Bíbélì Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́ Láti Rí Ayọ̀
BÓ TILẸ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé ìṣègùn, síbẹ̀ ó sọ̀rọ̀ lórí ipa tí èrò ọkàn èèyàn lè ní lórí ọpọlọ àti ìlera rẹ̀, ì báà jẹ́ èrò tó dára tàbí èyí tí kò dára. Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí tí ìdààmú bá ń mú kí àwọn egungun gbẹ.” Ó tún sọ síwájú sí i pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” (Òwe 17:22; 24:10) Ìrẹ̀wẹ̀sì lè tán wa lókun, ó lè sọ wá di aláìlera, kó sì wá tipa bẹ́ẹ̀ sọ wá dẹni tó lè tètè kó síṣòro tá ò sì ní fẹ́ ṣe ohunkóhun nípa rẹ̀ tàbí ká wá ìrànlọ́wọ́.
Ìrẹ̀wẹ̀sì tún lè nípa lórí ẹnì kan nípa tẹ̀mí. Àwọn èèyàn tó gbà pé àwọn ò já mọ́ nǹkankan sábà máa ń rò pé àwọn ò lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́, àti pé Ọlọ́run ò lè bù kún àwọn. Simone tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú ò gbà pé òun lè jẹ́ “ẹni tí Ọlọ́run máa fi ojú rere wò.” Àmọ́, nígbà tá a wo inú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a rí i pé Ọlọ́run ń fojú tó dáa wo àwọn tó ń sapá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
Ọlọ́run Bìkítà fún Wa
Bíbélì sọ fún wa pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.” Ọlọ́run kì í fojú tẹ́ńbẹ́lú “ọkàn-àyà tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀,” àmọ́ ó ṣèlérí “láti mú ẹ̀mí àwọn ẹni rírẹlẹ̀ sọ jí àti láti mú ọkàn-àyà àwọn tí a tẹ̀ rẹ́ sọ jí.”—Sáàmù 34:18; 51:17; Aísáyà 57:15.
Nígbà kan, Jésù, Ọmọ Ọlọ́run rí i pé ó ṣe pàtàkì láti jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun mọ̀ pé Ọlọ́run máa ń rí ànímọ́ rere táwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ ní. Ó lo àpèjúwe kan, ó sọ pé Ọlọ́run máa ń rí ológoṣẹ́ kan tó bá jábọ́ sórí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì rèé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ò ka ìyẹn sí nǹkan bàbàrà. Ó tún sọ pé kò sóhun tí Ọlọ́run ò mọ̀ nípa àwa èèyàn, kódà ó mọ iye irun orí wa. Jésù parí àpèjúwe rẹ̀ yìí nípa sísọ pé: “Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” (Mátíù 10:29-31)a Jésù fi hàn pé ohun yòówù táwọn èèyàn ì báà máa rò nípa ara wọn, àwọn tó nígbàgbọ́ níye lórí gan-an lójú Ọlọ́run. Kódà, àpọ́sítélì Pétérù rán wa létí pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.
Má Ṣe Jọ Ara Rẹ Lójú, Má sì Rora Rẹ Pin
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká má ṣe jọ ara wa lójú. Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “Nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fi fún mi, mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n láti ronú kí ó bàa lè ní èrò inú yíyèkooro, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pín ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún un.”—Róòmù 12:3.
Dájúdájú, a ò ní fẹ́ ro ara wa ju bó ti yẹ lọ débi tá a ó fi di agbéraga. Bẹ́ẹ̀ la ò tún ní rora wa pin pé a ò já mọ́ nǹkan kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa wo ara wa bá a ṣe rí gan-an, ìyẹn ni pé ká mọ ibi tágbára wa dé ká sì mọ̀wọ̀n ara wa. Ọ̀nà tí arábìnrin kan gbà sọ̀ ọ́ nìyí, ó ní: “Mi ò kì í ṣe èèyàn burúkú; bẹ́ẹ̀ ni mi ò sì dára ju àwọn èèyàn tó kù lọ. Mo láwọn ànímọ́ tó dára mo sì láwọn ànímọ́ tí ò dáa, bí gbogbo èèyàn tó kù sì ṣe rí nìyẹn.”
Ká sòótọ́, ẹnú dùn ròfọ́ lọ̀rọ̀ kéèyàn má ro ara rẹ̀ pin, kó má sì tún jọ ara rẹ̀ lójú. Ó lè gba ọ̀pọ̀ ìsapá ká tó lè mú èrò òdì tá a ti ní nípa ara wa kúrò, nítorí pé ó lè ti pẹ́ gan-an tá a ti ní irú èrò bẹ́ẹ̀ nípa ara wa. Síbẹ̀síbẹ̀, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, a lè yí èrò wa padà, kódà a lè yí ojú tá a fi ń wo àwọn nǹkan padà. Ní tòótọ́, ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká ṣe gan-an nìyẹn. A kà á pé: “Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà yín àtijọ́ ṣe déédéé, tí a sì ń sọ di ìbàjẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ atannijẹ; ṣùgbọ́n kí ẹ di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú yín ṣiṣẹ́, kí ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.”—Éfésù 4:22-24.
Tá a bá ń sa gbogbo ipá wa láti sọ ‘ipá tí ń mú èrò inú wa ṣiṣẹ́’ dọ̀tun, ìyẹn ohun tí ọkàn wa máa ń fà sí jù lọ, a lè yí èrò òdì tá à ń ní nípa ara wa padà , ká sì máa ronú lọ́nà tó dáa. Lena tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú yẹn wá mọ̀ nígbà tó yá pé ká ni òun ò mú èrò pé kó sẹ́ni tó nífẹ̀ẹ́ òun àti pé kò sẹ́ni tó lè ran òun lọ́wọ́ kúrò lọ́kàn ni, kò sóhun tí ì bá yí èrò òdì tóun máa ń ní nípa ara òun tẹ́lẹ̀ padà. Àwọn ìlànà gbígbéṣẹ́ wo ló wà nínú Bíbélì tó ran Lena, Simone àtàwọn mìíràn lọ́wọ́ láti ṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀?
Àwọn Ìlànà Bíbélì Tó Ń Jẹ́ Kéèyàn Túbọ̀ Láyọ̀
“Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.” (Sáàmù 55:22) Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àdúrà lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ojúlówó ayọ̀. Simone sọ pé: “Ìgbàkígbà tí ọkàn mi bá rẹ̀wẹ̀sì, Jèhófà ni mo máa ń yíjú sí pé kó ràn mí lọ́wọ́. Kò tíì sípò tí mo bára mi tí Ọlọ́run ò fún mi lókun àti ìtọ́sọ́nà rẹ̀.” Nígbà tí onísáàmù náà rọ̀ wá pé ká ju ẹrù ìnira wa sọ́dọ̀ Jèhófà, ńṣe ló ń rán wa létí pé kì í ṣe pé Jèhófà bìkítà nípa wa nìkan ni, àmọ́ ó tún kà wá sẹ́ni tóun lè ràn lọ́wọ́ tóun sì lè tì lẹ́yìn. Ní alẹ́ ọjọ́ Ìrékọjá ti ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, inú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bà jẹ́ nítorí pé Jésù sọ pé òun ò ní pẹ́ fi wọ́n sílẹ̀. Jésù rọ̀ wọ́n láti gbàdúrà sí Baba, ó sì wá fi kún un pé: “Ẹ béèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí a lè sọ ìdùnnú yín di kíkún.”—Jòhánù 16:23, 24.
“Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jésù fi kọ́ni, fífúnni ní nǹkan jẹ́ ọ̀nà pàtàkì láti rí ojúlówó ayọ̀ nígbèésí ayé ẹni. Fífi ọ̀rọ̀ Bíbélì yìí sọ́kàn ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti bójú tó ohun táwọn ẹlòmíì nílò dípò ká máa ronú nípa àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó wa. Nígbà tá a bá ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ tá a sì rí i bí wọ́n ṣe mọrírì rẹ̀ tó, a ó ní èrò tó dára nípa ara wa. Lena wá rí i pé sísọ ìhìn rere inú Bíbélì fáwọn èèyàn ní gbogbo ìgbà ran òun lọ́wọ́ lọ́nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ó sọ pé: “Lákọ̀ọ́kọ́, ó jẹ́ kí n ní irú ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tí Jésù sọ. Èkejì, àwọn èèyàn máa ń fetí sílẹ̀ gan-an, èyí sì ń fún mi láyọ̀.” Tá a bá ń yọ̀ǹda ara wa tinútinú, a ó rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Òwe 11:25 tó sọ pé: “Ẹni tí ó sì ń bomi rin àwọn ẹlòmíràn ní fàlàlà, a ó bomi rin òun náà ní fàlàlà.”
“Búburú ni gbogbo ọjọ́ ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́; ṣùgbọ́n ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ yá gágá a máa jẹ àsè nígbà gbogbo.” (Òwe 15:15) Ohun tó bá wu ẹnì kan ló lè rò nípa ara rẹ̀ àti nípa ipò tó wà. A lè jẹ́ ẹni tí kì í ro nǹkan tó dáa nípa ara rẹ̀, tọ́kàn rẹ̀ sì máa ń bàjẹ́ ṣáá, a sì tún lè máa ní èrò rere nípa ara wa, kí ‘ọkàn wa máa yá gágá,’ kínú wa sì máa dùn bíi pé a wà níbi àsè. Simone sọ pé: “Mo máa ń sa gbogbo ipá mi láti rí i pé mò ń ní èrò rere lọ́kàn nígbà gbogbo. Mo máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, mo tún ń jáde òde ẹ̀rí déédéé, mo sì ń gbàdúrà ní gbogbo ìgbà. Mo tún gbìyànjú láti rìn mọ́ àwọn èèyàn tó máa ń ní èrò tó dáa tínú wọn sì máa ń dùn, mo sì tún ń gbìyànjú láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ pẹ̀lú.” Irú ọkàn tó dáa bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kéèyàn ní ojúlówó ayọ̀, kódà Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ máa yọ̀ nínú Jèhófà, kí ẹ sì kún fún ìdùnnú, ẹ̀yin olódodo; kí ẹ sì fi ìdùnnú ké jáde, gbogbo ẹ̀yin adúróṣánṣán ní ọkàn-àyà.”—Sáàmù 32:11.
“Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Fífinú han ẹnì kan tó fẹ́ràn wa tàbí ẹnì kan tó ṣeé fọkàn tán tó lè gbà wá nímọ̀ràn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti borí èrò òdì ká sì mú un kúrò lọ́kàn wa pátápátá kó tó ṣàkóbá fún wa. Bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa ní èrò tó dáa tó sì bójú mu. Simone sọ pé: “Sísọ ohun tó wà lọ́kàn mi jáde ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Ó yẹ kéèyàn máa sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún ẹlòmíràn. Lọ́pọ̀ ìgbà, sísọ ọ́ jáde nìkan ti tó láti yanjú ìṣòro náà.” Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí i pé òótọ́ ni òwe tó sọ pé: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.”—Òwe 12:25.
Ohun Tó O Lè Ṣe
A ti gbé díẹ̀ lára ọ̀pọ̀ ìlànà tó gbéṣẹ́ tó sì dára gan-an tó wà nínú Bíbélì yẹ̀ wò, èyí tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí èrò òdì ká sì ní ojúlówó ayọ̀. Tó o bá wà lára àwọn tó ń làkàkà láti borí èrò pé kò sí nǹkan táwọn mọ̀ ọ́n ṣe, a gbà ọ́ níyànjú láti túbọ̀ máa ka Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. Kọ́ bó o ṣe máa ní èrò tó dáa tó sì bójú mu nípa ara rẹ àti nípa àjọṣe àárín ìwọ àti Ọlọ́run. Ó dá wa lójú pé pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, yóò ṣeé ṣe fún ọ láti rí ojúlówó ayọ̀ nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ lójú ìwé 22 àti 23.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, a ó láyọ̀