Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì
2 Torí náà, nígbà tí mo wá sọ́dọ̀ yín, ẹ̀yin ará, mi ò wá pẹ̀lú ọ̀rọ̀ kàbìtì-kàbìtì+ tàbí ọgbọ́n láti kéde àṣírí mímọ́+ Ọlọ́run fún yín. 2 Nítorí mo ti pinnu pé mi ò ní sọ̀rọ̀ nípa ohun míì láàárín yín àfi nípa Jésù Kristi, ẹni tí wọ́n kàn mọ́gi.*+ 3 Nígbà tí mo wá sọ́dọ̀ yín, ara mi ò le, ẹ̀rù ń bà mí, jìnnìjìnnì sì bá mi; 4 nígbà tí mo bá ń sọ̀rọ̀ tí mo sì ń wàásù, kì í ṣe àwọn ọ̀rọ̀ kàbìtì-kàbìtì tí àwọn ọlọ́gbọ́n ń lò ni mò ń sọ, àmọ́ ọ̀rọ̀ mi ń fi agbára ẹ̀mí mímọ́ hàn,+ 5 kí ẹ má bàa gbé ìgbàgbọ́ yín ka ọgbọ́n èèyàn, bí kò ṣe agbára Ọlọ́run.
6 Ní báyìí, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n láàárín àwọn tó dàgbà nípa tẹ̀mí,+ àmọ́ kì í ṣe ọgbọ́n ètò àwọn nǹkan yìí* tàbí ti àwọn alákòóso ètò àwọn nǹkan yìí, àwọn tó máa di asán.+ 7 Àmọ́ à ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n Ọlọ́run nínú àṣírí mímọ́,+ tó jẹ́ ọgbọ́n tí a fi pa mọ́, èyí tí Ọlọ́run ti yàn ṣáájú àwọn ètò àwọn nǹkan fún ògo wa. 8 Kò sí ìkankan nínú àwọn alákòóso ètò àwọn nǹkan yìí* tó mọ ọgbọ́n yìí,+ torí ká ní wọ́n mọ̀ ọ́n ni, wọn ì bá má pa Olúwa ológo.* 9 Àmọ́, bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Ojú kò tíì rí, etí kò sì tíì gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn èèyàn kò tíì ro àwọn ohun tí Ọlọ́run ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”+ 10 Nítorí àwa ni Ọlọ́run ti ṣí wọn payá fún+ nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀,+ nítorí ẹ̀mí ń wá inú ohun gbogbo, títí kan àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.+
11 Nítorí ta ló lè mọ ohun tí ẹnì kan ń rò àfi* onítọ̀hún? Bẹ́ẹ̀ náà ni kò sí ẹni tó mọ àwọn nǹkan ti Ọlọ́run, àfi ẹ̀mí Ọlọ́run. 12 Ní báyìí, kì í ṣe ẹ̀mí ayé ni àwa gbà, bí kò ṣe ẹ̀mí tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+ kí a lè mọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fi ṣe wá lóore. 13 Àwọn nǹkan yìí ni àwa náà ń sọ, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi kọ́ni nípa ọgbọ́n èèyàn,+ bí kò ṣe pẹ̀lú àwọn tí a fi kọ́ni nípasẹ̀ ẹ̀mí,+ bí a ṣe ń fi àwọn ọ̀rọ̀ tẹ̀mí ṣàlàyé àwọn nǹkan tẹ̀mí.*
14 Ẹni ti ara kì í tẹ́wọ́ gba* àwọn nǹkan ti ẹ̀mí Ọlọ́run, torí wọ́n jẹ́ nǹkan òmùgọ̀ lójú rẹ̀; kò sì lè mọ̀ wọ́n, nítorí ẹ̀mí la fi ń wádìí wọn. 15 Àmọ́ ẹni tẹ̀mí máa ń wádìí ohun gbogbo,+ ṣùgbọ́n èèyàn èyíkéyìí kì í wádìí òun fúnra rẹ̀. 16 Nítorí “ta ló ti wá mọ èrò inú Jèhófà,* kí ó lè kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́?”+ Àmọ́ àwa ní èrò inú Kristi.+