Àwọn Ọba Kìíní
19 Nígbà náà, Áhábù+ sọ gbogbo ohun tí Èlíjà ṣe fún Jésíbẹ́lì+ àti bí ó ṣe fi idà pa gbogbo àwọn wòlíì.+ 2 Ni Jésíbẹ́lì bá rán òjíṣẹ́ kan sí Èlíjà pé: “Kí àwọn ọlọ́run fìyà jẹ mí gan-an tí mi ò bá ṣe ọ́ bí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn* ní ìwòyí ọ̀la!” 3 Ẹ̀rù wá bẹ̀rẹ̀ sí í bà á, torí náà, ó gbéra, ó sì sá nítorí ẹ̀mí* rẹ̀.+ Ó wá sí Bíá-ṣébà+ tó jẹ́ ti Júdà,+ ó sì fi ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀. 4 Ó rin ìrìn ọjọ́ kan lọ sínú aginjù, ó dúró, ó jókòó sábẹ́ igi wíwẹ́, ó sì béèrè pé kí òun* kú. Ó sọ pé: “Ó tó gẹ́ẹ́! Jèhófà, gba ẹ̀mí* mi,+ nítorí mi ò sàn ju àwọn baba ńlá mi.”
5 Lẹ́yìn náà, ó dùbúlẹ̀, ó sì sùn lọ lábẹ́ igi náà. Àmọ́ lójijì, áńgẹ́lì kan fọwọ́ kàn án,+ ó sì sọ fún un pé: “Dìde, jẹun.”+ 6 Nígbà tó máa lajú, ó rí búrẹ́dì ribiti kan lórí àwọn òkúta gbígbóná níbi orí rẹ̀ àti ìgò omi. Ó jẹ, ó sì mu, lẹ́yìn náà, ó sùn pa dà. 7 Nígbà tó yá, áńgẹ́lì Jèhófà pa dà wá lẹ́ẹ̀kejì, ó fọwọ́ kàn án, ó sì sọ pé: “Dìde, jẹun, nítorí ibi tí ò ń lọ jìnnà gan-an, agbára rẹ ò ní lè gbé e.” 8 Nítorí náà, ó dìde, ó jẹ, ó mu, oúnjẹ náà sì fún un lágbára láti rin ìrìn ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru títí ó fi dé Hórébù, òkè Ọlọ́run tòótọ́.+
9 Ó wọnú ihò+ kan níbẹ̀, ó sì sùn mọ́jú; sì wò ó! Jèhófà bá a sọ̀rọ̀, ó sọ fún un pé: “Kí lò ń ṣe níbí, Èlíjà?” 10 Ó fèsì pé: “Ìtara Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun+ gbà mí lọ́kàn ni; nítorí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ti pa májẹ̀mú rẹ tì,+ wọ́n ti ya àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ,+ èmi nìkan ló sì ṣẹ́ kù. Ní báyìí, bí wọ́n ṣe máa gba ẹ̀mí* mi ni wọ́n ń wá.”+ 11 Àmọ́, ó sọ pé: “Jáde, kí o sì dúró sórí òkè níwájú Jèhófà.” Sì wò ó! Jèhófà ń kọjá lọ,+ ẹ̀fúùfù ńlá tó lágbára ń ya àwọn òkè, ó sì ń fọ́ àwọn àpáta níwájú Jèhófà,+ àmọ́ Jèhófà kò sí nínú ẹ̀fúùfù náà. Lẹ́yìn ẹ̀fúùfù náà, ìmìtìtì ilẹ̀+ wáyé, àmọ́ Jèhófà kò sí nínú ìmìtìtì ilẹ̀ náà. 12 Lẹ́yìn ìmìtìtì ilẹ̀ náà, iná sọ,+ àmọ́ Jèhófà kò sí nínú iná náà. Lẹ́yìn iná náà, ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kan sọ̀rọ̀.+ 13 Bí Èlíjà ṣe gbọ́ báyìí, ó fi ẹ̀wù oyè rẹ̀ wé ojú,+ ó jáde, ó sì dúró sí ẹnu ọ̀nà ihò náà. Ohùn kan wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí lò ń ṣe níbí, Èlíjà?” 14 Ó fèsì pé: “Ìtara Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun gbà mí lọ́kàn ni; nítorí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ti pa májẹ̀mú rẹ tì,+ wọ́n ti ya àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ, èmi nìkan ló sì ṣẹ́ kù. Ní báyìí, bí wọ́n ṣe máa gba ẹ̀mí* mi ni wọ́n ń wá.”+
15 Jèhófà sọ fún un pé: “Pa dà, lọ sí aginjù Damásíkù. Tí o bá débẹ̀, fi òróró yan Hásáẹ́lì+ ṣe ọba lórí Síríà. 16 Kí o fòróró yan Jéhù+ ọmọ ọmọ Nímúṣì ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì, kí o sì yan Èlíṣà* ọmọ Ṣáfátì láti Ebẹli-méhólà ṣe wòlíì ní ipò rẹ.+ 17 Ẹni tó bá bọ́ lọ́wọ́ idà Hásáẹ́lì,+ Jéhù yóò pa á;+ ẹni tó bá sì bọ́ lọ́wọ́ idà Jéhù, Èlíṣà yóò pa á.+ 18 Mo ṣì ní ẹgbẹ̀rún méje (7,000) èèyàn ní Ísírẹ́lì,+ tí gbogbo wọn ò kúnlẹ̀ fún Báálì,+ tí wọn ò sì fẹnu kò ó lẹ́nu.”+
19 Torí náà, ó kúrò níbẹ̀, ó sì rí Èlíṣà ọmọ Ṣáfátì níbi tó ti ń fi àwọn akọ màlúù tí wọ́n dì ní méjì-méjì sọ́nà méjìlá (12) túlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì wà pẹ̀lú ìkejìlá. Nítorí náà, Èlíjà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì ju ẹ̀wù oyè rẹ̀+ sí i lọ́rùn. 20 Ni ó bá fi àwọn akọ màlúù náà sílẹ̀, ó sì sáré tẹ̀ lé Èlíjà, ó sọ fún un pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n lọ fẹnu ko bàbá àti ìyá mi lẹ́nu. Lẹ́yìn náà, màá tẹ̀ lé ọ.” Ó dá a lóhùn pé: “Pa dà lọ, kí nìdí tí màá fi dá ọ dúró?” 21 Nítorí náà, ó pa dà lọ, ó mú akọ màlúù méjì, ó pa wọ́n,* ó sì fi ọ̀pá ohun èlò ìtúlẹ̀ náà se ẹran wọn, ó fún àwọn èèyàn náà, wọ́n sì jẹ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ó gbéra, ó tẹ̀ lé Èlíjà, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.+