgbọ́n bí ó ti hàn kedere nínú 2 Timoteu 3:16, “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọrun mí sí.” Kì í ṣe àbájáde ìtumọ̀ ìkọ̀kọ̀ ti ìṣẹ̀lẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn. “A kò fi ìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ [ìpolongo àwọn ohun tí ń bọ̀, àwọn àṣẹ Ọlọrun, ọ̀pá-ìdiwọ̀n ìwà-híhù ti Bibeli] wá nipa ìfẹ́-inú ènìyàn, ṣugbọn awọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.”—2 Peteru 1:21.
3. (a) Fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ tí ó fi hàn bí àwọn ènìyàn tí mọ ìníyelórí Bibeli tó ní onírúurú ilẹ̀. (b) Èéṣe tí àwọn kan fi ṣetán láti fi ẹ̀mí wọn wewu láti lè ka Ìwé Mímọ́?
3 Nítorí ìmọrírì wọn fún ìwúlò Bibeli, ọ̀pọ̀ ènìyàn ti dágbálé-ewu ìfinisẹ́wọ̀n, àní ikú pàápàá, láti lè ní in kí wọ́n sì kà á. Èyí jẹ́ òtítọ́ ní àwọn ọdún tí ó ti kọjá sẹ́yìn ní Spania tí àwọn onísìn Katoliki wa, níbi tí àwọn àwùjọ àlùfáà ti bẹ̀rù pé agbára ìdarí wọn ni a óò jìn lẹ́sẹ̀ bí àwọn ènìyàn bá ka Bibeli ní èdè ìbílẹ̀ wọn; bákan náà ni èyí jẹ́ òtítọ́ ní Albania, níbi tí a ti gbé òfin líle koko kalẹ̀ lábẹ́ ètò-ìjọba aláìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun láti lè fi òpin sí gbogbo ipa ìdarí ìsìn. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun ka àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ sí ohun ìṣúra, wọ́n kà wọ́n, wọ́n sì ṣàjọpín wọn pẹ̀lú ara wọn. Nígbà Ogun Àgbáyé II, ní ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Sachsenhausen, Bibeli ni a fi tìṣọ́ra tìṣọ́ra ta látaré láti ilé ẹ̀wọ̀n kan sí òmíràn (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi òfin dè é), àwọn tí ó sì rí i kọ́ apákan sórí láti ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ní àwọn ọdún 1950, ní ibi tí a mọ̀ nígbà náà sí Kọmunisti Ìlà-Oòrùn Germany, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí a fi sẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ wọn dágbálé ewu ìdánìkanwà fún àkókò pípẹ́ nígbà tí wọ́n ta àtagbà apákan Bibeli láti ọwọ́ ẹlẹ́wọ̀n kan sí òmíràn láti lè kà á ní alẹ́. Èéṣe tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? Nítorí pé wọ́n mọ̀ pé Bibeli jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, wọ́n sì mọ̀ pé ‘kì í ṣe nípa ounjẹ nìkan’ ṣùgbọ́n nípa “gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu OLUWA jáde ni ènìyàn wà láàyè.” (Deuteronomi 8:3) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí a kọ sílẹ̀ nínú Bibeli, mú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyẹn láti wà láàyè nípa tẹ̀mí láìka ìwà-ìkà tí ó ṣòro láti gbàgbọ́ tí wọ́n dojúkọ sí.
4. Ipò wo ni ó yẹ kí Bibeli wà nínú ìgbésí ayé wa?
4 Bibeli kì í ṣe ìwé kan tí a kàn lè fi sórí pẹpẹ ìkówèésí fún ìtọ́kasí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, bẹ́ẹ̀ni kì í ṣe fún lílò kìkì nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa bá péjọpọ̀ fún ìjọsìn. A gbọ́dọ̀ lò ó lójoojúmọ́ láti tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn ipò tí ń dojúkọ wá kí ó sì fi ọ̀nà tí ó tọ́ láti gbà hàn wá.—Orin Dafidi 25:4, 5.
Ó Wà fún Kíkà àti Lílóye
5. (a) Bí ó bá ṣeé ṣe rárá, kí ni ẹnìkọ̀ọ̀kan wa níláti ní? (b) Ní Israeli ìgbàanì, báwo ni àwọn ènìyàn ṣe ń mọ ohun tí ó wà nínú Ìwé Mímọ́? (d) Báwo ni Orin Dafidi 19:7-11 ṣe nípa lórí ìṣarasíhùwà rẹ sí Bibeli kíkà?
5 Ní ọjọ́ tiwa, àwọn ẹ̀dà Bibeli wà lárọ̀ọ́wọ́tó láìsí ìṣòro ní ilẹ̀ tí ó pọ̀ jùlọ, a sì rọ gbogbo àwọn òǹkàwé Ilé-Ìṣọ́nà láti ní ẹ̀dà kan. Ní ìgbà tí a ń kọ Bibeli, kò sí ohun ìtẹ̀wé. Àwọn ènìyàn ní gbogbogbòò kò ní ẹ̀dà tiwọn. Ṣùgbọ́n Jehofa ṣètò fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti gbọ́ ohun tí a kọ. Nípa báyìí, Eksodu 24:7 ròyìn pé, lẹ́yìn tí Mose ti ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí Jehofa darí rẹ̀ láti kọ, ó “mú ìwé májẹ̀mú nì, ó sì kà á ní etí àwọn ènìyàn.” Lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣẹlẹ́rìí àwọn ìran àfihàn tí ó ju ti ẹ̀dá lọ ní Òkè-Ńlá Sinai, wọ́n mọ̀ pé ohun tí Mose kà fún wọn wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun àti pé wọ́n níláti mọ àwọn ìsọfúnni wọ̀nyí. (Eksodu 19:9, 16-19; 20:22) Àwa pẹ̀lú níláti mọ ohun tí a kọ sílẹ̀ sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.—Orin Dafidi 19:7-11.
6. (a) Kí orílẹ̀-èdè Israeli tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí, kí ni Mose ṣe? (b) Báwo ni a ṣe lè ṣàfarawé àpẹẹrẹ Mose?
6 Bí orílẹ̀-èdè Israeli ti ń múra láti la Odò Jordani kọjá láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà, kí wọ́n sì tipa báyìí fi ìgbésí ayé alárìnkiri tí wọ́n ń gbé nínú aginjù sílẹ̀, ó yẹ kí wọ́n ṣàgbéyẹ̀wò Òfin Jehofa àti ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú wọn. Mose ṣe àyẹ̀wò Òfin náà pẹ̀lú wọn, nítorí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun sún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó rán wọn létí kúlẹ̀kúlẹ̀ Òfin náà, ó sì tún tẹnumọ́ àwọn ìlànà ìpìlẹ̀ àti ìṣarasíhùwà tí ó yẹ kí ó nípa lórí ipò-ìbátan wọn pẹ̀lú Jehofa. (Deuteronomi 4:9, 35; 7:7, 8; 8:10-14; 10:12, 13) Bí àwa lónìí ti ń gba àwọn iṣẹ́ àyànfúnni titun tàbí tí a ń dojúkọ àwọn ipò titun nínú ìgbésí-ayé, yóò dára bí àwa pẹ̀lú bá lè ṣàgbéyẹ̀wò bí àwọn ìmọ̀ràn inú Ìwé Mímọ́ ṣe níláti nípa lórí ohun tí a bá ń ṣe.
7. Kété lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israeli ré Jordani kọjá, kí ni a ṣe láti tẹ Òfin Jehofa mọ́ èrò-inú àti ọkàn-àyà wọn?
7 Kété lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israeli ti ré Odò Jordani kọjá tán, àwọn ènìyàn náà kórajọ láti ṣàtúnyẹ̀wò ohun tí Jehofa tí sọ fún wọn nípasẹ̀ Mose. Orílẹ̀-èdè náà péjọpọ̀ ní nǹkan bíi 50 kìlómítà ní àríwá Jerusalemu. Ìdajì àwọn ẹ̀yà náà wà níwájú Òkè-Ńlá Ebali, ìdajì sì wà níwájú Òkè-Ńlá Gerisimu. Níbẹ̀ Joṣua “ka gbogbo ọ̀rọ̀ òfin, ìbùkún àti ègún.” Nípa báyìí àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọ kéékèèké, papọ̀ pẹ̀lú àwọn àlejò, gbọ́ àtúnsọ àwọn òfin náà tí ó bọ́ sásìkò tí ń ṣàkóso ìhùwàsí tí yóò yọrí sí kí Jehofa má fi ojúrere tẹ́wọ́gbà wọ́n àti ti ìbùkún tí wọn yóò gbà bí wọ́n bá ṣègbọràn sí Jehofa. (Joṣua 8:34, 35) Ó yẹ kí ohun tí ó dára àti ohun tí ó burú lójú ìwòye Jehofa ṣe kedere nínú ọkàn wọn. Síwájú síi, ó yẹ kí wọ́n tẹ ìfẹ́ fún ohun tí ó dára àti ìkórìíra fún ohun tí ó burú mọ́ ọkàn-àyà wọn ṣinṣin, bí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti ń ṣe lónìí.—Orin Dafidi 97:10; 119:103, 104; Amosi 5:15.
8. Kí ni àǹfààní kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun láti ìgbà-dé-ìgbà ní àwọn àpéjọ kan tí ó jẹ́ ti orílẹ̀-èdè ní Israeli?
8 Ní àfikún sí kíka Òfin ní àwọn àkókò àṣeyẹ àkànṣe báwọ̀nyí, ìpèsè fún kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun déédéé ni a là sílẹ̀ ní Deuteronomi 31:10-12. Ní ọdún méjeméje orílẹ̀-èdè náà lápapọ̀ níláti péjọ láti gbọ́ kíkà Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Èyí pèsè oúnjẹ nípa tẹ̀mí fún wọn. Ó mú kí àwọn ìlérí nípa Irú-Ọmọ náà wà láàyè nínú èrò-inú àti ọkàn-àyà wọn kí ó sì tipa báyìí ṣiṣẹ́ láti darí àwọn olùṣòtítọ́ sí Messia náà. Ètò fún jíjẹ oúnjẹ nípa tẹ̀mí tí a dá sílẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ Israeli wà ní aginjù kò dópin nígbà tí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí. (1 Korinti 10:3, 4) Dípò bẹ́ẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni a mú sunwọ̀n síi nípa fífi ìṣípayá síwájú síi ti àwọn wòlíì kún un.
9. (a) Kìkì ìgbà tí àwọn ọmọ Israeli bá péjọ ní àwùjọ ńlá nìkan ni wọ́n ha máa ń ka Ìwé Mímọ́ bí? Ṣàlàyé. (b) Báwo ni a ṣe ń fúnni ní ìtọ́ni inú Ìwé Mímọ́ láàárín àwọn ìdílé kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú góńgó wo sì ni?
9 Àtúnyẹ̀wò àwọn ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní a kò gbọdọ̀ fimọ sí kìkì àwọn ìgbà wọ̀nyẹn tí àwọn ènìyàn bá péjọ ní àwùjọ ńlá. Apákan Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti àwọn ìlànà tí ó ní nínú ní a gbọ́dọ̀ jíròrò lójoojúmọ́. (Deuteronomi 6:4-9) Ní ibi púpọ̀ jùlọ lónìí, ó ṣeé ṣe fún àwọn ọ̀dọ́ láti ní ẹ̀dà Bibeli tiwọn, ó sì ṣàǹfààní púpọ̀ fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ní Israeli ìgbàanì, ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Nígbà náà lọ́hùn-ún, nígbà tí àwọn òbí bá fúnni ní ìtọ́ni láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, wọ́n níláti gbójúlé ohun tí wọ́n ti kọ́ sórí àti àwọn òtítọ́ tí wọ́n ti ṣìkẹ́ nínú ọkàn-àyà wọn, papọ̀ pẹ̀lú àyọkà díẹ̀ yòówù tí wọ́n ti kọ sílẹ̀ fúnra wọn. Nípa àwítúnwí léraléra, wọn yóò sakun láti gbé ìfẹ́ fún Jehofa àti àwọn ọ̀nà rẹ̀ ró nínú àwọn ọmọ wọn. Góńgó náà kì í ṣe láti wulẹ̀ kó ìmọ̀ jọ sínú ọpọlọ ṣùgbọ́n láti ran mẹ́ḿbà kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé lọ́wọ́ láti gbé ní ọ̀nà tí yóò fi ìfẹ́ fún Jehofa àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn.—Deuteronomi 11:18, 19, 22, 23.
Kíka Ìwé Mímọ́ Nínú Sinagọgu
10, 11. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìwé Mímọ́ kíkà wo ni a tẹ̀lé nínú sinagọgu, ojú wo sì ni Jesu fi wo àwọn àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí?
10 Nígbà kan lẹ́yìn tí a ti kó àwọn Júù nígbèkùn lọ sí Babiloni, sinagọgu ni a dá sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ibi ìjọsìn. Kí ó baà lè ṣeé ṣe láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kí wọ́n sì jíròrò rẹ̀ ní àwọn ibi ìpàdé wọ̀nyí, ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ púpọ̀ síi ni a ṣe. Èyí jẹ́ kókó abájọ fún lílàájá nǹkan bí ẹ̀dà 6,000 nínú àwọn tí a fi ọwọ́ kọ tí ó ní apákan Ìwé Mímọ́ lédè Heberu nínú.
11 Apá pàtàkì nínú iṣẹ́-ìsìn nínú sinagọgu ni kíka Torah, èyí tí ó dọ́gba pẹ̀lú ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ ti àwọn Bibeli òde-òní. Ìṣe 15:21 ròyìn pé ní ọ̀rúndún kìn-ínní C.E., irú ìwé kíkà bẹ́ẹ̀ ni a máa ń ṣe ní gbogbo ọjọ́ Sábáàtì, Mishnah sì fi hàn pé ní ọ̀rúndún kejì, kíka Torah pẹ̀lú wà ní gbogbo ọjọ́ kejì àti ìkarùn-ún ọ̀sẹ̀. Àwọn kan yóò nípìn-ín nínú kíka àwọn apá tí a yàn fún wọn, ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Àṣà àwọn Júù tí wọ́n gbé ní Babiloni ni láti ka Torah látòkèdélẹ̀ lọ́dọọdún; àṣà ti Palestine ni láti pín ìwé kíkà náà kí ó lè gba ọdún mẹ́ta. Apákan àkọsílẹ̀ àwọn Wòlíì ni a kà tí a sì ṣàlàyé pẹ̀lú. Ó jẹ́ àṣà Jesu láti máa pésẹ̀ fún ètò Bibeli kíkà ti Sábáàtì ní ibi tí ó gbé.—Luku 4:16-21.
Ìdáhùnpadà Ara-Ẹni àti Ìmúlò
12. (a) Nígbà tí Mose ka Òfin náà fún àwọn ènìyàn, báwo ni àwọn ènìyàn náà ṣe jàǹfààní? (b) Báwo ni àwọn ènìyàn náà ṣe dáhùnpadà?
12 Kíka Ìwé Mímọ́ tí a mí sí kò yẹ kí ó kàn jẹ́ ètò-àṣà lásán. A kò ṣe é kìkì láti tẹ́ ojúmìító àwọn ènìyàn lọ́rùn. Nígbà tí Mose ka “ìwé májẹ̀mú” fún àwọn ọmọ Israeli lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó dojúkọ Òkè-Ńlá Sinai, ó ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n ba lè mọ ẹrù-iṣẹ́ wọn sí Ọlọrun kí wọ́n sì mú wọn ṣẹ. Wọn yóò ha ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Ìwé kíkà náà béèrè fún ìdáhùnpadà. Àwọn ènìyàn náà mọ èyí, wọ́n sì sọ̀rọ̀ jáde, wí pé: “Gbogbo èyí tí OLUWA wí ni àwa óò ṣe, àwa óò sì gbọ́ràn.”—Eksodu 24:7; fiwé Eksodu 19:8; 24:3.
13. Nígbà tí Joṣua ka àwọn ègún tí ó wà fún àìgbọràn, kí ni àwọn ènìyàn náà gbọ́dọ̀ ṣe, pẹ̀lú góńgó wo sì ni?
13 Lẹ́yìn náà, nígbà tí Joṣua ka àwọn ìbùkún àti àwọn ègún, tàbí àwọn ìfiré, ìdáhùnpadà di dandan. Lẹ́yìn ìfiré kọ̀ọ̀kan, ìtọ́ni ni a fún wọn pé: “Gbogbo ènìyàn yóò sì wí pé, Àmín.” (Deuteronomi 27:4-26) Nípa báyìí, bí a ti ń gbé kókó kọ̀ọ̀kan yẹ̀wò wọ́n yóò máa sọ jáde pé àwọn fọwọ́ sí bí Jehofa ṣe dá àwọn ohun tí kò tọ̀nà tí a mẹ́nu kàn lẹ́bi. Ẹ wo irú ìṣẹ̀lẹ̀ arunilọ́kànsókè tí èyí níláti jẹ́ nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè náà pariwo ìfọwọ́sí wọn!
14. Ní àwọn ọjọ́ Nehemiah, èéṣe tí Òfin kíkà ní gbangba ṣe fi ẹ̀rí ṣíṣeni láǹfààní pàápàá ní pàtàkì hàn?
14 Ní àwọn ọjọ́ Nehemiah, nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn péjọ sí Jerusalemu láti gbọ́ Òfin náà, wọ́n rí i pé àwọn kò tí ì máa tẹ̀lé àwọn ìtọ́ni tí wọ́n kọ síbẹ̀. Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn wọ́n fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò kíákíá. Kí ni àbájáde rẹ̀? “Ayọ̀ ńláǹlà sì wà.” (Nehemiah 8:13-17) Lẹ́yìn kíka Bibeli lójoojúmọ́ fún ọ̀sẹ̀ kan nígbà àjọyọ̀ náà, wọ́n wá mọ̀ pé púpọ̀ síi ṣì wà tí a béèrè fún. Tàdúrà tàdúrà wọ́n ṣàgbéyẹ̀wò ìtàn bí Jehofa ṣe bá àwọn ènìyàn rẹ̀ lò láti ọjọ́ Abrahamu síwájú. Gbogbo èyí sún wọn láti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti mú ara wọn bá gbogbo ohun tí Òfin béèrè fún mu, àti láti yàgò fún ṣíṣègbeyàwó pẹ̀lú àwọn àjèjì, àti láti tẹ́wọ́gba iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe ti mímójútó tẹ́ḿpìlì àti iṣẹ́-ìsìn rẹ̀.—Nehemiah, orí 8 sí 10.
15. Báwo ni àwọn ìtọ́ni tí ó wà ní Deuteronomi 6:6-9 ṣe fi hàn pé, láàárín ìdílé, ìtọ́ni nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kò níláti jẹ́ ètò-àṣà lásán?
15 Bákan náà, láàárín agbo ìdílé, fífi Ìwé Mímọ́ kọ́ni kò yẹ kí ó jẹ́ ètò-àṣà lásán. Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i tẹ́lẹ̀, ní ọ̀nà ìṣàpẹẹrẹ ní Deuteronomi 6:6-9, àwọn ènìyàn náà ni a sọ fún láti ‘so ọ̀rọ̀ Ọlọrun mọ́ ọwọ́ wọn fún àmì’—nípa báyìí kí wọ́n sì fi ìfẹ́ wọn fún àwọn ọ̀nà Jehofa hàn nípa àpẹẹrẹ àti ìṣesí. Wọ́n sì níláti fi ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣe ‘ọ̀já ìgbàjú níwájú wọn’—nípa báyìí wọn yóò máa fi àwọn ìlànà tí ó wà nínú Ìwé Mímọ́ sọ́kàn nígbà gbogbo wọn yóò sì máa lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún àwọn ìpinnu wọn. (Ṣàfiwé èdè tí a lò ní Eksodu 13:9, 14-16.) Wọ́n níláti ‘kọ wọ́n sára òpó ilé wọn, àti sára ilẹ̀kùn ọ̀nà-òde wọn’—nípa báyìí kí wọ́n fi ilé wọn àti àdúgbò wọn hàn yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bí ibi tí a ti ń fi ọ̀wọ̀ hàn fún ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí a sì ń fi í sílò. Ní èdè mìíràn, ìgbésí-ayé wọn gbọ́dọ̀ fi ẹ̀rí tí ó pọ̀ rẹpẹtẹ hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jehofa wọ́n sì ń fi àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ sílò. Ẹ wo bí ìyẹn yóò ti ṣàǹfààní tó! Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ha hàn ketekete nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́ agbo-ilé wa bí? Ó ṣeniláàánú pé, àwọn Júù yí gbogbo èyí padà sí ètò-àṣà lásán, wọ́n sì ń so àwọn àpótí gígọntíọ tí wọ́n ní àkọsílẹ̀ ìwé mímọ́ bí ẹni pé wọ́n jẹ́ ońdè. Ìjọsìn wọn kò ti ọkàn wá mọ́, Jehofa sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀.—Isaiah 29:13, 14; Matteu 15:7-9.
Ẹrù-Iṣẹ́ Àwọn Wọnnì Tí Wọ́n Wà ní Ìpò Ìṣàbójútó
16. Èéṣe tí kíka Ìwé Mímọ́ déédéé fi ṣe pàtàkì fún Joṣua?
16 Níti ọ̀ràn kíka Ìwé Mímọ́, àkànṣe àfiyèsí ni a darí sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́ alábòójútó orílẹ̀-èdè náà. Fún Joṣua, Jehofa sọ pé: “Kíyèsí àti ṣe gẹ́gẹ́ bi gbogbo òfin.” Pẹ̀lú ojú-ìwòye láti mú ẹrù-iṣẹ́ náà ṣẹ, a sọ fún un pé: “Ìwọ óò máa ṣe àṣàrò nínú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, . . . nítorí nígbà náà ni ìwọ óò ṣe ọ̀nà rẹ ní rere, nígbà náà ni yóò sì dára fún ọ.” (Joṣua 1:7, 8) Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ òtítọ́ nípa Kristian alábòójútó èyíkéyìí lónìí, kíkà tí Joṣua ń ka Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ yóò ràn án lọ́wọ́ láti fi àwọn òfin pàtó tí Jehofa fi fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ sọ́kàn dáradára. Joṣua tún níláti lóye bí Jehofa ṣe bá àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ lò lábẹ́ oríṣiríṣi àyíká ipò. Bí ó ti ń ka àwọn àkọsílẹ̀ nípa ète Ọlọrun, ó ṣe pàtàkì fún un láti ronú nípa ẹrù-iṣẹ́ òun fúnra rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ète yẹn.
17. (a) Kí àwọn ọba tó lè jàǹfààní nínú kíka Ìwé Mímọ́ ní ọ̀nà tí Jehofa là sílẹ̀, kí ni wọ́n nílò ní àfikún sí kíkà á wọn? (b) Èéṣe tí Bibeli kíkà déédéé àti ṣíṣàṣàrò fi ṣe pàtàkì fún àwọn Kristian alàgbà?
17 Jehofa pàṣẹ pé kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣisẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí ọba lé àwọn ènìyàn Òun lórí, ṣe ẹ̀dà Òfin Ọlọrun, láti ìbẹ̀rẹ̀ ipò-ọba rẹ̀, kí ó gbé e karí ẹ̀dà tí àwọn àlùfáà tọ́jú pamọ́. Lẹ́yìn náà ó gbọ́dọ̀ máa “kà nínú rẹ̀ ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo.” Góńgó náà kì í ṣe láti wulẹ̀ kọ́ àwọn ohun tí ó wà nínú rẹ̀ sórí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí ó lè “kọ́ àti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun rẹ̀,” àti kí “àyà rẹ̀ kí ó má baà gbéga ju àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ.” (Deuteronomi 17:18-20) Èyí ń béèrè pé kí ó ṣàṣàrò jinlẹ̀jinlẹ̀ lórí ohun tí ó ń kà. Láìṣe àníàní àwọn kan lára àwọn ọba náà rò pé ọwọ́ àwọn ti dí jù nítorí àwọn ẹrù-iṣẹ́ ìṣàkóso tí ó wà láti ṣe, gbogbo orílẹ̀-èdè náà ni ó sì jìyà nítorí àìnáání wọn. Dájúdájú ipa-iṣẹ́ àwọn Kristian alàgbà nínú ìjọ kì í ṣe ti àwọn ọba. Síbẹ̀síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ òtítọ́ níti àwọn ọba, ó ṣekókó pé kí àwọn alàgbà ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kí wọ́n sì ṣàṣàrò lórí rẹ̀. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ wọn yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di ojú ìwòye tí ó tọ́ mú nípa àwọn wọnnì tí a fi sí abẹ́ àbójútó wọn. Yóò tún ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ẹrù-iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ṣẹ ní ọ̀nà tí yóò fi ọ̀wọ̀ hàn ní tòótọ́ fún Ọlọrun tí yóò sì fún àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wọn lókun.—Titu 1:9; fiwé Johannu 7:16-18; fi ìyàtọ̀ 1 Timoteu 1:6, 7 hàn.
18. Irú àpẹẹrẹ wo tí aposteli Paulu fi lélẹ̀ ni kíkà àti kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé yóò ràn wá lọ́wọ́ láti farawé?
18 Aposteli Paulu, Kristian alábòójútó ní ọ̀rúndún kìn-ínní, jẹ́ ẹni tí ó mọ Ìwé Mímọ́ gan-an. Nígbà tí ó jẹ́rìí fún àwọn ènìyàn ní Tessalonika ìgbàanì, ó ṣeé ṣe fún un láti fọ̀rọ̀wérọ̀ lọ́nà tí ó gbéṣẹ́ pẹ̀lú wọn láti inú Ìwé Mímọ́ kí ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye ìtumọ̀ rẹ̀. (Ìṣe 17:1-4) Ó dé inú ọkàn-àyà àwọn olùfetísílẹ̀ tòótọ́. Nípa báyìí, ọ̀pọ̀ nínú àwọn tí ó gbọ́ ọ di onígbàgbọ́. (1 Tessalonika 2:13) Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bibeli kíkà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ, ó ha ṣeé ṣe fún ọ láti fọ̀rọ̀wérọ̀ lọ́nà tí ó gbéṣẹ́ láti inú Ìwé Mímọ́ bí? Ipò tí Bibeli kíkà gbà nínú ìgbésí-ayé rẹ àti ọ̀nà tí o ń gbà ṣe é ha fi ẹ̀rí hàn pé nítòótọ́ ni o mọrírì ohun tí ó túmọ̀ sí láti ní Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní ìkáwọ́ rẹ bí? Nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e, a óò ṣàgbéyẹ̀wò bí a ṣe lè dáhùn bẹ́ẹ̀ni sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí àní pàápàá àwọn wọnnì tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ wọn dí gádígádí.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Èéṣe tí àwọn ènìyàn fi ṣetán láti fi ẹ̀mí àti òmìnira wewu kí wọ́n baà lè ka Bibeli?
◻ Báwo ni a ṣe jàǹfààní nípa ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ìpèsè tí a ṣe fún Israeli ìgbàanì láti gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun?
◻ Kí ni a níláti ṣe pẹ̀lú ohun tí a bá kà nínú Bibeli?
◻ Èéṣe tí Bibeli kíkà àti ṣíṣàṣàrò fi ṣe pàtàkì pàápàá fún àwọn Kristian alàgbà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Jehofa sọ fún Joṣua pé: “Ìwọ óò máa ṣe àṣàrò nínú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru”