Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Rúùtù
ÀWÒKẸ́KỌ̀Ọ́ tó sọ nípa ìtàn gidi ni. Ìtàn ọ̀hún sọ nípa ohun tó wáyé láàárín obìnrin méjì tí wọn ò yara wọn. Ó sì tún sọ nípa bí àwọn kan ṣe mọyì Jèhófà Ọlọ́run tí wọ́n sì gbà pé ètò tó máa ń ṣe dára. Ìtàn ọ̀hún sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ ìdílé tí Jésù ti wá jẹ Jèhófà lógún. Ó jẹ́ ìtàn tó wọni lọ́kàn nípa nǹkan ìbànújẹ́ tó ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé kan àti bí ìbànújẹ́ náà ṣe dayọ̀. Gbogbo àkọsílẹ̀ wọ̀nyí àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn la óò rí nínú ìwé kan tó wà nínú Bíbélì tá à ń pè ní Rúùtù.
Nǹkan bí ọdún mọ́kànlá làwọn ohun tó wà nínú ìwé Rúùtù fi ṣẹlẹ̀ “ní àwọn ọjọ́ tí àwọn onídàájọ́ ń ṣe ìdájọ́” ní Ísírẹ́lì. (Rúùtù 1:1) Ó ní láti jẹ́ pé kò pẹ́ sígbà táwọn onídàájọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèdájọ́ ní Ísírẹ́lì ni ohun tó wà nínú ìwé Rúùtù ṣẹlẹ̀. Ìdí èyí ni pé, ọmọ Ráhábù, obìnrin ìgbà ayé Jóṣúà, ni Bóásì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ìwé Rúùtù sọ̀rọ̀ rẹ̀. (Jóṣúà 2:1, 2; Rúùtù 2:1; Mátíù 1:5) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Sámúẹ́lì ló kọ ìwé Rúùtù ní ọdún 1090 ṣáájú Sànmánì Tiwa. Nínú Bíbélì, ìwé Rúùtù nìkan là ń fi orúkọ obìnrin tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì pè. Ọ̀rọ̀ tó wà nínú rẹ̀ “yè, ó sì ń sa agbára.”—Hébérù 4:12.
“IBI TÍ O BÁ LỌ NI ÈMI YÓÒ LỌ”
Nígbà tí Náómì àti Rúùtù dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, wọ́n di ìran àpéwò fún gbogbo aráàlú náà. Àwọn obìnrin ìlú náà bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè pé: “Ṣé Náómì nìyí?” Náómì wá dá wọn lóhùn pé: “Ẹ má pè mí ní Náómì. Márà ni kí ẹ máa pè mí, nítorí Olódùmarè ti mú kí ó korò gan-an fún mi. Mo kún nígbà tí mo lọ, ní ọwọ́ òfo sì ni Jèhófà mú kí n padà.”—Rúùtù 1:19-21.
Ìyàn kan tó mú ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì ló mú kí ìdílé Náómì gbéra láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, tí wọ́n sì forí lé Móábù. Bí Náómì ṣe “kún” nígbà tó lọ sí Móábù ni pé, ó ní ọkọ àti ọmọkùnrin méjì. Àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n fìdí kalẹ̀ sí Móábù ni ọkọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Elimélékì kú. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ọmọkùnrin Náómì méjèèjì gbé àwọn ọmọbìnrin Móábù tórúkọ wọn ń jẹ́ Ópà àti Rúùtù níyàwó. Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá, àwọn ọmọkùnrin Náómì méjèèjì náà tún kú láìbímọ. Bí Náómì, Ópà àti Rúùtù ṣe di opó nìyẹn. Nígbà tí Náómì pinnu pé òun fẹ́ padà sí ilẹ̀ Júdà, àwọn aya ọmọ rẹ̀ méjèèjì tẹ̀ lé e. Bí wọ́n ṣe ń lọ, Náómì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n padà sí Móábù kí wọ́n sì wá ọkọ fẹ́ láàárín àwọn èèyàn wọn. Ópà gbà, ó sì padà. Àmọ́ Rúùtù fà mọ́ Náómì ó sì sọ pé: “Ibi tí o bá lọ ni èmi yóò lọ, ibi tí o bá sì sùn mọ́jú ni èmi yóò sùn mọ́jú. Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi.”—Rúùtù 1:16.
Ìgbà tí ìkórè ọkà bálì bẹ̀rẹ̀ ni àwọn opó méjì yìí, Náómì àti Rúùtù, dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Rúùtù lo àǹfààní ètò kan tó wà nínú òfin Ọlọ́run, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pèéṣẹ́ ní oko ọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bóásì. Àgbàlagbà lọkùnrin yìí, Júù ni, ó sì jẹ́ ìbátan Elimélékì. Rúùtù rí ojúure Bóásì ó sì ń pèéṣẹ́ nínú oko rẹ̀ “títí di ìgbà tí ìkórè ọkà bálì àti ìkórè àlìkámà fi wá sí òpin.”—Rúùtù 2:23.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
1:8—Kí nìdí tí Náómì fi sọ fáwọn aya ọmọ rẹ̀ pé kí ‘olúkúlùkù wọn padà sí ilé ìyá rẹ̀’ dípò tí ì bá fi sọ fún wọn pé kí wọ́n padà sí ilé bàbá wọn? Bíbélì ò sọ bóyá bàbá Ópà ṣì ń bẹ láàyè nígbà yẹn tàbí ó ti kú. Àmọ́, bàbá Rúùtù ṣì ń bẹ lókè èèpẹ̀. (Rúùtù 2:11) Ó lè jẹ́ pé ohun tí Náómì rò tó fi sọ pé kí wọ́n padà sí ilé ìyá wọn ni pé ìyẹn á rán wọn létí ìkẹ́ tí ọmọ máa ń gbádùn lọ́dọ̀ ìyá tó bí i lọ́mọ. Èyí máa tù wọ́n nínú nítorí pé inú wọn bà jẹ́ gan-an bí wọ́n ṣe fẹ́ fi ìyá ọkọ wọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sílẹ̀. Bó ṣe jẹ́ pé ilé ìyá wọn ni Náómì sọ pé kí wọ́n padà sí tún fi hàn pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ilé ìyá Rúùtù àti ti ìyá Ópà jẹ́ ilé téèyàn pọ̀ sí, tí kò rí bí ilé Náómì.
1:13, 21—Ṣé Jèhófà ló fa àjálù tó mú kí ayé Náómì korò? Rárá o. Náómì ò fẹ̀sùn ibi kan Ọlọ́run o. Àmọ́ ó rò pé Ọlọ́run bínú sí òun ni nítorí gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i yẹn. Inú rẹ̀ bà jẹ́, gbogbo nǹkan sì tojú sú u. Síwájú sí i, láyé ìgbà yẹn, ìbùkún Ọlọ́run ni wọ́n kà á sí tóbìnrin bá rọ́mọ bí, ègún sì ni tó bá yàgàn. Nítorí pé Náómì kò ní ọmọ-ọmọ tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì sì ti kú, ó ṣeé ṣe kó rò pé òun ò jẹ̀bi tóun bá rò pé Jèhófà ló mú kí ògo òun wọmi.
2:12—Kí ni “owó ọ̀yà pípé” tí Jèhófà fún Rúùtù? Rúùtù láǹfààní láti di ọ̀kan lára àwọn tí Jésù Kristi wá láti ìlà ìdílé wọn, ìyẹn ìlà ìdílé tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìtàn.—Rúùtù 4:13-17; Mátíù 1:5, 16.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
1:8; 2:20. Bí nǹkan ìbànújẹ́ tó ṣẹlẹ̀ sí Náómì ṣe pọ̀ tó yẹn, ó ṣì gbọ́kàn lé inú rere onífẹ̀ẹ́ Jèhófà pé kò ní fi òun sílẹ̀. Ó yẹ kí àwa náà gbọ́kàn lé inú rere onífẹ̀ẹ́ Jèhófà, pàápàá nígbà tá a bá rí àdánwò.
1:9. Kò yẹ kí ilé wulẹ̀ jẹ́ ibi tí bàbá, ìyá àtàwọn ọmọ ti ń jẹun tí wọ́n sì ń sùn lásán. Ó yẹ kó jẹ́ ibi tí àlàáfíà wà, kó jẹ́ ibi tí wọ́n ti máa ń rí ìsinmi àti ìtura.
1:14-16. Ópà “padà sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ àti àwọn ọlọ́run rẹ̀,” àmọ́ Rúùtù kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ó yááfì ìgbádùn àti ìfọ̀kànbalẹ̀ tó wà ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, kò sì fi Jèhófà sílẹ̀. Tá a bá ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí Ọlọ́run tá a sì jẹ́ ẹni tó ń fi tàwọn ẹlòmíràn ṣáájú tara wa, èyí ò ní jẹ́ ká mọ tara wa nìkan, a ò sì ní “fà sẹ́yìn sí ìparun.”—Hébérù 10:39.
2:2. Rúùtù fẹ́ láti lo àǹfààní ètò pípèéṣẹ́ tó wà fún àwọn tó wá láti ilẹ̀ òkèèrè àtàwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́. Èyí fi hàn pé ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Bákan náà, ó yẹ kí Kristẹni kan fi ìrẹ̀lẹ̀ gba ìrànwọ́ táwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ bá ṣe fún un tàbí ìrànwọ́ tó lẹ́tọ̀ọ́ sí tí ìjọba orílẹ̀-èdè rẹ̀ bá ṣe.
2:7. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Rúùtù lẹ́tọ̀ọ́ láti pèéṣẹ́, ó kọ́kọ́ tọrọ àyè. (Léfítíkù 19:9, 10) Ìyẹn fi hàn pé ó jẹ́ ọlọ́kàn tútù. Ọlọgbọ́n ni wá tá a bá “wá ọkàn-tútù,” nítorí pé “àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sefanáyà 2:3; Sáàmù 37:11.
2:11. Rúùtù fi hàn pé òun kì í wulẹ̀ẹ́ ṣe ìbátan Náómì. Ó fi hàn pé ojúlówó ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni òun. (Òwe 17:17) Àjọṣe wọn lágbára gan-an nítorí pé orí àwọn ànímọ́ tó dára ló dá lé, ìyẹn àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, dídúró-tini, àánú, inú rere, àti fífi tàwọn ẹlòmíràn ṣáájú tara ẹni. Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, Rúùtù àti Náómì jẹ́ kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn dá lé orí ìfẹ́ tí wọ́n ní láti sin Jèhófà àti ìfẹ́ tí wọ́n ní láti wà láàárín àwọn olùjọsìn rẹ̀. Àwa náà láǹfààní láti bá àwọn olùjọsìn tòótọ́ dọ́rẹ̀ẹ́, ká jọ jẹ́ ojúlówó ọ̀rẹ́.
2:15-17. Kódà, nígbà tí Bóásì ṣèrànwọ́ tó lè mú kí Rúùtù dín iṣẹ́ pípèéṣẹ́ tó ń ṣe kù, ‘Rúùtù ṣì ń bá a lọ láti pèéṣẹ́ nínú pápá títí di ìrọ̀lẹ́.’ Òṣìṣẹ́ kára ni Rúùtù. Ó yẹ kí wọ́n mọ Kristẹni sí ẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára.
2:19-22. Náómì àti Rúùtù jọ máa ń gbádùn ìjíròrò alárinrin ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́. Náómì á máa bi Rúùtù nípa iṣẹ́ tó ṣe lọ́jọ́ náà, oníkálukú á sì máa sọ èrò rẹ̀ ní fàlàlà. Ǹjẹ́ kì í ṣe bó ṣe yẹ kí ọ̀rọ̀ rí nínú ìdílé Kristẹni nìyẹn?
2:22, 23. Rúùtù ò ṣe bíi ti Dínà ọmọbìnrin Jékọ́bù, àwọn olùjọ́sìn Jèhófà ló ń bá kẹ́gbẹ́. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ tó yẹ ká tẹ̀ lé nìyẹn!—Jẹ́nẹ́sísì 34:1, 2; 1 Kọ́ríńtì 15:33.
NÁÓMÌ PADÀ “KÚN”
Náómì ti dàgbà kọjá ẹni tó lè bímọ. Nítorí náà ó ní kí Rúùtù rọ́pò òun nípa ṣíṣe ìgbéyàwó tí wọ́n máa ń ṣe nípasẹ̀ ìtúnnirà, ìyẹn ni pé kí ẹnì kan ṣú Rúùtù lópó dípò òun. Rúùtù tẹ̀ lé ohun tí Náómì kọ́ ọ pé kó ṣe, ó sì sọ fún Bóásì pé kó tún òun rà. Bóásì gbà pé òun á ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ìbátan kan wà tó sún mọ́ wọn ju Bóásì lọ tó yẹ kí wọ́n kọ́kọ́ fún láǹfààní náà.
Kíá ni Bóásì ti wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ náà. Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, ó kó àgbà ọkùnrin Bẹ́tílẹ́hẹ́mù mẹ́wàá jọ. Níṣojú wọn, ó bi ìbátan ọ̀hún pé ṣé á fẹ́ láti ṣe ìtúnnirà náà. Ọkùnrin náà sọ pé òun ò lè ṣe é. Nítorí náà, Bóásì ṣe ìtúnnirà náà ó sì gbé Rúùtù níyàwó. Rúùtù bí ọmọkùnrin kan fún Bóásì, wọ́n sì sọ ọ́ ní Óbédì. Óbédì yìí ni bàbá-bàbá Ọba Dáfídì. Àwọn obìnrin Bẹ́tílẹ́hẹ́mù wá sọ fún Náómì pé: ‘Ìbùkún ni fún Jèhófà. . . . Ó ti di olùmú ọkàn rẹ padà bọ̀ sípò àti ẹni tí yóò ṣe ìtọ́jú rẹ ní ọjọ́ ogbó, nítorí aya ọmọkùnrin rẹ tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ ní ti gidi, ẹni tí ó sàn fún ọ ju ọmọkùnrin méje lọ, ti bímọ.’ (Rúùtù 4:14, 15) Nípa báyìí, obìnrin tó padà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù “ní ọwọ́ òfo” tún padà “kún”!—Rúùtù 1:21.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
3:11—Kí ló sọ Rúùtù dẹni tí wọ́n mọ̀ sí “obìnrin títayọ lọ́lá”? Kì í ṣe “irun dídì,” bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe ‘àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà tàbí àwọn ẹ̀wù àwọ̀lékè’ ni Rúùtù wọ̀ tó jẹ́ káwọn èèyàn máa gbóṣùbà fún un. Àmọ́, ó jẹ́ nítorí ‘irú ẹni tó jẹ́ ní ọkàn,’ ìyẹn ẹ̀mí ìdúrótini àti ìfẹ́ tó ní, bó ṣe jẹ́ ẹlẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ àti ọlọ́kàn tútù, tó tún jẹ́ òṣìṣẹ́ kára tó sì máa ń fi tẹlòmíràn ṣáájú tara rẹ̀. Obìnrin èyíkéyìí tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run tó bá fẹ́ ní orúkọ rere bíi tí Rúùtù gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti ní àwọn ànímọ́ wọ̀nyí.—1 Pétérù 3:3, 4; Òwe 31:28-31.
3:14—Kí nìdí tí Rúùtù àti Bóásì fi dìde kí ọ̀yẹ̀ tó là? Kì í ṣe nítorí pé wọ́n ti hùwà àìmọ́ ní òru tí wọn ò sì fẹ́ kí àṣírí tú. Ó dájú pé ohun tí Rúùtù ṣe lóru ọjọ́ yẹn kò ta ko ohun tí òfin là sílẹ̀ nípa ohun tí obìnrin lè ṣe tó bá fẹ́ kí wọ́n fún òun lẹ́tọ̀ọ́ òun nípa ṣíṣú òun lópó. Ohun tí Náómì sì kọ́ ọ pé kó ṣe ló ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, èsì tí Bóásì fún Rúùtù fi hàn pé kò rí ohun tó burú nínú nǹkan tí Rúùtù ṣe. (Rúùtù 3:2-13) Ó hàn gbangba pé ìdí tí Bóásì àti Rúùtù fi tètè dìde kí ilẹ̀ tó mọ́ ni káwọn èèyàn má bàa máa sọ ìsọkúsọ kiri.
3:15—Kí ni fífún tí Bóásì fún Rúùtù ní òṣùwọ̀n ọkà bálì mẹ́fà fi hàn? Ó ṣeé ṣe kó fi hàn pé ọjọ́ tí Rúùtù máa sinmi ti sún mọ́lé, nítorí pé ọjọ́ mẹ́fà ni wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n sì máa ń sinmi lọ́jọ́ keje. Bóásì fẹ́ rí i dájú pé Rúùtù ní “ibi ìsinmi” ní ilé ọkọ rẹ̀. (Rúùtù 1:9; 3:1) Ó tún lè fi hàn pé Rúùtù ò lè rù ju òṣùwọ̀n ọkà bálì mẹ́fà lọ.
3:16—Kí nìdí tí Náómì fi bi Rúùtù pé, “ta ni ọ́, ọmọbìnrin mi?” Ṣé kò mọ̀ pé òun ló wọlé ni? Ó lè jẹ́ pé kò mọ̀ pé òun ló wọlé, nítorí pé ó ṣeé ṣe kí ọ̀yẹ̀ máà tíì là nígbà tó padà délé. Ó sì tún lè jẹ́ pé ńṣe ni Náómì fẹ́ mọ̀ bóyá Rúùtù ti di obìnrin tuntun, ìyẹn ni pé ó fẹ́ láti mọ̀ bóyá ẹni tó máa tún un rà ti gbà láti ṣú u lópó.
4:6—Lọ́nà wo ni olùtúnnirà fi lè “run” ogún rẹ̀ tó bá ṣe ìtúnnirà? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, tẹ́nì kan tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di akúùṣẹ́ bá ti ta ilẹ̀ tó jogún, olùtúnnirà kan yóò ní láti bá a ra ilẹ̀ náà padà ní iye owó tó bá jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú iye ọdún tó kù kí wọ́n fi dé ọdún Júbílì tó máa tẹ̀ lé e. (Léfítíkù 25:25-27) Tí olùtúnnirà náà bá rà á, èyí á dín àwọn ohun tó ní kù. Yàtọ̀ síyẹn, kì í ṣe ìbátan olùtúnnirà náà ló máa jogún ilẹ̀ tó bá rà yìí, ọmọ tí Rúùtù bá bí ló máa jogún rẹ̀.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
3:12; 4:1-6. Bóásì tẹ̀ lé ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ kínníkínní. Ǹjẹ́ àwa náà ń fi tọkàntọkàn tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú ètò àjọ Jèhófà?—1 Kọ́ríńtì 14:40.
3:18. Náómì fọkàn tán Bóásì. Ǹjẹ́ kò yẹ káwa náà máa fọkàn tán àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa? Rúùtù gbà kí ọkùnrin tí kò mọ̀ rí ṣú òun lópó, ọkùnrin tó jẹ́ pé olùtúnnirà nìkan la mọ̀ ọ́ sí nínú Bíbélì. (Rúùtù 4:1) Kí nìdí tó fi gbà? Ìdí ni pé ó gbà pé ètò tí Ọlọ́run ṣe dára. Ṣé àwa náà gbà bẹ́ẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń wá ẹni tá a fẹ́ fẹ́, ṣé a máa ń gba ìmọ̀ràn tó sọ pé ká gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa”?—1 Kọ́ríńtì 7:39.
4:13-16. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ni Rúùtù ní yìí, ẹni tó jẹ́ pé ará Móábù ni, tó sì jẹ́ pé ọlọ́run tí wọ́n ń pè ní Kémóṣì ló ń sìn tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀! Èyí fi hàn pé òótọ́ ni ìlànà tó sọ pé: “Kò sinmi lé ẹni tí ń fẹ́ tàbí lé ẹni tí ń sáré, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń ṣe àánú.”—Róòmù 9:16.
Ọlọ́run “Lè Gbé Yín Ga ní Àkókò Yíyẹ”
Ìwé Rúùtù fi hàn pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó ní ìfẹ́ tí kò lẹ́gbẹ́, tó máa ń ṣe nǹkan nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ sí i. (2 Kíróníkà 16:9) Tá a bá ronú nípa èrè tí Ọlọ́run fún Rúùtù, àá rí i pé yóò fún àwa náà lérè tá a bá fi ìgbàgbọ́ tó lágbára gbọ́kàn lé e, tá a gbà gbọ́ láìkù síbì kan “pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.”—Hébérù 11:6.
Rúùtù, Náómì àti Bóásì gbà láìkù síbì kan pé ètò tí Jèhófà ṣe dára, ó sì yọrí sí ìbùkún fún wọn. Bákan náà, “Ọlọ́run ń mú kí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ fún ire àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí í ṣe àwọn tí a pè ní ìbámu pẹ̀lú ète rẹ̀.” (Róòmù 8:28) Nítorí náà, ẹ já ká fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pétérù sọ́kàn, pé: “Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run, kí ó lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ; bí ẹ ti ń kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.”—1 Pétérù 5:6, 7.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ǹjé o mọ ìdí tí Rúùtù kò fi fi Náómì sílẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Kí ló sọ Rúùtù dẹni táwọn èèyàn mọ̀ sí “obìnrin títayọ lọ́lá”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Kí ni “owó ọ̀yà pípé” tí Jèhófà fún Rúùtù?