Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Àwọn Ọba Kejì
IBI tí ìwé Àwọn Ọba Kìíní nínú Bíbélì parí ìtàn rẹ̀ sí ni ìwé Àwọn Ọba Kejì ti bẹ̀rẹ̀ tirẹ̀. Ó jẹ́ ìtàn nípa àwọn ọba mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, méjìlá wá látinú ìjọba Ísírẹ́lì níhà àríwá, àwọn mẹ́tàdínlógún sì wá látinú ìjọba Júdà níhà gúúsù. Ìwé Àwọn Ọba Kejì tún sọ nípa iṣẹ́ tí wòlíì Èlíjà, Èlíṣà àti Aísáyà ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò to àwọn ìtàn náà bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra, síbẹ̀ àkọsílẹ̀ náà tún sọ ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n pa ìlú Samáríà àti Jerúsálẹ́mù run. Lápapọ̀, ìwé Àwọn Ọba kejì sọ ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín ọ̀ọ́dúnrún ó lé ogójì [340] ọdún, ìyẹn láti ọdún 920 ṣáájú Sànmánì Kristẹni títí dé ọdún 580 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, lákòókò tí wòlíì Jeremáyà parí kíkọ ìwé yìí.
Báwo ni ìwé Àwọn Ọba Kejì ti ṣe pàtàkì fún wa tó? Ẹ̀kọ́ wo ló kọ́ wa nípa Jèhófà àti bó ṣe bá àwọn èèyàn lò? Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ìṣe àwọn ọba, àwọn wòlíì, àtàwọn mìíràn tí ìwé náà mẹ́nu kàn? Ẹ jẹ́ ká wo ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ látinú ìwé Àwọn Ọba Kejì.
ÈLÍṢÀ GBAPÒ ÈLÍJÀ
Ahasáyà ọba Ísírẹ́lì ṣubú nílé rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàìsàn. Wòlíì Élíjà sọ fún un pé kíkú ni yóò kú. Ahasáyà kú lóòtọ́, Jèhórámù arakùnrin rẹ̀ sì gorí ìtẹ́. Jèhóṣáfátì ni ọba nílẹ̀ Júdà ní gbogbo àkókò yẹn. Ìjì ẹlẹ́fùúùfù gbé Èlíjà lọ, Èlíṣà, tó jẹ́ igbá kejì rẹ̀ sì di wòlíì. Èlíṣà ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu láàárín nǹkan bí ọgọ́ta ọdún tó fi wà lẹ́nu iṣẹ́ náà.—Wo àpótí tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Tí Èlíṣà Ṣe.”
Nígbà tí ọba àwọn ará Móábù ṣọ̀tẹ̀ sí Ísírẹ́lì, Jèhórámù, Jèhóṣáfátì, àti ọba Édómù lọ gbógun bá a. Wọ́n ṣẹ́gun nítorí ìṣòtítọ́ Jèhóṣáfátì. Lẹ́yìn ìyẹn, ọba Síríà pinnu láti lọ kógun bá Ísírẹ́lì lójijì. Àmọ́, Èlíṣà tú àṣírí ohun tó fẹ́ ṣe yìí. Ọba Síríà bínú gan-an, ó sì rán “àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun àti ẹgbẹ́ ológun tí ó bùáyà” pé kí wọ́n lọ mú Èlíṣà wá. (2 Àwọn Ọba 6:14) Èlíṣà ṣe iṣẹ́ ìyanu méjì níbẹ̀, àwọn ará Síríà sì padà síbi tí wọ́n ti wá láìfa wàhálà kankan. Nígbà tó yá, Bẹni-Hádádì ọba Síríà tún fi ogun yí Samáríà ká. Èyí sì yọrí sí ìyàn líle koko, àmọ́ Èlíṣà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ìyàn náà yóò kásẹ̀ nílẹ̀.
Láìpẹ́ sí àkókò yẹn, Èlíṣà lọ sí Damásíkù. Bẹni-Hádádì Ọba wà lórí àìsàn lákòókò yẹn, ó sì rán Hásáélì pé kó lọ béèrè bóyá àìsàn náà máa pa òun. Èlíṣà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ọba náà yóò kú, Hásáélì yóò sì jọba nípò rẹ̀. Ọjọ́ kejì gan-an ni Hásáélì da “aṣọ ìtẹ́lébùsùn” tí omi rin bo ọba náà lójú, ó sì kú, Hásáélì sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀. (2 Àwọn Ọba 8:1) Jèhórámù ọmọ Jèhóṣáfátì di ọba ní Júdà, Ahasáyà ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.—Wo àpótí tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Àwọn Ọba Júdà àti ti Ísírẹ́lì.”
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ
2:9—Kí nìdí tí Èlíṣà fi béèrè “ipa méjì” nínú ẹ̀mí Èlíjà? Kí Èlíṣà lè ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì ní Ísírẹ́lì, ó ní láti ní irú ẹ̀mí tí Èlíjà ní, ìyẹn ẹ̀mí ìgboyà àti àìṣojo. Ìdí nìyí tí Èlíṣà fi béèrè fún ìlọ́po méjì ẹ̀mí Èlíjà. Èlíjà yan Èlíṣà láti rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì lẹ́yìn tó ti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ fún ọdún mẹ́fà gbáko. Nípa bẹ́ẹ̀, Èlíṣà ka Èlíjà sí bàbá rẹ̀ nípa tẹ̀mí, bí àkọ́bí ọmọ nípa tẹ̀mí ni Èlíṣà sì ṣe rí sí Èlíjà. (1 Àwọn Ọba 19:19-21; 2 Àwọn Ọba 2:12) Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí ọmọ ṣe máa ń gba ipa méjì nínú ogún bàbá rẹ̀ náà ni Èlíṣà ṣe béèrè fún ipa méjì nínú ogún tẹ̀mí tí Èlíjà ní, ó sì rí i gbà.
2:11—Kí ni “ọ̀run” tí ‘Èlíjà gòkè lọ nínú ìjì ẹlẹ́fùúùfù’? Àwọn ọ̀run yìí kì í ṣe ibi kan tó jìnnà ní ìsálú ọ̀run bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ibi tẹ̀mí tí Ọlọ́run àtàwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ọmọ rẹ̀ ń gbé. (Diutarónómì 4:19; Sáàmù 11:4; Mátíù 6:9; 18:10) Inú òfuurufú ni “ọ̀run” tí Èlíjà lọ. (Sáàmù 78:26; Mátíù 6:26) Bí kẹ̀kẹ́ oníná náà ṣe gbé Èlíjà gba inú òfuurufú lọ, ó dájú pé apá ibòmíràn láyé ló gbé e lọ, ó sì wà níbẹ̀ fúngbà díẹ̀. Kódà, Èlíjà kọ lẹ́tà kan sí Jèhórámù ọba Júdà ní ọdún bíi mélòó kan lẹ́yìn àkókò yẹn.—2 Kíróníkà 21:1, 12-15.
5:15, 16—Kí nìdí tí Èlíṣà ò fi gba ẹ̀bùn tí Náámánì fún un? Èlíṣà kọ̀ láti gba ẹ̀bùn náà nítorí ó gbà pé agbára Jèhófà ló ṣe iṣẹ́ ìyanu tó mú Náámánì lára dá, kì í ṣe agbára òun. Kò gbà pé ó bójú mu kóun máa jèrè látinú iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn òun sí. Àwọn olùjọsìn tòótọ́ òde òní kì í ronú àtijèrè nǹkan tara látinú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ọ̀rọ̀ Jésù ni wọ́n máa ń fi sọ́kàn ní gbogbo ìgbà, èyí tó sọ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.”—Mátíù 10:8.
5:18, 19—Ṣé Náámánì ń tọrọ àforíjì nítorí pé ó máa ń lọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà ni? Ọba Síríà ti darúgbó, kò sì lágbára mọ́, nítorí náà ó ní láti fara ti Náámánì kó má bàa ṣubú. Nígbà tí ọba náà bá tẹrí ba láti jọ́sìn Rímónì, Náámánì náà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Náámánì wulẹ̀ ń tẹrí ba kí ọba tó fara tì í má bàa ṣubú ni kì í ṣe pé ó fẹ́ jọ́sìn. Náámánì wá ń bẹ Jèhófà pé kó darí ji òun nítorí iṣẹ́ tóun ń ṣe fún ọba yìí. Èlíṣà gbà pé òótọ́ lohun tí Náámánì sọ yìí, ó sì sọ fún un pé: “Máa lọ ní àlàáfíà.”
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:13, 14. Kíkẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹlòmíràn àti níní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ lè gba ẹ̀mí ẹni là.
2:2, 4, 6. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bí ọdún mẹ́fà ni Èlíṣà fi jẹ́ ìránṣẹ́ fún Èlíjà, síbẹ̀ ó kọ̀ jálẹ̀ pé òun kò ní fi wòlíì náà sílẹ̀. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ rere lèyí jẹ́ fún wa láti jẹ́ adúróṣinṣin àti ọ̀rẹ́ tó ṣeé fọkàn tán!—Òwe 18:24.
2:23, 24. Ó ní láti jẹ́ pé ohun tó mú káwọn ọmọ náà máa fi Èlíṣà ṣe yẹ̀yẹ́ ni rírí tí wọ́n rí i pé ọkùnrin kan tó párí lọ wọ ẹ̀wù tí Èlíjà fi ń ṣiṣẹ́ wòlíì. Àwọn ọmọdé náà mọ̀ pé aṣojú Jèhófà ni Èlíṣà, wọ́n ò sì fẹ́ rí i ní sàkání wọn rárá. Wọ́n sọ fún un pé “gòkè lọ,” ìyẹn ni pé, kó máa lọ sí Bẹ́tẹ́lì tàbí kí wọ́n gbé òun náà lọ sókè bíi ti Èlíjà. Ó hàn gbangba pé ńṣe làwọn ọmọ náà ń fi ẹ̀mí búburú táwọn òbí wọn ní hàn. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an káwọn òbí máa kọ́ àwọn ọmọ wọn láti máa bọ̀wọ̀ fáwọn aṣojú Ọlọ́run!
3:14, 18, 24. Àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà máa ń ṣẹ.
3:22. Oòrùn àárọ̀ tó tàn yòò ni ìtànṣán rẹ̀ mú kó dà bíi pé ẹ̀jẹ̀ ni omi náà, ìyẹn sì lè jẹ́ nítorí pé amọ̀ pupa wà lára erùpẹ̀ inú àwọn kòtò tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbẹ́ náà. Kò sí nǹkan tí Jèhófà ò lè lò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ.
4:8-11. Obìnrin ará Ṣúnémù kan rí i pé “ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run” ni Èlíṣà, ó sì fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ hàn sí i. Ǹjẹ́ kò yẹ káwa náà máa ṣe bákan náà sáwọn olóòótọ́ olùjọsìn Jèhófà?
5:3. Ọmọdébìnrin ará Ísírẹ́lì yẹn nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu. Ó tún nígboyà láti sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ǹjẹ́ ẹ̀yin ọ̀dọ́ máa ń sapá láti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tẹ́ ẹ ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run túbọ̀ lágbára sí i? Ṣé ẹ sì máa ń fìgboyà wàásù fáwọn olùkọ́ àtàwọn ọmọ ilé ìwé yín?
5:9-19. Ǹjẹ́ àpẹẹrẹ Náámánì ò fi hàn pé agbéraga èèyàn lè di onírẹ̀lẹ̀?—1 Pétérù 5:5.
5:20-27. Ẹ ò rí i pé àbájáde irọ́ pípa ò dáa rárá! Ríronú lórí ìbànújẹ́ àti àjálù tí gbígbé ìgbésí ayé kò-ṣeku-kò-ṣẹyẹ máa ń fà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀.
ÍSÍRẸ́LÌ ÀTI JÚDÀ LỌ SÍGBÈKÙN
Wọ́n fòróró yan Jéhù gẹ́gẹ́ bí ọba lórí Ísírẹ́lì. Kò sì fàkókò ṣòfò rárá tó fi wá bóun ṣe máa pa gbogbo àwọn aráalé Áhábù run. Jéhù fọgbọ́n ‘pa ìjọsìn Báálì rẹ́ ráúráú kúrò ní Ísírẹ́lì.’ (2 Àwọn Ọba 10:28) Nígbà tí Ataláyà gbọ́ pé Jéhù ti pa Ahasáyà ọmọ òun, ‘ó dìde, ó sì pa gbogbo ọmọ ìjọba Júdà run,’ ó wá gbé ara rẹ̀ gorí ìtẹ́. (2 Àwọn Ọba 11:1) Jèhóáṣì, ọmọkùnrin kékeré tí Ahasáyà bí nìkan ni kò rí pa, wọ́n sì fi ọmọ náà jọba lórí Júdà lẹ́yìn ọdún mẹ́fà tí wọ́n ti gbé e pa mọ́. Jèhóáṣì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tó tọ́ lójú Jèhófà ní gbogbo ìgbà tí Jèhóádà fi ń fún un nítọ̀ọ́ni.
Lẹ́yìn Jéhù, gbogbo ọba tó jẹ́ ní Ísírẹ́lì ni kò ṣe ohun tó tọ́ lójú Jèhófà. Àkókò tí ọmọ ọmọ Jéhù jẹ́ ọba ni Èlíṣà kú wọ́ọ́rọ́wọ́. Áhásì ni ọba kẹrin tó jẹ tẹ̀ lé Jèhóáṣì ní Júdà, “kò sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà.” (2 Àwọn Ọba 16:1, 2) Àmọ́, Hesekáyà, ọmọ rẹ̀ jẹ́ ọba kan tó “ń bá a nìṣó ní fífà mọ́ Jèhófà.” (2 Àwọn Ọba 17:20; 18:6) Lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Hesekáyà jọba lórí Júdà tí Hóṣéà sì jọba lórí Ísírẹ́lì, Ṣálímánésà ọba Ásíríà ‘gba Samáríà, ó sì kó Ísírẹ́lì nígbèkùn lọ sí Ásíríà.’ (2 Àwọn Ọba 17:6) Bí àkókò ti ń lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè wá sí Ísírẹ́lì, bí ìsìn àwọn ará Samáríà ṣe bẹ̀rẹ̀ níbẹ̀ nìyẹn.
Nínú àwọn ọba méjèèje tó jẹ ní Júdà lẹ́yìn Hesekáyà, Jòsáyà nìkan ṣoṣo ló sapá láti mú ìjọsìn èké kúrò nílẹ̀ náà. Níkẹyìn, lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Bábílónì ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù, ‘Júdà sì lọ sí ìgbèkùn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀.’—2 Àwọn Ọba 25:21.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
13:20, 21—Ǹjẹ́ iṣẹ́ ìyanu yìí fi hàn pé ó dára láti máa jọ́sìn àwọn ẹni tó ti kú? Rárá o. Bíbélì kò sọ pé àwọn èèyàn jọ́sìn eegun Èlíṣà rí. Agbára Ọlọ́run ló jẹ́ kí iṣẹ́ ìyanu yìí wáyé, bó ṣe rí nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí Èlíṣà ṣe nígbà tó wà láyé.
15:1-6—Kí nìdí tí Jèhófà ṣe fi àrùn ẹ̀tẹ̀ kọ lu Asaráyà (Ùsáyà, 15:6, aláyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW)? “Gbàrà tí [Ùsáyà] di alágbára, ọkàn-àyà rẹ̀ di onírera . . , tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣe àìṣòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, tí ó sì wá sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí.” Nígbà táwọn àlùfáà “dìde dúró lòdì sí Ùsáyà” tí wọ́n sì sọ fún un pé kó “jáde kúrò ní ibùjọsìn,” ó bínú sí àwọn àlùfáà náà, ẹ̀tẹ̀ sì bò ó.—2 Kíróníkà 26:16-20.
18:19-21, 25—Ṣé lóòótọ́ ni Hesekáyà wá ìrànlọ́wọ́ lọ sí Íjíbítì? Rárá o. Irọ́ gbuu ni Rábúṣákè pa, bí irú ìgbà tó sọ pé “ọlá àṣẹ lọ́wọ́ Jèhófà” ni òun fi ń sọ ọ̀rọ̀ tó ń tẹnu òun jáde. Jèhófà ni Hesekáyà Ọba tó jẹ́ olóòótọ́ gbára lé pátápátá.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
9:7, 26. Ìdájọ́ mímúná tó wá sórí ilé Áhábù fi hàn pé Jèhófà kórìíra ìjọsìn èké àti títa ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.
9:20. Pípè tí wọ́n pe Jéhù ní ẹni tó fi gbogbo agbára rẹ̀ wa kẹ̀kẹ́ ẹṣin fi ẹ̀rí hàn pé ó fi ìtara ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un. Ǹjẹ́ àwọn èèyàn mọ ìwọ náà sẹ́ni tó ń fìtara polongo Ìjọba Ọlọ́run?—2 Tímótì 4:2.
9:36, 37; 10:17; 13:18, 19, 25; 14:25; 19:20, 32-36; 20:16, 17; 24:13. Ọkàn wa lè balẹ̀ pé ‘ọ̀rọ̀ tó ti ẹnu Jèhófà jáde máa ń ní àṣeyọrí sí rere.’—Aísáyà 55:10, 11.
10:15. Bí Jèhónádábù ṣe fi gbogbo ọkàn rẹ̀ gbà láti tẹ̀ lé Jéhù nígbà tó ní kó wọnú kẹ̀kẹ́ ogun òun náà ni “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ṣe ń fi gbogbo ọkàn gbárùkù ti Jésù Kristi tó jẹ́ Jéhù òde òní àtàwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀.—Ìṣípayá 7:9.
10:30, 31. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtàn Jéhù fi hàn pé òun náà ṣàṣìṣe, síbẹ̀ Jèhófà mọrírì gbogbo ohun tó ṣe. Dájúdájú, ‘Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ wa.’—Hébérù 6:10.
13:14-19. Níwọ̀n bí Jèhóáṣì, ọmọ ọmọ Jéhù ò ti sa gbogbo ipá rẹ̀, àmọ́ tó jẹ́ pé ìgbà mẹ́ta péré ló ta ọ̀fà sórí ilẹ̀, ìwọ̀nba àṣeyọrí díẹ̀ ló ṣe ní ṣíṣẹ́gun àwọn ará Síríà. Jèhófà retí pé ká fi gbogbo ọkàn wa ṣe iṣẹ́ tí òun yàn fún wa, ká sì ṣe é tìtaratìtara.
20:2-6. Jèhófà jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà.”— Sáàmù 65:2.
24:3, 4. Jèhófà ‘kò gbà láti dárí ji’ Júdà, nítorí pé Mánásè jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Ọlọ́run ò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ẹ̀jẹ̀ àwọn aláìmọwọ́-mẹsẹ̀. A lè ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ nípa pípa àwọn tó ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ run.— Sáàmù 37:9-11; 145:20.
Ó Ṣàǹfààní fún Wa
Ìwé Àwọn Ọba Kejì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Lílọ táwọn olùgbé orílẹ̀-èdè méjèèjì lọ sígbèkùn, ìyẹn ilẹ̀ Ísírẹ́lì lákọ̀ọ́kọ́ àti lẹ́yìn náà ilẹ̀ Júdà, jẹ́ ká mọ̀ dájú pé àwọn ìdájọ́ tá a sọ àsọtẹ́lẹ̀ wọn nínú Diutarónómì 28:15–29:28 nímùúṣẹ. Ìwé Àwọn Ọba Kejì sọ pé Èlíṣà jẹ́ wòlíì tó nítara tó ga fún orúkọ Jèhófà àti fún ìjọsìn tòótọ́. Ó pe Hesekáyà àti Jòsáyà ní àwọn ọba tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún Òfin Ọlọ́run.
Bá a ṣe ń ronú nípa ìwà àti ìṣe àwọn ọba, àwọn wòlíì, àtàwọn mìíràn tí ìwé Àwọn Ọba Kejì mẹ́nu kàn, ǹjẹ́ a rí ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye kọ́ nípa ohun tó yẹ ká sapá láti ṣe àti ohun tó yẹ ká yẹra fún? (Róòmù 15:4; 1 Kọ́ríńtì 10:11) Dájúdájú, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.”—Hébérù 4:12.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
ÀWỌN IṢẸ́ ÌYANU TÍ ÈLÍṢÀ ṢE
1. Ó mú kí omi Jọ́dánì pín sí méjì.—2 Àwọn Ọba 2:14
2. Ó sọ omi burúkú tó wà ní Jẹ́ríkò di afúnni-nílera.—2 Àwọn Ọba 2:19-22.
3. Béárì pa àwọn ọmọ tó ya pòkíì.—2 Àwọn Ọba 2:23, 24
4. Ó pèsè omi fáwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.—2 Àwọn Ọba 3:16-26.
5. Opó kan rí ọ̀pọ̀ òróró gbà.—2 Àwọn Ọba 4:1-7.
6. Obìnrin ará Ṣúnémù tó yàgàn rí ọmọ bí.—2 Àwọn Ọba 4:8-17.
7. Ó jí ọmọ kan dìde nígbà tó kú.—2 Àwọn Ọba 4:18-37.
8. Ó sọ ọbẹ̀ tó lóró di èyí tó ṣeé jẹ.—2 Àwọn Ọba 4:38-41.
9. Ó fi ogún [20] ìṣù ọkà bọ́ ọgọ́rùn-ún ọkùnrin.—2 Àwọn Ọba 4:42-44.
10. Ó wo ẹ̀tẹ̀ Náámánì sàn.—2 Àwọn Ọba 5:1-14.
11. Ẹ̀tẹ̀ Náámánì wá sára Géhásì.—2 Àwọn Ọba 5:24-27.
12. Ó mú kí irin àáké léfòó.—2 Àwọn Ọba 6:5-7.
13. Ó mú kí ìránṣẹ́ kan rí kẹ̀kẹ́ ẹṣin àwọn áńgẹ́lì.—2 Àwọn Ọ ba 6:15-17.
14. Ó mú kí Ọlọ́run bu ìfọ́jú lu ẹgbẹ́ ọmọ ogun Síríà.— 2 Àwọn Ọba 6:18
15. Ojú àwọn ọmọ ogun Síríà tó fọ́ là.—2 Àwọn Ọba 6:19-23
16. Ọkùnrin kan tó kú jíǹde.—2 Àwọn Ọba 13:20, 21
[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
ÀWỌN ỌBA JÚDÀ ÀTI TI ÍSÍRẸ́LÌ
Sọ́ọ̀lù/Dáfídì/Sólómọ́nì: 1117/1077/1037 ṣáájú Sànmánì Kristẹni [Ṣ.S.K.]a
ÌJỌBA JÚDÀ DÉÈTÌ (Ṣ.S.K.) ÌJỌBA ÍSÍRẸ́LÌ
Rèhóbóámù ․․ 997 ․․ Jèróbóámù
Ábíjà/Ásà ․․ 980/978 ․․
․․ 976/975/952 ․․ Nádábù/Bááṣà/Éláhì
․․ 951/951/951 ․․ Símírì/Ómírì/Tíbínì
․․ 940 ․․ Áhábù
Jèhóṣáfátì ․․ 937 ․․
․․ 920/917 ․․ Ahasáyà/Jèhórámù
Jèhórámù ․․ 913 ․․
Ahasáyà ․․ 906 ․․
(Ataláyà) ․․ 905 ․․ Jéhù
Jèhóáṣì ․․ 898 ․․
․․ 876/859 ․․ Jèhóáhásì/Jèhóáṣì
Amasááyà ․․ 858 ․․
․․ 844 ․․ Jèróbóámù Kejì
Asaráyà (Ùsáyà) ․․ 829 ․․
․․ 803/791/791 ․․ Sekaráyà/Ṣálúmù/
Ménáhémù
․․ 780/778 ․․ Pekaháyà/Pékà
Jótámù/Áhásì ․․ 777/762 ․․
․․ 758 ․․ Hóṣéà
Hesekáyà ․․ 746 ․․
․․ 740 ․․ Wọ́n ṣẹ́gun Samáríà
Mánásè/Ámọ́nì/Jòsáyà ․․ 716/661/659 ․․
Jèhóáhásì/Jèhóákímù ․․ 628/628 ․․
Jèhóákínì/Sedekáyà ․․ 618/617 ․․
Wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run ․․ 607 ․․
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn déètì kan jẹ́ ọdún tá a fojú bù pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jọba.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Náámánì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, agbára Jèhófà sì mú un lára dá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Èlíjà nígbà tó ‘gòkè lọ nínú ìjì ẹlẹ́fùúùfù’?