Alágbára Ńlá Ni Jèhófà, Síbẹ̀ Ó Ń Gba Tẹni Rò
“[Jèhófà] fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.”—SM. 103:14.
1, 2. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe yàtọ̀ sáwọn aláṣẹ ayé tó bá dọ̀rọ̀ bó ṣe ń bá àwọn èèyàn lò? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
ÀWỌN aláṣẹ àtàwọn tó lẹ́nu láwùjọ sábà máa ń jẹ gàba lórí àwọn tó wà lábẹ́ wọn. (Mát. 20:25; Oníw. 8:9) Àmọ́ Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sí wọn! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Alágbára Ńlá ni, síbẹ̀ ó máa ń gba tàwa èèyàn aláìpé rò. Aláàánú ni, ó sì máa ń fi inúure hàn sí wa. Kódà, ó máa ń kíyè sí bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa, ó sì máa ń fún wa láwọn nǹkan tá a nílò. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà “rántí pé ekuru ni wá,” torí náà kì í béèrè ohun tó ju agbára wa lọ.—Sm. 103:13, 14.
2 Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì nípa bí Jèhófà ṣe gba tàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ rò. Àmọ́, a máa jíròrò àpẹẹrẹ mẹ́ta nínú àpilẹ̀kọ yìí. Lákọ̀ọ́kọ́, a máa rí bí Jèhófà ṣe gba ti Sámúẹ́lì rò, tó sì ràn án lọ́wọ́ láti jíṣẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run fún Élì tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà. Ìkejì ni bí Jèhófà ṣe mú sùúrù fún Mósè nígbà tí Mósè ronú pé òun ò tóótun fún iṣẹ́ tí Ọlọ́run fún un láti darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nínú àpẹẹrẹ kẹta, a máa rí bí Jèhófà ṣe gba tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì rò nígbà tó mú wọn jáde kúrò ní Íjíbítì. Bá a ṣe ń jíròrò ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àpẹẹrẹ yìí, ẹ jẹ́ ká máa ronú nípa ohun tí wọ́n kọ́ wa nípa Jèhófà àtàwọn nǹkan míì táwa náà lè rí kọ́.
JÈHÓFÀ GBA TI ỌMỌDÉ KAN RÒ
3. Nǹkan àràmàǹdà wo ló ṣẹlẹ̀ sí Sámúẹ́lì lálẹ́ ọjọ́ kan, ìbéèrè wo nìyẹn lè gbé wá sọ́kàn wa? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
3 Àtikékeré ni Sámúẹ́lì ti ń “ṣe ìránṣẹ́ fún Jèhófà” nínú àgọ́ ìjọsìn. (1 Sám. 3:1) Lálẹ́ ọjọ́ kan tí Sámúẹ́lì lọ sùn, ohun àràmàǹdà kan ṣẹlẹ̀.a (Ka 1 Sámúẹ́lì 3:2-10.) Ó gbọ́ tí ohùn kan pe orúkọ rẹ̀. Sámúẹ́lì rò pé Élì tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà ló ń pe òun, ló bá sáré lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì sọ fún Élì pé: “Èmi nìyí, nítorí tí ìwọ pè mí.” Àmọ́ Élì sọ pé òun ò pè é. Lẹ́yìn tí èyí tún ṣẹlẹ̀ nígbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, Élì fòye mọ̀ pé Ọlọ́run ló ń pe Sámúẹ́lì. Élì wá ṣàlàyé ohun tí Sámúẹ́lì máa ṣe tó bá tún gbọ́ ohùn náà, Sámúẹ́lì sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu. Àmọ́ kí nìdí tí Jèhófà ò fi jẹ́ kí Sámúẹ́lì mọ̀ nígbà àkọ́kọ́ pé òun lòun ń pè é? Bíbélì ò sọ, àmọ́ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn jẹ́ ká rí i pé ṣe ni Jèhófà gba ti Sámúẹ́lì tó jẹ́ ọmọdé rò. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
4, 5. (a) Báwo ni iṣẹ́ tí Jèhófà rán Sámúẹ́lì ṣe rí lára rẹ̀, kí ló sì ṣẹlẹ̀ láàárọ̀ ọjọ́ kejì? (b) Kí ni ìtàn yìí kọ́ wa nípa Jèhófà?
4 Ka 1 Sámúẹ́lì 3:11-18. Nínú Òfin Mósè, Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fáwọn àgbàlagbà, pàápàá àwọn tó bá ń múpò iwájú. (Ẹ́kís. 22:28; Léf. 19:32) Torí náà, báwo ló ṣe máa rọrùn tó fún Sámúẹ́lì láti lọ bá Élì kó sì kéde ìdájọ́ Ọlọ́run fún un? Ó dájú pé kò ní rọrùn! Kódà Bíbélì sọ pé Sámúẹ́lì “fòyà láti sọ fún Élì nípa àfihàn náà.” Àmọ́, Ọlọ́run jẹ́ kó ṣe kedere sí Élì pé òun lòun ń pe Sámúẹ́lì. Èyí ló mú kí Élì fúnra ẹ̀ pe Sámúẹ́lì, tó sì pàṣẹ fún un pé: “[Má ṣe] fi ọ̀rọ̀ kan pa mọ́ fún mi nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó sọ fún ọ.” Sámúẹ́lì ṣègbọràn, ó sì “sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún un.”
5 Iṣẹ́ tí Sámúẹ́lì jẹ́ yìí ò lè ṣàjèjì sí Élì torí pé ṣáájú ìgbà yẹn ni “ènìyàn Ọlọ́run” kan ti kéde irú ìdájọ́ yìí kan náà fún Élì. (1 Sám. 2:27-36) Ìtàn yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń gba tèèyàn rò àti pé ọgbọ́n rẹ̀ ò láàlà.
6. Kí la rí kọ́ nínú ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ran Sámúẹ́lì lọ́wọ́?
6 Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, ìtàn Sámúẹ́lì tá a gbé yẹ̀ wò yìí á jẹ́ kó ṣe kedere sí ẹ pé Jèhófà lóye àwọn ìṣòro tó ò ń kojú, ó sì mọ bọ́rọ̀ ṣe ń rí lára rẹ. Ó lè jẹ́ pé ojú máa ń tì ẹ́ láti wàásù fáwọn tó dàgbà jù ẹ́ lọ tàbí pé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti dá yàtọ̀ sáwọn míì tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ẹgbẹ́. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́. Torí náà gbàdúrà, kó o sì sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún un. (Sm. 62:8) Máa ṣàṣàrò lórí àpẹẹrẹ àwọn ọ̀dọ́ bíi Sámúẹ́lì. O lè lọ bá àwọn Kristẹni míì yálà wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí àgbà, kó o sì béèrè bí wọ́n ṣe borí àwọn ìṣòro tó fara jọ èyí tíwọ náà ń kojú báyìí. Wọ́n lè sọ àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ àti bó ṣe dáhùn àdúrà wọn lọ́nà tí wọn ò lérò.
JÈHÓFÀ GBA TI MÓSÈ RÒ
7, 8. Báwo ni Jèhófà ṣe fi ìgbatẹnirò àrà ọ̀tọ̀ hàn sí Mósè?
7 Nígbà tí Mósè pé ẹni ọgọ́rin (80) ọdún, Jèhófà gbé iṣẹ́ ńlá kan fún un. Jèhófà sọ fún un pé òun ló máa gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lóko ẹrú ní Íjíbítì. (Ẹ́kís. 3:10) Iṣẹ́ yìí kà á láyà torí pé àti ogójì (40) ọdún ni Mósè ti ń ṣiṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn nílẹ̀ Mídíánì. Mósè tiẹ̀ sọ pé: “Ta ni èmi tí èmi yóò fi lọ bá Fáráò, tí n ó sì fi mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì?” Ọlọ́run wá fi í lọ́kàn balẹ̀ pé: “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ.” (Ẹ́kís. 3:11, 12) Kódà, Ọlọ́run ṣèlérí fún un pé àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì ‘yóò fetí sí ohùn rẹ̀.’ Síbẹ̀, Mósè sọ pé: ‘Ká ní wọn kò fetí sí mi ńkọ́?’ (Ẹ́kís. 3:18; 4:1) Ṣe ló dà bí ìgbà tí Mósè ń sọ pé ohun tí Jèhófà sọ lè má tọ̀nà. Síbẹ̀, Jèhófà mú sùúrù fún un, kódà ó tún fún Mósè lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, Mósè lẹni àkọ́kọ́ tí Jèhófà fún lágbára yìí nínú Bíbélì.—Ẹ́kís. 4:2-9, 21.
8 Mósè tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàwáwí, ó sọ fún Jèhófà pé òun ò mọ ọ̀rọ̀ sọ. Àmọ́ Jèhófà dá a lóhùn pé: “Èmi alára yóò sì wà pẹ̀lú ẹnu rẹ, èmi yóò sì kọ́ ọ ní ohun tí ó yẹ kí o sọ.” Ṣé Mósè wá gbà láti lọ ṣiṣẹ́ náà? Rárá o, torí ó tún bẹ Jèhófà pé kó rán ẹlòmíì. Èyí mú kí inú bí Jèhófà, síbẹ̀ ó gba ti Mósè rò, ó sì gbà pẹ̀lú ohun tó sọ. Jèhófà wá yan Áárónì láti jẹ́ agbẹnusọ fún Mósè.—Ẹ́kís. 4:10-16.
9. Báwo ni sùúrù Jèhófà ṣe mú kí Mósè di aṣáájú tó ta yọ?
9 Kí ni ìtàn yìí kọ́ wa nípa Jèhófà? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Alágbára Ńlá ni Jèhófà, ó sì lè fagbára mú Mósè kó lè ṣègbọràn láìjanpata. Àmọ́, Jèhófà ò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló mú sùúrù fún Mósè, ó sì fi ìránṣẹ́ rẹ̀ onírẹ̀lẹ̀ yìí lọ́kàn balẹ̀ pé òun máa wà pẹ̀lú rẹ̀. Ṣé ọ̀nà tí Jèhófà lò yìí gbéṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ ni, torí pé Mósè di aṣáájú tó ta yọ, ó sì máa ń gba tàwọn míì rò gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe gba tiẹ̀ náà rò.—Núm. 12:3.
10. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń gba tàwọn míì rò bíi ti Jèhófà?
10 Kí la rí kọ́ nínú ìtàn yìí? Tó o bá jẹ́ ọkọ, òbí tàbí alàgbà nínú ìjọ, á jẹ́ pé o ní ọlá àṣẹ déwọ̀n àyè kan lórí àwọn míì nìyẹn. Torí náà, ó ṣe pàtàkì kó o fara wé Jèhófà, kó o máa gba tiwọn rò, kó o sì máa ṣe sùúrù pẹ̀lú wọn. (Kól. 3:19-21; 1 Pét. 5:1-3) Tó o bá ń sapá láti fara wé Jèhófà àti Jésù tó jẹ́ Mósè Títóbi Jù, wàá jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́, ara sì máa tu àwọn míì nígbà tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ rẹ. (Mát. 11:28, 29) Wàá sì tún jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn míì.—Héb. 13:7.
OLÙGBÀLÀ TÓ LÁGBÁRA TÓ SÌ Ń GBA TẸNI RÒ
11, 12. Kí ni Jèhófà ṣe tó mú kọ́kàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń jáde kúrò ní Íjíbítì?
11 Ó ṣeé ṣe kí iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta nígbà tí wọ́n máa kúrò ní Íjíbítì lọ́dún 1513 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àwọn ọmọdé wà láàárín wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àgbàlagbà, àwọn aláìlera títí kan àwọn aláàbọ̀ ara. Ẹni tó bá máa darí adúrú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ láti Íjíbítì gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó lóye, tó sì ń gba tẹni rò. Irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an nìyẹn, ó sì lo Mósè láti gbé àwọn ànímọ́ yìí yọ. Torí náà, ọkàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń fi Íjíbítì tó jẹ́ ibì kan ṣoṣo tí wọ́n mọ̀ sílẹ̀.—Sm. 78:52, 53.
12 Kí ni Jèhófà ṣe tó mú kọ́kàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì balẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, Jèhófà ṣètò wọn sí àwùjọ-àwùjọ, wọ́n sì dà bí ẹgbẹ́ ọmọ ogun. (Ẹ́kís. 13:18) Irú ètò yìí jẹ́ kó dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú pé Jèhófà ló ń darí wọn. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àmì kan táá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun wà pẹ̀lú wọn. Bíbélì sọ pé ó fi “àwọsánmà ṣamọ̀nà wọn ní ọ̀sán àti ìmọ́lẹ̀ iná ní gbogbo òru.” (Sm. 78:14) Ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà ń sọ fún wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù torí mo wà pẹ̀lú yín, màá sì dáàbò bò yín.” Kò sí àní-àní pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nílò ìdánilójú yìí torí pé ohun kan máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ táá mú kẹ́rù bà wọ́n.
13, 14. (a) Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òkun Pupa tó fi hàn pé ó gba tiwọn rò? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun lágbára ju àwọn ará Íjíbítì lọ?
13 Ka Ẹ́kísódù 14:19-22. Fojú inú wò ó pé o wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́jọ́ yẹn. Òkun Pupa rèé níwájú, àwọn ọmọ ogun Fáráò sì ń ya bọ̀ lẹ́yìn. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà ṣe ohun àrà kan. Ṣe ni ọwọ̀n àwọsánmà náà ṣí kúrò níwájú yín, ó sì pààlà sáàárín ẹ̀yin àtàwọn ọmọ ogun Íjíbítì. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé àwọsánmà náà mú kí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Íjíbítì ṣókùnkùn biribiri, àmọ́ ṣe ni ọ̀dọ̀ tiyín mọ́lẹ̀ rekete! Lẹ́yìn náà lo rí i tí Mósè na ọwọ́ rẹ̀ sí òkun, afẹ́fẹ́ kan sì fẹ́ wá láti ìlà oòrùn, afẹ́fẹ́ náà lágbára débi pé ó pín òkun náà sí méjì, ó sì la ọ̀nà sáàárín rẹ̀. Gbogbo àwọn èèyàn náà títí kan ìwọ àti ìdílé rẹ àtàwọn ẹran ọ̀sìn yín sì rọra tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ gba àárín omi náà kọjá. Àmọ́, o tún kíyè sí ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ṣe ni orí ilẹ̀ tẹ́ ẹ̀ ń rìn gbẹ táútáú, kò sí ẹrẹ̀ níbẹ̀ débi pé á máa yọ̀, ìyẹn sì mú kó rọrùn fún gbogbo yín títí kan àwọn ọmọdé àtàwọn aláìlera láti rìn kọjá níbẹ̀. Gbogbo yín sì sọdá òkun náà láyọ̀ àti àlàáfíà.
14 Ka Ẹ́kísódù 14:23, 26-30. Agbéraga ni Fáráò, ìyẹn sì mú kóun àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ rọ́ wọnú òkun náà. Àmọ́ ìwà agọ̀ gbáà nìyẹn jẹ́! Lẹ́yìn ìyẹn, Mósè na ọwọ́ rẹ̀ sí òkun náà. Lọ́tẹ̀ yìí, òkun tó pínyà náà pa dà, ó sì ya bo Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ láti ẹ̀gbẹ́ méjèèjì. Bí Fáráò àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ ṣe pa rẹ́ ráúráú nìyẹn!—Ẹ́kís. 15:8-10.
15. Kí ni ìtàn yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
15 Ìtàn yìí jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run ètò ni Jèhófà, ànímọ́ yìí sì ń fi wá lọ́kàn balẹ̀. (1 Kọ́r. 14:33) Bákan náà, a rí i pé olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, ó sì máa ń fìfẹ́ bójú tó àwọn tó jẹ́ tirẹ̀. Ìyẹn máa ń mú kó pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n nílò. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá. Àwọn ohun tá a mọ̀ yìí fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé mìmì kan ò lè mì wá bá a ṣe ń sún mọ́ òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí!—Òwe 1:33.
16. Tá a bá ń ṣàyẹ̀wò bí Jèhófà ṣe gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì là, àǹfààní wo nìyẹn máa ṣe wá?
16 Bákan náà lónìí, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn rẹ̀ lápapọ̀, ó sì máa ń bójú tó wa nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Èyí mú kó dá wa lójú pé á dáàbò bò wá bí ìpọ́njú ńlá ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé. (Ìṣí. 7:9, 10) Torí náà, gbogbo àwa èèyàn Jèhófà lọ́mọdé lágbà, yálà ẹni tára ẹ̀ le tàbí aláàbọ̀ ara, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà máa dáàbò bò wá nígbà ìpọ́njú ńlá.b Dípò ká máa bẹ̀rù ohun táá ṣẹlẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá, ṣe ni inú wa á máa dùn! Àá máa rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, pé: “Ẹ gbé ara yín nà ró ṣánṣán, kí ẹ sì gbé orí yín sókè, nítorí pé ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:28) Kódà, nígbà tí Gọ́ọ̀gù ìyẹn àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè tó lágbára ju àwọn ọmọ ogun Íjíbítì lọ bá gbéjà kò wá, ọkàn wa á balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. (Ìsík. 38:2, 14-16) Kí ló máa jẹ́ kọ́kàn àwa èèyàn Ọlọ́run balẹ̀? Ọkàn wa máa balẹ̀ torí a mọ̀ pé Jèhófà kò ní yí pa dà, bó ṣe wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà àtijọ́, á wà pẹ̀lú àwa náà, á gba tiwa rò, á sì gbà wá là.—Aísá. 26:3, 20.
17. (a) Tá a bá ń ṣàṣàrò nípa bí Jèhófà ṣe bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀, àǹfààní wo nìyẹn máa ṣe wá? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
17 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti jíròrò díẹ̀ nínú àwọn àpẹẹrẹ tó jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń gba tàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ rò, ó sì máa ń fìfẹ́ bójú tó wọn. Ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó bá ń darí wọn àti nígbà tó bá fẹ́ gbà wọ́n là. Bó o ṣe ń ṣàṣàrò lórí àwọn ìtàn yìí, máa kíyè sí àwọn kókó tó o lè má fọkàn sí tẹ́lẹ̀ táá jẹ́ kó o túbọ̀ lóye àwọn ànímọ́ Jèhófà. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí ìgbàgbọ́ rẹ sì lágbára sí i. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò bá a ṣe lè máa gba tàwọn míì rò bíi ti Jèhófà. A máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè fi ìgbatẹnirò hàn nínú ìdílé, nínú ìjọ àti lóde ẹ̀rí.
a Òpìtàn Júù náà, Josephus sọ pé ọmọ ọdún méjìlá (12) ni Sámúẹ́lì nígbà yẹn.
b Ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé àwọn aláàbọ̀ ara máa wà lára àwọn tó máa la Amágẹ́dọ́nì já. Bí àpẹẹrẹ, “gbogbo onírúurú àìlera ara” táwọn èèyàn ní ni Jésù wò sàn nígbà tó wà láyé, ìyẹn sì jẹ́ ìtọ́wò nǹkan tó máa ṣe fáwọn tó máa la Amágẹ́dọ́nì já. (Mát. 9:35) Àwọn tó máa jíǹde ò ní nílò irú ìwòsàn yìí torí pé ara wọn á ti jí pépé nígbà ti wọ́n bá jíǹde.