Sí Àwọn Ará Éfésù
4 Nítorí náà, èmi, ẹlẹ́wọ̀n+ nínú Olúwa, pàrọwà fún yín láti máa rìn lọ́nà tó yẹ+ pípè tí a pè yín, 2 pẹ̀lú gbogbo ìrẹ̀lẹ̀*+ àti ìwà tútù, pẹ̀lú sùúrù,+ kí ẹ máa fara dà á fún ara yín nínú ìfẹ́,+ 3 kí ẹ máa sapá lójú méjèèjì láti pa ìṣọ̀kan ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà.+ 4 Ara kan ló wà+ àti ẹ̀mí kan,+ bó ṣe jẹ́ pé ìrètí kan ṣoṣo + la pè yín sí; 5 Olúwa kan,+ ìgbàgbọ́ kan, ìbatisí kan; 6 Ọlọ́run kan àti Baba gbogbo èèyàn, tó wà lórí ohun gbogbo, tó ń ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ ohun gbogbo àti nínú ohun gbogbo.
7 A fún kálukú wa ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí bí Kristi ṣe díwọ̀n ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ náà fúnni.+ 8 Torí ó sọ pé: “Nígbà tó gòkè lọ sí ibi gíga, ó kó àwọn èèyàn lẹ́rú; ó fúnni ní àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn.”+ 9 Tóò, kí ni gbólóhùn náà pé “ó gòkè” túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé ó ti kọ́kọ́ wá sísàlẹ̀, ìyẹn sí ayé. 10 Ẹni tó sọ̀ kalẹ̀ náà ni ẹni tó tún gòkè+ kọjá gbogbo ọ̀run,+ kí ó lè mú ohun gbogbo ṣẹ.
11 Ó fúnni ní àwọn kan gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì,+ àwọn kan gẹ́gẹ́ bíi wòlíì,+ àwọn kan gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere,*+ àwọn kan gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn àti olùkọ́,+ 12 láti tọ́ àwọn ẹni mímọ́ sọ́nà,* fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, láti gbé ara Kristi ró,+ 13 títí gbogbo wa á fi ṣọ̀kan* nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run, tí a ó fi di géńdé* ọkùnrin,+ tí a ó sì dàgbà dé ìwọ̀n kíkún ti Kristi. 14 Torí náà, kò yẹ ká jẹ́ ọmọdé mọ́, tí à ń gbá kiri bí ìgbì òkun ṣe ń gbá nǹkan kiri, tí gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́ ẹ̀tàn àwọn èèyàn sì ń gbá síbí sọ́hùn-ún+ nípasẹ̀ ọgbọ́nkọ́gbọ́n tí a fi hùmọ̀ ẹ̀tàn. 15 Àmọ́ nípa sísọ òótọ́, ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ máa mú ká dàgbà sókè nínú ohun gbogbo sínú ẹni tó jẹ́ orí, ìyẹn Kristi.+ 16 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni gbogbo ara+ ti para pọ̀ di ọ̀kan, tí a sì mú kí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nípasẹ̀ gbogbo oríkèé tó ń pèsè ohun tí a nílò. Tí ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan bá ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, èyí á mú kí ara máa dàgbà sí i bó ṣe ń gbé ara rẹ̀ ró nínú ìfẹ́.+
17 Nítorí náà, ohun tí màá sọ, tí màá sì jẹ́rìí sí nínú Olúwa ni pé kí ẹ má ṣe rìn mọ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ń rìn,+ torí inú èrò asán* ni wọ́n ti ń rìn.+ 18 Ìrònú wọn ti ṣókùnkùn, wọ́n sì ti di àjèjì sí ìyè tó jẹ́ ti Ọlọ́run, torí pé wọ́n jẹ́ aláìmọ̀kan àti nítorí ọkàn wọn ti yigbì.* 19 Bí wọ́n ṣe wá kọjá gbogbo òye ìwà rere, wọ́n fi ara wọn fún ìwà àìnítìjú*+ láti máa fi ojúkòkòrò hu oríṣiríṣi ìwà àìmọ́.
20 Àmọ́, ẹ ò mọ Kristi sírú ẹni bẹ́ẹ̀, 21 tó bá jẹ́ pé òótọ́ lẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí a sì tipasẹ̀ rẹ̀ kọ́ yín, gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ṣe wà nínú Jésù. 22 Ẹ ti kẹ́kọ̀ọ́ pé kí ẹ bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀,+ èyí tó bá ọ̀nà ìgbésí ayé yín ti tẹ́lẹ̀ mu, tí àwọn ìfẹ́ rẹ̀ tó ń tanni jẹ sì ń sọ di ìbàjẹ́.+ 23 Torí náà, ẹ máa di tuntun nínú agbára tó ń darí ìrònú yín,*+ 24 kí ẹ sì gbé ìwà tuntun wọ̀,+ èyí tí a dá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.
25 Torí náà, ní báyìí tí ẹ ti fi ẹ̀tàn sílẹ̀, kí kálukú yín máa bá ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́,+ nítorí ẹ̀yà ara kan náà ni wá.+ 26 Tí inú bá bí yín, ẹ má ṣẹ̀;+ ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ìbínú;+ 27 ẹ má gba Èṣù láyè.*+ 28 Kí ẹni tó ń jalè má jalè mọ́; kàkà bẹ́ẹ̀, kó máa ṣiṣẹ́ kára, kó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe iṣẹ́ rere,+ kó lè ní nǹkan tó máa fún ẹni tí kò ní.+ 29 Kí ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́* má ṣe ti ẹnu yín jáde,+ ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró nìkan ni kí ẹ máa sọ bó bá ṣe yẹ, kí ó lè ṣe àwọn tó ń gbọ́ yín láǹfààní.+ 30 Bákan náà, ẹ má ṣe máa kó ẹ̀dùn ọkàn* bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run,+ èyí tí a fi gbé èdìdì lé+ yín fún ọjọ́ ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà.+
31 Ẹ mú gbogbo inú burúkú,+ ìbínú, ìrunú, ariwo àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín,+ títí kan gbogbo ohun tó lè ṣeni léṣe.+ 32 Àmọ́ ẹ jẹ́ onínúure sí ara yín, kí ẹ máa ṣàánú,+ kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà bí Ọlọ́run náà ṣe tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.+