Oníwàásù
7 Orúkọ rere* sàn ju òróró dáradára,+ ọjọ́ ikú sì sàn ju ọjọ́ tí a bíni lọ. 2 Ó sàn láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju láti lọ sí ilé àsè,+ torí pé ìyẹn ni òpin gbogbo èèyàn, ó sì yẹ kí àwọn alààyè fi sọ́kàn. 3 Ìbànújẹ́ sàn ju ẹ̀rín lọ,+ torí ojú tó fà ro ń mú kí ọkàn túbọ̀ ṣiṣẹ́ dáadáa.+ 4 Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀, àmọ́ ilé ìdùnnú* ni ọkàn òmùgọ̀ wà.+
5 Ó sàn kéèyàn fetí sí ìbáwí ọlọ́gbọ́n+ ju kéèyàn máa gbọ́ orin àwọn òmùgọ̀. 6 Torí pé bí ẹ̀gún tó ń jó lábẹ́ ìkòkò ṣe máa ń ta pàrà, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀rín òmùgọ̀ rí;+ asán sì ni èyí pẹ̀lú. 7 Ìnilára lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bíi wèrè, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì ń sọ ọkàn dìdàkudà.+
8 Òpin nǹkan sàn ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ. Ó sàn kéèyàn ní sùúrù ju pé kéèyàn ní ẹ̀mí ìgbéraga.+ 9 Má ṣe máa yára* bínú,+ torí pé àyà àwọn òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.*+
10 Má sọ pé, “Kí nìdí tí àwọn ọjọ́ àtijọ́ fi sàn ju ti ìgbà yìí lọ?” torí pé kì í ṣe ọgbọ́n ló mú kí o béèrè bẹ́ẹ̀.+
11 Ọgbọ́n pẹ̀lú ogún jẹ́ ohun tó dáa, ó sì jẹ́ àǹfààní fún àwọn tó ń rí ìmọ́lẹ̀ ọjọ́.* 12 Nítorí ọgbọ́n jẹ́ ààbò+ bí owó ṣe jẹ́ ààbò,+ àmọ́ àǹfààní ìmọ̀ ni pé: Ọgbọ́n máa ń dá ẹ̀mí àwọn tó ní in sí.+
13 Kíyè sí iṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, ta ló lè mú kí ohun tó ṣe ní wíwọ́ tọ́?+ 14 Ní ọjọ́ tí nǹkan bá dáa, jẹ́ kó hàn lójú rẹ,+ àmọ́ ní ọjọ́ àjálù, fiyè sí i pé Ọlọ́run ti ṣe àkọ́kọ́ àti èkejì,+ kí aráyé má bàa lè sọ ní pàtó* ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn lọ́jọ́ iwájú.+
15 Ohun gbogbo ni mo ti rí ní gbogbo ìgbé ayé asán mi,+ látorí olódodo tó ṣègbé nínú òdodo rẹ̀,+ dórí ẹni burúkú tó pẹ́ láyé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà burúkú ló ń hù.+
16 Má ṣe òdodo àṣelékè,+ bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe gbọ́n ní àgbọ́njù.+ Àbí o fẹ́ pa ara rẹ ni?+ 17 Má sọ ìwà burúkú dàṣà, má sì ya òmùgọ̀.+ Ṣé ó yẹ kí o kú láìtọ́jọ́ ni?+ 18 Ó sàn kéèyàn gba ìkìlọ̀ àkọ́kọ́, kó má sì jẹ́ kí èkejì bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́;+ nítorí ẹni tó bá bẹ̀rù Ọlọ́run yóò pa méjèèjì mọ́.
19 Ọgbọ́n máa ń mú kí ọlọ́gbọ́n lágbára ju akíkanjú ọkùnrin mẹ́wàá tó ń ṣọ́ ìlú.+ 20 Nítorí kò sí olódodo kankan láyé tó ń ṣe rere nígbà gbogbo tí kì í dẹ́ṣẹ̀.+
21 Bákan náà, má ṣe máa fọkàn sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí àwọn èèyàn bá sọ;+ àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, o lè gbọ́ tí ìránṣẹ́ rẹ ń bú* ọ; 22 torí o mọ̀ lọ́kàn rẹ dáadáa pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnra rẹ ti bú àwọn míì.+
23 Gbogbo èyí ni mo ti fi ọgbọ́n dán wò, mo sì sọ pé: “Màá di ọlọ́gbọ́n.” Àmọ́, ó kọjá agbára mi. 24 Ohun tó ti wà, ọwọ́ ò lè tó o, ó sì jinlẹ̀ gidigidi. Ta ló lè lóye rẹ̀?+ 25 Mo darí ọkàn mi kí n lè mọ̀, kí n lè wádìí, kí n sì lè wá ọgbọ́n àti ohun tó ń fa àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀, mo sì darí rẹ̀ kí n lè lóye aburú tó wà nínú ìwà ẹ̀gọ̀ àti àìlọ́gbọ́n tó wà nínú ìwà wèrè.+ 26 Mo wá rí i pé: Ohun tó korò ju ikú lọ ni obìnrin tó dà bí àwọ̀n ọlọ́dẹ, tí ọkàn rẹ̀ dà bí àwọ̀n ńlá, tí ọwọ́ rẹ̀ sì dà bíi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀. Ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ á bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀,+ àmọ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ á kó sọ́wọ́ rẹ̀.+
27 Akónijọ+ sọ pé, “Wò ó! èyí ni mo ti rí. Mo gbé àwọn nǹkan yẹ̀ wò lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan kí n lè mọ ibi tí màá parí èrò sí, 28 àmọ́ mi* ò tíì rí ohun tí mò ń fi ìgbà gbogbo wá. Mo rí ọkùnrin kan* nínú ẹgbẹ̀rún, àmọ́ mi ò tíì rí obìnrin kan nínú wọn. 29 Èyí nìkan ṣoṣo ni mo ti rí pé: Ọlọ́run tòótọ́ dá aráyé ní adúróṣinṣin,+ àmọ́ wọ́n ti wá ọ̀pọ̀ ètekéte.”+